-
“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!Ilé Ìṣọ́—2015 | July 15
-
-
14, 15. Ìkójọpọ̀ wo ló máa wáyé lẹ́yìn tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run? Kí ni ìkójọpọ̀ náà?
14 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run? Ohun kan náà ni Mátíù àti Máàkù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Wọ́n ní: “[Ọmọ ènìyàn] yóò sì rán àwọn áńgẹ́lì jáde, yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun ilẹ̀ ayé títí dé ìkángun ọ̀run.” (Máàkù 13:27; Mát. 24:31) Ìkójọpọ̀ wo ni Jésù ń sọ níbí? Kì í ṣe ìgbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ẹni àmì òróró jọ ló ń sọ, kì í sì í ṣe ìgbà tá a fi èdìdì ìkẹyìn di àwọn ẹni àmì òróró yòókù. (Mát. 13:37, 38) Kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀ ni èdìdì yẹn á ti wáyé. (Ìṣí. 7:1-4) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń sọ nípa àkókò tí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa gba èrè wọn ní ọ̀run. (1 Tẹs. 4:15-17; Ìṣí. 14:1) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì máa wáyé lẹ́yìn tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ìsík. 38:11) Lẹ́yìn náà ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí máa ṣẹ. Ó sọ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo yóò máa tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.”—Mát. 13:43.b
15 Ṣé ohun tí èyí wá túmọ̀ sí ni pé a máa “gba” àwọn ẹni àmì òróró “lọ” sí ọ̀run? Bí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò yìí ṣe yé ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sí nìyẹn. Wọ́n gbà pé a máa gba àwọn Kristẹni lọ sọ́run nínú ẹran ara. Àti pé lẹ́yìn náà, wọ́n á fi ojúyòójú rí Jésù nígbà ìpadàbọ̀ rẹ̀ láti wá máa ṣàkóso ayé. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé “àmì Ọmọ ènìyàn” máa fara hàn ní ọ̀run, Jésù yóò sì máa bọ̀ “lórí àwọsánmà ọ̀run.” (Mát. 24:30) Ohun tí gbólóhùn méjèèjì yìí túmọ̀ sí ni pé a kò ní lè fi ojúyòójú rí Jésù. Ní àfikún sí ìyẹn, “ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run.” Torí náà, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ “yí” àwọn tá a máa mú lọ sọ́run “padà, ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn.”c (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:50-53.) Àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù ni a óò sì kó jọpọ̀ lójú ẹsẹ̀.
-
-
“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!Ilé Ìṣọ́—2015 | July 15
-
-
c Àwọn ẹni àmì òróró tó wà láàyè kò ní gbé ara ìyára wọn lọ sí ọ̀run. (1 Kọ́r. 15:48, 49) Ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run palẹ̀ ara wọn mọ́ ní ọ̀nà kan náà tó gbà palẹ̀ òkú Jésù mọ́.
-