Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JULY 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | KÓLÓSÈ 1-4
“Ẹ Bọ́ Ìwà Àtijọ́ Sílẹ̀, Kí Ẹ sì Fi Ìwà Tuntun Wọ Ara Yín Láṣọ”
Ẹ̀mí Ọlọ́run Ni Kó O Gbà, Má Ṣe Gba Ẹ̀mí Ayé
12 Irú ẹ̀mí wo ló ń darí ọ̀nà tí mo gbà ń hùwà? (Ka Kólósè 3:8-10, 13.) Ńṣe ni ẹ̀mí ayé máa ń gbé iṣẹ́ ti ara lárugẹ. (Gál. 5:19-21) Torí náà, ẹ̀mí tó ń darí wa kì í tètè fara hàn nígbà tí àwọn nǹkan bá ń lọ déédéé, àmọ́ ó dìgbà tí nǹkan ò bá lọ bó ṣe yẹ, irú bíi kí arákùnrin tàbí arábìnrin kan má kà wá sí, kó mú wa bínú tàbí kó tiẹ̀ ṣẹ̀ wá pàápàá. Ní àfikún sí ìyẹn, irú ẹ̀mí tó ń darí wa lè fara hàn nínú ọ̀nà tí à ń gbà bá àwọn alábàágbé wa lò. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu ká ṣe àyẹ̀wò ara wa. Bi ara rẹ pé, ‘Ní oṣù mẹ́fà sẹ́yìn, ǹjẹ́ mo ti túbọ̀ fìwà jọ Kristi àbí mo ti jó àjórẹ̀yìn tí mo sì ń sọ̀rọ̀ tí kò bójú mu tàbí hu àwọn ìwà kan tí kò dára?’
13 Ẹ̀mí Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀,” ká sì fi “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ ara wa láṣọ. Ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn ká sì jẹ́ onínúure. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ la ṣẹ ara wa, ó máa rọrùn fún wa láti dárí ji ara wa fàlàlà. Bá a bá rí ẹnì kan tó ṣe ohun tá a kà sí èyí tí kò tọ́, a kò ní gbà kí ìyẹn yọrí sí “ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú.” Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa sapá láti fi “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” hàn.—Éfé. 4:31, 32.
Ǹjẹ́ Ẹ Ti Para Dà?
18 Tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ká yí pa dà, ohun tá a máa ṣe kọjá ká kàn máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń ka Bíbélì látìgbàdégbà, débi pé wọ́n ti wá dojúlùmọ̀ àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀. Bóyá o ti bá irú àwọn bẹ́ẹ̀ pàdé lóde ẹ̀rí. Àwọn kan tiẹ̀ wà tó lè sọ ohun tí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sọ lórí. Àmọ́, kò fi bẹ́ẹ̀ hàn nínú bí wọ́n ṣe ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan pé wọ́n tiẹ̀ mọ Bíbélì rárá. Kí ló fà á? Ohun kan ni pé kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó lè mú kẹ́nì kan yí pa dà, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà wọ òun lọ́kàn ṣinṣin. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà nínú Bíbélì. Ó bọ́gbọ́n mú ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo gbà pé ohun tí mò ń kà yìí kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀kọ́ ìsìn kan? Ṣé mo gbà pé òtítọ́ lohun tí mò ń kà yìí? Ṣé bí mo ṣe máa fi nǹkan tí mò ń kọ́ sílò ní ìgbésí ayé mi ló máa ń jẹ mí lógún ni àbí bí mo ṣe máa fi kọ́ àwọn ẹlòmíì ló máa ń gbà mí lọ́kàn? Ṣé ó máa ń ṣe mí bíi pé Jèhófà gan-an ló ń bá mi sọ̀rọ̀?’ Tá a bá ń ronú tá a sì ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìbéèrè yìí, á mú kó túbọ̀ máa wù wá láti sún mọ́ Jèhófà. Àá sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tá a bá wá nírú ìfẹ́ àtọkànwá bẹ́ẹ̀ fún Jèhófà, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ.—Òwe 4:23; Lúùkù 6:45.
19 Bá a ṣe ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà, ṣe ló máa mú ká túbọ̀ tẹra mọ́ ohun kan tó ṣeé ṣe ká ti ṣe tẹ́lẹ̀ déwọ̀n àyè kan. Ìyẹn ni pé, ó ṣeé ṣe ká ti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé: ‘Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀.’ (Kól. 3:9, 10) Ohun kan dájú, bá a ṣe túbọ̀ ń lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó sì ń ní ipa rere lórí ìgbésí ayé wa, bẹ́ẹ̀ ni a ṣe túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú. Àá tipa bẹ́ẹ̀ gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tó máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ètekéte Sátánì.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 169 ¶3-5
Ìjọba Ọlọ́run
“Ìjọba Ọmọ Ìfẹ́ Rẹ̀.” Ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn tí Jésù pa dà sí ọ̀run, ìyẹn lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jésù tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, wọ́n rí àrídájú pé a ti “gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.” (Iṣe 1:8, 9; 2:1-4, 29-33) Ìgbà yẹn ni “májẹ̀mú tuntun” bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí wọn, wọ́n sì para pọ̀ di “orílẹ̀-èdè mímọ́” tuntun, tá a tún ń pè ní Ísírẹ́lì tẹ̀mí.—Heb 12:22-24; 1Pe 2:9, 10; Ga 6:16.
Kristi ti wà ní ọwọ́ ọ̀tún Bàbá rẹ̀ báyìí, òun sì ni Orí ìjọ yìí. (Ef 5:23; Heb 1:3; Flp 2:9-11) Ìwé Mímọ́ fi hàn pé bẹ̀rẹ̀ láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, a gbé ìjọba tẹ̀mí kan kalẹ̀ tó ń darí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. Ní ọ̀rúndún kìíní, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Kólósè, ó sọ níbẹ̀ pé Jésù Kristi ti ní ìjọba kan, ó ní: “[Ọlọ́run] gbà wá lọ́wọ́ àṣẹ òkùnkùn, ó sì mú wa lọ sínú ìjọba Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.”—Kol 1:13; fi wé Iṣe 17:6, 7.
Bẹ̀rẹ̀ láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni ìjọba yìí ti ń ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ìyẹn àwọn Kristẹni tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ti yàn láti di ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. (Jo 3:3, 5, 6) Nígbà tí àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn yìí bá gba èrè wọn ní ọ̀run, wọn ò ní sí lábẹ́ ìjọba Kristi lórí ilẹ̀ ayé mọ́, ṣe ni wọ́n máa di ọba pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run.—Ifi 5:9, 10.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Gálátíà, Éfésù, Fílípì àti Kólósè
2:8—Kí ni “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé” tí Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa wọn? Àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé ni àwọn nǹkan tó wà nínú ayé Sátánì, ìyẹn àwọn nǹkan táwọn èèyàn kà sí pàtàkì, tàbí àwọn ìlànà tó ń darí àwọn èèyàn nínú ayé tó sí ń tì wọ́n ṣe àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe. (1 Jòh. 2:16) Lára àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìmọ̀ ọgbọ́n orí, ìfẹ́ ọrọ̀, àti gbogbo ìsìn èké ayé yìí.
Bíbélì Kíkà
JULY 8-14
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 TẸSALÓNÍKÀ 1-5
“Ẹ Máa Fún Ara Yín Níṣìírí, Kí Ẹ sì Máa Gbé Ara Yín Ró”
“Ní Ẹ̀mí Ìkanisí Fún Àwọn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Láàárín Yín”
12 ‘Ṣíṣe àbójútó’ ìjọ kò mọ sórí kéèyàn máa kọ́ni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù lo gbólóhùn kan náà nínú 1 Tímótì 3:4, ó sọ pé alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ “ọkùnrin kan tí ń ṣe àbójútó agbo ilé tirẹ̀ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, tí ó ní àwọn ọmọ tí wọ́n ní ìtẹríba pẹ̀lú gbogbo ìwà àgbà.” Bó ṣe lo gbólóhùn náà “tí ń ṣe àbójútó” níbí jẹ́ ká rí i pé ìtumọ̀ rẹ̀ kò mọ sórí kíkọ́ àwọn ọmọ, àmọ́ ó tún kan mímú ipò iwájú nínú ìdílé àti mímú kí ‘àwọn ọmọ wà ní ìtẹríba.’ Ojúṣe àwọn alàgbà ni pé kí wọ́n máa mú ipò iwájú nínú ìjọ kí wọ́n sì máa ran àwọn ará lọ́wọ́ láti wà ní ìtẹríba fún Jèhófà.—1 Tím. 3:5.
“Ẹ Ní Ẹ̀mí Ìkanisí Fún Àwọn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Láàárín Yín”
19 Kí lo máa ṣe tó o bá rí ẹ̀bùn tí ẹnì kan dìídì fi ránṣẹ́ sí ẹ gbà? Ṣé wàá fi hàn pé o mọrírì ẹ̀bùn náà nípa lílò ó? Jèhófà tipasẹ̀ Jésù Kristi fún ẹ ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.” Ọ̀nà kan tó o lè gbà fi ìmoore hàn fún àwọn ẹ̀bùn yìí ni pé kó o máa tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí àsọyé tí wọ́n bá ń sọ kó o sì tún máa fi àwọn ohun tí wọ́n sọ sílò. O tún lè fi ìmọrírì rẹ hàn nípa lílóhùn sí àwọn ìpàdé, kó o máa ṣe àlàyé tó nítumọ̀. Máa kọ́wọ́ ti iṣẹ́ táwọn alàgbà ń múpò iwájú nínú rẹ̀, irú bí iṣẹ́ ìwàásù. Bó o bá ti jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn tí alàgbà kan fún ẹ, o ò ṣe sọ fún un? Yàtọ̀ síyẹn, o ò ṣe máa fi ìmọrírì hàn fún àwọn tó wà nínú ìdílé àwọn alàgbà? Ẹ má ṣe gbàgbé pé kí alàgbà kan tó lè ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ, ìdílé rẹ̀ ti ní láti fi àkókò tó yẹ kí wọ́n fi wà pẹ̀lú rẹ̀ du ara wọn.
“Kí A Nífẹ̀ẹ́ . . . ní Ìṣe àti Òtítọ́”
13 Ẹ máa ṣèrànwọ́ fáwọn aláìlera nípa tẹ̀mí. Bíbélì rọ̀ wá pé “ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.” Ọwọ́ tá a bá fi mú ìmọ̀ràn yìí ló máa sọ bóyá a nífẹ̀ẹ́ àbí a ò nífẹ̀ẹ́. (1 Tẹs. 5:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ tí ìgbàgbọ́ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára tẹ́lẹ̀ ti wá di alágbára nípa tẹ̀mí, síbẹ̀, àwọn ará wa kan wà tó gba pé ká máa ṣe sùúrù fún wọn, ká sì máa tì wọ́n lẹ́yìn láìdáwọ́ dúró. A lè ràn wọ́n lọ́wọ́ tá a bá ń fi Bíbélì gbà wọ́n níyànjú, tá a bá jọ lọ sóde ẹ̀rí tàbí tá à ń wáyè tẹ́tí sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, dípò tá a fi máa ka àwọn ará kan sí aláìlera, tá a sì máa ka àwọn míì sí alágbára nípa tẹ̀mí, ó yẹ ká mọ̀ pé gbogbo wa la níbi tá a dáa sí àti ibi tá a kù sí. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà gbà pé òun láwọn àìlera tòun tàbí àwọn ibi tóun kù sí. (2 Kọ́r. 12:9, 10) Torí náà, gbogbo wa pátá la lè ran ara wa lọ́wọ́ lẹ́nì kìíní kejì.
Ẹ Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ àti Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ Bíi Ti Jésù
16 Ọ̀rọ̀ wa. Tá a bá ń fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn èèyàn á mú ká máa “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹs. 5:14) Ọ̀rọ̀ wo la lè sọ tó máa fún irú àwọn ẹni yìí níṣìírí? A lè fún wọn níṣìírí tá a bá ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún àti pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tọkàntọkàn. A lè yìn wọ́n látọkàn wá kí wọ́n lè rí àwọn ìwà tó dáa tí wọ́n ní àti pé àwọn nǹkan kan wà tí wọ́n lè ṣe dáadáa. A lè rán wọn létí pé Jèhófà fà wọ́n sún mọ́ Ọmọ rẹ̀, ìyẹn sì fi hàn pé wọ́n ṣeyebíye lójú rẹ̀. (Jòh. 6:44) A lè mú un dá wọn lójú pé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ ‘oníròbìnújẹ́ ní ọkàn’ àtàwọn “tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀” jẹ Jèhófà lógún gan-an ni. (Sm. 34:18) Ọ̀rọ̀ tá a sọ fún wọn tìfẹ́tìfẹ́ lè jẹ́ ìtura fáwọn tó nílò ìtùnú.—Òwe 16:24.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 863-864
Àgbèrè
Àgbèrè burú débi pé, a lè yọ ẹni tó bá ṣe é lẹ́gbẹ́. (1Kọ 5:9-13; Heb 12:15, 16) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Kristẹni tó bá ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara rẹ̀, ṣe ló ń lo ẹ̀yà ara ìbímọ rẹ̀ lọ́nà tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu. Ẹni náà ti di aláìsàn nípa tẹ̀mí, ó ti sọ ìjọ Ọlọ́run di ẹlẹ́gbin, ó sì lè kó àwọn àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí táwọn èèyàn máa ń kó nídìí ìṣekúṣe. (1Kọ 6:18, 19) Ẹni tó bá ṣe ìṣekúṣe ti yan àwọn arákùnrin rẹ̀ jẹ (1Tẹ 4:3-7) ní ti pé (1) ó ti mú àìmọ́, ìtìjú àti ẹ̀gàn wá fún ìjọ (Heb 12:15, 16), (2) ẹ́ni tó ṣe ìṣekúṣe ti sọ ẹni tó bá ṣe ìṣekúṣe di aláìmọ́, tó bá jẹ́ pé ẹni náà ò tíì ṣègbéyàwó, ó ti di aláìmọ́ nìyẹn fún ẹni tó máa fẹ́, (3) ẹni tó ṣe ṣèṣekúṣe náà ti ba orúkọ rere ìdílé rẹ̀ jẹ́, ó tún ti (4) ṣe ohun tí kò dáa sí ìdílé, ọkọ tàbí àfẹ́sọ́nà ẹni tó bá ṣe ìṣekúṣe. Ó ti ṣẹ̀ sí òfin, kì í ṣe òfin èèyàn tó lè gba ìṣekúṣe láyè nígbà míì, àmọ́ òfin Ọlọ́run ló ṣẹ̀ sí, Ọlọ́run ló sì máa fìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́.—1Tẹ 4:8.
“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!
14 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run? Ohun kan náà ni Mátíù àti Máàkù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Wọ́n ní: “[Ọmọ ènìyàn] yóò sì rán àwọn áńgẹ́lì jáde, yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun ilẹ̀ ayé títí dé ìkángun ọ̀run.” (Máàkù 13:27; Mát. 24:31) Ìkójọpọ̀ wo ni Jésù ń sọ níbí? Kì í ṣe ìgbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ẹni àmì òróró jọ ló ń sọ, kì í sì í ṣe ìgbà tá a fi èdìdì ìkẹyìn di àwọn ẹni àmì òróró yòókù. (Mát. 13:37, 38) Kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀ ni èdìdì yẹn á ti wáyé. (Ìṣí. 7:1-4) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń sọ nípa àkókò tí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa gba èrè wọn ní ọ̀run. (1 Tẹs. 4:15-17; Ìṣí. 14:1) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì máa wáyé lẹ́yìn tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ìsík. 38:11) Lẹ́yìn náà ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí máa ṣẹ. Ó sọ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo yóò máa tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.”—Mát. 13:43.
15 Ṣé ohun tí èyí wá túmọ̀ sí ni pé a máa “gba” àwọn ẹni àmì òróró “lọ” sí ọ̀run? Bí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò yìí ṣe yé ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sí nìyẹn. Wọ́n gbà pé a máa gba àwọn Kristẹni lọ sọ́run nínú ẹran ara. Àti pé lẹ́yìn náà, wọ́n á fi ojúyòójú rí Jésù nígbà ìpadàbọ̀ rẹ̀ láti wá máa ṣàkóso ayé. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé “àmì Ọmọ ènìyàn” máa fara hàn ní ọ̀run, Jésù yóò sì máa bọ̀ “lórí àwọsánmà ọ̀run.” (Mát. 24:30) Ohun tí gbólóhùn méjèèjì yìí túmọ̀ sí ni pé a kò ní lè fi ojúyòójú rí Jésù. Ní àfikún sí ìyẹn, “ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run.” Torí náà, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ “yí” àwọn tá a máa mú lọ sọ́run “padà, ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:50-53.) Àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù ni a óò sì kó jọpọ̀ lójú ẹsẹ̀.
Bíbélì Kíkà
JULY 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 TẸSALÓNÍKÀ 1-3
“A Ó Fi Arúfin Náà Hàn”
it-1 972-973
Ìfọkànsin Ọlọ́run
Àṣírí kan tún lèyí, èyí tó ta ko “àṣírí mímọ́” Jèhófà pátápátá. Àṣírí náà ni “àṣírí ìwà ìkà yìí.” Àṣírí lọ̀rọ̀ yìí jẹ́ sí àwọn Kristẹni tòótọ́ torí pé nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ẹni tí “ọkùnrin arúfin” náà jẹ́ kò tíì ṣe kedere sáwọn èèyàn nígbà yẹn lọ́hùn ún. Kódà lẹ́yìn tí ẹni tí “ọkùnrin” yẹn jẹ́ bá ṣe kedere, ó ṣì máa jẹ́ àṣírí fún ọ̀pọ̀ èèyàn torí pé á máa ṣe bíi pé òun ń fọkàn sin Ọlọ́run, àmọ́ lábẹ́lẹ̀, á máa hùwà burúkú. Àmọ́ ká sòótọ́, òdìkejì ìfọkànsin Ọlọ́run ló ń ṣe. Pọ́ọ̀lù sọ pé “àṣírí ìwà ìkà yìí” ti wà látìgbà yẹn lọ́hùn ún, torí pé àwọn kan ti ń kó ìwà àìlófin wọn ran àwọn míì nínú ìjọ, àwọn ló sì máa di apẹ̀yìndà lẹ́yìn-ò-rẹyìn. Ṣùgbọ́n Jésù Kristi máa pa àwọn yìí run nígbà tó bá ṣe kedere pé ó ti wà níhìn-ín. Apẹ̀yìndà yìí, “ọkùnrin” tí Sátánì ń darí yìí máa gbé ara rẹ̀ “lékè gbogbo àwọn tí wọ́n ń pè ní ọlọ́run tàbí ohun ìjọsìn” (ní Gíríìkì., seʹba·sma). Torí náà, ẹni yìí tí Sátánì ń lò láti ta ko Ọlọ́run á máa tanni jẹ gan-an, ó sì máa mú ìparun wá fún gbogbo àwọn tó bá ń tẹ̀ lẹ́ àpẹẹrẹ rẹ̀. Ohun tó máa mú kí “ọkùnrin arúfin” yìí rọ́wọ́ mú gan-an ni pé, ṣe ló ń díbọ́n bíi pé òun ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn.—2Tẹ 2:3-12; fi wé Mt 7:15, 21-23.
it-2 245 ¶7
Irọ́
Jèhófà Ọlọ́run máa ń “jẹ́ kí ohun tó ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn” lọ sínú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ irọ́ “kí wọ́n lè gba irọ́ gbọ́” dípò ìhìn rere nípa Jésù Kristi. (2Tẹ 2:9-12) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọba Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Áhábù jẹ́ ká lóye ìlànà yìí. Àwọn wòlíì onírọ́ kan fi dá Áhábù lójú pé ó máa borí nínú ogun tó fẹ́ lọ jà pẹ̀lú Ramoti-gílíádì, ṣùgbọ́n òdìkejì ohun táwọn wòlíì yìí sọ ni Mikáyà tó jẹ́ wòlíì Jèhófà sọ fún ọba náà. Nínú ìran tí Jèhófà fi han Mikáyà, Jèhófà mú kí ẹ̀dá ẹ̀mí kan di “ẹ̀mí tó ń tanni jẹ”, ó sì gbẹnu àwọn wòlíì èké yẹn sọ̀rọ̀. Ìyẹn ni pé ẹ̀mí yẹn mú kí wọ́n sọ ohun tó jẹ́ èké, tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ náà, ohun tí wọ́n máa sọ nìyẹn torí pé ohun tí Áhábù fẹ́ gbọ́ lẹ́nu wọn náà nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kìlọ̀ fún Áhábù, ó wù ú láti gbọ́ irọ́ tí wọ́n ń pa, ẹ̀mí rẹ̀ sì lọ sí i.—1Ọb 22:1-38; 2Kr 18.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 834 ¶5
Iná
Pétérù kọ̀wé pé a “tọ́jú àwọn ọ̀run àti ayé tó wà báyìí pa mọ́ de iná.” Àyíká ọ̀rọ̀ yìí, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe iná gidi ni Pétérù ń sọ níbí, bí kò ṣe ìparun ayérayé. Bí Ìkún-omi ọjọ́ Nóà ṣe pa àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa rí nígbà tí Jésù bá dé pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tó ń jó lala, kì í ṣe ọ̀run àti ayé yìí ni wọ́n fẹ́ pa run, àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n máa pa run yán-án-yán, pa pọ̀ pẹ̀lú ètò nǹkan burúkú yìí.—2Pe 3:5-7, 10-13; 2Tẹ 1:6-10; fi wé Ais 66:15, 16, 22, 24.
it-1 1206 ¶4
Ìmísí
“Ọ̀rọ̀ onímìísí”—Òtítọ́ àti Èké. Oríṣiríṣi ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni àwọn àpọ́sítélì gbà lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà pneuʹma (ẹ̀mí) nígbà tí wọ́n ń kọ̀wé. Bí àpẹẹrẹ, nínú 2 Tẹsalóníkà 2:2, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará tó wà nílùú Tẹsalóníkà níyànjú pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun yẹ̀ wọ́n lẹ́sẹ̀ “nítorí ọ̀rọ̀ onímìísí [ní tààràtà, “ẹ̀mí”] tàbí nítorí iṣẹ́ tí a fẹnu jẹ́ tàbí nítorí lẹ́tà kan tó dà bíi pé ó wá látọ̀dọ̀ wa, tó ń sọ pé ọjọ́ Jèhófà ti dé.” Ó ṣe kedere níbí pé Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ náà pneuʹma (ẹ̀mí) gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti báni sọ̀rọ̀, bóyá èyí tí wọ́n “fẹnu” sọ tàbí “lẹ́tà.” Fún ìdí yìí, ìwé Commentary on the Holy Scriptures (ojú ìwé 126) tí Lange kọ, sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ yìí pé: “Ohun tí Àpọ́sítélì yìí ń sọ níbí ni, àbá tẹ́nì kan dá, àsọtẹ́lẹ̀ èké tàbí ọ̀rọ̀ tí wòlíì kan sọ.” (Látọwọ́ P. Schaff, 1976) Ìwé Word Studies in the New Testament tí Vincent ṣe, sọ pé: “Nípase ẹ̀mí. Ọ̀rọ̀ onímìísí táwọn kan nínú ìjọ Kristẹni ń sọ, tí wọ́n sì ń sọ pé Ọlọ́run ló mí sí àwọn.” (1957, Ìdìpọ̀ Kẹrin, ojú ìwé 63) Torí náà, àwọn kan tú ọ̀rọ̀ náà pneuʹma sí “ẹ̀mí,” àwọn míì sì túmọ̀ rẹ̀ sí “ọ̀rọ̀ Ẹ̀mí” (The Bible—An American Translation), “àwítẹ́lẹ̀” (The Jerusalem Bible), “ìmísí” (D’Ostervald; Segond [French]), “ọ̀rọ̀ onímìísí” (NW ).
Bíbélì Kíkà
JULY 22-28
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 TÍMÓTÌ 1-3
“Iṣẹ́ Rere Ni Kó O Máa Lé”
Ǹjẹ́ O Lè Fi Kún Ohun Tó Ò Ń Ṣe Nínú Ìjọsìn Ọlọ́run?
3 Ka 1 Tímótì 3:1. Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tá a tú sí “nàgà fún” túmọ̀ sí kéèyàn nawọ́ kọ́wọ́ rẹ̀ lè tó ohun tó ń fẹ́. Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò yìí jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn gbọ́dọ̀ sapá kọ́wọ́ rẹ̀ tó lè tẹ àwọn ohun tó ń lé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé arákùnrin kan tí kò tíì di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ronú nípa bó ṣe lè fi kún ohun tó ń ṣe nínú ìjọ. Ó mọ̀ pé kóun tó lè kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, òun gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ní láti dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè kó tó lè di alàgbà. Èyí fi hàn pé ó gba ìsapá kéèyàn tó lè tóótun láti ní àfikún iṣẹ́ èyíkéyìí nínú ìjọ.
km 12/79 3 ¶7
Àwọn Tó “Ń Ṣe Orúkọ Rere Fún Ara Wọn”
7 Nígbà náà, ó rọrùn láti lóye ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ nípa irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ wípé wọ́n “ṣe orúkọ rere fún ara wọn.” Èyí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ ọ́, pé ó jẹ́ ìlọsíwájú nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n bójú tó àwọn nǹkan “dáadáa” ni a fún ní ìdánilójú ìbùkún Jèhófà àti ti Jésù, gbogbo ìjọ bọ̀wọ̀ fún wọn, wọ́n sì ń tì wọ́n lẹ́yìn. Wọ́n lè ‘sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.’ Torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́, a mọrírì wọn fún iṣẹ́ ìsìn wọn; wọ́n ní ìgbàgbọ́ tí ó dúró, wọn sì lè kéde ìgbàgbọ́ wọn láìṣe ojo tàbí bẹ̀rù nítorí ìṣáátá.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 914-915
Ìtàn Ìdílé
Kò sí àǹfààní kankan nínú ẹ̀ téèyàn bá ń fi àkókò ṣòfò láti kẹ́kọ̀ọ́ tàbí jíròrò irú ọ̀rọ̀ báyìí, pàápàá jù lọ nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ ọ̀rọ̀ yìí sí Tímótì. Kò di dandan kéèyàn mọ ìlà ìdílé tó ti ṣẹ̀ wá, torí pé ní báyìí lójú Ọlọ́run, kò sí ìyàtọ̀ láàárín àwọn Júù àti Kèfèrí nínú ìjọ Kristẹni. (Ga 3:28) Àkọsílẹ̀ ìtàn ìdílé sì ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìlà Dáfídì ni Kristi ti wá. Yàtọ̀ síyẹn, kò pẹ́ lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àkọsílẹ̀ ìtàn àwọn Júù, Ọlọ́run ò pa àwọn àkọsílẹ̀ yẹn mọ́. Torí náà, Pọ́ọ̀lù ò fẹ́ kí Tímótì àtàwọn ará ìjọ máa fi gbogbo àkókò wọn wá ìsọfúnni, kí wọ́n sì máa bá ara wọn jiyàn lórí ọ̀rọ̀ ìlà ìdílé tí wọ́n ti wá, ìyẹn ò lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára sí i. Ìtàn ìlà ìdílé tí Bíbélì sọ ti tó láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Kristi ni Mèsáyà náà, ìlà ìdílé ẹni tó sì ṣe pàtàkì jù lọ fún àwa Kristẹni nìyẹn. Àwọn ìtàn ìlà ìdílé míì tó wà nínú Bíbélì kàn fi ń hàn wá pé òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ó sì ń jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ gan-an ni àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì.
“Wò Ó! Ọlọ́run Wa Nìyí”
15 Orúkọ oyè mìíràn tó tún wà fún Jèhófà nìkan ṣoṣo ni “Ọba ayérayé.” (1 Tímótì 1:17; Ìṣípayá 15:3) Kí ni èyí túmọ̀ sí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára òye wa kò lè gbé e láti mọ ohun tó túmọ̀ sí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, síbẹ̀ òtítọ́ pọ́ńbélé ni pé Jèhófà jẹ́ ẹni ayérayé, láìní ìbẹ̀rẹ̀ láìlópin. Sáàmù 90:2 sọ pé: “Àní láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ ni Ọlọ́run.” Nípa báyìí, Jèhófà kò ní ìbẹ̀rẹ̀ rárá; kò sígbà kankan rí tí kò wà. Ìyẹn ló ṣe tọ́ bí a ṣe pè é ní “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” torí pé ó ti ń bẹ láti ayérayé wá ṣáájú ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tó wà láyé àtọ̀run! (Dáníẹ́lì 7:9, 13, 22) Nítorí náà, ta ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa béèrè nípa ẹ̀tọ́ tó ní láti jẹ́ Olúwa Ọba Aláṣẹ?
Bíbélì Kíkà
JULY 29–AUGUST 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 TÍMÓTÌ 4-6
“Ìfọkànsin Ọlọ́run Tàbí Ọrọ̀”
Kíkọ́ Béèyàn Ṣe Ń Lẹ́mìí Ohun-Moní-Tómi
Olórí ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn ni ẹ̀mí ohun-moní-tómi tó ní. Kí wá ni níní ẹ̀mí ohun-moni-tómi túmọ̀ sí? Láìfọ̀rọ̀gùn, ó tùmọ́ sí níní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémáàní. Tìtorí èyí ni Pọ́ọ̀lù ṣe sọ fún Tímótì tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pé: “Láìsí àní-àní, ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi. Nítorí a kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tímótì 6:6-8.
Ṣàkíyèsí pé Pọ́ọ̀lù so ẹ̀mí ohun-moní-tómi pọ̀ mọ́ ìfọkànsin Ọlọ́run. Ó rí i pé ayọ̀ tòótọ́ máa ń wá látinú ìfọkànsin Ọlọ́run, ìyẹn ni látinú fífi iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run sí ipò kìíní kì í ṣe látinú àwọn ohun ìní ti ara tàbí ọrọ̀. “Ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ” wulẹ̀ jẹ́ ohun tí yóò jẹ́ kí o máa bá a lọ ní lílépa ìfọkànsin Ọlọ́run ni. Nítorí náà, àṣírí ẹ̀mi ohun-moní-tómi tí Pọ́ọ̀lù ní ni pé kéèyàn gbára lé Jèhófà, láìka ipòkípò tó bá wà sí.
Ṣó O Ti Pinnu Láti Di Ọlọ́rọ̀? Kí Ló Lè Yọrí sí fún Ẹ?
Lóòótọ́ o, ọ̀pọ̀ èèyàn wà tó jẹ́ pé kì í ṣe ìlépa ọrọ̀ ló ń ṣekú pa wọ́n. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé ńṣe nirú wọn wulẹ̀ wà láyé bí aláìsí láyé níbi tí wọ́n ti ń lépa ọrọ̀. Wọ́n sì tún lè máà rójú ráyè bó bá di pé wàhálà iṣẹ́ tàbí àìríná àìrílò ti mú kí àwọn àìlera tó lè pani láìtọ́jọ́ máa ṣe wọ́n, ìyẹn àwọn bí àìróorunsùn tó, kí orí máa fọ́ni lákọlákọ tàbí ọgbẹ́ inú. Bá a bá sì wá rẹ́ni tó pe orí ara ẹ̀ wálé tó sì fẹ́ yí ohun tó fi sípò àkọ́kọ́ padà, ó lè ti pẹ́ jù fún un. Ọkọ tàbí aya ẹ̀ lè má gbà á gbọ́ mọ́, ìdààmú ọkàn lè ti sọ àwọn ọmọ ẹ̀ dìdàkudà, kí ròkè rodò sì ti sọ òun náà di aláìlera. Bóyá ó ṣeé ṣe kéèyàn rí nǹkan ṣe sí díẹ̀ lára irú àwọn ìṣòro yìí, àmọ́ ó máa gba ìsapá ńláǹlà. Ìdí sì ni pé irú àwọn bẹ́ẹ̀ ti “fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:10.
Ohun Mẹ́fà Tó Lè Mú Káyé Yẹni
Gẹ́gẹ́ báa ṣe rí i nínú èyí àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, gbogbo àwọn tó bá rò pé lílépa ọrọ̀ ló lè mú káyé yẹ àwọn wulẹ̀ ń sáré lé ẹ̀fúùfù lásán ni. Yàtọ̀ sí pé wọ́n á rí ìjákulẹ̀, wọ́n á tún fa ọ̀pọ̀ ìrora sórí ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn èèyàn bá ń fi gbogbo ara lépa ọrọ̀, wọ́n sábà máa ń fi àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn dí i. Àwọn míì kì í sùn nítorí iṣẹ́ tàbí nítorí àníyàn àti ìdààmú ọkàn. Oníwàásù 5:12 sọ pé: ‘Dídùn ni oorun oníṣẹ́, ì báà jẹ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀: ṣùgbọ́n ìtẹ́lọ́rùn ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.’—Bibeli Mimọ.
Kì í wulẹ̀ ṣe pé owó jẹ́ òǹrorò ọ̀gá nìkan ni, àmọ́ ó tún kún fún ẹ̀tàn. Jésù Kristi sọ̀rọ̀ nípa “agbára ìtannijẹ ọrọ̀.” (Máàkù 4:19) Èyí tó túmọ̀ sí pé ó lè dà bíi pé owó máa ń fúnni láyọ̀, àmọ́ kì í fúnni láyọ̀ tòótọ́. Èèyàn á wulẹ̀ máa fẹ́ láti lówó púpọ̀ sí i ni. Bíbélì The New English Bible sọ pé: “Ẹni tó bá fẹ́ owó, owó kì yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn.”—Oníwàásù 5:10.
Ní kúkúrú, ẹní bá nífẹ̀ẹ́ owó máa para ẹ̀ láyò gbẹ̀yìn ni, ọwọ́ ẹ̀ lè má tẹ owó tó ń wá, owó tó rí lè máà tó o, tàbí kó tiẹ̀ fipá wá a. (Òwe 28:20) Àwọn nǹkan tó máa ń mú káyé yẹni ní tòótọ́ ni ìwà ọ̀làwọ́, ẹ̀mí ìdáríjì, ìwà mímọ́, ìfẹ́ àti àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Bó O Ṣe Lè Ní Ẹ̀rí Ọkàn Rere
17 Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ di ẹ̀rí-ọkàn rere mú.” (1 Pétérù 3:16) Ẹ̀bùn tí ò láfiwé ni ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. Ó yàtọ̀ sí ẹ̀rí ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí. Pọ́ọ̀lù firú ẹ̀rí ọkàn bẹ́ẹ̀ wé èyí “tí [wọ́n] ti sàmì sí . . . gẹ́gẹ́ bí pé pẹ̀lú irin ìsàmì.” (1 Tímótì 4:2) Irin ìsàmì dà bí irin gbígbóná táwọn alágbẹ̀dẹ fi ń ṣiṣẹ́, téèyàn bá sì gbé e lé ara ńṣe lara ọ̀hún máa bó yànmàkàn, tá á dégbò, tó bá sì yá ńṣe ló máa gíràn-án. Ẹ̀rí ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn ti kú, ìyẹn ni pé ó ti gíràn-án débi pé kò kì wọ́n nílọ̀ mọ́, kì í dá wọn lẹ́bi tí wọ́n bá hùwà tí kò tọ́, gbogbo nǹkan ló sì máa ń gbà láìjanpata. Àwọn kan tiẹ̀ wà tí wọn ò fẹ́ mọ ẹ̀bi wọn lẹ́bi mọ́.
it-2 714 ¶1-2
Kíkàwé Ní Gbangba
Nínú Ìjọ Kristẹni. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìwọ̀nba àwọn díẹ̀ ló ní àwọn àkájọ ìwé Bíbélì lọ́wọ́, ìdí nìyí tó fi di dandan kẹ́nì kan kà á sétí àwọn tó kù nínú ìjọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé kí wọ́n máa ka àwọn lẹ́tà òun sétí àwọn ará nínú ìpàdé ìjọ, ó sì tún sọ fún àwọn ará ìjọ pé kí wọ́n gba lẹ́tà tí òun kọ sí ìjọ míì, kí wọ́n kà á, kí àwọn náà sì fún ìjọ míì ní tọwọ́ wọn, kí àwọn náà lè kà á. (Kol 4:16; 1Tẹ 5:27) Pọ́ọ̀lù gba Tímótì tó jẹ́ ọ̀dọ́, tó sì jẹ́ alábòójútó níyànjú láti máa ‘tẹra mọ́ kíkàwé fún ìjọ, kó máa gbani níyànjú, kó sì máa kọ́ni.’—1Ti 4:13.
Ẹni tó ń kàwé ní gbangba gbọ́dọ̀ kà á lọ́nà tó já geere. (Hab 2:2) Ìdí tí wọ́n fi ń kàwé ní gbangba ni pé kí wọ́n lè kọ́ àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́, torí náà, ẹni tó ń kàwé fún àwọn ará gbọ́dọ̀ mọ ohun tó ń kà, kó sì lóye ohun tẹ́ni tó kọ̀wé náà ní lọ́kàn, ó gbọ́dọ̀ rọra kàwé náà kí ohun tó ń kà má lọ ní ìtumọ̀ míì létí àwọn tó ń gbọ́ ọ. Níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Ìfihàn 1:3, àwọn tó ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àtàwọn tó ń gbọ́ ọ, tí wọ́n sì ń pa àwọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́, máa láyọ̀.
Bíbélì Kíkà