-
Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn AgboA Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
-
-
5 Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì àti èyí tó kọ sí Títù, ó sọ àwọn ohun tí ẹni tó fẹ́ di alábòójútó gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n rẹ̀. Ìwé 1 Tímótì 3:1-7 sọ pé: “Tí ọkùnrin kan bá ń sapá láti di alábòójútó, iṣẹ́ rere ló fẹ́ ṣe. Nítorí náà, alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn, tí kò ní ju ìyàwó kan lọ, tí kì í ṣe àṣejù, tó ní àròjinlẹ̀, tó wà létòlétò, tó ń ṣe aájò àlejò, tó kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni, kì í ṣe ọ̀mùtí, kì í ṣe oníwà ipá, àmọ́ kó máa fòye báni lò, kì í ṣe oníjà, kì í ṣe ẹni tó fẹ́ràn owó, kó jẹ́ ọkùnrin tó ń bójú tó ilé rẹ̀ dáadáa, tí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ń tẹrí ba, tí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn (torí tí ọkùnrin kan ò bá mọ bó ṣe máa bójú tó ilé ara rẹ̀, báwo ló ṣe máa bójú tó ìjọ Ọlọ́run?), kì í ṣe ẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn pa dà, torí ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbéraga, kó sì ṣubú sínú ìdájọ́ tí a ṣe fún Èṣù. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí àwọn tó wà níta máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa kó má bàa ṣubú sínú ẹ̀gàn àti pańpẹ́ Èṣù.”
-
-
Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn AgboA Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
-
-
8 Àwọn alábòójútó kì í ṣe ọmọdé tàbí àwọn ọkùnrin tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ti ní ìrírí nípa bó ṣe yẹ kí Kristẹni máa gbé ìgbé ayé rẹ̀, wọ́n ní ìmọ̀ Bíbélì dáadáa, wọ́n ní òye tó jinlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́, wọ́n sì tún ní ìfẹ́ àtọkànwá fún ìjọ. Wọn kì í bẹ̀rù láti bá ẹni tó hùwà àìtọ́ nínú ìjọ sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì tọ́ onítọ̀hún sọ́nà, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bo àwọn ará ìjọ lọ́wọ́ ẹni tó fẹ́ rẹ́ wọn jẹ. (Àìsá. 32:2) Àwọn ará ìjọ gbà pé àwọn alábòójútó jẹ́ ẹni tẹ̀mí, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ agbo Ọlọ́run dénúdénú.
-