ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì?
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 1
    • “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 TÍMÓTÌ 3:16, 17.

      Ọ̀RỌ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa bí Bíbélì ṣe níye lórí tó yìí mà lágbára gan-an o! Ó dájú pé àwọn ìwé Bíbélì tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ̀ nígbà yẹn ló ń sọ, ìyẹn àwọn ìwé táwọn èèyàn sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn kan gbogbo ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] tó wà nínú Bíbélì, títí kan èyí táwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni.

      Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ǹjẹ́ ìwọ náà ń fojú iyebíye wo Bíbélì? Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run mí sí àwọn tó kọ Bíbélì lóòótọ́? Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gbà pé ó rí bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ́ yẹn kò mì fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tó tẹ̀ lé e. Bí àpẹẹrẹ, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ John Wycliffe sọ pé Bíbélì jẹ́ “ìlànà òtítọ́ tí kò láṣìṣe.” Ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ìyẹn The New Bible Dictionary, sọ nípa ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tá a fàyọ níbẹ̀rẹ̀ pé, “ìmísí [Ọlọ́run] ló fìdí gbogbo ohun tí Bíbélì sọ múlẹ̀ pé ó jóòótọ́.”

  • Bíbélì Ní Ìmísí Ọlọ́run Lóòótọ́
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 1
    • KÍ NI àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Bíbélì “ni imísi Ọlọrun”? (2 Tímótì 3:16 Bibeli Mimọ) Ní olówuuru, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò níbí yìí túmọ̀ sí “Ọlọ́run mí èémí sí.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni pé Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì láti kọ ohun tó fẹ́ kí wọ́n kọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́