ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
    • 6 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Títù pé: “Mo fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè, kí o lè ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí kò tọ́, kí o sì lè yan àwọn alàgbà láti ìlú dé ìlú, bí mo ṣe sọ fún ọ pé kí o ṣe: bí ọkùnrin èyíkéyìí bá wà tí kò ní ẹ̀sùn lọ́rùn, tí kò ní ju ìyàwó kan lọ, tí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọn kò sì ní ẹ̀sùn lọ́rùn pé wọ́n jẹ́ oníwà pálapàla tàbí ọlọ̀tẹ̀. Torí pé alábòójútó jẹ́ ìríjú Ọlọ́run, kò gbọ́dọ̀ ní ẹ̀sùn lọ́rùn, kó má ṣe jẹ́ ẹni tó ń ṣe tinú ara rẹ̀, kó má ṣe jẹ́ ẹni tó ń tètè bínú, kó má ṣe jẹ́ ọ̀mùtípara, kó má ṣe jẹ́ oníwà ipá, kó má sì jẹ́ ẹni tó máa ń wá èrè tí kò tọ́, àmọ́ kó jẹ́ ẹni tó ń ṣe aájò àlejò, tó nífẹ̀ẹ́ ohun rere, tó ní àròjinlẹ̀, tó jẹ́ olódodo, olóòótọ́, tó máa ń kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó ń di ọ̀rọ̀ òtítọ́ mú ṣinṣin nínú ọ̀nà tó ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, kó lè fi ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní gbani níyànjú kó sì bá àwọn tó ń ṣàtakò wí.”​—Títù 1:5-9.

  • Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
    • 9 Àwọn tó kúnjú ìwọ̀n láti di alábòójútó ní láti máa gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Tí alábòójútó bá ti ní ìyàwó, ó gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nípa ìgbéyàwó, ìyẹn ni pé kò gbọ́dọ̀ ní ju ìyàwó kan lọ, ó sì gbọ́dọ̀ máa bójú tó ilé rẹ̀ dáadáa. Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá jẹ́ onígbàgbọ́, tí wọ́n ń tẹrí ba, tí wọ́n jẹ́ onígbọràn, tí wọn kò sì ní ẹ̀sùn lọ́rùn pé wọ́n jẹ́ oníwà pálapàla tàbí ọlọ̀tẹ̀, á yá àwọn ará ìjọ lára láti lọ bá alábòójútó náà pé kó fún àwọn nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìdílé àti ìgbésí ayé. Alábòójútó tún ní láti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn, tí kò ní ẹ̀sùn lọ́rùn, tí àwọn tó wà níta pàápàá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa. Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí wọ́n fi ẹ̀sùn tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ kàn pé ó hu ìwàkiwà tó lè kó ẹ̀gàn bá ìjọ. Kò yẹ kó jẹ́ ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fún ní ìbáwí lórí ìwà àìtọ́ tó burú jáì. Àwọn ará ìjọ á fẹ́ láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere rẹ̀, inú wọn á sì dùn pé kó máa tọ́ àwọn sọ́nà nínú ìjọsìn Ọlọ́run.​—1 Kọ́r. 11:1; 16:15, 16.

      10 Irú àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n yìí á lè ṣiṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni bíi ti àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ “ọlọ́gbọ́n àti olóye àti onírìírí.” (Diu. 1:13) Àwọn alàgbà ìjọ Kristẹni kì í ṣe ẹni tí kò lè dẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ará ìjọ àtàwọn ará àdúgbò mọ̀ pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, wọ́n ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n sì ti fi hàn pé ìlànà Ọlọ́run ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé nínú ìgbésí ayé wọn. Torí pé wọ́n jẹ́ aláìlẹ́bi, wọ́n lẹ́nu ọ̀rọ̀ nínú ìjọ.​—Róòmù 3:23.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́