ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Àwọn Ohun Fífani-lọ́kàn-mọ́ra” Ń kún Ilé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́—2000 | January 15
    • 9. Èé ṣe tí Jésù ò fi lè wọ òkè ọ̀run lọ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, báwo la sì ṣe yanjú ìyẹn?

      9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti di Ọmọ Ọlọ́run, tí a fi ẹ̀mí yàn, ọwọ́ rẹ̀ ò tíì lè tẹ ìyè ní òkè ọ̀run. Èé ṣe? Nítorí ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 15:44, 50) Níwọ̀n bí ara ènìyàn tí Jésù ní ti jẹ́ ìdènà fún un, ní rẹ́gí, ó ṣàpẹẹrẹ aṣọ ìkélé táa fi pín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run láyé ìgbàanì. (Hébérù 10:20) Ṣùgbọ́n ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn tí Jésù kú, ẹ̀mí Ọlọ́run jí i dìde. (1 Pétérù 3:18) Ìgbà yìí ló tó lè wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ tó wà nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí—ìyẹn ni ọ̀run gan-an. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí tí Kristi kò wọlé sí ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe [dájúdájú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ló ń tọ́ka sí], tí ó jẹ́ ẹ̀dà ti òtítọ́, bí kò ṣe sí ọ̀run, nísinsìnyí láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún wa.”—Hébérù 9:24.

      10. Kí ni Jésù ṣe nígbà tó padà sí ọ̀run?

      10 Nígbà tí Jésù dé òkè ọ̀run, ó ‘wọ́n ẹ̀jẹ̀’ ìrúbọ rẹ̀ nípa gbígbé ìtóye ẹbọ ìràpadà ti ẹ̀jẹ̀ ìwàláàyè rẹ̀ lọ síwájú Jèhófà. Síbẹ̀, ohun tí Jésù ṣe tún ju ìyẹn lọ. Nígbà tó kù díẹ̀ kí ó kú, ó ti sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nítorí pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.” (Jòhánù 14:2, 3) Nítorí náà, wíwọ̀ tí Jésù wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, tàbí òkè ọ̀run ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn mìíràn. (Hébérù 6:19, 20) Àwọn wọ̀nyí, tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ni yóò jẹ́ àlùfáà ọmọ abẹ́ nínú ìṣètò tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 7:4; 14:1; 20:6) Gan-an gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì ṣe kọ́kọ́ gbé ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ láti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn àlùfáà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìtóye ẹ̀jẹ̀ Jésù táa ta sílẹ̀ ṣe kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ fún ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, àwọn àlùfáà ọmọ abẹ́ wọ̀nyí.b

  • “Àwọn Ohun Fífani-lọ́kàn-mọ́ra” Ń kún Ilé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́—2000 | January 15
    • b Jésù yàtọ̀ sí àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì, ní ti pé kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan tó máa ṣètùtù fún. Àmọ́ ṣá o, ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwọn àlùfáà alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, nítorí pé lára aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ la ti rà wọ́n.—Ìṣípayá 5:9, 10.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́