ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bó O Ṣe Lè Mú Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016 | October
    • 2 Àwọn èèyàn inú ayé náà máa ń fojú sọ́nà fún àwọn nǹkan kan, àmọ́ kò dá wọn lójú pé ọwọ́ wọn á tẹ nǹkan ọ̀hún. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ máa ń retí pé lọ́jọ́ kan, àwọn á jẹ. Àmọ́ wọ́n gbà pé èyí-jẹ èyí-ò-jẹ lọ̀rọ̀ tẹ́tẹ́ títa. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìgbàgbọ́ táwa Kristẹni ní jẹ́ “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú” nípa àwọn ohun tí a ń retí. (Héb. 11:⁠1) Àmọ́, o lè máa ronú pé, báwo ni àwọn ohun tí mò ń retí ṣe lè túbọ̀ dá mi lójú? Tó bá dá mi lójú pé àwọn ohun tí mò ń retí máa dé, àǹfààní wo ni màá rí?

      3. Kí nìdí tó fi dá àwa Kristẹni lójú pé gbogbo ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ?

      3 Wọn ò bí ìgbàgbọ́ mọ́ wa torí pé inú ẹ̀ṣẹ̀ la bí wa sí, bẹ́ẹ̀ sì ni èèyàn kì í jogún rẹ̀. Tá a bá fẹ́ ní ìgbàgbọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí ọkàn wa. (Gál. 5:22) Bíbélì ò sọ pé Jèhófà ní ìgbàgbọ́ tàbí pé ó nílò ìgbàgbọ́. Ìdí ni pé Jèhófà ló lágbára jù lọ láyé àtọ̀run, òun ló sì gbọ́n jù, torí náà kò sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Ó dá Jèhófà lójú pé àwọn ìbùkún tó ṣèlérí máa ṣẹ débi pé lójú rẹ̀, àfi bíi pé wọ́n ti ṣẹ. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Wọ́n ti ṣẹlẹ̀!” (Ka Ìṣípayá 21:​3-6.) Jèhófà jẹ́ ‘Ọlọ́run tó ṣe é gbíyè lé,’ ìdí nìyẹn tó fi dá àwa Kristẹni lójú pé gbogbo ìlérí rẹ̀ máa ṣẹ.​—⁠Diu. 7:⁠9.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN OLÓÒÓTỌ́ TÓ NÍ ÌGBÀGBỌ́ LÁYÉ ÀTIJỌ́

      4. Ìrètí wo làwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin olóòótọ́ nígbà àtijọ́ ní?

      4 Ìwé Hébérù orí 11 mẹ́nu kan àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin olóòótọ́ mẹ́rìndínlógún [16] tó nígbàgbọ́. Orí yìí sọ nípa wọn àtàwọn míì pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. (Héb. 11:39) Gbogbo wọn ló ní “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú,” wọ́n sì ní ìrètí pé Ọlọ́run máa lo “irú-ọmọ” tó ṣèlérí náà láti pa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ run, irú-ọmọ yìí náà ló sì máa mú gbogbo ìlérí Ọlọ́run ṣẹ. (Jẹ́n. 3:15) Jésù Kristi ni “irú-ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí náà, àmọ́ gbogbo àwọn olóòótọ́ yìí ti kú kí Jésù tó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti lọ sọ́run. (Gál. 3:16) Torí pé àwọn ìlérí Ọlọ́run kì í yẹ̀, ó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa jí àwọn olóòótọ́ yìí dìde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì dẹni pípé. A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà o!​—⁠Sm. 37:11; Aísá. 26:19; Hós. 13:⁠14.

  • Bó O Ṣe Lè Mú Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016 | October
    • 7. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà pèsè fún wa kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára, ọwọ́ wo ló sì yẹ ká fi mú wọn?

      7 Kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára, Jèhófà ti fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Tá a bá fẹ́ láyọ̀, tá a sì fẹ́ ṣàṣeyọrí, a gbọ́dọ̀ máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Sm. 1:​1-3; ka Ìṣe 17:11.) Bíi tàwọn olóòótọ́ ìgbàanì, àwa náà gbọ́dọ̀ máa ronú nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run, ká sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún ń tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí fún wa. (Mát. 24:45) Torí náà, tá a bá mọyì ohun tá à ń kọ́ látinú àwọn nǹkan tí Jèhófà ń pèsè yìí, a máa dà bí àwọn olóòótọ́ ìgbàanì tí wọ́n ní ìdánilójú pé Ìjọba táwọn ń retí náà máa dé.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́