ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Nìṣó
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Èrè púpọ̀ wà nínú kéèyàn máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o dá ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ò ń kọ́ dúró. Kí nìdí tó fi yẹ kó o sapá láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó? Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí ẹ̀kọ́ náà ò fi ní sú ẹ?

      1. Àǹfààní wo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ṣe ẹ́?

      “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára.” (Hébérù 4:12) Bíbélì ń ṣeni láǹfààní gan-an torí ó jẹ́ ká mọ èrò Ọlọ́run àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Yàtọ̀ sí pé Bíbélì máa jẹ́ kó o ní ìmọ̀, ó tún máa jẹ́ kó o ní ọgbọ́n tòótọ́ àti ìrètí. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Bíbélì máa jẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa nípa rere lórí ìgbésí ayé rẹ.

      2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká mọ àǹfààní tí ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ṣe wá?

      Àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì dà bí ìṣúra iyebíye. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi rọ̀ wá pé ká ‘ra òtítọ́, ká má sì tà á láé.’ (Òwe 23:23) Tá a bá ń fi sọ́kàn pé ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ṣe wá láǹfààní púpọ̀, àá máa ṣiṣẹ́ kára láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó kódà tí ohunkóhun bá fẹ́ dí wa lọ́wọ́.​—Ka Òwe 2:4, 5.

      3. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó?

      Jèhófà fẹ́ kó o mọ òun torí òun ni Ẹlẹ́dàá rẹ atóbilọ́lá àti Ọ̀rẹ́ rẹ. Ó lè ‘mú kó wù ẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀, kó sì fún ẹ ní agbára láti ṣe é.’ (Ka Fílípì 2:13.) Torí náà, tí ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ò ń kọ́ bá fẹ́ sú ẹ tàbí tí kò rọrùn fún ẹ láti fi àwọn ohun tó ò ń kọ́ sílò, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tí ohunkóhun bá ń dí ẹ lọ́wọ́ tàbí tí àwọn kan ń ta kò ẹ́, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Máa gbàdúrà déédéé sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó.​—1 Tẹsalóníkà 5:17.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Kọ́ bó o ṣe lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ta kò ẹ́ tàbí tó o bá ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣe. Wàá sì tún kọ́ bí Jèhófà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó.

      4. Fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ò ń kọ́

      Nígbà míì ọwọ́ wa máa ń dí gan-an, táá sì máa ṣe wá bíi pé a ò lè ráyè láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́? Ka Fílípì 1:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Lérò tìẹ, kí ni “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” nígbèésí ayé ẹni?

      • Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ò ń kọ́ ṣe pàtàkì sí ẹ?

      A. Àwòrán: Ike tí wọ́n kó òkúta àti iyanrìn sí. 1. Iyanrìn àtàwọn òkúta ńlá. 2. Ike tí iyanrìn fẹ́rẹ̀ẹ́ kún inú rẹ. 3. Ike tí iyanrìn wà nínú rẹ̀ kò lè gba àwọn òkúta ńlá náà tán. B. Àwòrán: 1. Iyanrìn kan náà àtàwọn òkúta ńlá kan náà. 2. Ike kan náà tí òkúta ńlá fẹ́rẹ̀ẹ́ kún inú rẹ̀. 3. Iyanrìn wà nínú ike táwọn òkúta ńlá náà wà, ó sì kún dẹ́nu. Iyanrìn díẹ̀ ṣẹ́ kù sílẹ̀, torí pé kò lè gba inú ike náà tán.
      1. Tó o bá kọ́kọ́ da iyanrìn sínú ike kan kó o tó kó òkúta sínú ẹ̀, àyè ò ní gba àwọn òkúta yẹn

      2. Tó o bá kọ́kọ́ kó òkúta sínú ike náà, wàá rí àyè tó o máa da èyí tó pọ̀ jù nínú iyanrìn náà sí. Bákan náà ló rí tó o bá fi “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ, wàá lè ṣe wọ́n láṣeyọrí, wàá sì tún rí àyè láti ṣe àwọn nǹkan míì

      Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á jẹ́ kó o mọ Ọlọ́run, kó o sún mọ́ ọn, kó o sì máa jọ́sìn rẹ̀. Ka Mátíù 5:3, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Àǹfààní wo ló máa ṣe wá tá a bá fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ Bíbélì?

      5. Máa fara dà á tí wọ́n bá ń ta kò ẹ́

      Ó lè ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan ò ní fẹ́ kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wo àpẹẹrẹ Francesco. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Ìfaradà Rẹ̀ Lérè (5:22)

      Apá kan nínú fídíò ‘Ìfaradà Rẹ̀ Lérè’ Francesco kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ lẹ́yìn tó ti sọ fún wọn pé òun ò ní bá wọn ṣọ̀rẹ́ mọ́.
      • Nínú fídíò yẹn, kí làwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé Francesco ṣe nígbà tó sọ ohun tó ń kọ́ fún wọn?

      • Báwo ni Ọlọ́run ṣe san èrè fún Francesco torí pé kò jáwọ́ nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

      Ka 2 Tímótì 2:24, 25, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Ṣé inú ìdílé rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ dùn sí ohun tó ò ń kọ́?

      • Bí àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣe sọ, kí ló yẹ kó o ṣe táwọn kan bá ń ṣe ohun tí kò dáa sí ẹ torí pé ò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Kí nìdí tí wàá fi ṣe bẹ́ẹ̀?

      6. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́

      Bá a bá ṣe ń sún mọ́ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ lá máa wù wá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Síbẹ̀, ó lè nira fún wa láti ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé wa tó máa bá ìlànà rẹ̀ mu. Tó bá nira fún ẹ, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Jèhófà Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Ṣe Àyípadà Tó Yẹ (3:56)

      • Nínú fídíò yẹn, àwọn àyípadà wo ni Jim ṣe kó lè ṣe ìfẹ́ Jèhófà?

      • Kí ló wú ẹ lórí nínú ohun tó ṣe?

      Ka Hébérù 11:6, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí ni Jèhófà máa ṣe fún àwọn “tó ń wá a tọkàntọkàn,” ìyẹn àwọn tó ń sapá gan-an láti mọ̀ ọ́n kí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀?

      • Báwo lo ṣe rò pé ó máa ń rí lára Jèhófà bó ṣe ń rí gbogbo akitiyan rẹ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó?

      ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí nìdí tó o fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?”

      • Kí lo máa sọ?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í rọrùn nígbà gbogbo láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kó o lè gbádùn ayé rẹ títí láé. Ṣáà máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa san ẹ́ lérè.

      Kí lo rí kọ́?

      • Kí nìdí tí ẹ̀kọ́ Bíbélì fi ṣeyebíye sí ẹ?

      • Báwo lo ṣe lè “máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù”?

      • Kí nìdí tó fi yẹ kó o bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Wo ohun mẹ́rin tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ tí wọ́n fi ń lo àkókò wọn lọ́nà tó dáa.

      “Bó O Ṣe Lè Máa Lo Àkókò Rẹ Lọ́nà Tó Dáa” (Jí!, February 2014)

      Wo bí Jèhófà ṣe ran obìnrin kan lọ́wọ́ tí ọkọ rẹ̀ ò kọ́kọ́ mọ ìdí tó fi ń sapá láti sin Ọlọ́run.

      Jèhófà Ń Fún Wa Lókun Ká Lè Gbé Ẹrù Wa (5:05)

      Wo bí ọkùnrin kan ṣe jàǹfààní torí pé ìyàwó rẹ̀ fara da àtakò.

      Mo Wádìí Òtítọ́ Wò (6:30)

      Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń fẹ̀sùn kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé à ń tú ìdílé ká. Àmọ́, ṣé òótọ́ ni?

      “Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Tú Ìdílé Ká Ni àbí Wọ́n Ń Mú Kí Ìdílé Wà Níṣọ̀kan?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

  • Ìrìbọmi Ṣe Pàtàkì!
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • 3. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kẹ́nì kan ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi?

      Tó o bá fẹ́ ṣèrìbọmi, ó ṣe pàtàkì pé kó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kó o sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú rẹ̀. (Ka Hébérù 11:6.) Bí ìmọ̀ rẹ ṣe ń pọ̀ sí i, tí ìgbàgbọ́ rẹ sì ń lágbára sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ó dájú pé á máa wù ẹ́ láti sọ fún àwọn èèyàn nípa Jèhófà, wàá sì fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ. (2 Tímótì 4:2; 1 Jòhánù 5:3) Tó o bá ti ń gbé ìgbé ayé rẹ “lọ́nà tó yẹ Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún,” o lè pinnu láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kó o sì ṣèrìbọmi.​—Kólósè 1:9, 10.a

  • Ìrìbọmi Ṣe Pàtàkì!
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • a Tẹ́nì kan bá ti ṣèrìbọmi nínú ẹ̀sìn tó ń ṣe tẹ́lẹ̀, ńṣe la máa tún ìrìbọmi ṣe fún ẹni náà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹ̀sìn yẹn kò kọ́ni ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì.​—Wo Ìṣe 19:1-5 àti Ẹ̀kọ́ 13.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́