ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Mósè
    Ilé Ìṣọ́—2014 | April 15
    • 1, 2. (a) Ìpinnu wo ni Mósè ṣe nígbà tó pé ẹni ogójì ọdún? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí nìdí tí Mósè fi yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run?

      MÓSÈ mọ àwọn nǹkan tí òun lè gbádùn nílẹ̀ Íjíbítì. Ó rí àwọn ilé gbàràmù gbaramu táwọn ọlọ́rọ̀ ní. Ààfin ọba ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Wọ́n fún un “ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì,” èyí tó ṣeé ṣe kó ní nínú ìmọ̀ nípa iṣẹ́ ọnà, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà, ìṣirò àti nípa àwọn nǹkan míì. (Ìṣe 7:22) Àwọn nǹkan tó jẹ́ àléèbá fún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Íjíbítì, irú bí ọrọ̀, agbára àti ọlá tún wà níkàáwọ́ rẹ̀!

      2 Síbẹ̀, nígbà tí Mósè pé ogójì ọdún, ó ṣe ìpinnu kan tó ti ní láti ya àwọn tó ń gbé láàfin ọba Íjíbítì lẹ́nu. Ká tiẹ̀ gbà pé kò yàn láti gbé ìgbésí ayé ẹni ńlá, ṣebí ì bá tiẹ̀ yàn láti máa gbé irú ìgbésí ayé tí ọ̀pọ̀ àwọn ará Íjíbítì ń gbé, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yàn láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹrú. Kí nìdí? Ìdí ni pé Mósè ní ìgbàgbọ́. (Ka Hébérù 11:24-26.) Ìgbàgbọ́ yìí mú kí Mósè wò ré kọjá ohun téèyàn lè fi ojú lásán rí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ ẹni tẹ̀mí, ó ní ìgbàgbọ́ nínú “Ẹni tí a kò lè rí,” ìyẹn Jèhófà. Ó sì tún ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ní ìmúṣẹ.—Héb. 11:27.

  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Mósè
    Ilé Ìṣọ́—2014 | April 15
    • 6. (a) Kí nìdí tí Mósè fi kọ̀ pé kí wọ́n máa “pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò”? (b) Kí nìdí tó o fi rò pé ìpinnu tó tọ́ ni Mósè ṣe?

      6 Ìgbàgbọ́ tí Mósè ní tún ràn án lọ́wọ́ láti pinnu ohun tó máa fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Bíbélì sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè, nígbà tí ó dàgbà, fi kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò.” (Héb. 11:24) Mósè kò ronú pé òun lè máa gbé ní ààfin Ọba kóun máa sin Ọlọ́run níbẹ̀ kóun sì máa fi ọrọ̀ àti ọlá tí òun ní ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ èèyàn òun lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló pinnu pé òun máa fi gbogbo ọkàn-àyà òun àti gbogbo ọkàn òun àti gbogbo okunra òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Diu. 6:5) Ìpinnu tí Mósè ṣe yìí ni kò jẹ́ kó ní ẹ̀dùn ọkàn. Kò sì pẹ́ tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣúra tí Mósè pa tì yìí fi bọ́ mọ́ àwọn ará Íjíbítì lọ́wọ́ tó sì wá di ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kís. 12:35, 36) Fáráò kàbùkù, Ọlọ́run sì fìyà ikú jẹ ẹ́. (Sm. 136:15) Ṣùgbọ́n Ọlọ́run dá ẹ̀mí Mósè sí, ó sì lò ó láti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. Dájúdájú, ìgbésí ayé Mósè nítumọ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́