-
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ MósèIlé Ìṣọ́—2014 | April 15
-
-
1, 2. (a) Ìpinnu wo ni Mósè ṣe nígbà tó pé ẹni ogójì ọdún? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí nìdí tí Mósè fi yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run?
MÓSÈ mọ àwọn nǹkan tí òun lè gbádùn nílẹ̀ Íjíbítì. Ó rí àwọn ilé gbàràmù gbaramu táwọn ọlọ́rọ̀ ní. Ààfin ọba ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Wọ́n fún un “ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì,” èyí tó ṣeé ṣe kó ní nínú ìmọ̀ nípa iṣẹ́ ọnà, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà, ìṣirò àti nípa àwọn nǹkan míì. (Ìṣe 7:22) Àwọn nǹkan tó jẹ́ àléèbá fún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Íjíbítì, irú bí ọrọ̀, agbára àti ọlá tún wà níkàáwọ́ rẹ̀!
2 Síbẹ̀, nígbà tí Mósè pé ogójì ọdún, ó ṣe ìpinnu kan tó ti ní láti ya àwọn tó ń gbé láàfin ọba Íjíbítì lẹ́nu. Ká tiẹ̀ gbà pé kò yàn láti gbé ìgbésí ayé ẹni ńlá, ṣebí ì bá tiẹ̀ yàn láti máa gbé irú ìgbésí ayé tí ọ̀pọ̀ àwọn ará Íjíbítì ń gbé, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yàn láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹrú. Kí nìdí? Ìdí ni pé Mósè ní ìgbàgbọ́. (Ka Hébérù 11:24-26.) Ìgbàgbọ́ yìí mú kí Mósè wò ré kọjá ohun téèyàn lè fi ojú lásán rí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ ẹni tẹ̀mí, ó ní ìgbàgbọ́ nínú “Ẹni tí a kò lè rí,” ìyẹn Jèhófà. Ó sì tún ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ní ìmúṣẹ.—Héb. 11:27.
-
-
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ MósèIlé Ìṣọ́—2014 | April 15
-
-
4. Kí ni Mósè mọ̀ nípa “ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀”?
4 Torí pé Mósè ní ìgbàgbọ́, ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ni “ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀” wà fún. Àwọn kan lè ronú pé bó tílẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Íjíbítì ti jingiri sínú ìbọ̀rìṣà àti ìbẹ́mìílò, ó di agbára ayé, síbẹ̀, àwọn èèyàn Jèhófà ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ẹrú! Láìka ìyẹn sí, Mósè mọ̀ pé Ọlọ́run lè yí ipò táwọn èèyàn rẹ̀ wà pa dà. Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé àwọn tó ń ṣe ohun tó wù wọ́n ń rọ́wọ́ mú, síbẹ̀ Mósè ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ẹni burúkú máa tó pa run. Látàrí ìyẹn, kò wù ú láti ‘jẹ̀gbádùn ẹ̀ṣẹ̀ kódà fún ìgbà díẹ̀.’
5. Kí ni kò ní jẹ́ ká fẹ́ láti ‘jẹ̀gbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀’?
5 Kí ló máa mú kó o kọ̀ láti ‘jẹ̀gbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀’? Má ṣe gbàgbé pé ìgbádùn téèyàn ń rí nínú dídá ẹ̀ṣẹ̀ kì í tọ́jọ́. Máa fi ojú ìgbàgbọ́ wò ó pé “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (1 Jòh. 2:15-17) Máa ṣe àṣàrò lórí ohun tó máa gbẹ̀yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà. “Orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́ ni” wọ́n wà, “tí a mú wọn wá sí òpin wọn nípasẹ̀ ìpayà òjijì!” (Sm. 73:18, 19) Tó o bá dojú kọ ìdẹwò láti dẹ́ṣẹ̀, bí ara rẹ pé, ‘Ibo ni mo fẹ́ kí ayé mí já sí?’
-