ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bó O Ṣe Lè Mú Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016 | October
    • 10. Sọ àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó kọ̀ láti ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ló sì fún wọn lókun láti ṣe bẹ́ẹ̀?

      10 Nínú ìwé Hébérù orí 11, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa onírúurú àdánwò táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fara dà. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan àwọn obìnrin tó nígbàgbọ́ táwọn ọmọ wọn kú, àmọ́ tí àwọn ọmọ náà tún jíǹde. Ó tún mẹ́nu ba àwọn míì tí kò “tẹ́wọ́ gba ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà kankan, kí ọwọ́ wọn lè tẹ àjíǹde tí ó sàn jù.” (Héb. 11:35) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ àwọn tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn, síbẹ̀ wọ́n sọ Nábótì àti Sekaráyà lókùúta pa torí pé wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. (1 Ọba 21:​3, 15; 2 Kíró. 24:​20, 21) Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò “tẹ́wọ́ gba ìtúsílẹ̀,” ìyẹn ni pé wọ́n yàn láti fẹ̀mí wọn wewu dípò kí wọ́n ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run, èyí sì mú kí “wọ́n dí ẹnu àwọn kìnnìún,” kí ‘wọ́n sì dá ipá iná dúró’ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.​—⁠Héb. 11:​33, 34; Dán. 3:​16-18, 20, 28; 6:​13, 16, 21-23.

  • Bó O Ṣe Lè Mú Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016 | October
    • 12. Ta ló fi àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn fara da àdánwò, kí ló sì jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀?

      12 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti mẹ́nu kan àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tó nígbàgbọ́, ó wá sọ àpẹẹrẹ ẹni tó ta yọ jù lọ, ìyẹn Jésù Kristi Olúwa wa. Kí ló jẹ́ kí àpẹẹrẹ Jésù ta yọ? Hébérù 12:2 sọ pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” Kódà, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká ‘ronú jinlẹ̀’ dáadáa nípa bí Jésù ṣe lo ìgbàgbọ́ láìka àwọn àdánwò lílekoko tó kójú. (Ka Hébérù 12:⁠3.) Bíi ti Jésù, àwọn Kristẹni míì yàn láti kú dípò kí wọ́n ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Lára wọn ni ọmọ ẹ̀yìn náà Áńtípà. (Ìṣí. 2:13) Àwọn Kristẹni yìí láǹfààní láti jíǹde sí ọ̀run. Lóòótọ́, “àjíǹde tí ó sàn jù” ni Bíbélì sọ pé àwọn ẹni ìgbàanì tó nígbàgbọ́ ń retí, síbẹ̀ àjíǹde ti ọ̀run dára jùyẹn lọ. (Héb. 11:35) Lẹ́yìn ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́dún 1914, Jèhófà jí àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tó ti kú dìde sí ọ̀run, kí wọ́n lè ṣàkóso pẹ̀lú Jésù.​—⁠Ìṣí. 20:⁠4.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́