-
Jehofa Ń Fòyebánilò!Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | August 1
-
-
Ìfòyebánilò Àmì Ọgbọ́n Àtọ̀runwá
6. Kí ni àwọn ìtumọ̀ olówuuru àti ìtumọ̀ abẹ́nú ti ọ̀rọ̀ Griki náà tí Jakọbu lò fún ṣíṣàpèjúwe ọgbọ́n àtọ̀runwá?
6 Ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu lo ọ̀rọ̀ fífanimọ́ra kan láti ṣàpèjúwe ọgbọ́n Ọlọrun tí ó mọwọ́ọ́yípadà lọ́nà gíga jùlọ yìí. Ó kọ̀wé pé: “Ọgbọ́n tí ó wá lati òkè . . . ń fòyebánilò.” (Jakọbu 3:17, NW) Ọ̀rọ̀ Griki náà tí ó lò níhìn-ín (e·pi·ei·kesʹ) ṣòro láti túmọ̀. Àwọn olùtúmọ̀ ti lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “ẹni pẹ̀lẹ́,” “afàánúhàn,” “alámùúmọ́ra,” àti “olùgbatẹnirò.” Bibeli New World Translation túmọ̀’ rẹ̀ sí “fòyebánilò,” pẹ̀lú àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé tí ń fihàn pé ìtumọ̀ rẹ̀ ní olówuuru ni “jíjuwọ́sílẹ̀.”a Ọ̀rọ̀ náà tún gbé ìtumọ̀ ṣíṣàì rinkinkin mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú òfin jáde, kí a máṣe mógìírí tàbí lekoko jù. Ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ William Barclay ṣàlàyé nínú New Testament Words pé: “Ohun ìpìlẹ̀ tí ó sì ṣekókó jùlọ nípa epieikeia ni pé ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Bí Ọlọrun bá rinkinkin mọ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀, bí Ọlọrun kò bá lo ohunkóhun fún wa bíkòṣe àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n aláìṣeéyípadà ti òfin, níbo ni àwa ìbá wà? Ọlọrun ni àpẹẹrẹ gíga jùlọ ti ẹnìkan tí ó jẹ́ epieikēs tí ó sì ń bá àwọn ẹlòmíràn lò pẹ̀lú epieikeia.”
7. Báwo ni Jehofa ṣe fi ìfòyebánilò hàn nínú ọgbà Edeni?
7 Ronú nípa àkókò náà nígbà tí aráyé ṣọ̀tẹ̀ lòdìsí ipò ọba-aláṣẹ Jehofa. Báwo ni ìbá ti rọrùn tó fún Ọlọrun láti mú ikú wá sórí àwọn aláìlọ́pẹ́ ọlọ̀tẹ̀ mẹ́ta wọnnì—Adamu, Efa, àti Satani! Ẹ sì wo bí ìrora ọkàn náà lọ́wọ́ èyí tí òun ìbá ti gba ara rẹ̀ kalẹ̀ ìbá ti pọ̀ tó! Ta ni ìbá sì jẹ́ jiyàn pé òun kò ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún irúfẹ́ ìdájọ́ òdodo ṣíṣe pàtó bẹ́ẹ̀? Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jehofa kò yọ̀ọ̀da kí ètò-àjọ rẹ̀ òkè-ọ̀run tí ó dàbí kẹ̀kẹ́-ẹṣin dúró gbagidi sínú ọ̀pá-ìdíwọ̀n ìdájọ́-òdodo kan tí kò ṣeé yípadà, tí kò sì ṣeé mú bá ipò mú. Nítorí náà kẹ̀kẹ́-ẹṣin yẹn kò yí gbirigbiri lu ìdílé ẹ̀dá ènìyàn àti gbogbo ìfojúsọ́nà fún ọjọ́-ọ̀la aláyọ̀ ti aráyé kí ó sì tẹ̀ wọ́n rẹ́. Ní òdìkejì sí ìyẹn, Jehofa fọgbọ́ndarí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ pẹ̀lú ìyárakánkán bíi ti kíkọ mànàmáná. Ní kété lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ náà, Jehofa Ọlọrun ṣe ìlàlẹ́sẹẹsẹ onígbà-pípẹ́ kan ti o nawọ́ àánú àti ìrètí sí gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ Adamu.—Genesisi 3:15.
8. (a) Báwo ni ojú-ìwòye aláṣìṣe tí Kristẹndọm ní nípa ìfòyebánilò ṣe yàtọ̀ sí ojúlówó ìfòyebánilò ti Jehofa? (b) Èéṣe tí a fi lè sọ pé ìfòyebánilò Jehofa kò túmọ̀ ní tààràtà sí pé òun lè fi àwọn ìlànà àtọ̀runwá bánidọ́rẹ̀ẹ́?
8 Bí ó ti wù kí ó rí, ìfòyebánilò Jehofa kò túmọ̀ ní tààràtà sí pé òun lè fi àwọn ìlànà àtọ̀runwá bánidọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm ìwòyí lè ronú pé àwọn ń fòyebánilò nígbà tí wọ́n bá fojútín-ín-rín ìwà pálapàla kìkì nítorí àti wá ojúrere àwọn agbo wọn oníwà wíwọ́. (Fiwé 2 Timoteu 4:3.) Jehofa kìí rú àwọn òfin tirẹ̀ fúnraarẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kìí fi àwọn ìlànà rẹ̀ bánidọ́rẹ̀ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ìmúratán hàn láti juwọ́sílẹ̀, láti mú ara rẹ̀ bá àwọn àyíká ipò mu, kí ó baà lè fi àwọn ìlànà wọnnì sílò pẹ̀lú ìdájọ́-òdodo àti àánú. Nígbà gbogbo ni ó ń rántí láti mú ìfisílò ìdájọ́-òdodo àti agbára rẹ̀ wà déédéé pẹ̀lú ìfẹ́ àti ọgbọ́n ìfòyebánilò rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà mẹ́ta tí Jehofa ń gbà fi ìfòyebánilò hàn.
‘Múra Láti Dáríjì’
9, 10. (a) Kí ni ‘mímúra láti dáríjì’ níí ṣe pẹ̀lú ìfòyebánilò? (b) Báwo ni Dafidi ṣe jàǹfààní láti inú ìmúratán Jehofa láti dáríjì, èésìtiṣe?
9 Dafidi kọ̀wé pé: “Nítorí ìwọ, Oluwa, o ṣeun, o sì múra àti dáríjì; o sì pọ̀ ní àánú fún gbogbo àwọn tí ń képè ọ́.” (Orin Dafidi 86:5) Nígbà tí a túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu sí èdè Griki, ọ̀rọ̀ náà fún “múra láti dáríjì” ni a túmọ̀ sí e·pi·ei·kesʹ, tàbí “ìfòyebánilò.” Nítòótọ́, mímúra láti dáríjì kí a sì fi àánú hàn ni ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀nà tí ó ṣekókó náà láti fi ìfòyebánilò hàn.
10 Dafidi fúnraarẹ̀ mọ̀ dáradára nípa bí Jehofa ti ń fòyebánilò tó lọ́nà yìí. Nígbà tí Dafidi ṣe panṣágà pẹ̀lú Batṣeba tí ó sì ṣètò láti mú kí a pa ọkọ rẹ̀, òun àti Batṣeba ni ó tọ́ pé kí a fìyà ikú jẹ. (Deuteronomi 22:22; 2 Samueli 11:2-27) Bí ó bá jẹ́ pé àwọn onídàájọ́ ènìyàn tí ìpinnu wọn kìí yípadà ni wọ́n ti bójútó ọ̀ràn náà, ó ṣeéṣe kí àwọn méjèèjì ti pàdánù ìwàláàyè wọn. Ṣùgbọ́n Jehofa fi ìfòyebánilò (e·pi·ei·kesʹ) hàn, èyí tí ó jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà Vine’s Expository Dictionary of Biblical Words ti sọ ọ́, “ó ṣàfihàn ìgbatẹnirò náà tí ń fi ‘inúrere àti ìfòyebánilò’ wo ‘àwọn òtítọ́ tí ń bẹ nídìí ọ̀ràn kan.’” Ó ṣeéṣe kí àwọn òtítọ́ náà tí ó mú kí Jehofa ṣe ìpinnu tí ó kún fún àánú ti wémọ́ ìrònúpìwàdà olótìítọ́-inú ti àwọn oníwà-àìtọ́ náà àti àánú tí Dafidi fúnraarẹ̀ ti fihàn fún àwọn ẹlòmíràn ṣáájú. (1 Samueli 24:4-6; 25:32-35; 26:7-11; Matteu 5:7; Jakọbu 2:13) Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí Jehofa gbà ṣàpèjúwe ara rẹ̀ nínú Eksodu 34:4-7, ohun tí ó fi ìfòyebánilò hàn ni pé Jehofa yóò fún Dafidi ní ìbáwí ìtọ́ni. Ó rán wòlíì Natani sí Dafidi pẹ̀lú ìhìn-iṣẹ́ lílágbára, ní títẹ òtítọ́ náà mọ́ Dafidi lọ́kàn pé ó ti tẹ́ḿbẹ́lú ọ̀rọ̀ Jehofa. Dafidi ronúpìwàdà kò sì kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.—2 Samueli 12:1-14.
-
-
Jehofa Ń Fòyebánilò!Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | August 1
-
-
a Lẹ́yìn lọ́hùn-ún ní 1769, aṣàkójọ ọ̀rọ̀ John Parkhurst túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà sí “jíjuwọ́sílẹ̀, ti ìwà ìjuwọ́sílẹ̀, jíjẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, oníwàtútù, onísùúrù.” Àwọn ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mìíràn pẹ̀lú ti fúnni ní “jíjuwọ́sílẹ̀” gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀.
-