ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Má Ṣe Fi Ètò Jèhófà Sílẹ̀
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
    • 8 Jémíìsì jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká ní ìfaradà nígbà tó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó máa mú kí ẹ ní ìfaradà. Àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì máa ṣe ohun tó tọ́ nínú ohun gbogbo, láìkù síbì kan.” (Jém. 1:2-4) Jémíìsì sọ pé kí àwa Kristẹni máa retí àdánwò, ká sì máa yọ̀ nígbà tí àdánwò bá dé torí pé á jẹ́ ká lè ní ìfaradà. Ṣé ìwọ náà gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Jémíìsì wá sọ pé ìfaradà níṣẹ́ tó ń ṣe nígbèésí ayé àwa Kristẹni, ó ń jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ rere, ó sì ń jẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wá. Ó dájú pé bá a ṣe ń dojú kọ ìṣòro lójoojúmọ́, tá a sì ń borí rẹ̀, ṣe ni àá túbọ̀ máa ní ìfaradà. Ìfaradà yìí á wá mú ká ní àwọn ìwà rere míì tá a nílò.

  • Má Ṣe Fi Ètò Jèhófà Sílẹ̀
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
    • 10 Tá a bá fẹ́ máa fara dà á nìṣó lákòókò tí nǹkan le koko yìí, ó ṣe pàtàkì káwa Kristẹni máa fojú tó tọ́ wo ìyà tó ń jẹ wá. Ká rántí ohun tí Jémíìsì sọ pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀.” Ká sòótọ́, ìyà ò dáa lára, torí ìrora àti ìdààmú ọkàn tó máa ń bá a rìn. Àmọ́ ká máa rántí pé àfi ká fara dà á, ká tó lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn àpọ́sítélì jẹ́ ká rí i pé a lè máa yọ̀ bá a tiẹ̀ ń jìyà. Ìtàn náà wà nínú ìwé Ìṣe, ó kà pé: “Wọ́n sì pe àwọn àpọ́sítélì, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù mọ́, wọ́n wá fi wọ́n sílẹ̀. Torí náà, wọ́n jáde kúrò níwájú Sàhẹ́ndìrìn, wọ́n ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ Jésù.” (Ìṣe 5:40, 41) Àwọn àpọ́sítélì yẹn mọ̀ pé torí àwọn ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù làwọn èèyàn ṣe ń fìyà jẹ àwọn, ó sì tún jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí Ọlọ́run mí sí Pétérù láti kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, ó jẹ́ káwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ mọ̀ pé ohun iyì ni bí wọ́n bá ń jìyà nítorí òdodo.​—1 Pét. 4:12-16.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́