ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Ẹrú Olóòótọ́’ Náà Yege Nígbà Àbẹ̀wò!
    Ilé Ìṣọ́—2004 | March 1
    • 15, 16. (a) Ìgbà wo ni àkókò tó láti ṣèṣirò? (b) Àkọ̀tun àǹfààní wo ni a fún àwọn olóòótọ́ láti “ṣòwò”?

      15 Àkàwé náà ń bá a lọ pé: “Lẹ́yìn àkókò gígùn, ọ̀gá ẹrú wọnnì dé, ó sì yanjú ìṣírò owó pẹ̀lú wọn.” (Mátíù 25:19) Ní ọdún 1914, ìyẹn àkókò gígùn lẹ́yìn ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ni wíwà níhìn-ín Jésù Kristi nínú ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ lẹ́yìn náà, ní ọdún 1918, ó wá sí tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Ọlọ́run láti mú ọ̀rọ̀ Pétérù ṣẹ pé: “Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti tó fún ìdájọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run.” (1 Pétérù 4:17; Málákì 3:1) Àkókò ti tó láti ṣèṣirò.

  • ‘Ẹrú Olóòótọ́’ Náà Yege Nígbà Àbẹ̀wò!
    Ilé Ìṣọ́—2004 | March 1
    • Nínú Mátíù orí 24 àti 25, ọ̀rọ̀ náà “dé” ni a lò fún Jésù ní oríṣiríṣi ọ̀nà. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà tó gbéra láti ibì kan wá kí a tó sọ pé ó “dé.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó “dé” ní ìtumọ̀ pé ó yí àfiyèsí rẹ̀ sí aráyé tàbí sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà láti ṣèdájọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ní ọdún 1914, ó “dé” láti bẹ̀rẹ̀ wíwà níhìn-ín rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba tá a gbé gorí ìtẹ́. (Mátíù 16:28; 17:1; Ìṣe 1:11) Ní ọdún 1918, ó “dé” gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́ májẹ̀mú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèdájọ́ àwọn tó sọ pé àwọn ń sin Jèhófà. (Málákì 3:1-3; 1 Pétérù 4:17) Ní Amágẹ́dọ́nì, Jésù yóò “dé” láti dá àwọn ọ̀tá Jèhófà lẹ́jọ́.—Ìṣípayá 19:11-16.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́