-
Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá NáàIlé Ìṣọ́—2013 | November 15
-
-
4. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Látàrí èyí, báwo ló ṣe yẹ kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ máa ṣe sí àwọn àgùntàn Ọlọ́run? Bíbélì rọ àwọn ará ìjọ pé kí wọ́n “jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín” wọn. Ó tún gba àwọn alàgbà níyànjú pé kí wọ́n má ṣe máa “jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí.” (Héb. 13:17; ka 1 Pétérù 5:2, 3.) Báwo wá ni àwọn alàgbà á ṣe máa múpò iwájú tí wọ́n kò sì ní jẹ olúwa lé agbo Ọlọ́run lórí? Ká sọ ọ́ lọ́nà míì, báwo ni àwọn alàgbà ṣe máa bójú tó àwọn àgùntàn láìlo àṣẹ tí Ọlọ́run fún wọn nílòkulò?
-
-
Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá NáàIlé Ìṣọ́—2013 | November 15
-
-
9. Èrò wo ni Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní?
9 Èrò Jésù nípa ojúṣe àwọn olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ yàtọ̀ sí èrò tí Jákọ́bù àti Jòhánù ní nígbà kan. Àwọn àpọ́sítélì méjì yìí ń wá ipò ńlá nínú Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ Jésù yí èrò wọn pa dà, ó ní: “Ẹ mọ̀ pé àwọn olùṣàkóso orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn ènìyàn ńlá a sì máa lo ọlá àṣẹ lórí wọn. Báyìí kọ́ ni láàárín yín; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín.” (Mát. 20:25, 26) Àwọn àpọ́sítélì náà ní láti dènà bó ṣe ń wù wọ́n láti “jẹ olúwa lórí” àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tàbí kí wọ́n máa pàṣẹ fún àwọn èèyàn.
10. Báwo ni Jésù ṣe fẹ́ káwọn alàgbà máa ṣe sí àwọn àgùntàn Ọlọ́run, àpẹẹrẹ wo sì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí?
10 Jésù ń fẹ́ káwọn alàgbà máa ṣe sí àwọn àgùntàn Ọlọ́run bóun ṣe ṣe sí wọn. Wọ́n gbọ́dọ̀ múra tán láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọn kò ní jẹ ọ̀gá lé wọn lórí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nírú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yẹn, nítorí ó sọ fún àwọn àgbà ọkùnrin ní ìjọ Éfésù pé: “Ẹ̀yin mọ̀ dunjú, bí ó ti jẹ́ pé láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo dé sí àgbègbè Éṣíà ni mo ti wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àkókò, tí mo ń sìnrú fún Olúwa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú títóbi jù lọ.” Àpọ́sítélì yìí fẹ́ kí àwọn alàgbà yẹn ran àwọn yòókù lọ́wọ́ tọkàntọkàn pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. Ó sọ pé: “Mo ti fi hàn yín nínú ohun gbogbo pé nípa ṣíṣe òpò lọ́nà yìí, ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlera.” (Ìṣe 20:18, 19, 35) Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé òun kò jẹ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ kí wọ́n lè ní ìdùnnú. (2 Kọ́r. 1:24) Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn alàgbà òde òní nípa béèyàn ṣe lè níwà ìrẹ̀lẹ̀, kó sì máa ṣiṣẹ́ kára.
-
-
Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá NáàIlé Ìṣọ́—2013 | November 15
-
-
“ÀPẸẸRẸ FÚN AGBO”
Àwọn alàgbà máa ń ran ìdílé wọn lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 13)
13, 14. Àwọn ọ̀nà wo ni alàgbà kan ní láti gbà jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo Ọlọ́run?
13 Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù ti gba àwọn alàgbà ìjọ nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe ‘jẹ olúwa lé àwọn tó wà níkàáwọ́ wọn lórí,’ ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n “di àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Pét. 5:3) Báwo ni alàgbà kan ṣe lè jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo? Ẹ jẹ́ ká gbé méjì yẹ̀ wò lára ohun tá à ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó “ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó.” Ó ní láti jẹ́ ẹni tó “yè kooro ní èrò inú,” ó sì gbọ́dọ̀ máa “ṣe àbójútó agbo ilé tirẹ̀ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.” Bí alàgbà kan bá ní ìdílé, ó gbọ́dọ̀ máa bójú tó o lọ́nà tó ṣeé fi ṣe àpẹẹrẹ, nítorí “bí ọkùnrin èyíkéyìí kò bá mọ agbo ilé ara rẹ̀ bójú tó, báwo ni yóò ṣe bójú tó ìjọ Ọlọ́run?” (1 Tím. 3:1, 2, 4, 5) Kí ọkùnrin kan tó kúnjú ìwọ̀n láti di alábòójútó, ó gbọ́dọ̀ yè kooro ní èrò inú ní ti pé á lóye àwọn ìlànà Ọlọ́run dáadáa, á sì mọ bí á ṣe máa tẹ̀ lé wọn nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tára rẹ̀ balẹ̀, tí kì í sì í fi ìkánjú ṣèpinnu. Tí àwọn ará ìjọ bá rí i pé àwọn alàgbà ní àwọn ànímọ́ yìí, wọ́n á lè fọkàn tán wọn.
14 Mímú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìsìn pápá jẹ́ ọ̀nà míì tí àwọn alábòójútó lè gbà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni. Nínú ọ̀ràn yìí, Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn alábòójútó. Apá pàtàkì nínú iṣẹ́ tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó fi bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà hàn wọ́n. (Máàkù 1:38; Lúùkù 8:1) Lóde òní, ẹ wo bó ṣe ń fún àwọn akéde níṣìírí tó nígbà tí wọ́n bá ń wàásù pẹ̀lú àwọn alàgbà, tí wọ́n ń wo bí àwọn alàgbà ṣe ń fìtara ṣe iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí, tí wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú bí àwọn alàgbà ṣe ń kọ́ni! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ àwọn alábòójútó máa ń dí, bí wọ́n ṣe ń fi àkókò àti okun wọn wàásù ìhìn rere náà pẹ̀lú ìtara ń fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti ní irú ìtara kan náà. Àwọn alàgbà tún lè fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn ará nípa mímúra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀, kí wọ́n sì máa kópa nípàdé àti nínú àwọn iṣẹ́ míì bíi mímú Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní.—Éfé. 5:15, 16; ka Hébérù 13:7.
Àwọn alábòójútó ń fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá (Wo ìpínrọ̀ 14)
-