ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Kó Gbogbo Àníyàn Yín Lé Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | November 15
    • 8, 9. Ìtùnú wo ni a lè rí gbà láti inú 1 Peteru 5:​6-⁠11?

      8 Peteru fikún un pé: “Nitori naa, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọrun, kí oun lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ; bí ẹ̀yin ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e, nitori ó ń bìkítà fún yín. Ẹ pa awọn agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyèsára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà lati pa ẹni kan jẹ. Ṣugbọn ẹ mú ìdúró yín lòdì sí i, ní dídúró gbọn-⁠in ninu ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé awọn ohun kan naa ní ọ̀nà ìyà jíjẹ ni a ń ṣe ní àṣeparí ninu gbogbo ẹgbẹ́ awọn arákùnrin yín ninu ayé. Ṣugbọn, lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọrun inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo, ẹni tí ó pè yín sí ògo àìnípẹ̀kun rẹ̀ ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Kristi, yoo fúnra rẹ̀ parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín, oun yoo fìdí yín múlẹ̀ gbọn-⁠in, yoo mú yín lókunlágbára. Oun ni kí agbára ńlá jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.”​—⁠1 Peteru 5:​6-⁠11, NW.

  • Ẹ Kó Gbogbo Àníyàn Yín Lé Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | November 15
    • 10. Àwọn ànímọ́ mẹ́ta wo tí 1 Peteru 5:​6, 7 mẹ́nubà ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú àníyàn fúyẹ́?

      10 Peteru Kìn-⁠ín-⁠ní 5:​6, 7 (NW) mẹ́nuba àwọn ànímọ́ mẹ́ta tí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àníyàn. Ọ̀kan ni ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú.” Ẹsẹ̀ 6 parí pẹ̀lú gbólóhùn náà “ní àkókò yíyẹ,” tí ń dámọ̀ràn àìní náà fún sùúrù. Ẹsẹ̀ 7 fihàn pé a lè fi ìgbọ́kànlé kó gbogbo àníyàn wa lé Ọlọrun ‘nítorí tí ó ń bìkítà fún wa,’ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sì fún wa ní ìṣírí láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jehofa. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a wo bí ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn, sùúrù, àti ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ọlọrun ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú àníyàn fúyẹ́.

      Bí Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Ṣe Lè Ṣèrànlọ́wọ́

      11. Báwo ni ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àníyàn?

      11 Bí a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn, àwa yóò gbà pé èrò Ọlọrun ju tiwa lọ fíìfíì. (Isaiah 55:​8, 9) Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ibi tí agbára ìrònú wa mọ ní ìfiwéra pẹ̀lú agbára ìwòye Jehofa tí ó ríran dé ibi gbogbo. Ó ń rí àwọn nǹkan tí àwa kò lè fi òye ronú wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn nínú ọ̀ràn ti Jobu ọkùnrin olódodo nì. (Jobu 1:7-⁠12; 2:1-⁠6) Nípa rírẹ ara wa sílẹ̀ “lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọrun,” a ń jẹ́wọ́ ipò rírẹlẹ̀ wa ní ìbámu pẹ̀lú Ọba-Aláṣẹ Onípò Àjùlọ náà. Ní ìdàkejì, èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn àyíká ipò tí òun bá yọ̀ọ̀da. Ọkàn-àyà wa lè yánhànhàn fún ìtura ojú-ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n níwọ̀n bí àwọn ànímọ́ Jehofa ti wà déédéé lọ́nà pípé pérépéré, ó mọ ìgbà náà ní pàtó tí ó yẹ kí òun gbé ìgbésẹ̀ àti bí ó ṣe yẹ kí òun gbé e nítorí tiwa. Nígbà náà, bí àwọn ọmọ kékeré, ẹ jẹ́ kí a fi ìrẹ̀lẹ̀ rọ̀ mọ́ ọwọ́ agbára ńlá Jehofa, pẹ̀lú ìdánilójú pé òun yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn àníyàn wa.​—⁠Isaiah 41:​8-⁠13.

      12. Bí a bá fi àwọn ọ̀rọ̀ Heberu 13:5 sílò pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ipa wo ni ó lè ní lórí àníyàn níti àìléwu nípa ohun ti ara?

      12 Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn wémọ́ ìmúratán láti fi ìmọ̀ràn láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílò, èyí tí ó lè máa fìgbà gbogbo dín àníyàn kù. Fún àpẹẹrẹ, bí àníyàn wa bá ti jẹ́ ìyọrísí rírì tí a ri ara wa bọ inú àwọn ìlépa ohun ti ara, a lè ṣe dáradára láti ronú lórí ìmọ̀ràn Paulu pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí-ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu awọn nǹkan ìsinsìnyí. Nitori [Ọlọrun] ti wí pé: ‘Dájúdájú emi kì yoo fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tabi ṣá ọ tì lọ́nàkọnà.’” (Heberu 13:5, NW) Nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn fi irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ sílò, ọ̀pọ̀ ti sọ ara wọn di òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn púpọ̀ níti àìléwu nípa ohun ti ara. Nígbà tí ó jẹ́ pé ipò wọn níti ọ̀ràn ìnáwó lè ṣaláì tíì sunwọ̀n síi, kò gba gbogbo ìrònú wọn ní ṣíṣokùnfà ìpalára wọn nípa tẹ̀mí.

      Ipa tí Sùúrù Ń Kó

      13, 14. (a) Níti ìfaradà tí ń bá sùúrù rìn, àpẹẹrẹ wo ni ọkùnrin náà Jobu pèsè? (b) Kí ni fífi sùúrù dúró de Jehofa lè ṣe fún wa?

      13 Gbólóhùn náà “ní àkókò yíyẹ” nínú 1 Peteru 5:6 dámọ̀ràn àìní náà fún ìfaradà tí ń bá sùúrù rìn. Ní àwọn ìgbà mìíràn ìṣòro kan lè máa bá a nìṣó fún àkókò gígùn, ìyẹn sì lè mú kí àníyàn pọ̀ síi. Ní ìgbà yẹn gan-⁠an ni ó yẹ kí a fi ọ̀ràn lé Jehofa lọ́wọ́. Ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu kọ̀wé pé: “Awọn wọnnì tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nipa ìfaradà Jobu ẹ sì ti rí àbárèbábọ̀ tí Jehofa mú wá, pé Jehofa jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jakọbu 5:11, NW) Jobu ní ìrírí ọrọ̀-ajé tí ó wọmi, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wàá kú, ó jìyà òkùnrùn tí ń kóninírìíra, àwọn olùtùnú èké sì dẹ́bi fún un lọ́nà òdì. Ó kérétán àníyàn díẹ̀ yóò jẹ́ ohun yíyẹ lábẹ́ irúfẹ́ àwọn àyíká ipò bẹ́ẹ̀.

      14 Lọ́nàkọnà, Jobu jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ níti ìfaradà tí ń bá sùúrù rìn. Bí a bá ń ní ìrírí ìdánwò ìgbàgbọ́ lílekoko, ó lè béèrè pé kí a dúró de ìtura, àní gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe. Ṣùgbọ́n Ọlọrun gbé ìgbésẹ̀ nítorí tirẹ̀, ní mímú kí Jobu rí ìtura gbà kúrò nínú ìjìyà rẹ̀ àti sísan èrè fún un lọ́pọ̀ yanturu ní àṣẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. (Jobu 42:​10-⁠17) Fífi sùúrù dúró de Jehofa ń mú kí sùúrù wa gbèrú ó sì ń ṣípayá bí ìfọkànsìn wa sí i ṣe jinlẹ̀ tó.​—⁠Jakọbu 1:​2-⁠4.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́