-
Ìdáhùn sí Ìbéèrè Mẹ́rin Nípa Òpin AyéIlé Ìṣọ́—2010 | August 1
-
-
Kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Pétérù sọ pé Ọlọ́run “kò sì fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ ayé ìgbàanì, ṣùgbọ́n ó pa Nóà, oníwàásù òdodo mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pétérù 2:5) Pétérù sọ nípa àwọn tó ń pẹ̀gàn pé: “Nítorí, ní ìbámu pẹ̀lú ìdàníyàn wọn, òtítọ́ yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí wọn, pé àwọn ọ̀run wà láti ìgbà láéláé àti ilẹ̀ ayé kan tí ó dúró digbí-digbí láti inú omi àti ní àárín omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; àti nípasẹ̀ ohun wọnnì, ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ kan náà, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayéb tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 3:5-7.
-
-
Ìdáhùn sí Ìbéèrè Mẹ́rin Nípa Òpin AyéIlé Ìṣọ́—2010 | August 1
-
-
b Níbí yìí, Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ ayé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Mósè tóun náà wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ ayé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ó kọ̀wé pé: “Gbogbo ilẹ̀ ayé ń bá a lọ láti jẹ́ èdè kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:1) Bí ilẹ̀ ayé tí Mósè mẹ́nu kàn kò ṣe lè sọ “èdè kan,” bẹ́ẹ̀ náà ni ilẹ̀ ayé tí Pétérù sọ̀rọ̀ rẹ̀ kò lè pa run. Kàkà bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe sọ, àwọn èèyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ló máa pa run.
-