-
Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti WáGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
1. Tó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn ló kọ Bíbélì, kí nìdí tá a fi sọ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú ẹ̀?
Nǹkan bí ogójì (40) ọkùnrin ló kọ Bíbélì, ó sì tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) ọdún tí wọ́n fi kọ ọ́, ìyẹn 1513 Ṣ.S.K. sí nǹkan bíi 98 S.K. Àwọn tó kọ Bíbélì yàtọ̀ síra lóríṣiríṣi ọ̀nà. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ò ta kora. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:13.) Kì í ṣe èrò àwọn tó kọ Bíbélì ló wà níbẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n “sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.”a (2 Pétérù 1:21) Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú kí wọ́n kọ èrò rẹ̀ sílẹ̀.—2 Tímótì 3:16.
-
-
Irú Ẹni Wo Ni Jèhófà?Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
4. Ẹ̀mí mímọ́ ni agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́
Bó ṣe jẹ́ pé àwa èèyàn máa ń fi ọwọ́ wa ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ agbára tí Jèhófà máa ń fi ṣe àwọn nǹkan tó bá fẹ́ ṣe. Ka Lúùkù 11:13 àti Ìṣe 2:17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ọlọ́run máa ‘tú ẹ̀mí mímọ́’ rẹ̀ sára àwọn tó bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣó o rò pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹnì kan àbí ó jẹ́ agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣe àwọn ohun ìyanu. Ka Sáàmù 33:6 àti 2 Pétérù 1:20, 21, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀?
-