-
Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Tó Fẹ́ Yí Ọ̀rọ̀ Inú Rẹ̀ Pa DàIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 4
-
-
Ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan: Ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n parí kíkọ Bíbélì, ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan kan fi ọ̀rọ̀ yìí kún 1 Jòhánù 5:7, “ní ọ̀run, Baba, Ọ̀rọ̀, àti Ẹ̀mí Mímọ́: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí jẹ́ ọ̀kan.” Gbólóhùn yìí kò sí nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Onímọ̀ nípa Bíbélì kan tó ń jẹ́ Bruce Metzger sọ pé: “Láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ni ọ̀rọ̀ yìí ti ń fara hàn lemọ́lemọ́ nínú ìwé àfọwọ́kọ àwọn Látìn Àtijọ́ àti ti Vulgate lédè Látìn.”
-
-
Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Tó Fẹ́ Yí Ọ̀rọ̀ Inú Rẹ̀ Pa DàIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 4
-
-
Ìkejì, bí àwọn ìwé àfọwọ́kọ ṣe wà lóríṣiríṣi lónìí ti jẹ́ kó rọrùn fún àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì láti rí ibi tí àṣìṣe wà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn fi ń kọ́ àwọn èèyàn pé Bíbélì èdè Látìn táwọn ń lò ni ojúlówó Bíbélì tó bá ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi fọ̀rọ̀ tiwọn kún 1 Jòhánù 5:7, bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Àṣìṣe yìí tún wọnú Bíbélì King James Version lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì tí wọ́n ṣàwárí fi hàn pé kò sí ọ̀rọ̀ yẹn nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bruce Metzger sọ pé: “Gbólóhùn tó wà [nínú 1 Jòhánù 5:7] yẹn kò sí nínú gbogbo àwọn ìwé àfọwọ́kọ ayé ìgbàanì míì tí wọ́n rí, àwọn ìwé àfọwọ́kọ bíi (Syriac, Coptic, Armenian, Ethiopic, Arabic, Slavonic), àyàfi nínú ti èdè Látìn nìkan.” Èyí ló mú kí wọ́n yọ gbólóhùn náà kúrò nínú Bíbélì King James Version tí wọ́n tún ṣe àtàwọn Bíbélì míì.
-