ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 10/1 ojú ìwé 32
  • Fífi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Tí Ó Nílò Ìrànwọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Tí Ó Nílò Ìrànwọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 10/1 ojú ìwé 32

Fífi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Tí Ó Nílò Ìrànwọ́

ÀWỌN Kristẹni ní ojúṣe àti àǹfààní fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn tí ó nílò ìrànwọ́. (Jòhánù Kíní 3:17, 18) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn wọnnì tí wọ́n bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Láìpẹ́ yìí, arákùnrin kan tí ó ti ń sin Jèhófà fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀wádún mẹ́rin báyìí nírìírí ìfẹ́ àwọn Kristẹni ará nígbà àìsàn aya rẹ̀ àti ikú rẹ̀ lẹ́yìn náà. Ó kọ̀wé pé:

“Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ nílé ni mo ti ń tọ́jú aya mi nígbà tí ó ń ṣàìsàn, kò ṣeé ṣe fún mi láti ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ fún nǹkan bí oṣù méjì. Ẹ wo bí ara ti tù mí tó nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ wá ṣèrànwọ́ fún wa tinútinú! Ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn owó—‘láti ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ìnáwó ńlá tí ẹ̀ ń ṣe,’ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó máa ń wà nínú káàdì tí a mú pẹ̀lú rẹ̀—ṣeé fi bójú tó owó ilé, àwọn ohun amáyé dẹrùn, àti àwọn ìnáwó mìíràn.

“Ọ̀sẹ̀ méjì tí ó ṣáájú ikú aya mi, alábòójútó àyíká wa ṣe ìbẹ̀wò oníṣìírí sọ́dọ̀ wa. Ó tilẹ̀ fi àwòrán ara ògiri tí ìjọ yóò wò ní òpin ọ̀sẹ̀ hàn wá. Ó ṣeé ṣe fún wa láti tẹ́tí sí ohun tí ń lọ nínú ìpàdé lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù—títí kan àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tí alábòójútó àyíká darí. Nínú ọ̀kan lára àwọn ìpàdé wọ̀nyí, ó ní kí gbogbo àwọn tí ó pésẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá sọ pé, ‘ẹ kú déédéé ìwòyí ó’ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan sí aya mi. Nípa báyìí, bí ó tilẹ̀ wà ní àdádó nípa ti ara, òun kò nímọ̀lára pé òun dá wà.

“Láàárín wákàtí kan tí ó kú, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo alàgbà ni ó ti wà nílé mi. Iye tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún arákùnrin àti arábìnrin ni ó ṣèbẹ̀wò ní ọjọ́ yẹn gan-an. Oúnjẹ ‘ṣàdédé’ fara hàn lórí tábìlì fún gbogbo ẹni tí ó pésẹ̀. N kò lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ gbogbo ẹ̀bùn, ọ̀rọ̀ ìkẹ́dùn, ọ̀rọ̀ ìtùnú, àti àdúrà tí a gbà fún mi. Ẹ wo bí wọ́n ti fún mi lókun tó! Mo ní láti sọ fún àwọn ará nígbẹ̀yìngbẹ́yín pé kí wọ́n dáwọ́ dúró pípèsè oúnjẹ àti títúnlé ṣe fún mi!

“Ibòmíràn wo yàtọ̀ sí inú ètò àjọ Jèhófà ni a ti lè rí irú ìyọ́nú, ìkẹ́, àti ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan bí èyí? Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn lónìí ni ọ̀rẹ́ tòótọ́ tí wọ́n ní kò tó nǹkan. Jèhófà ti fi ìdílé gbígbòòrò ti àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí bù kún wa!”—Máàkù 10:29, 30.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́