ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Lo Lè Ṣe Tó O Bá Dá Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Burú Gan-an?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • 4. Jèhófà máa ń ṣàánú àwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀

      Tẹ́nì kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an, tó sì kọ̀ láti tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, a máa yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ, a ò sì ní bá a ṣe wọléwọ̀de mọ́. Ka 1 Kọ́ríńtì 5:6, 11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Bó ṣe jẹ́ pé ìwúkàrà máa ń mú kí ìyẹ̀fun wú, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìjọ tí wọ́n bá ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí kò ronú pìwà dà?

      Bí Jèhófà ṣe máa ń ṣàánú àwa èèyàn aláìpé, àwọn alàgbà náà máa ń fàánú hàn sáwọn tá a ti yọ kúrò nínú ìjọ. Wọ́n máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbáwí ò rọrùn, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti yọ kúrò nínú ìjọ ló ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, tí wọ́n sì gbà pé bí wọ́n ṣe yọ àwọn ló ran àwọn lọ́wọ́ láti tún èrò àwọn ṣe.—Sáàmù 141:5.

      • Báwo ni ọwọ́ tí Jèhófà fi ń mú àwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀ ṣe fi hàn pé ó ń fòye báni lò, ó jẹ́ aláàánú, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa?

      5. Jèhófà máa dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà

      Jésù sọ àpèjúwe tó jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà. Ka Lúùkù 15:1-7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí ni àpèjúwe yìí jẹ́ kó o mọ̀ nípa Jèhófà?

      Ka Ìsíkíẹ́lì 33:11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • 1. Báwo làwọn míì ṣe lè mú kó nira fún wa láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà?

      Àwọn kan lè máa ṣe ohun tí ò ní jẹ́ ká sin Jèhófà bó ṣe yẹ, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa rọ̀ wá pé ká fi Jèhófà sílẹ̀. Àwọn wo ló lè ní ká ṣe irú ìpinnu burúkú bẹ́ẹ̀? Àwọn kan tó ti fi Jèhófà sílẹ̀ máa ń sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa ètò Ọlọ́run kí wọ́n lè mú kó nira fún wa láti fọkàn tán ètò Ọlọ́run. Bíbélì pe irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní apẹ̀yìndà. Bákan náà, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan máa ń sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn sì lè mú kí àwọn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ wọn fi Jèhófà sílẹ̀. Ó léwu gan-an láti máa bá àwọn alátakò yìí sọ̀rọ̀, kò sì yẹ ká máa ka àwọn ìwé wọn, lọ sórí ìkànnì wọn tàbí wo fídíò tí wọ́n gbé jáde. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tó ń fini mọ̀nà ni wọ́n. Tí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa já sí.”​—Mátíù 15:14.

      2. Báwo làwọn ìpinnu tá à ń ṣe ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà?

      Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun táá mú ká lọ́wọ́ sí ẹ̀sìn èké. Torí náà, a gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ wa, ẹgbẹ́ tá à ń ṣe àtàwọn nǹkan mí ì tá à ń lọ́wọ́ sí, ká sì rí i pé wọn ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn èké. Jèhófà kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ jáde kúrò nínú [Bábílónì Ńlá], ẹ̀yin èèyàn mi.”​—Ìfihàn 18:2, 4.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè dúró lórí ìpinnu ẹ láti jẹ́ adúróṣinṣin táwọn kan bá tiẹ̀ fẹ́ kó o fi Jèhófà sílẹ̀. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá, kó o lè fi hàn pé o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà.

      3. Má ṣe máa tẹ́tí sí àwọn olùkọ́ èké

      Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá gbọ́ àwọn nǹkan tí kì í ṣe òótọ́ nípa ètò Jèhófà? Ka Òwe 14:15, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́?

      Ka 2 Jòhánù 9-11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí ni kò yẹ ká máa ṣe sáwọn apẹ̀yìndà?

      • Tá ò bá tiẹ̀ bá àwọn apẹ̀yìndà sọ̀rọ̀ lójúkojú, àwọn ọ̀nà míì wo là lè gbà máa tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ wọn?

      • Báwo ló ṣe máa rí lára Jèhófà tá a bá ń fetí sí ohun tí ò dáa táwọn èèyàn ń sọ nípa rẹ̀ tàbí nípa ètò rẹ̀?

      4. Jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà tí ẹnì kan nínú ìjọ bá dẹ́ṣẹ̀

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́