ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Aájò Àlejò Kristẹni Nínú Ayé Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | October 1
    • “Nítorí náà, a wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti gba irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, kí a lè di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.”—JÒHÁNÙ KẸTA 8.

  • Aájò Àlejò Kristẹni Nínú Ayé Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | October 1
    • 3. Báwo ni a ṣe lè rí ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́?

      3 Ẹ wo bí nǹkan ì bá ti yàtọ̀ tó ká ní àwọn ènìyàn fara wé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá àwọn ẹlòmíràn lò—ní jíjẹ́ onínúure, ọlọ́làwọ́, àti aláájò àlejò! Ó mú un ṣe kedere pé àṣírí ayọ̀ tòótọ́ kì í ṣe gbígbìyànjú tí a bá gbìyànjú láti tẹ́ àwọn ìfẹ́ ọkàn wa lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, kọ́kọ́rọ́ náà nìyí pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírí gbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Láti rí ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́, a gbọ́dọ̀ ṣẹ́pá àwọn ìdènà àti ìpínyà tí ó lè dí wa lọ́wọ́. A sì gbọ́dọ̀ fà mọ́ àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà. Ó ṣe pàtàkì pé kí a kọbi ara sí ìmọ̀ràn náà pé: “Nítorí náà, a wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti gba irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, kí a lè di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.” (Jòhánù Kẹta 8) Fífi aájò àlejò hàn sí àwọn tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí i, títí dé ibi tí àyíká ipò wa bá fàyè gbà, ṣàǹfààní lọ́nà méjì—ó ṣàǹfààní fún olùfúnni àti ẹni tí ń gbà á. Nígbà náà, àwọn wo ni ó wà lára àwọn tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí i, tí a ní láti ‘gbà pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò’?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́