ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bí Ìṣípayá Ṣe Kàn Ọ́
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 3, 4. Kí ni áńgẹ́lì náà ń bá a lọ láti sọ fún Jòhánù, báwo sì làwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ṣe ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀?

      3 Jòhánù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ó tún sọ fún mi pé: ‘Má ṣe fi èdìdì di àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí, nítorí àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti sún mọ́lé. Ẹni tí ń ṣe àìṣòdodo, kí ó máa ṣe àìṣòdodo síbẹ̀; kí a sì sọ ẹni tí ó jẹ́ eléèérí di eléèérí síbẹ̀; ṣùgbọ́n kí olódodo máa ṣe òdodo síbẹ̀, kí a sì sọ ẹni mímọ́ di mímọ́ síbẹ̀.’”—Ìṣípayá 22:10, 11.

  • Bí Ìṣípayá Ṣe Kàn Ọ́
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 5. (a) Báwọn èèyàn ò bá fẹ́ láti fiyè sí àwọn ìkìlọ̀ àti ìmọ̀ràn inú Ìṣípayá ńkọ́? (b) Kí ló yẹ kí àwọn onínú tútù àti olódodo ṣe?

      5 Báwọn èèyàn ò bá fẹ́ láti fiyè sí àwọn ìkìlọ̀ àti ìmọ̀ràn tí ń bẹ nínú ìwé Ìṣípayá, tóò, kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó! “Ẹni tí ń ṣe àìṣòdodo, kí ó máa ṣe àìṣòdodo síbẹ̀.” Àwọn tí ń yíràá nínú ẹ̀gbin sànmánì tó gbọ̀jẹ̀gẹ́ yìí lè kú sínú ẹ̀gbin yẹn tó bá wù wọ́n bẹ́ẹ̀. Láìpẹ́, Jèhófà yóò mú àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ pátápátá, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìparun Bábílónì Ńlá. Kí àwọn onínú tútù máa fi aápọn kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì náà pé: “Ẹ wá Jèhófà . . . Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.” (Sefanáyà 2:3) Ní ti àwọn tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà nísinsìnyí, “kí olódodo máa ṣe òdodo síbẹ̀, kí a sì sọ ẹni mímọ́ di mímọ́ síbẹ̀.” Àwọn tó gbọ́n mọ̀ pé àǹfààní onígbà kúkúrú tí ń wá láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kò tó àwọn ìbùkún àìlópin tí àwọn tí ń lépa òdodo àti ìjẹ́mímọ́ yóò gbádùn. Bíbélì wí pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:5) Ipa ọ̀nà tó o bá yàn láti máa tọ̀ ló máa pinnu irú èrè tí wàá rí gbà.—Sáàmù 19:9-11; 58:10, 11.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́