-
Ǹjẹ́ Orúkọ Rẹ Wà Nínú Ìwé Ìyè?Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
10. Apá tó ń fúnni ní ìṣírí wo ni Jésù kíyè sí nínú ìjọ tó wà ní Sádísì, báwo lèyí sì ṣe kàn wá?
10 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tẹ̀ lé e fún ìjọ tó wà ní Sádísì túbọ̀ fúnni ní ìṣírí. Ó ní: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ní àwọn orúkọ díẹ̀ ní Sádísì tí wọn kò sọ ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn di ẹlẹ́gbin, dájúdájú, wọn yóò bá mi rìn nínú èyí tí ó funfun, nítorí wọ́n yẹ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni a ó fi ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun ṣe ní ọ̀ṣọ́ báyìí; dájúdájú, èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ lọ́nàkọnà kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ mímọ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi àti níwájú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.” (Ìṣípayá 3:4, 5) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ò fún wa níṣìírí àti okun tó lè jẹ́ ká dúró ti ìpinnu wa láti jẹ́ olùṣòtítọ́? Bí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kan bá ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn nǹkan, ó lè di pé kí ìjọ lódindi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìka ìjọsìn Ọlọ́run sí. Síbẹ̀, a lè rí àwọn kọ̀ọ̀kan tá a máa sapá tìgboyàtìgboyà láti rí i pé àwọn ò sọ ìwà Kristẹni àwọn nù kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ máa bá a lọ láti ní orúkọ rere pẹ̀lú Jèhófà.—Òwe 22:1.
-
-
Ǹjẹ́ Orúkọ Rẹ Wà Nínú Ìwé Ìyè?Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
13. Àwọn ìbùkún wo ló ń dúró de àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọn ò “sọ ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn di ẹlẹ́gbin”?
13 Àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ ní Sádísì tí wọn ò sì sọ ìwà Kristẹni wọn nù rí ìrètí àgbàyanu kan gbà. Lẹ́yìn tí Ìjọba Mèsáyà fìdí múlẹ̀ lọ́dún 1914, wọ́n jíǹde sí ìyè ti ẹ̀mí àti pé gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣẹ́gun, wọ́n wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun èyí tó ṣàpẹẹrẹ òdodo wọn tí ò lálèébù tí ò sì lábààwọ́n. Níwọ̀n bí wọ́n ti rìn ní ojú ọ̀nà híhá tí ń sinni lọ sí ìyè, wọ́n á gba èrè ayérayé.—Mátíù 7:14; tún wo Ìṣípayá 6:9-11.
Títí Láé Nínú Ìwé Ìyè!
14. Kí ni “ìwé ìyè,” orúkọ àwọn wo ló sì wà nínú rẹ̀?
14 Kí ni “ìwé ìyè,” orúkọ àwọn wo ló sì máa wà nínú rẹ̀? Ìwé, tàbí àkájọ ìwé ìyè túmọ̀ sí àkọsílẹ̀ nípa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n tóótun láti gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. (Málákì 3:16) Ìṣípayá yìí mẹ́nu ba orúkọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Síbẹ̀ ó tún mẹ́nu ba orúkọ àwọn tí wọ́n tóótun láti gba ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn orúkọ kan lè di ‘àwátì’ nínú ìwé yẹn. (Ẹ́kísódù 32:32, 33) Bó ti wù kó rí, àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ẹgbẹ́ Jòhánù tí orúkọ wọn bá wà nínú ìwé ìyè títí tí wọ́n fi kú á gba ìyè àìleèkú ní ọ̀run. (Ìṣípayá 2:10) Àwọn wọ̀nyí ló máa jẹ́ orúkọ tí Jésù fọwọ́ sí ní pàtàkì níwájú Baba rẹ̀ àti níwájú àwọn áńgẹ́lì Rẹ̀. Èrè yẹn má ga lọ́lá o!
15. Ọ̀nà wo ni orúkọ àwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe máa wà títí láé nínú ìwé ìyè?
15 Àwọn Ogunlọ́gọ̀ ńlá tí orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè máa la ìpọ́njú ńlá já láàyè. Bí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ jálẹ̀ Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Jésù tí wọ́n sì yege ìdánwò àṣekágbá tí yóò tẹ̀ lé e, wọ́n á jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Dáníẹ́lì 12:1; Ìṣípayá 7:9, 14; 20:15; 21:4) Ìgbà yẹn lórúkọ wọn máa wá wà nínú ìwé ìyè títí láé. Bí ẹ̀mí mímọ́ ti ṣe wá jẹ́ kí ohun tó wà níbí yé ọ, ǹjẹ́ o ò ní fẹ́ tara ṣàṣà láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Jésù ń sọ lásọtúnsọ pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ”?—Ìṣípayá 3:6.
-