-
Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
2. Àwọn wo ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù?
Jésù nìkan kọ́ ló máa dá ṣàkóso. Àwọn èèyàn látinú “gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè . . . máa ṣàkóso bí ọba lé ayé lórí.” (Ìfihàn 5:9, 10) Àwọn mélòó ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi? Látìgbà tí Jésù ti wá sáyé, àìmọye èèyàn ló ti di Kristẹni. Àmọ́, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) péré lára wọn ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run. (Ka Ìfihàn 14:1-4.) Gbogbo àwọn Kristẹni tó kù láyé sì máa jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run.—Sáàmù 37:29.
-
-
Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
6. Ọ̀rọ̀ wa yé Jésù àtàwọn tó máa bá a ṣàkóso
Torí pé Jésù Ọba wa ti gbé ayé rí gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó lè “bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.” (Hébérù 4:15) Bákan náà, “látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè” ni Jèhófà ti yan àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa bá Jésù ṣàkóso.—Ìfihàn 5:9.
Ṣé ọkàn ẹ balẹ̀ bó o ṣe mọ̀ pé Jésù àti gbogbo àwọn tó máa bá a ṣàkóso mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Jèhófà ti yan àwọn ọkùnrin àti obìnrin látinú gbogbo ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù
-