ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jòhánù Rí Jésù Tí Ọlọ́run Ti Ṣe Lógo
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 5. (a) Kí ni ohùn kan ké sí Jòhánù láti ṣe? (b) Èé ṣe tí ibi tí “ìjọ méje” náà wà fi rọrùn láti fi àkájọ ìwé ránṣẹ́ sí wọn?

      5 Nínú ìran àkọ́kọ́ yìí, kí Jòhánù tó rí ohunkóhun, ó gbọ́ ohùn kan. Ó sọ pé: “Mo sì gbọ́ ohùn líle bí ti kàkàkí lẹ́yìn mi, tí ó wí pé: ‘Kọ ohun tí ìwọ rí sínú àkájọ ìwé, kí o sì fi í ránṣẹ́ sí ìjọ méje, ní Éfésù àti ní Símínà àti ní Págámù àti ní Tíátírà àti ní Sádísì àti ní Filadéfíà àti ní Laodíkíà.’” (Ìṣípayá 1:10b, 11) Bí ìgbà tí wọ́n bá fi ìpè kàkàkí pàṣẹ fúnni, ohùn kan ké sí Jòhánù láti kọ̀wé sí “ìjọ méje.” Wọ́n á fi iṣẹ́ tó pọ̀ rán an, á sì kọ àwọn ohun tó bá rí tó sì gbọ́. Ṣàkíyèsí pé àwọn ìjọ tí ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu kàn wà lóòótọ́ nígbà ayé Jòhánù. Gbogbo wọn wà ní Éṣíà Kékeré. Ìsọdá òkun ni wọ́n wà téèyàn bá lọ síbẹ̀ láti Pátímọ́sì. Ká sọ pé ońṣẹ́ kan ló ń gbé àkájọ ìwé náà lọ láti ìjọ kan sí èkejì, kò ní ṣòro fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé àwọn ọ̀nà tó dára gan-an táwọn ará Róòmù là, èyí tó mú kó rọrùn láti ti ìjọ kan dé èkejì, wà ní àgbègbè náà. Ìjọ méjèèje wọ̀nyí fara jọ ìpín kan nínú àyíká àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní.

  • Jòhánù Rí Jésù Tí Ọlọ́run Ti Ṣe Lógo
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • [Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

      Àwókù àwọn ìlú tí àwọn awalẹ̀pìtàn rí níbi táwọn ìjọ méje náà wà fi hàn pé òótọ́ ni àkọsílẹ̀ Bíbélì. Ibẹ̀ ni àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní ti gba iṣẹ́ tó ń fúnni níṣìírí tí Jésù rán sí wọn, èyí tó ń fún àwọn ìjọ níṣìírí jákèjádò ayé lónìí.

      PÁGÁMÙ

      SÍMÍNÀ

      TÍÁTÍRÀ

      SÁDÍSÌ

      ÉFÉSÙ

      FILADÉFÍÀ

      LAODÍKÍÀ

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́