-
Jòhánù Rí Jésù Tí Ọlọ́run Ti Ṣe LógoÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
12. Kí ni “idà gígùn olójú méjì mímú” fi hàn?
12 Jòhánù ń tẹ̀ síwájú láti sọ ohun tó rí, ó ní: “Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, idà gígùn olójú méjì mímú sì yọ jáde láti ẹnu rẹ̀, ìrísí ojú rẹ̀ sì dà bí oòrùn nígbà tí ó bá ń ràn nínú agbára rẹ̀. Nígbà tí mo sì rí i, mo ṣubú bí òkú lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀.” (Ìṣípayá 1:16, 17a) Jésù tìkára rẹ̀ ṣàlàyé ìtumọ̀ ìràwọ̀ méje náà kété lẹ́yìn náà. Ṣùgbọ́n ṣàkíyèsí ohun tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde, ìyẹn “Idà gígùn olójú méjì mímú.” Ìrísí yìí bá a mu gan-an ni. Ìdí ni pé Jésù ni ẹni tí Jèhófà yàn pé kó kéde ìdájọ́ ìkẹyìn Òun lórí àwọn ọ̀tá Òun. Ọ̀rọ̀ àṣẹ tó ti ẹnu rẹ̀ jáde yóò yọrí sí fífi ikú pa gbogbo àwọn èèyàn búburú.—Ìṣípayá 19:13, 15.
13. (a) Kí ni ojú Jésù tó mọ́lẹ̀ yòò tó sì ń kọ̀ mànà rán wa létí rẹ̀? (b) Kí ni ohun pàtàkì tí àpèjúwe tí Jòhánù ṣe nípa Jésù tẹ̀ mọ́ wa lọ́kàn?
13 Ojú Jésù tó mọ́lẹ̀ yòò tó sì ń kọ mànà rán wa létí pé ojú Mósè mú àwọn ìtànṣán tó ń kọ mànà jáde lẹ́yìn tí Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ lórí Òkè Sínáì. (Ẹ́kísódù 34:29, 30) Tún rántí pé nígbà tí a pa Jésù lára dà lójú mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn, “ojú rẹ̀ sì tàn bí oòrùn, ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ sì wá tàn yòò bí ìmọ́lẹ̀.” (Mátíù 17:2) Bákan náà, nínú ìran tó ṣàpẹẹrẹ Jésù ní ọjọ́ Olúwa, ojú Jésù ń dán mànà ó sì ní ògo gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti wà lọ́dọ̀ Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 3:18) Dájúdájú, ohun pàtàkì tí ìran Jòhánù tẹ̀ mọ́ wa lọ́kàn ni ògo tí ń dán yanran. Irun tó funfun bí òjò dídì, ẹyinjú tó dà bí iná tó ń jó fòfò, ojú tí ń kọ mànà àti ẹsẹ̀ tí ń ràn yòò, jẹ́ ìran tó dára gan-an nípa Ẹni tó ń gbé nísinsìnyí “nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́.” (1 Tímótì 6:16) Ó hàn gbangba pé ohun gidi ni ìran yìí! Kí ni àpọ́sítélì Jòhánù ṣe nígbà tó rí ìran yìí tí jìnnìjìnnì sì bò ó ré kọjá ààlà? Ó sọ pé: “Nígbà tí mo sì rí i, mo ṣubú bí òkú lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀.”—Ìṣípayá 1:17.
-
-
A Rí Ìtumọ̀ Àṣírí Ọlọ́wọ̀ KanÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
2. (a) Orúkọ oyè wo ni Jésù pe ara rẹ̀? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ, pé “Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ èmi sì ni ẹni ìkẹyìn” túmọ̀ sí? (d) Kí ni orúkọ oyè Jésù náà “Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn” pe àfiyèsí sí?
2 Àmọ́ ṣá o, kò yẹ kí ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tá a ní fa ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì fún wa. Jésù fi àpọ́sítélì Jòhánù lọ́kàn balẹ̀, ìyẹn sì lohun tí Jòhánù sọ tẹ̀ lé e. Ó ní: “Ó sì gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó sì wí pé: ‘Má bẹ̀rù. Èmi ni Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn, àti alààyè.’” (Ìṣípayá 1:17b, 18a) Nínú Aísáyà 44:6, Jèhófà fi ẹ̀tọ́ sọ ipò tóun wà, ó ní òun nìkan ni Ọlọ́run Olódùmarè. Bó ṣe sọ ọ́ rèé: “Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, yàtọ̀ sí mi, kò sí Ọlọ́run kankan.”a Nígbà tí Jésù lo orúkọ oyè náà “Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn” fún ara rẹ̀, kò sọ pé òun bá Jèhófà tó jẹ́ Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá dọ́gba. Ọlọ́run ló fi orúkọ oyè tó lò yìí jíǹkí rẹ̀ lọ́nà ẹ̀tọ́. Nínú ìwé Aísáyà yẹn, Jèhófà sọ pé ipò Òun ò lẹ́gbẹ́, pé Òun ni Ọlọ́run tòótọ́ náà. Òun ni Ọlọ́run ayérayé, àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí òun. (1 Tímótì 1:17) Nínú ìwé Ìṣípayá, nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa orúkọ oyè tí Ọlọ́run fi jíǹkí rẹ̀, àjíǹde rẹ̀ tó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ló ń pe àfiyèsí sí.
3. (a) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn”? (b) Kí ni níní tí Jésù ní “kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì” túmọ̀ sí?
3 Lóòótọ́, Jésù ni “Ẹni Àkọ́kọ́” nínú àwọn tó jíǹde sí ìwàláàyè àìleèkú ti ẹ̀mí. (Kólósè 1:18) Yàtọ̀ síyẹn òun ni “Ẹni Ìkẹyìn” tí Jèhófà fọwọ́ ara rẹ̀ jí dìde. Nípa bẹ́ẹ̀, ó di “alààyè . . . [tó] wà láàyè títí láé àti láéláé.” Ó jẹ́ ẹ̀dá aláìleèkú. Ó fèyí jọ Baba rẹ̀ aláìleèkú, tá à ń pè ní “Ọlọ́run alààyè.” (Ìṣípayá 7:2; Sáàmù 42:2) Jésù ni “àjíǹde àti ìyè” fún gbogbo ẹ̀dá èèyàn yòókù. (Jòhánù 11:25) Níbàámu pẹ̀lú èyí, ó sọ fún Jòhánù pé: “Mo sì ti di òkú tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n, wò ó! mo wà láàyè títí láé àti láéláé, mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì lọ́wọ́.” (Ìṣípayá 1:18b) Jèhófà ti fún Jésù láṣẹ láti jí àwọn òkú dìde. Ìdí nìyẹn tó fi lè sọ pé òun ní kọ́kọ́rọ́ láti ṣí ibodè fún àwọn tí ikú àti Hédíìsì (ìyẹn ipò òkú) gbé dè.—Fi wé Mátíù 16:18.
-