ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Mú Àwọn Ẹlẹ́rìí Méjì Náà Sọ Jí
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 23. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹlẹ́rìí méjì náà lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àtààbọ̀, báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sì ṣe rí lára àwọn ọ̀tá wọn? (b) Ìgbà wo ni Ìṣípayá 11:11, 12 àti àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa mímí tí Jèhófà mí sára àwọn egungun gbígbẹ àfonífojì kan ní ìmúṣẹ ti òde òní?

      23 Àwọn ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àlùfáà nínú fífi ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ba àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́. Ìwé ìròyìn kan tiẹ̀ sọ pé: “A ti sọ òpin ìwé The Finished Mystery.” Àmọ́ irọ́ pátápátá gbáà ni èyí. Àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà kò jẹ́ òkú títí lọ. A kà pé: “Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì wọnú wọn, wọ́n sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn, ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí ń wò wọ́n. Wọ́n sì gbọ́ tí ohùn rara kan láti ọ̀run wí fún wọn pé: ‘Ẹ máa bọ̀ lókè níhìn-ín.’ Wọ́n sì gòkè lọ sínú ọ̀run nínú àwọsánmà, àwọn ọ̀tá wọn sì rí wọn.” (Ìṣípayá 11:11, 12) Nípa báyìí, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn jọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn egungun gbígbẹ tó wà ní àfonífojì tí Ìsíkíẹ́lì ṣèbẹ̀wò sí nínú ìran. Jèhófà mí sára àwọn egungun gbígbẹ wọ̀nyẹn, wọ́n sì sọ jí, èyí tó ń ṣàpẹẹrẹ títún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bí lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún ní ìgbèkùn Bábílónì. (Ìsíkíẹ́lì 37:1-14) Ọdún 1919 làwọn àsọtẹ́lẹ̀ méjì wọ̀nyí, ti inú Ìsíkíẹ́lì àti tinú Ìṣípayá, ní ìmúṣẹ ti òde òní, ó sì jẹ́ lọ́nà tó pabanbarì, ìyẹn nígbà tí Jèhófà mú àwọn “olóògbé” ẹlẹ́rìí rẹ̀ wá sí ìyè tó jí pépé.

      24. Nígbà táwọn ẹlẹ́rìí méjì náà sọ jí, báwo lèyí ṣe rí lára àwọn onísìn tó ń ṣenúnibíni sí wọn?

      24 Ẹ wo jìnnìjìnnì tí èyí kó bá àwọn tó ń ṣenúnibíni wọ̀nyẹn! Òkú àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà tún sọ jí lójijì wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà ní pẹrẹu. Èyí jẹ́ ohun tí kò bára dé rárá fáwọn àlùfáà wọnnì, pàápàá níwọ̀n bí àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ tí wọ́n di rìkíṣí mọ́ láti fi sẹ́wọ̀n ti wá di òmìnira padà, tí ìjọba sì tún dá wọn láre ní kíkún lẹ́yìn náà. Kò sí àní-àní pé jìnnìjìnnì tó bò wọ́n ti ní láti ga sí i ní September ọdún 1919, nígbà táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe àpéjọ kan ní Cedar Point, Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Níbi àpéjọ yìí ni J. F. Rutherford tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tú sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ti ru àwọn tó pé jọ sókè pẹ̀lú àsọyé kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Kíkéde Ìjọba Náà,” èyí tá a gbé ka Ìṣípayá 15:2 àti Aísáyà 52:7. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ẹgbẹ́ Jòhánù tún bẹ̀rẹ̀ sí í “sọ tẹ́lẹ̀,” ìyẹn ni pé wọ́n ń wàásù fáwọn èèyàn. Wọ́n ń ní okun síwájú àti síwájú sí i, wọ́n sì ń tú àgàbàgebè àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó láìbẹ̀rù.

  • A Mú Àwọn Ẹlẹ́rìí Méjì Náà Sọ Jí
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • c Ṣàkíyèsí pé bá a ti ń ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Ọlọ́run lákòókò yìí, ó jọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé oṣù méjìlélógójì [42] náà dúró fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ ní ti gidi, ọjọ́ mẹ́ta àtààbọ̀ kò túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta àtààbọ̀ gidi tó jẹ́ wákàtí mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84]. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí tí wọ́n fi mẹ́nu kan ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ lẹ́ẹ̀mejì (ní ẹsẹ 9 àti 11) jẹ́ láti fi hàn gbangba pé sáà kúkúrú kan ni yóò jẹ́ tá a bá fi wé ìgbòkègbodò ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó ṣáájú rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́