ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jà
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 25. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ mìíràn tó jáde wá? (b) Kí ni ìwo méjì tí ẹranko ẹhànnà tuntun yìí ní àti jíjáde tó jáde wá látinú ilẹ̀ ayé fi hàn?

      25 Ẹranko ẹhànnà míì ló wá jáde wá báyìí. Jòhánù ròyìn pé: “Mo sì rí ẹranko ẹhànnà mìíràn tí ń gòkè bọ̀ láti inú ilẹ̀ ayé, ó sì ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́ àgùntàn, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ bíi dírágónì. Ó sì ń lo gbogbo ọlá àṣẹ ẹranko ẹhànnà àkọ́kọ́ lójú rẹ̀. Ó sì ń mú kí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ jọ́sìn ẹranko ẹhànnà àkọ́kọ́ náà, èyí tí ọgbẹ́ ikú rẹ̀ sàn. Ó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ńláǹlà, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò tilẹ̀ mú kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé lójú aráyé.” (Ìṣípayá 13:11-13) Ẹranko ẹhànnà yìí ní ìwo méjì, tó fi hàn pé ìjọba alágbára méjì ló para pọ̀. Jòhánù sì sọ pé látinú ilẹ̀ ayé ló ti jáde wá, kì í ṣe látinú òkun. Èyí túmọ̀ sí pé ó wá látinú ètò àwọn nǹkan ti Sátánì tó ti fìdí múlẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ó ní láti jẹ́ ìjọba alágbára kan, tó ti wà tẹ́lẹ̀, tó wá ń kó ipa pàtàkì ní ọjọ́ Olúwa.

  • Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jà
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 27. (a) Kí ni mímú tí ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà mú kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá látọ̀run fi hàn nípa ìwà rẹ̀? (b) Ojú wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo alábàádọ́gba ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà lóde òní?

      27 Ẹranko ẹhànnà oníwo méjì yìí ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ńláńlá, kódà ó ń mú kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run. (Fi wé Mátíù 7:21-23.) Àmì tá a sọ gbẹ̀yìn yìí rán wa létí Èlíjà, wòlíì Ọlọ́run ìgbàanì tó bá àwọn wòlíì Báálì wọ̀jà. Nígbà tó ní kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá látọ̀run ní orúkọ Jèhófà tó sì rí bẹ́ẹ̀, èyí fi hàn kedere pé wòlíì tòótọ́ ni, àti pé, wòlíì èké làwọn wòlíì Báálì. (1 Àwọn Ọba 18:21-40) Bíi tàwọn wòlíì Báálì, ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà gbà pé òun ní ẹ̀rí tó pọ̀ tó láti jẹ́ wòlíì. (Ìṣípayá 13:14, 15; 19:20) Họ́wù, ó sọ pé òun ti rẹ́yìn ẹgbẹ́ ogun olubi nínú ogun àgbáyé méjèèjì, ó sì ṣẹ́gun ohun tá a mọ̀ sí ìjọba Kọ́múníìsì tí kò náání Ọlọ́run! Ó dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wo ohun tí ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà dúró fún lóde òní gẹ́gẹ́ bí ohun tó máa sọ àwọn èèyàn dòmìnira tó sì máa fún wọn ní àwọn ohun ìní tara tó dára.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́