-
Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jàÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
32. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ọ̀nà tí Sátánì gbà ń darí apá tó jẹ́ ti ìṣèlú lára ètò rẹ̀ tó ṣeé fojú rí kó lè kó ìyà jẹ àwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin Ọlọ́run?
32 Jòhánù ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí bí Sátánì ṣe ń darí àwọn apá tó jẹ́ ti ìṣèlú nínú ètò rẹ̀ tó ṣeé fojú rí kó lè fi baríbakú ìyà jẹ àwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ó ń bá àpèjúwe “ẹranko ẹhànnà náà” nìṣó báyìí pé: “Ó sì ṣe é ní ọ̀ranyàn fún gbogbo ènìyàn, ẹni kékeré àti ẹni ńlá, àti ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, àti òmìnira àti ẹrú, pé kí wọ́n fún àwọn wọ̀nyí ní àmì kan ní ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí ní iwájú orí wọn, àti pé kí ẹnì kankan má lè rà tàbí tà àyàfi ẹni tí ó bá ní àmì náà, orúkọ ẹranko ẹhànnà náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀. Níhìn-ín ni ibi tí ọgbọ́n ti wọlé: Kí ẹni tí ó ní làákàyè gbéṣirò lé nọ́ńbà ẹranko ẹhànnà náà, nítorí pé nọ́ńbà ènìyàn ni; nọ́ńbà rẹ̀ sì ni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà, ẹẹ́wàá mẹ́fà, àti ẹyọ mẹ́fà.”—Ìṣípayá 13:16-18.
-
-
Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jàÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
35. Kí ló túmọ̀ sí láti gba àmì orúkọ ẹranko ẹhànnà náà sí iwájú orí tàbí sí ọwọ́ ọ̀tún?
35 Kí ló túmọ̀ sí láti gba àmì orúkọ ẹranko ẹhànnà náà sí iwájú orí tàbí sí ọwọ́ ọ̀tún? Nígbà tí Jèhófà fún Ísírẹ́lì ní Òfin, ó sọ fún wọn pé: “Kí ẹ . . . fi ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí ọkàn-àyà yín àti ọkàn yín, kí ẹ sì dè wọ́n gẹ́gẹ́ bí àmì mọ́ ọwọ́ yín, wọn yóò sì jẹ́ ọ̀já ìgbàjú láàárín àwọn ojú yín.” (Diutarónómì 11:18) Èyí túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti máa fiyè sí Òfin náà nígbà gbogbo, kí ó bàa lè máa nípa lórí gbogbo ìṣesí àti ìrònú wọn. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ẹni àmì òróró ni a sọ pé wọ́n ní orúkọ Baba àti ti Jésù tí a kọ sí iwájú orí wọn. Èyí fi hàn pé wọ́n jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. (Ìṣípayá 14:1) Sátánì náà ṣe àfarawé, ó lo àmì ẹlẹ́mìí èṣù ti ẹranko ẹhànnà náà. Ó wá ń sọ ọ́ di dandan fún ẹnikẹ́ni tó bá ń lọ́wọ́ nínú ètò káràkátà ojoojúmọ́ láti máa ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tí ẹranko ẹhànnà náà ń gbà ṣe é, àpẹẹrẹ kan ni ti ṣíṣayẹyẹ ọdún. Ó ń retí pé kí wọ́n jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà, kí wọ́n jẹ́ kó máa darí ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n bàa lè gba àmì rẹ̀.
36. Ìṣòro wo làwọn tí wọ́n kọ̀ láti gba àmì ẹranko ẹhànnà náà ní?
36 Àwọn tí wọ́n kọ̀ láti gba àmì ẹranko ẹhànnà náà ń ní ìṣòro nígbà gbogbo. Bí àpẹẹrẹ, bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ọdún 1930, àìmọye ìgbà làwọn kan tí fojú ba ilé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn èèyànkéèyàn ti ṣe àwọn míì léṣe, nígbà táwọn míì fojú winá inúnibíni. Láwọn orílẹ̀-èdè ìjọba oníkùmọ̀, wọ́n sọ àwọn míì sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, ọ̀pọ̀ lára wọn sì kú sọ́hùn-ún. Látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, àìmọye ọ̀dọ́kùnrin ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ, wọ́n dá àwọn kan lóró, wọ́n pa àwọn míì, nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kò ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni láti rà tàbí kí wọ́n tà; kò tiẹ̀ ṣeé ṣe fáwọn kan láti ní dúkìá tara wọn; wọ́n fipá bá àwọn mìíràn lò pọ̀, wọ́n pa àwọn míì, wọ́n sì lé àwọn míì kúrò ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn. Kí nìdí? Nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ra káàdì ẹgbẹ́ ìṣèlú.d—Jòhánù 17:16.
37, 38. (a) Kí nìdí tí ayé fi jẹ́ ibi tó ṣòro fáwọn tí wọ́n kọ̀ láti gba àmì ẹranko ẹhànnà náà? (b) Àwọn wo ni wọn ń pa ìwà títọ́ mọ́, kí ni wọ́n sì ti pinnu láti ṣe?
37 Ní àwọn ibì kan lórí ilẹ̀ ayé, ìsìn ti kó wọ àwọn èèyàn lórí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ẹnikẹ́ni tó bá mú ìdúró rẹ̀ fún òtítọ́ Bíbélì ni ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ máa ń ta nù. Ó gba pé kéèyàn nígbàgbọ́ tó lágbára láti lè fara dà á. (Mátíù 10:36-38; 17:22) Nínú ayé tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ti ń lé ọrọ̀ yìí, tí ìwà àìṣòótọ́ sì gbòde kan, Kristẹni tòótọ́ ní láti fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kó sì dá a lójú pé Jèhófà ò ní pa òun tì bóun ò bá ṣíwọ́ láti máa ṣe ohun tó tọ́. (Sáàmù 11:7; Hébérù 13:18) Nínú ayé tí ìṣekúṣe ti gbòde yìí, ó gba pé kí wọ́n dúró gbọn-in ti ìpinnu wọn láti wà ní mímọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn dókítà àtàwọn olùtọ́jú aláìsàn máa ń yọ àwọn Kristẹni tí wọ́n dùbúlẹ̀ àìsàn lẹ́nu kí wọ́n lè rú òfin Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀; àwọn Kristẹni wọ̀nyí sì máa ń kọ̀ jálẹ̀ bí ilé ẹjọ́ tiẹ̀ pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ohun tó lòdì sí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (Ìṣe 15:28, 29; 1 Pétérù 4:3, 4) Àti pé láwọn àkókò tí àìníṣẹ́lọ́wọ́ ń ga sí i yìí, ó túbọ̀ ń ṣòro fún Kristẹni tòótọ́ láti kọ iṣẹ́ tó máa mú kó ṣe ohun tó lòdì sí ìwà títọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.—Míkà 4:3, 5.
38 Kò sírọ́ ńbẹ̀, ayé jẹ́ ibi tó ṣòro fáwọn tí kò gba àmì ẹranko ẹhànnà náà. Àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ń jẹ́ ká rí ọwọ́ agbára Jèhófà àti bó ṣe ń fìbùkún rẹ̀ sórí àwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin náà, tó fi mọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà tí wọ́n ń pa ìwà títọ́ mọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn náà ní ohun tó ń tì wọ́n gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n kí wọ́n bàa lè rú òfin Ọlọ́run. (Ìṣípayá 7:9) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa jákèjádò ilẹ̀ ayé máa bá a nìṣó ní gbígbé Jèhófà àti àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀ ga, bá a ṣe ń kọ̀ láti gba àmì ẹranko ẹhànnà náà.—Sáàmù 34:1-3.
-