-
Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti WáGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
2. Ṣe gbogbo èèyàn ni Bíbélì wúlò fún?
Ọlọ́run sọ pé “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn” ló máa jàǹfààní látinú ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì. (Ka Ìfihàn 14:6.) Ó sì rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Torí pé nínú gbogbo ìwé tó wà láyé lóde òní, Bíbélì ló wà ní èdè tó pọ̀ jù lọ! Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ní Bíbélì lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ rí, láìka ibi tí wọ́n ń gbé sí tàbí èdè yòówù kí wọ́n máa sọ.
-
-
Ohun Tó Yẹ Ká Mọ̀ Nípa Àwọn Áńgẹ́lìGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
4. Àwọn áńgẹ́lì máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà
Àwọn áńgẹ́lì kọ́ ló ń wàásù fáwọn èèyàn ní tààràtà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń darí àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ sọ́dọ̀ àwọn tó bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Ka Ìfihàn 14:6, 7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tá a fi nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn áńgẹ́lì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
Ṣé inú ẹ dùn bó o ṣe mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì lè darí ẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
-