-
Kristi Bá Àwọn Ìjọ Sọ̀rọ̀Ilé Ìṣọ́—2003 | May 15
-
-
7, 8. Ìṣòro ńlá wo ló wà nínú ìjọ Éfésù, báwo làwa náà sì ṣe lè borí irú ipò bẹ́ẹ̀?
7 Síbẹ̀, àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù ní ìṣòro ńlá kan. Jésù sọ pé: “Mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.” Àwọn tó wà nínú ìjọ ní láti bu epo síná ìfẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ní fún Jèhófà. (Máàkù 12:28-30; Éfésù 2:4; 5:1, 2) Àwa náà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa pàdánù ìfẹ́ tá a kọ́kọ́ ní fún Ọlọ́run. (3 Jòhánù 3) Àmọ́, bí àwọn nǹkan bí ìfẹ́ fún ọrọ̀ àlùmọ́nì tàbí lílépa ìgbádùn bá lọ di ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn jù nínú ìgbésí ayé wa ńkọ́? (1 Tímótì 4:8; 6:9, 10) Nígbà náà, a ní láti gbàdúrà àtọkànwá pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà àti ìmọrírì fún gbogbo ohun tí òun àti Ọmọ rẹ̀ ti ṣe fún wa rọ́pò irú èrò ọkàn bẹ́ẹ̀.—1 Jòhánù 4:10, 16.
-
-
Kristi Bá Àwọn Ìjọ Sọ̀rọ̀Ilé Ìṣọ́—2003 | May 15
-
-
11. Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe fún wa láti fi kún ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà?
11 Àwọn ará Éfésù ti pàdánù ìfẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ní, àmọ́ bí irú ipò bẹ́ẹ̀ bá dìde nínú ìjọ kan lónìí ńkọ́? Ẹ jẹ́ kí àwa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan fi kún ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà nípa sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ tó ń gbà ṣe nǹkan. A lè fi ìmọrírì hàn fún ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn ní pípèsè ìràpadà nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. (Jòhánù 3:16; Róòmù 5:8) Nígbà tó bá yẹ, a lè mẹ́nu kan ìfẹ́ Ọlọ́run nínú àwọn ìdáhùn wa àti nínú àwọn iṣẹ́ tá a bá ní láwọn ìpàdé. A lè fi ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà hàn nípa yíyin orúkọ rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. (Sáàmù 145:10-13) Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa lè ṣe púpọ̀ láti bu epo sí iná ìfẹ́ tí ìjọ kan kọ́kọ́ ní tàbí kó fún un lókun.
-