ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìbínú Ọlọ́run Parí
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 6. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì kẹta da àwokòtò kẹta jáde, àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Jòhánù sì gbọ́ látẹnu áńgẹ́lì kan àti láti inú pẹpẹ?

      6 Bíi ti ìró kàkàkí kẹta, àwọn ìsun omi aláìníyọ̀ ni áńgẹ́lì kẹta da ìrunú Ọlọ́run tó wà nínú àwokòtò kẹta sí. “Ẹkẹta sì da àwokòtò rẹ̀ jáde sínú àwọn odò àti àwọn ìsun omi. Wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀. Mo sì gbọ́ tí áńgẹ́lì ti orí àwọn omi wí pé: ‘Ìwọ, Ẹni tí ń bẹ, tí ó sì ti wà, Ẹni ìdúróṣinṣin, jẹ́ olódodo, nítorí pé ìwọ ti ṣe ìpinnu wọ̀nyí, nítorí pé wọ́n tú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti ti àwọn wòlíì jáde, ìwọ sì ti fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu. Ó tọ́ sí wọn.’ Mo sì gbọ́ tí pẹpẹ náà wí pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ.’”—Ìṣípayá 16:4-7.

  • Ìbínú Ọlọ́run Parí
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 10. Kí ni “áńgẹ́lì ti orí àwọn omi” sọ, kí sì ni “pẹpẹ náà” jẹ́ kó túbọ̀ hàn gbangba?

      10 “Áńgẹ́lì ti orí àwọn omi,” ìyẹn áńgẹ́lì tó da ohun tó wà nínú àwokòtò yìí sínú omi, gbé Jèhófà ga lọ́lá gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ Àgbáyé, ẹni tí àwọn ìpinnu òdodo rẹ̀ pé pérépéré láìkù síbì kan. Abájọ tó fi sọ nípa ìdájọ́ yìí pé: “Ó tọ́ sí wọn.” Láìsí àní-àní, áńgẹ́lì náà fúnra rẹ̀ ti fojú rí púpọ̀ lára ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìwà ìkà tí àwọn ẹ̀kọ́ èké àti ọgbọ́n ayé burúkú yìí ti ń ṣokùnfà rẹ̀ látọjọ́ pípẹ́. Fún ìdí yìí, ó mọ̀ pé ìpinnu ìdájọ́ Jèhófà tọ́. Kódà “pẹpẹ” Ọlọ́run pàápàá sọ̀rọ̀ jáde. Nínú Ìṣípayá 6:9, 10, ọkàn àwọn tí wọ́n pa nítorí ìgbàgbọ́ wọn ni Bíbélì sọ pé ó wà ní ìsàlẹ̀ pẹpẹ yẹn. Nítorí náà “pẹpẹ náà” jẹ́ kó túbọ̀ hàn gbangba pé òdodo làwọn ìpinnu Jèhófà.a Dájúdájú, ó bá a mu rẹ́gí pé ká fi ẹ̀jẹ̀ rọ àwọn tí wọ́n ti tàjẹ̀ sílẹ̀ tí wọ́n sì ti lo ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ̀ nílòkulò, èyí tó ń ṣàpẹẹrẹ ìyà ikú tí Jèhófà máa fi jẹ wọ́n.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́