ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọ̀fọ̀ àti Ayọ̀ Nígbà Ìparun Bábílónì
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • Ẹ̀bi Ẹ̀jẹ̀ Tó Búburú Jáì

      14. Kí ni áńgẹ́lì alágbára náà sọ pé ó fà á tí ìdájọ́ Jèhófà fi le tó bẹ́ẹ̀, kí sì ni ohun tí Jésù sọ tó jọ ọ́ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé?

      14 Ní ìparí, áńgẹ́lì alágbára náà sọ ìdí tí Jèhófà fi ṣe ìdájọ́ Bábílónì Ńlá lọ́nà tó le koko bẹ́ẹ̀. Áńgẹ́lì náà wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́ àti ti gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 18:24) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ fún àwọn aṣáájú ìsìn ní Jerúsálẹ́mù pé wọn yóò jíhìn fún “gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí a ti ta sílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé . . . [bẹ̀rẹ̀] láti ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì olódodo” lọ. Bó ṣe sọ, ìran èèyàn oníwà wíwọ́ yẹn pa run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. (Mátíù 23:35-38) Lónìí, ìran èèyàn mìíràn, ìyẹn àwọn onísìn, jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ nítorí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run.

      15. Báwo ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nígbà ìjọba Násì nílẹ̀ Jámánì ṣe jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lọ́nà méjì?

      15 Nínú ìwé ọ̀gbẹ́ni Guenter Lewy tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ The Catholic Church and Nazi Germany, ó kọ̀wé pé: “Nígbà tí wọ́n ká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kò ní Bavaria ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù April ọdún [1933], Ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ètò Ẹ̀kọ́ àti Ìsìn gbé fún un, pé kó máa sọ tó bá rí ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀ya ìsìn náà tó ṣì ń ṣe ìsìn tí wọ́n kà léèwọ̀ náà.” Nípa bẹ́ẹ̀, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì pẹ̀lú jẹ̀bi títi ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́ ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́; ọrùn rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n pa wà. Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, irú bí Wilhelm Kusserow, fi hàn pé ẹ̀rù ò ba àwọn láti kú ikú ìbọn látọwọ́ àwọn àgbájọ ọmọ ogun, Hitler pinnu pé fífi ẹ̀yìn àwọn tó kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe ohun tóun fẹ́ tàgbá kò burú tó; nítorí náà, wọ́n fi ẹ̀rọ bẹ́ Wolfgang àbúrò Wilhelm lórí lọ́mọ ogún ọdún. Lákòókò yẹn kan náà, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń fún àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Jámánì tí wọ́n jẹ́ Kátólíìkì níṣìírí láti kú nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ baba wọn. Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó wà lọ́rùn ṣọ́ọ̀ṣì mà hàn kedere sí gbogbo ayé o!

      16, 17. (a) Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wo ni Jèhófà yóò kà sí Bábílónì Ńlá lọ́rùn, báwo sì ni àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì ṣe jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àwọn Júù tí wọ́n kú nínú ìpakúpa rẹpẹtẹ látọwọ́ ìjọba Násì? (b) Kí ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí ìsìn èké gbà jẹ̀bi ikú ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn nínú ọgọ́rọ̀ọ̀rún ogun tó jà lóde òní nìkan?

      16 Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé ọrùn Bábílónì Ńlá ni Jèhófà yóò ka ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ “gbogbo àwọn tí [wọ́n] ti pa lórí ilẹ̀ ayé” sí. Dájúdájú, ìyẹn ti já sí òótọ́ lóde òní. Bí àpẹẹrẹ, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ètò ìmùlẹ̀ Kátólíìkì ran Hitler lọ́wọ́ láti dé orí àlééfà ìjọba ilẹ̀ Jámánì, a jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì náà nípìn-ín nínú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ odindi mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Júù tí àwọn Násì pa nípakúpa. Síwájú sí i, lóde òní nìkan, ó ju àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rùn-ún èèyàn lọ tí wọ́n ti pa nínú ọgọ́rọ̀ọ̀rún ogun. Ṣé ìsìn èké la máa dá lẹ́bi èyí? Bẹ́ẹ̀ ni, lọ́nà méjì.

      17 Ọ̀nà kan ni pé ọ̀pọ̀ ogun tó wáyé jẹ́ nítorí àwọn aáwọ̀ ìsìn. Bí àpẹẹrẹ, ìsìn ló dá ìjà sílẹ̀ nílẹ̀ Íńdíà láàárín àwọn Mùsùlùmí àti Híńdù lọ́dún 1946 sí 1948. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀mí ló ṣòfò. Aáwọ̀ ẹ̀ya ìsìn ló sì fa ìforígbárí láàárín orílẹ̀-èdè Iraq àti Iran ní àwọn ọdún 1980, tí wọ́n sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn. Ìjà tó wáyé láàárín àwọn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ní Northern Ireland ti gbẹ̀mí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn. Nígbà tí wọ́n ṣèwádìí káàkiri nípa ọ̀rọ̀ yìí, akọ̀ròyìn C. L. Sulzberger sọ ní 1976 pé: “Ó jẹ́ ohun tó bani nínú jẹ́, pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdajì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn ogun tí wọ́n ń jà nísinsìnyí káàkiri ayé ló jẹ́ ogun ìsìn tàbí kó jẹ mọ́ aáwọ̀ àwọn ìsìn.” Bí Bábílónì Ńlá oníwàhálà sì ṣe ń ṣe látìgbà tó ti wà nìyẹn.

      18. Ọ̀nà kejì wo ni àwọn ìsìn ayé gbà jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀?

      18 Kí ni ọ̀nà kejì tí ìsìn gbà jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀? Lójú Jèhófà, àwọn ìsìn ayé jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ nítorí pé wọn kò fi ohun náà gan-an tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn lọ́nà tó fi máa dá wọn lójú. Wọn kò kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà táwọn èèyàn fi máa gbà gbọ́ pé àwọn tí ń jọ́sìn olùjọsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi kí wọ́n sì fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí. (Míkà 4:3, 5; Jòhánù 13:34, 35; Ìṣe 10:34, 35; 1 Jòhánù 3:10-12) Nítorí pé àwọn ìsìn tí wọ́n para pọ̀ di Bábílónì Ńlá kò kọ́ni ní nǹkan wọ̀nyí, àwọn ọmọ ìjọ wọn kó sínú hílàhílo ogun làwọn orílẹ̀-èdè ayé. Ẹ wo bí èyí ti hàn gbangba tó nínú ogun àgbáyé méjèèjì tó wáyé ní ọ̀rúndún ogún, tí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ tí ìsìn Kristẹni ti gbilẹ̀ tó sì yọrí sí pípa tí àwọn onísìn kan náà ń pa ara wọn! Ì bá jẹ́ pé gbogbo àwọn tí wọ́n sọ pé Kristẹni làwọn ti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì ni, ogun wọ̀nyẹn kì bá ti wáyé rárá.

      19. Ẹrù ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ lápọ̀jù wo ni Bábílónì Ńlá rù?

      19 Jèhófà ka ẹ̀bi gbogbo ìtàjẹ̀sílẹ̀ yìí sọ́rùn Bábílónì Ńlá. Ká ní àwọn aṣáájú ìsìn, pàápàá jù lọ àwọn aṣáájú ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì, bá ti kọ́ àwọn èèyàn wọn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì ni, irú ìtàjẹ̀sílẹ̀ rẹpẹtẹ bẹ́ẹ̀ kì bá tí wáyé. Nítorí náà, lọ́nà tó ṣe tààràtà tàbí lọ́nà tí kò ṣe tààràtà, Bábílónì Ńlá tí í ṣe aṣẹ́wó ńlá àti ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé gbọ́dọ̀ jíhìn fún Jèhófà, kì í ṣe nítorí “ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́” tó ti ṣe inúnibíni sí tó sì ti pa nìkan ni, àmọ́ nítorí ẹ̀jẹ̀ “gbogbo àwọn tí [wọ́n] ti pa lórí ilẹ̀ ayé.” Dájúdájú, Bábílónì Ńlá ti ru ẹrù ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ lápọ̀jù. À-kú-tún-kú ẹ̀ nígbà tí ìparun ẹ̀ ìkẹyìn bá dé!

  • Ọ̀fọ̀ àti Ayọ̀ Nígbà Ìparun Bábílónì
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 270]

      Aburú Tí Ìgbagbẹ̀rẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Fà

      Guenter Lewy kọ ìwé kan tó pe àkọlé rẹ̀ ní The Catholic Church and Nazi Germany, ó sì sọ nínú ìwé rẹ̀ náà pé: “Ká ní Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ilẹ̀ Jámánì ti ta ko ìjọba Násì látìbẹ̀rẹ̀ ni, bóyá ohun tó ṣẹlẹ̀ ì bá má ṣẹlẹ̀. Bí àtakò wọn ò tiẹ̀ borí Hitler tí kò sì dènà òbítíbitì ìwà ìkà tó hù, ì bá ti buyì kún Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì gan-an. Ká sòótọ́, ẹ̀mí tí ì bá lọ sí irú àtakò bẹ́ẹ̀ ì bá pọ̀ gan-an, àmọ́ ìyẹn ì bá jẹ́ nítorí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ká ní Hitler rí i pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè òun ò ní ti òun lẹ́yìn ni, ó ṣeé ṣe kó má gbójúgbóyà láti lọ sógun, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó kú ì bá má sì kú. . . . Nígbà tí wọ́n dá ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wọ́n ta kò ìjọba Násì lóró títí tí wọ́n fi kú ní àwọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Hitler, nígbà tí wọ́n pa àwọn ọ̀mọ̀ràn ilẹ̀ Poland nípakúpa, nígbà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà kú látàrí ṣíṣe tí wọ́n ṣe wọ́n ṣúkaṣùka nítorí pé wọ́n kà wọ́n sí Slavic Untermenschen, [ìyẹn ààbọ̀ èèyàn], nígbà tí wọ́n pa mílíọ̀nù mẹ́fà [6,000,000] èèyàn nítorí pé wọn ‘kì í ṣe ẹ̀yà Aryan,’ ńṣe làwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì ní Jámánì ń ṣètìlẹyìn fún ìjọba Násì tó hu ìwà ìkà wọ̀nyí. Póòpù tó wà ní Róòmù náà ò sọ nǹkan kan nípa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ òun ni olórí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti ẹni tó ga jù lọ lára àwọn tó ń kọ́ àwọn Kátólíìkì níwà rere.”—Ojú ìwé 320, 341.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́