ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 9/1 ojú ìwé 27-31
  • Ilé-ẹjọ́ Gíga Ti Europe Gbèjà Ẹ̀tọ́ Láti Wàásù Ní Greece

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ilé-ẹjọ́ Gíga Ti Europe Gbèjà Ẹ̀tọ́ Láti Wàásù Ní Greece
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Ipò Àtilẹ̀wá ní Ipilẹ̀ṣẹ̀
  • Ìgbẹ́jọ́ Àṣeyẹ̀wò
  • Àwọn Àríyànjiyàn Ẹjọ́ Náà
  • Ìgbẹ́jọ́ ní Strasbourg
  • Ìpinnu Náà
  • Àwọn Àbájáde Ìpinnu Náà
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 9/1 ojú ìwé 27-31

Ilé-ẹjọ́ Gíga Ti Europe Gbèjà Ẹ̀tọ́ Láti Wàásù Ní Greece

ÈÉṢE tí ọkùnrin kan tí àwọn aládùúgbò rẹ̀ ń yìn yóò fi di ẹni tí a fàṣẹ-ọba mú ju ọgọ́ta ìgbà lọ láti 1938 wá? Èéṣe tí onílé-ìtàjà aláìlábòsí yìí láti erékùṣù Krete ti Griki yóò fi di ẹni tí a mú wá síwájú àwọn ilé-ẹjọ́ Griki ní ìgbà méjìdínlógún kí ó sì sìn fún ohun tí ó ju ọdún mẹ́fà lọ nínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n? Bẹ́ẹ̀ni, èéṣe tí Minos Kokkinakis, ọkùnrin onídìílé alákíkanjú-iṣẹ́ yìí, yóò fi di ẹni tí a mú lọ kúrò lọ́dọ̀ aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ márùn-ún kí á sì rán an ní ìgbèkùn lọ sí onírúurú erékùṣù ìfìyàjẹni?

Àwọn òfin tí a fàṣẹ tẹ́wọ́gbà ní 1938 àti 1939 tí ń ka ìyíninísìnpadà léèwọ̀ ni ó fà á ní ìwọ̀n tí ó pọ̀ jùlọ. Àwọn òfin wọ̀nyí ni Ioannis Metaxas aláṣe bóofẹ́-bóokọ̀ Griki, ẹni tí ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ agbára-ìdarí Ṣọ́ọ̀ṣì Greek Orthodox gbékalẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìṣòfin yìí, láti 1938 sí 1992, 19,147 iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí a ti fàṣẹ-ọba-mú ni ó wà, àwọn ilé-ẹjọ́ sì dájọ́ ìjìyà tí àròpọ̀ rẹ̀ jẹ́ 753 ọdún, èyí tí a lo 593 ọdún nínú rẹ̀ níti gidi. Gbogbo èyí ni a ṣe nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí ní Greece, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí níbòmíràn, tẹ̀lé àwọn ìtọ́ni Jesu Kristi láti “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, . . . kí ẹ máa kọ́ wọn láti fìṣọ́ra kíyèsí ohun gbogbo” ni ó paláṣẹ.—Matteu 28:19, 20, NW.

Ṣùgbọ́n ní May 25, 1993, ìjà ńláǹlà fún òmìnira ìjọsìn ni a jà ní àjàṣẹ́gun! Ní ọjọ́ yẹn Ilé-Ẹjọ́ Europe tí ń rí sí Awọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Strasbourg, France, gbèjà ẹ̀tọ́ tí ọlọ̀tọ̀ Griki kan ní láti fi àwọn ìgbàgbọ́ rẹ̀ kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Ní pípàṣẹ bẹ́ẹ̀, ilé-ẹjọ́ gíga ti Europe yìí dá ààbò gbígbòòrò fún òmìnira tí ó lè ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìgbésí-ayé àwọn ènìyàn níbi gbogbo sílẹ̀.

Ẹ jẹ́ kí á túbọ̀ wo àwọn ìdàgbàsókè náà tímọ́tímọ́, papọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀gàn tí kìkì ọ̀kan lára àwọn ọlọ̀tọ̀ Griki yìí jìyà, tí ó wá ṣamọ̀nà sí ìpinnu ṣíṣe pàtàkì gidigidi ti ilé-ẹjọ́ yìí.

Ipò Àtilẹ̀wá ní Ipilẹ̀ṣẹ̀

Ní 1938 ọlọ̀tọ̀ yìí, Minos Kokkinakis, di ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí a ó dálẹ́bi ní ilé-ẹjọ́ lábẹ́ òfin Griki tí ó sọ ìyíninísìnpadà di ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀daràn. Láìsí àǹfààní ìgbẹ́jọ́, òun ni a rán láti lo oṣù mẹ́tàlá ní ìgbèkùn lórí erékùṣù Aegean ti Amorgos. Ní 1939 òun ni a dájọ́ ìjìyà fún lẹ́ẹ̀mejì tí a sì fi sẹ́wọ̀n fún oṣù méjì àti ààbọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ìgbà náà.

Ní 1940, Kokkinakis ni a rán lọ sí ìgbèkùn fún oṣù mẹ́fà sí erékùṣù Melos. Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, lákòókò Ogun Àgbáyé Kejì, òun ni a sọ sẹ́wọ̀n nínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n ológun ní Ateni fún iye tí ó ju oṣù méjìdínlógún lọ. Nípa àkókò yẹn, ó padà rántí pé:

“Àìsí oúnjẹ nínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n náà ń burú bògìrì síi. A di aláìlágbára tóbẹ́ẹ̀ débi pé a kò lè rìn. Bí kìí bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí láti Ateni àti àgbègbè Piraeus tí wọ́n pèsè oúnjẹ fún wa láti inú ìpèsè tí àwọn náà ń gínjẹ, à bá ti kú.” Lẹ́yìn náà, ní 1947, òun ni a tún dájọ́ ìjìyà fún lẹ́ẹ̀kan síi tí ó sì lo oṣù mẹ́rin àti ààbọ̀ mìíràn nínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n.

Ní 1949, Minos Kokkinakis ni a rán lọ sí ìgbèkùn sí erékùṣù Makrónisos, orúkọ kan tí ń mú àwòrán ẹ̀rù wá sọ́kàn àwọn Griki nítorí ọgbà-ẹ̀wọ̀n tí ó wà níbẹ̀. Lára nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí a sọ sẹ́wọ̀n nígbà náà ní Makrónisos, àwọn bí ogójì ni wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ lédè Griki náà Papyros Larousse Britannica ṣàkíyèsí pé: “Ọ̀nà ìgbàdánilóró rírorò náà, . . . àwọn ipò ìgbésí-ayé, èyí tí kò ṣètẹ́wọ́gbà fún orílẹ̀-èdè ọlọ́làjú, àti ìwà arẹninípòwálẹ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ sí àwọn ẹlẹ́wọ̀n . . . jẹ́ ìbẹ̀tẹ́lù fún ìtàn Greece.”

Kokkinakis, ẹni tí ó lo ọdún kan nínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n ní Makrónisos, ṣàpèjúwe bí ìpò nǹkan ti rí: “Àwọn ọmọ-ogun, bí àwọn mẹ́ḿbà Aṣèwádìí-gbógun-ti-àdámọ̀, yóò fìbéèrè wádìí ọ̀rọ̀ wò lọ́wọ́ ẹlẹ́wọ̀n kọ̀ọ̀kan láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. Oró tí wọ́n dáni kò ṣeé fẹsusọ. Orí ọ̀pọ̀ ẹlẹ́wọ̀n dàrú; a pa àwọn mìíràn; ọ̀pọ̀ àìmọye ni a sọ di abirùn. Ní àwọn alẹ́ bíbanilẹ́rù wọ̀nyẹn nígbà tí a ń gbọ́ igbe àti ìkérora àwọn wọnnì tí a ń dálóró, àwa yóò gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí agbo kan.”

Lẹ́yìn líla àwọn ìnira já ní Makrónisos, Kokkinakis ni a fàṣẹ-ọba-mú ní ìgbà mẹ́fà síi ní àwọn ọdún 1950 ó sì ṣe oṣù mẹ́wàá nínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n. Ní àwọn ọdún 1960 òun ni a fàṣẹ-ọba-mú ní ìgbà mẹ́rin ní àfikún tí a sì dájọ́ ìjìyà oṣù mẹ́jọ ní ọgbà-ẹ̀wọ̀n fún un. Ṣùgbọ́n rántí, Minos Kokkinakis ni ẹnìkanṣoṣo láàárín ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí a fàṣẹ-ọba-mú tí a sì fi sẹ́wọ̀n nítorí pé wọ́n bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá!

Èéṣe tí ó fi jẹ́ pé àìṣèdájọ́-òdodo tí a ṣe lòdìsí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Greece wá síwájú Ilé-Ẹjọ́ Europe tí ń rí sí Àwọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn níkẹyìn?

Ìgbẹ́jọ́ Àṣeyẹ̀wò

Ẹjọ́ náà ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní March 2, 1986. Ní ọjọ́ yẹn Minos Kokkinakis, oníṣòwò ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin tí ó ti fẹ̀yìntì nígbà náà, àti aya rẹ̀ lọ sí ilé Ìyáàfin Georgia Kyriakaki ní Sitia, Krete. Ọkọ Ìyáàfin Kyriakaki, tí ó jẹ́ aṣáájú kan ní ṣọ́ọ̀ṣì Orthodox àdúgbò, fi tó àwọn ọlọ́pàá létí. Àwọn ọlọ́pàá wá wọ́n sì fàṣẹ-ọba-mú Ọ̀gbẹ́ni àti Ìyáàfin Kokkinakis, àwọn tí a mú lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá àdúgbò lẹ́yìn náà. Níbẹ̀ ni a fipá mú wọn láti dúró sí títí di ilẹ̀-mọ́.

Kí ni ẹ̀sùn tí a fi kàn wọ́n? Ọ̀kan náà tí a fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà ní àádọ́ta ọdún ṣáájú ni, tíí ṣe, pé wọ́n ń yíninísìnpadà. Òfin-ìpilẹ̀ Griki (1975), Apá 13, sọ pé: “Ìyíninísìnpadà ni a kàléèwọ̀.” Ṣàgbéyẹ̀wò òfin Griki síwájú síi, ìpín 4, nọmba 1363/1938 àti 1672/1939, èyí tí ó sọ ìyíninísìnpadà di ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀daràn. Ó sọ pé:

“Pẹ̀lú ‘ìyíninísìnpadà’ ó túmọ̀, ní pàtàkì sí, ìgbìdánwò tààràtà tàbí tí kìí ṣe tààràtà láti yọjúràn sí àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn ẹnìkan tí ó jẹ́ ti ìgbàgbọ́ ìsìn kan pàtó . . . , pẹ̀lú èrò dídín agbára àwọn ìgbàgbọ́ náà kù, yálà nípasẹ̀ irú ìrọnilọ́kàn tàbí ìlérí ìrọnilọ́kàn tàbí ìtìlẹ́yìn ohun ti ara, tàbí nípasẹ̀ ọ̀nà màgòmágó, tàbí nípa lílo àìnírìírí, ìfọkàntánni, àìní, òye tí ó rẹlẹ̀ tàbí ànímọ́ gbígbà láìjanpata rẹ̀.”

Ilé-Ẹjọ́ Ìwà-Ọ̀daràn ní Lasithi, Krete, gbọ́ ẹjọ́ náà ní March 20, 1986, ó sì mú Ọ̀gbẹ́ni àti Ìyáàfin Kokkinakis ní ẹlẹ́bi fún ìyíninísìnpadà. Àwọn méjèèjì ní a dájọ́ oṣù mẹ́rin nínú ẹ̀wọ̀n fún. Ní dídá tọkọtaya náà lẹ́bi, ilé-ẹjọ́ náà polongo pé ẹni tí a fẹ̀sùn ọ̀ràn kàn náà ti yọjúràn “sí àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn àwọn Kristian tí wọ́n jẹ́ Orthodox . . . nípa ṣíṣàmúlò àìnírìírí, òye rírẹlẹ̀ àti ànímọ́ gbígbà láìjanpata wọn.” Ẹni tí a fẹ̀sùn ọ̀ràn kàn náà ni a fẹ̀sùn kàn síwájú síi pẹ̀lú “fífún [Ìyáàfin Kyriakaki] níṣìírí nípasẹ̀ àwọn àlàyé àfẹ̀sọ̀ṣe, jíjáfáfá kan . . . láti yí ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ ti Kristian Orthodox padà.”

Ìpinnu náà ni a pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn rẹ̀ sí Ilé-Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Krete. Ní March 17, 1987, ilé-ẹjọ́ Krete yìí dá Ìyáàfin Kokkinakis sílẹ̀ láìjẹ̀bi ṣùgbọ́n ó di ìjẹ̀bi ọkọ rẹ̀ mú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dín ìdájọ́ ìjìyà rẹ̀ kù sí oṣù mẹ́ta. Ìdájọ́ náà sọ pé Ọ̀gbẹ́ni Kokkinakis ti lo “àǹfààní àìnírìírí [Ìyáàfin Kyriakaki], òye rírẹlẹ̀ rẹ̀ àti ànímọ́ gbígbà láìjanpata rẹ̀.” Ó sọ pé Ọ̀gbẹ́ni Kokkinakis “bẹ̀rẹ̀ síí ka àyọkà jáde láti inú Ìwé Mímọ́, èyí tí ó fi ọgbọ́n ṣàlàyé kínníkínní ní ọ̀nà kan tí obìnrin tí ó jẹ́ Kristian náà, nítorí àìní ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ tí ó pọ̀ tó, kò lè gbé ìpèníjà dìde sí.”

Nínú èrò kan tí ó yàtọ̀, ọ̀kan lára àwọn adájọ́ tí ń pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kọ̀wé pé Ọ̀gbẹ́ni Kokkinakis “ni à bá ti dá sílẹ̀ láìjẹ̀bi pẹ̀lú, níwọ̀n bí kò ti sí èyíkéyìí nínú ẹ̀rí náà tí ó fihàn pé Georgia Kyriakaki . . . jẹ́ aláìnírìírí ní pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ Kristian Orthodox, pàápàá bí ó ti jẹ́ pé aya aṣáájú kan ni, tàbí jẹ́ olóye rírẹlẹ̀ ní pàtàkì tàbí alánìímọ́ gbígbà láìjanpata, débi pé ẹni tí a fẹ̀sùn ọ̀ràn kàn náà fi lè lo àǹfààní náà . . . kí ó sì [tipa báyìí] mú un di mẹ́ḿbà ẹ̀ya-ìsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.”

Ọ̀gbẹ́ni Kokkinakis pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé-Ẹjọ́ Awọ́gilépinnu-ìdájọ́, Ilé-Ẹjọ́ Gíga Jùlọ ti Greece. Ṣùgbọ́n ilé-ẹjọ́ yẹn tú ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà ká ní April 22, 1988. Nítorí náà ní August 22, 1988, Ọ̀gbẹ́ni Kokkinakis kọ̀wé sí Àjọ Europe tí ń rí sí Àwọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Ìwé-ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ ni a tẹ́wọ́gbà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ní February 21, 1992, tí a sì gbé e wọnú Ilé-Ẹjọ́ Europe tí ń rí sí Àwọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn.

Àwọn Àríyànjiyàn Ẹjọ́ Náà

Níwọ̀n bí Greece ti jẹ́ orílẹ̀-èdè mẹ́ḿbà Àjọ Europe, ó ní àìgbọ́dọ̀máṣe láti faramọ́ àwọn Ìwé-àdéhùn òfin ti Ìlànà-Ìpìlẹ̀-Àtẹ́wọ́gbà Europe lórí Àwọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Apá 9 Ìlànà-Ìpìlẹ̀-Àtẹ́wọ́gbà náà kà pé: “Olúkúlùkù ènìyàn ni ó ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira èrò, ẹ̀rí-ọkàn àti ìsìn; ẹ̀tọ́ yìí ní nínú òmìnira láti yí ìsìn tàbí ìgbàgbọ́ àti òmìnira rẹ̀ padà, yálà ní òun nìkan tàbí nínú àwùjọ pẹ̀lú àwọn mìíràn àti ní gbangba tàbí níkọ̀kọ̀, láti fi ìsìn tàbí ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn, nínú ìjọsìn, ẹ̀kọ́, ìṣe-àṣà àti àyẹyẹ.”

Nípa báyìí, ìjọba Griki di ẹni tí yóò dáhùn ọ̀ràn ní ilé-ẹjọ́ Europe. A fi ẹ̀sùn dídẹ́ṣẹ̀ ní gbangba sí ìpìlẹ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí ọlọ̀tọ̀ Griki kan ní láti ṣe ìsìn ní ìṣègbọràn sí àṣẹ Jesu Kristi, tíí ṣe, ‘láti kọ́ni kí á sì sọni di ọmọ-ẹ̀yìn’ kàn án. (Matteu 28:19, 20) Síwájú síi, aposteli Peteru sọ pé: “[Jesu] pàṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí.”—Iṣe 10:42.

Ìtẹ̀jáde 1992 ti àkànṣe ìwé-ìròyìn Human Rights Without Frontiers ní ẹṣin-ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn-ìwé náà “Greece—Ìmọ̀ọ́mọ̀ Ṣẹ̀ sí Àwọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn.” Ìwé-ìròyìn náà ṣàlàyé ní ojú-ìwé 2 pé: “Greece ni orílẹ̀-èdè kanṣoṣo ní EC [European Community (Àwùjọ Europe)] àti ní Europe tí ó ní òfin ìfìyàjẹni tí ó fààyègba owó-ìtanràn àti ìdájọ́ ìjìyà ọgbà-ẹ̀wọ̀n tí a níláti gbékarí ẹnikẹ́ni tí ń sún ẹlòmíràn láti yí ìsìn rẹ̀ padà.”

Nítorí náà lákòókò yìí ìfojúsọ́nà amárayágágá púpọ̀ wà nínú àti lẹ́yìn agbo àwọn amòfin. Kí ni a ó pinnu nípa òfin Griki náà tí ó ka fífi ìgbàgbọ́ ẹni kọ́ àwọn ẹlòmíràn léèwọ̀?

Ìgbẹ́jọ́ ní Strasbourg

Ọjọ́ ìgbẹ́jọ́ náà dé níkẹyìn—November 25, 1992. Ojú-ọjọ ṣúdùdù ní Strasbourg, òtútù sì mú rinrin, ṣùgbọ́n nínú Ilé-ẹjọ́ àwọn agbẹjọ́rò ń fi ìtara-ọkàn gbé àlàyé wọn kalẹ̀. Fún wákàtí méjì ni a fi gbé ẹ̀rí kalẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Phedon Vegleris, tí ó jẹ́ aṣojú Kokkinakis lábẹ́ òfin, sọ ojú abẹ ọ̀ràn náà níkòó, ní bíbéèrè pé: ‘Ó ha yẹ kí òfin kíkánilọ́wọ́kò yìí tí a pète láti dáàbòbo àwọn mẹ́ḿbà Ṣọ́ọ̀ṣì Orthodox Griki láti máṣe di ẹni tí a yí lọ́kàn padà sí ìgbàgbọ́ mìíràn máa báa lọ láti wà kí a sì máa fisílò bí?’

Ní fífi hàn pé ọ̀ràn náà tojú sú òun, Ọ̀jọ̀gbọ́n Vegleris béèrè pé: “Ó yà mí lẹ́nu ìdí tí òfin [ìyíninísìnpadà] yìí ṣe fi jíjẹ́ orthodox wéra pẹ̀lú ẹ̀gọ̀ àti aláìmọ̀kan. Mo sábà máa ń ṣe kàyéfì ìdí tí jíjẹ́ orthodox fi nílò ààbò kúrò lọ́wọ́ ẹ̀gọ̀, kúrò nínú àìtóótun tẹ̀mí . . . Èyí jẹ́ ohun kan tí ń dà mí láàmú ó sì ń já mi láyà.” Ní pàtàkì, aṣojú ìjọba náà kò lè pèsè àpẹẹrẹ ìgbà kan níbi tí a ti fi òfin yìí sílò fún àwọn ẹlòmíràn ju àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ.

Aṣojú Kokkinakis kejì lábẹ́ òfin, Ọ̀gbẹ́ni Panagiotis Bitsaxis, fi bi òfin ìyíninísìnpadà ṣe jẹ́ aláìbọ́gbọ́nmu tó hàn. Ó sọ pé: “Gbígbà tí a gba agbára-ìdarí tọ̀tún-tòsì jẹ́ ohun àkọ́kọ́béèrè fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀ láàárín àwọn tí ó ti dàgbà. Bí kìí bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwa yóò jẹ́ apákan àwùjọ ṣíṣàjèjì ti àwọn ẹranko tí kìí sọ̀rọ̀, tí wọn yóò ronú ṣùgbọ́n tí wọn kì yóò sọ̀rọ̀ jáde, tí wọn yóò sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n tí wọn kì yóò bánisọ̀rọ̀pọ̀, tí wọn yóò wà ṣùgbọ́n tí wọn kò ní bánigbépọ̀.”

Ọ̀gbẹ́ni Bitsaxis tún jiyàn pé “Ọ̀gbẹ́ni Kokkinakis ni a dálẹ́bi kìí ṣe ‘fún ohun kan tí ó ṣe’ ṣùgbọ́n [fún] ‘ohun tí ó jẹ́.’” Nítorí náà Ọ̀gbẹ́ni Bitsaxis fihàn pé, kìí ṣe pé a ti ṣẹ̀ sí àwọn ìlànà òmìnira ìsìn nìkan ni ṣùgbọ́n a ti fọ́ ọ túútúú pátápátá.

Àwọn aṣojú ìjọba Griki gbìyànjú láti gbé àwòrán kan tí ó yàtọ̀ sí ọ̀kan tí ó jẹ́ gidi yọ, ní sísọ pé Greece jẹ́ “paradise fún àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.”

Ìpinnu Náà

Ọjọ́ tí a ti ń reti tipẹ́ náà fún fífi ìpinnu lélẹ̀ dé—May 25, 1993. Pẹ̀lú ìbò adájọ́ mẹ́fà sí mẹ́ta, Ilé-ẹjọ́ náà pàṣẹ pé ìjọba Griki ti ṣẹ̀ sí òmìnira ìsìn Minos Kokkinakis ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin. Ní àfikun sí dídá ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ̀ ti iṣẹ́-òjíṣẹ́ ìtagbangba láre, ó san ẹ̀bùn $14,400 fún un fún ìbanilórúkọjẹ́. Ilé-ẹjọ́ náà tipa báyìí kọ àlàyé ìjọba Griki náà pé Kokkinakis àti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń lo ìkìmọ́lẹ̀ àwọn ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ẹlòmíràn jíròrò ìgbàgbọ́ wọn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin-ìpilẹ̀ Griki àti òfin ìgbà láéláé Griki lè ka ìyíninísìnpadà léèwọ̀, ilé-ẹjọ́ ní Europe pàṣẹ pé lílo òfin yìí láti ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò tọ̀nà. Kò sí ní ìbámu pẹ̀lú Apa 9 nínú Ìlànà-Ìpìlẹ̀-Àtẹ́wọ́gbà Europe Lórí Àwọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn.

Ìpinnu ilé-ẹjọ́ náà ṣàlàyé pé: “Ìsìn jẹ́ apákan ‘èrò ènìyàn tí a ń sọ dọ̀tun lemọ́lemọ́’ kò sì ṣeéṣe láti gbèrò nípa rẹ̀ pé kí á yọ ọ́ kúrò lára ohun tí a ń sọ̀rọ̀ lé lórí ní gbangba.”

Èrò mo-faramọ́-ọn láti ẹnu ọ̀kan lára àwọn adájọ́ mẹ́sàn-án náà sọ pé: “Ìyíninísìnpadà, tí a túmọ̀ sí ‘ìtara nínú títan ìgbàgbọ́ ká,’ ni a kò lè fìyà jẹni lé lórí lọ́nà bẹ́ẹ̀; ó jẹ́ ọ̀nà kan—tí ó bófinmu nínú araarẹ̀—láti ‘fi ìsìn ẹni hàn.’

“Nínú ọ̀ràn tí ó wà nílẹ̀ yìí ẹni tí ó kọ̀wé béèrè [Ọ̀gbẹ́ni Kokkinakis] ni a dálẹ́bi kìkì fún fífi irú ìtara bẹ́ẹ̀ hàn, láìsí àìbójúmu èyíkéyìí ní apá ọ̀dọ̀ rẹ̀.”

Àwọn Àbájáde Ìpinnu Náà

Ìdarí kedere ti Ilé-Ẹjọ́ Europe tí ń rí sí Àwọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ni pé kí àwọn òṣìṣẹ́-olóyè ìjọba Griki dáwọ́ àṣìlò òfin tí ó ka ìyíninísìnpadà léèwọ̀ dúró. A retí pé, Greece yóò tẹ̀lé ìdarí ilé-ẹjọ́ náà tí yóò sì ṣíwọ́ inúnibíni rẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.

Kìí ṣe ète àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti mú àwọn ìyípadà ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà wọlé tàbí láti tún ètò-ìgbékalẹ̀ òfin ṣe. Olórí àníyàn wọn ni láti wàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun ní ìgbọràn sí àṣẹ Jesu Kristi. Láti ṣe èyí, bí ó ti wù kí ó rí, ó tẹ́ wọn lọ́rùn láti ‘gbèjà kí wọ́n sì fìdí ìhìnrere múlẹ̀ lọ́nà òfin,’ gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti ṣe ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní.—Fillipi 1:7.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ ọlọ̀tọ̀ atẹ̀lé-òfin ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn ń gbé. Lékè gbogbo rẹ̀, bí ó ti wù kí ó rí, a fi dandan mú wọn láti ṣègbọràn sí òfin àtọ̀runwá gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Bibeli Mímọ́. Nítorí náà, bí òfin ilẹ̀ èyíkéyìí bá kà á léèwọ̀ fún wọn láti máṣe sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn tí a gbékarí Bibeli fún àwọn ẹlòmíràn, a fipá mú wọn láti mú ìdúró kan-náà bíi tí àwọn aposteli pé: “Àwa kò gbọ́dọ̀ má gbọ́ ti Ọlọrun ju ti ènìyàn lọ.”—Iṣe 5:29.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]

ÀWỌN INÚNIBÍNI PÚPỌ̀ SÍI TÍ ÀWỌN ÀLÙFÁÀ RUSÓKÈ

Àwọn ìgbìdánwò láti ọ̀dọ̀ àwùjọ-àlùfáà ní Greece láti ‘fi òfin dìmọ̀ wàhálà’ ti ń báa lọ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. (Orin Dafidi 94:20) Àpẹẹrẹ mìíràn lórí erékùṣù Krete ni a yanjú lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1987 bíṣọ́ọ̀bù àdúgbò kan àti àwọn àlùfáà mẹ́tàlá ti fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́sàn-án fún ìyíninísìnpadà. Níkẹyìn, ní January 24, 1992, ẹjọ́ náà wá sí ìgbẹ́jọ́.

Yàrá ilé-ẹjọ́ náà kún fọ́fọ́. Nǹkan bí àlùfáà márùndínlógójì wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹ̀sùn ìpẹ̀jọ́ náà. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ìjókòó náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti wá láti fún àwọn Kristian arákùnrin wọn níṣìírí ti gbà. Àní ṣáájú kí ìgbẹ́jọ́ déédéé tó bẹ̀rẹ̀, aṣojú-ẹni-lábẹ́ òfin fún ẹni tí a fẹ̀sùn kàn náà tọ́ka àṣìṣe ńlá ti òfin tí àwọn tí ó penilẹ́jọ́ náà ṣe.

Àbárèbábọ̀ náà ni pé àwọn wọnnì tí ìgbẹ́jọ́ náà ní nínú kórajọ fún àpérò ìkọ̀kọ̀. Lẹ́yìn ìfikùnlukùn oníwákàtí méjì àti ààbọ̀, Ààrẹ Ilé-ẹjọ́ náà kéde pé agbẹjọ́rò fún ẹni tí a fẹ̀sùn ọ̀ràn kàn náà tọ̀nà. Nítorí náà àwọn ẹ̀sùn tí a fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́sàn-án náà ni a wọ́gilé! Ó pàṣẹ pé àwọn ìwádìíwò náà ni a níláti padà bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i láti fìdí yálà ẹni tí a fẹ̀sùn kàn náà jẹ̀bi ìyíninísìnpadà tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ múlẹ̀.

Gbàrà tí a ṣe ìkéde yìí, rúdurùdu bẹ́ sílẹ̀ nínú yàrá ilé-ẹjọ́ náà. Àwọn àlùfáà bẹ̀rẹ̀ síí kígbe ìhalẹ̀mọ́ni àti èébú. Àlùfáà kan kojú agbẹjọ́rò fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan pẹ̀lú àgbélébùú kan láti fipá mú un láti jọ́sìn rẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá níláti dásí ọ̀ràn náà, àwọn Ẹlẹ́rìí náà sì ráàyè fi ibẹ̀ sílẹ̀ wọ́ọ́rọ́wọ́ níkẹyìn.

Lẹ́yìn tí a wọ́gilé ìgbẹ́jọ́ náà, apenilẹ́jọ́ ìtagbangba múra ẹ̀sùn titun kan lòdìsí àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́sàn-án náà. Ìgbẹ́jọ́ náà ni a ṣètò kí ó wáyé ní April 30, 1993, ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré ṣáájú kí Ilé-Ẹjọ́ Europe tí ń rí sí Àwọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn tó gbé ìpinnu rẹ̀ nínú ọ̀ràn Kokkinakis kalẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà ní wọ́n wà ní ìkàlẹ̀.

Àwọn agbẹjọ́rò fún àwọn mẹ́sàn-án tí a fẹ̀sùn ọ̀ràn kàn náà fi àìfaramọ́ náà lélẹ̀ pé àwọn olùfẹ̀sùnkanni àwọn Ẹlẹ́rìí náà kò sí níbẹ̀ ní ilé-ẹjọ́. Níbi tí ó ti ń kánjú láti múra ẹ̀sùn titun, olùpenilẹ́jọ́ ìtagbangba ti ṣe àṣìṣe ńlá ti ṣíṣàì fi àwọn ìwé àṣẹ láti farahàn ní ilé-ẹjọ́ ránṣẹ́ sí àwọn tí a fẹ̀sùn kàn. Nítorí náà àwọn agbẹjọ́rò fún àwọn Ẹlẹ́rìí béèrè lọ́wọ́ ilé-ẹjọ́ láti wọ́gilé ìgbẹ́jọ́ náà lórí ìpìlẹ̀ àṣìṣe ńlá yìí.

Fún ìdí yìí, àwọn adájọ́ fi yàrá ilé-ẹjọ́ náà sílẹ̀ wọ́n sì fikùnlukùn papọ̀ fún nǹkan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó wákàtí kan. Nígbà tí wọ́n padà dé, Ààrẹ Ilé-ẹjọ́ náà, ní ìdoríkodò, polongo gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́sẹ̀ẹ̀sán ní aláìmọwọ́mẹsẹ̀ nínú ọ̀ràn náà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Greece kún fún ìmoore fún àbájáde ẹjọ́ yìí, àti fún ìpinnu tí Ilé-Ẹjọ́ Europe tí ń rí sí Àwọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn fi lélẹ̀ nínú ọ̀ràn Kokkinakis ní May 25 ọdún yìí. Àdúrà wọn ni pé gẹ́gẹ́ bí àbájáde ìjagunmólú ti òfin wọ̀nyí, wọn yóò lè máa bá ìgbésí-ayé Kristian wọn lọ ‘ní jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, wọ́ọ́rọ́wọ́, àti pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà-àgbà.’—1 Timoteu 2:1, 2, NW.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Minos Kokkinakis pẹ̀lú aya rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́