-
Kò Sí Ohun Tí Ó Dára Bí Òtítọ́Ilé Ìṣọ́—1998 | January 1
-
-
Kò Sí Ohun Tí Ó Dára Bí Òtítọ́
Gẹ́gẹ́ Bí G. N. Van Der Bijl Ṣe Sọ ọ́
Ní June ọdún 1941, a fà mí lé Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ lọ́wọ́, wọ́n sì mú mi lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen nítòsí Berlin ní Germany. Ibẹ̀ ni mo wà, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n tí nọ́ńbà rẹ̀ jẹ́ 38190, títí di àkókò ìtonilọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ pa, olókìkí burúkú náà, ní April ọdún 1945. Ṣùgbọ́n kí n tó sọ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn ṣe wáyé, ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí mo ṣe di ẹlẹ́wọ̀n.
A BÍ mi ní Rotterdam ní Netherlands, kété lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ̀rẹ̀, ní ọdún 1914. Àjọ ọlọ́kọ̀ ojú irin ni bàbá mi ń bá ṣiṣẹ́, ilé kékeré tí a ń gbé sì wà nítòsí ojú irin. Nígbà tí ogun náà ń parí lọ ní ọdún 1918, mo rí ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ojú irin, tí wọ́n wà fún ìtọ́jú pàjáwìrì, tí wọ́n ń kọjá fòìfòì. Kò sí iyè méjì pé àwọn sójà tí ó ti fara gbọgbẹ́ ni wọ́n ń rù lọ sílé láti ojú ogun.
Nígbà tí mo di ọmọ ọdún 12, mo fi ilé ìwé sílẹ̀ láti wáṣẹ́ lọ. Ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, mo gba iṣẹ́ alámòójútó jíjẹ mímu nínú ọkọ̀ òkun akérò, fún ọdún mẹ́rin tí ó tẹ̀ lé e, mo ń rìnrìn àjò òkun láti Netherlands sí United States.
Nígbà tí a gúnlẹ̀ sí èbúté New York ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1939, ogun mìíràn ti ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin kan wọnú ọkọ̀ òkun wa, tí ó sì fi ìwé Government, tí ó sọ nípa ìṣàkóso òdodo lọ̀ mí, mo tẹ́wọ́ gbà á tayọ̀tayọ̀. Nígbà tí mo pa dà sí Rotterdam, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wáṣẹ́ sórí ilẹ̀, níwọ̀n bí ìgbésí ayé lórí òkun ti dà bí èyí tí kò fọkàn ẹni balẹ̀ mọ́. Ní September 1, Germany gbógun ti Poland, a sì ti àwọn orílẹ̀-èdè sínú Ogun Àgbáyé Kejì.
Kíkọ́ Òtítọ́ Bíbélì
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday kan ní March ọdún 1940, ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi kan tí ó ti gbéyàwó ni mo wà tí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi tẹ aago ẹnu ọ̀nà. Mo sọ fún un pé mo ti ní ìwé Government, mo sì béèrè nípa ọ̀run àti àwọn tí ń lọ síbẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Mo rí ìdáhùn tí ó ṣe kedere, tí ó sì bọ́gbọ́n mu gbà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí mo fi sọ fún ara mi pé, ‘Òtítọ́ náà rèé.’ Mo fún un ní àdírẹ́sì mi, mo sì ní kí ó kàn sí mi nílé mi.
Lẹ́yìn ìbẹ̀wò mẹ́ta péré, nínú èyí tí a ti jíròrò dáadáa nínú Bíbélì, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá Àwọn Ẹlẹ́rìí lọ ṣe iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé. Nígbà tí a dé ìpínlẹ̀ wa, ó fi ibi tí n ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ hàn mí, mo sì ń dá wàásù. Nígbà náà lọ́hùn-ún, bí wọ́n ṣe ń fi ojú ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun mọ iṣẹ́ ìwàásù nìyẹn. Wọ́n fún mi nímọ̀ràn pé kí n máa dúró ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ nígbàkigbà tí mo bá ń fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni, kí a má baà rí mi ní òpópónà. Ó gba ìṣọ́ra gidigidi ní àwọn àkókò tí ogun ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ yẹn.
Ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn náà, ní May 10, ọdún 1940, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Germany gbógun ti Netherlands, nígbà tí ó sì di May 29, kọmíṣọ́nnà ìjọba Reich, Seyss-Inquart, kéde pé a ti fòfin de ètò àjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwùjọ kéékèèké nìkan ni a ti ń pàdé, a sì lo ìṣọ́ra gidigidi láti máà jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ibi tí a ti ń ṣèpàdé. Ohun tí ó fún wa lókun ní pàtàkì ni ìbẹ̀wò àwọn alábòójútó arìnrìn àjò.
Fìkan-ràn-kan ni mí, nígbà tí mo fi sìgá lọ Ẹlẹ́rìí tí o ń bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́, tí mo sì rí i pé kì í mu sìgá, mo wí pé: “N kò lè fi sìgá sílẹ̀ láé!” Ṣùgbọ́n, láìpẹ́ lẹ́yìn náà, bí mo ti ń rìn lọ ní òpópónà, mo ronú pé, ‘Bí n óò bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí, mo fẹ́ jẹ́ ojúlówó Ẹlẹ́rìí.’ Nítorí náà, n kò tún mu sìgá mọ́.
Dídi Ìdúró Mú fún Òtítọ́
Ní June ọdún 1940, kò tí ì pé oṣù mẹ́ta tí mo bá Ẹlẹ́rìí yẹn pàdé lẹ́nu ọ̀nà ẹ̀gbọ́n mi, mo ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì ṣe ìrìbọmi. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ní October ọdún 1940, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Ní àkókò yẹn, a fún mi ní ẹ̀wù tí a ń pè ní jákẹ́ẹ̀tì aṣáájú ọ̀nà. Ó ní ọ̀pọ̀ àpò fún ìwé ńlá àti ìwé kékeré, ó sì ṣeé wọ̀ sábẹ́ kóòtù.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé láti ìgbà tí àwọn ará Germany ti gbàṣàkóso, ni a ti ń dọdẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kiri, tí a sì ń fàṣẹ ọba mú wọn. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan ní February ọdún 1941, mo wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí díẹ̀. Bí wọ́n ti ń kàn sí àwọn ènìyàn ní apá kan àdúgbò náà, mò ń ṣiṣẹ́ ní apá kejì láti pàdé wọn. Nígbà tí ó yá, mo lọ wo ohun tí ó ń dá wọn dúró, mo sì bá ọkùnrin kan pàdé tí ó béèrè pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ní èyíkéyìí nínú àwọn ìwé kéékèèké wọ̀nyí bí?”
Mo fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Bí ó ṣe fàṣẹ ọba mú mi nìyẹn, tí ó sì mú mi lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Wọ́n fi mí sí àhámọ́ fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́rin. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọlọ́pàá náà ṣèèyàn. Níwọ̀n bí a kò bá ti fa ẹnì kan lé Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ lọ́wọ́, a lè dá a sílẹ̀ nípa wíwulẹ̀ fọwọ́ sí ìwé ìpolongo kan pé òun kò ní pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́. Nígbà tí wọ́n ní kí n fọwọ́ sí irú ìwé ìpolongo bẹ́ẹ̀, mo fèsì pé: “Kódà bí ẹ bá fún mi ní owó rẹpẹtẹ, síbẹ̀, n kò ní fọwọ́ sí i.”
Lẹ́yìn tí wọ́n ti tì mí mọ́lé fún àkókò díẹ̀ sí i, wọ́n fà mí lé Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ lọ́wọ́. Ìgbà náà ni wọ́n mú mi lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen ní Germany.
Ìgbésí Ayé ní Sachsenhausen
Nígbà tí mo débẹ̀ ní June ọdún 1941, nǹkan bí 150 Ẹlẹ́rìí—tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọ́n jẹ́ ará Germany—ti wà ní Sachsenhausen. Wọ́n kó àwa ẹlẹ́wọ̀n tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lọ sí apá kan àgọ́ náà tí a pè ní Àdádó. Níbẹ̀, àwọn Kristẹni arákùnrin wa tọ́jú wa, wọ́n sì mú wa gbára dì fún ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, wọ́n tún kó Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn dé láti Netherlands. Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n ni kí a lọ máa dúró sí ojú kan náà, níwájú bárékè, láti aago méje òwúrọ̀ títí di aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́. Nígbà míràn, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́ fún ọ̀sẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Láìka ìwà ìdánilágara náà sí, àwọn arákùnrin tètè rí i pé ó pọn dandan láti wà létòlétò, kí a sì gba oúnjẹ tẹ̀mí sínú. Lójoojúmọ́ ni a ń yan ẹnì kan láti múra ọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì kan. Lẹ́yìn náà, ní àgbàlá tí a ń pé jọ sí, Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan yóò tọ ẹni náà lọ, yóò sì fetí sí ohun tí ó ti múra sílẹ̀. Lọ́nà kan ṣáá, a máa ń yọ́ kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọnú àgọ́ náà, a sì máa ń péjọ ní ọjọọjọ́ Sunday, tí a óò sì ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pọ̀ nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí.
Lọ́nà kan ṣáá, a yọ́ mú ẹ̀dà ìwé Children, tí a ti gbé jáde ní àpéjọpọ̀ St. Louis ní United States ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1941, wọ Sachsenhausen. Kí wọ́n má baà tètè rí ìwé náà, kí wọ́n sì run ún, a yọ ọ́ sí abala-abala, a sì pín àwọn ewé ìwé náà kiri láàárín àwọn ará kí olúkúlùkù baà lè gbà á kà.
Nígbà tí ó yá, àwọn alábòójútó àgọ́ náà fura pé a ń ṣe ìpàdé. Nítorí náà, wọ́n pín àwa tí a jẹ́ Ẹlẹ́rìí sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n sì fi wá sí bárékè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìyẹn fún wa láǹfààní gígalọ́lá láti wàásù fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòó kù, ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn ará Poland, Ukraine, àti àwọn mìíràn gba òtítọ́.
Ìjọba Nazi kò fi èrò rẹ̀ láti run tàbí pa àwọn Bibelforscher, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà, pa mọ́ rárá. Ní àbáyọrí èyí, pákáǹleke tí a mú bá wa ga. Wọ́n sọ fún wa pé àwọn lè dá wa sílẹ̀ bí a bá fọwọ́ sí ìwé ìpolongo náà pé a sẹ́ ìgbàgbọ́ wa. Àwọn ará kan bẹ̀rẹ̀ sí í wí àwíjàre pé, “Bí a bá dá mi sílẹ̀, n óò lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn díẹ̀ fọwọ́ sí i, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ará wa di ìdúró wọn mú ṣinṣin láìtàrọ̀ ìfi-nǹkan-duni, ìfiniṣẹ̀sín, àti híhùwà ìkà síni. A kò gbúròó àwọn kan lára àwọn tí wọ́n fi ìgbàgbọ́ wọn báni dọ́rẹ̀ẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n, ó dùn mọ́ni pé, àwọn mìíràn kọ́fẹ pa dà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n sì jẹ́ ògbóṣáṣá Ẹlẹ́rìí síbẹ̀.
Ìgbà gbogbo ni a máa ń fipá mú wa láti wo bí a ṣe ń fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́nà òǹrorò, irú bí i nínà wọn lẹ́gba 25. Nígbà kan, wọ́n pa àwọn ọkùnrin mẹ́rin lójú wa nípa fífokùn sí wọn lọ́rùn. Àwọn ìrírí wọ̀nyẹn nípa lórí ẹni gidigidi. Arákùnrin gíga kan, tí ó sì lẹ́wà, tí ó ń gbé ní bárékè kan náà tí mò ń gbé, sọ fún mi pé: “Kí n tó wá síhìn-ín, bí mo bá fojú kan ẹ̀jẹ̀, ojú ẹsẹ̀ ni n óò dákú. Ṣùgbọ́n ní báyìí ọkàn mi ti le.” Síbẹ̀, bí ọkàn wa tilẹ̀ le, a kì í ṣe ọ̀dájú. Mo gbọ́dọ̀ sọ pé, n kò ní ẹ̀tanú tàbí ìkórìíra sí àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí.
Lẹ́yìn bíbá kommando (ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́) kan ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀, a gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn nítorí ara gbígbóná kọjá ààlà. Dókítà ará Norway kan tí ó jẹ́ onínúure àti nọ́ọ̀sì ará Czechoslovakia kan ràn mí lọ́wọ́, ó sì dà bí ẹni pé inúure wọn ni ó gbà mí là.
Ìtonilọ́wọ̀ọ̀wọ́ Lọ Pa
Nígbà tí yóò fi di April ọdún 1945, ó ṣe kedere pé Germany kò lè rọ́wọ́ mú nínú ogun náà. Àwọn alájọṣepọ̀ ti ìwọ̀ oòrùn ń gbógun bọ̀ lọ́nà yíyára kánkán láti ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ará Soviet ń gbógun bọ̀ láti ìlà oòrùn. Kò ṣeé ṣe fún ìjọba Nazi láti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn tí ó wà ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì palẹ̀ òkú wọn mọ́ láàárín ọjọ́ díẹ̀ láìfi àmì kankan sílẹ̀. Nítorí náà, wọ́n pinnu láti pa gbogbo àwọn aláìsàn, kí wọ́n sì kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ó kù lọ sí èbúté tí ó sún mọ́ tòsí jù lọ. Wọn pinnu pé àwọn yóò kó wọn sínú ọkọ̀ òkun níbẹ̀, wọn yóò sì mú kí àwọn ọkọ̀ òkun náà rì sí agbami.
Ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ nǹkan bí 26,000 ẹlẹ́wọ̀n láti Sachsenhausen bẹ̀rẹ̀ ní alẹ́ April 20. Kí a tó fi àgọ́ náà sílẹ̀, a gbé àwọn arákùnrin wa tí ń ṣàìsàn kúrò ní ilé ìwòsàn. A gba kẹ̀kẹ́ ẹrù kan tí a óò fi gbé wọn lọ. Lápapọ̀, àwa 230 ni ó wà níbẹ̀ tí a wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Arákùnrin Arthur Winkler, tí ó ti sapá púpọ̀ nínú ìmúgbòòrò iṣẹ́ náà ní Netherlands, wà lára àwọn tí ń ṣàìsàn. Àwa Ẹlẹ́rìí ni a wà lẹ́yìn nínú ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ náà, a sì ń bá a lọ láti fún ara wa níṣìírí láti máa nìṣó.
Lákọ̀ọ́kọ́, a rìn fún wákàtí 36 láìdúró. Lórí ìrìn, oorun gbé mi lọ nítorí ipò ìnira àti àárẹ̀. Ṣùgbọ́n dídúró sẹ́yìn tàbí sísinmi kò gbọ́dọ̀ wáyé nítorí àwọn ẹ̀ṣọ́ yóò yin olùwa rẹ̀ níbọn. Ní alẹ́, orí pápá tàbí inú igbó ni a máa ń sùn. Oúnjẹ tí ó wà kò tó nǹkan tàbí kí ó má tilẹ̀ sí rárá. Nígbà tí ìyà ebi náà kò ṣeé fara dà mọ́, mo la ọṣẹ ìfọyín tí àjọ Alágbèélébùú Pupa ti Sweden fún wa.
Ní àkókò kan, nítorí àwọn ẹ̀ṣọ́ ará Germany kò mọ ibi tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Rọ́ṣíà àti ti United States wà, a wà nínú igbó fún ọjọ́ mẹ́rin. Èyí ṣe wá láǹfààní púpọ̀ nítorí pé, ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a kò tètè dé Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Lübeck láti wọnú àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n ti pète pé yóò rù wa lọ sí ibú sàréè wa. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, lẹ́yìn ọjọ́ 12, tí a sì ti rìn fún nǹkan bíi 200 kìlómítà, a dé Igbo Crivitz. Ibí kò jìnnà sí Schwerin, ìlú kan tí ó tó nǹkan bí 50 kìlómítà sí Lübeck.
Àwọn ará Soviet wà lọ́wọ́ ọ̀tún wa, àwọn ará Amẹ́ríkà sì wà lọ́wọ́ òsì wa. Bí a ti ń gbọ́ ìró ìbọn ńláńlá, tí a sì ń gbọ́ ìró ọta ìbọn àgbétèjìká tí kò dáwọ́ dúró, ni a ti mọ̀ pé a ti ń sún mọ́ ibi tí ọwọ́ ogun ti le. Jìnnìjìnnì bo àwọn ẹ̀ṣọ́ ará Germany; àwọn kan fẹsẹ̀ fẹ, àwọn mìíràn bọ́ aṣọ ológun wọn sílẹ̀, wọ́n sì kó sínú ẹ̀wù àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n bọ́ lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ó ti kú, ní ríretí pé a kò ní dá wọn mọ̀. Láàárín ìdàrúdàpọ̀ náà, àwa Ẹlẹ́rìí péjọ láti gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà.
Àwọn arákùnrin tí ń ṣe kòkáárí pinnu pé a gbọ́dọ̀ gbéra ní òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, kí a sì forí lé apá ibi tí àwọn ọmọ ogun United States wà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlàjì tí ó kú tàbí tí a pa lójú ọ̀nà lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ó bẹ̀rẹ̀ ìtonilọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ pa náà, gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí pátá ni ó là á já.
Ọmọ ogun ilẹ̀ Kánádà kan fi ọkọ̀ gbé mi dé ìlú Nijmegen, níbi tí mo mọ̀ pé ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ń gbé. Àmọ́ nígbà tí mo débẹ̀, mo gbọ́ pé ó ti kó kúrò níbẹ̀. Nítorí náà, mò ń fẹsẹ̀ rìn lọ sí Rotterdam. Ní rírìnnàkore, bí mo ti ń lọ lọ́nà, ẹnì kan fi ọkọ̀ àdáni gbé mi lọ sí ibi tí mo ń lọ tààrà.
Òtítọ́ Ti Jẹ́ Ìgbésí Ayé Mi
Ní ọjọ́ tí mo dé Rotterdam gan-an, mo tún pa dà fọwọ́ sí ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn náà, mo wà níbi tí a yàn mí sí ní ìlú Zutphen, níbi tí mo ti sìn fún ọdún kan ààbọ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Ní àkókò yẹn, mo jèrè díẹ̀ nínú okun mi pa dà. Lẹ́yìn náà, a yàn mí sípò alábòójútó àyíká, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ arìnrìn àjò. Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, a pè mí sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ní South Lansing, New York. Lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kejìlá ní ilé ẹ̀kọ́ náà ní February ọdún 1949, a yàn mí sí Belgium.
Mo ti sìn ní onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní Belgium, títí kan ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́jọ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àti ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún nínú iṣẹ́ arìnrìn àjò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká àti alábòójútó àgbègbè. Ní ọdún 1958, mo gbé Justine, ẹni tí ó di alábàákẹ́gbẹ́ mi nínú iṣẹ́ ìrìnrìn àjò, níyàwó. Wàyí o, bí mo ti ń darúgbó sí i, mo ṣì ní ayọ̀ níní àǹfààní láti sìn lọ́nà kan gẹ́gẹ́ bí adelé alábòójútó arìnrìn àjò.
Nígbà tí mo bá bojú wẹ̀yìn wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi, mo lè sọ ní tòótọ́ pé: “Kò sí ohun tí ó dára bí òtítọ́.” Àmọ́ ṣáá o, kò fìgbà gbogbo rọrùn. Mo ti rí ìjẹ́pàtàkì kíkẹ́kọ̀ọ́ láti inú àṣìṣe àti ìkù-díẹ̀-káàtó mi. Nítorí náà, nígbà tí mo bá ń bá àwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀, mo sábà máa ń sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin pẹ̀lú yóò ṣàṣìṣe tàbí kí ẹ tilẹ̀ rélànà kọjá lọ́nà búburú jáì, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe purọ́ nípa rẹ̀. Ẹ jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú àwọn òbí yín tàbí alàgbà kan, kí ẹ sì ṣe àtúnṣe tí ó yẹ.”
Ní nǹkan bí 50 ọdún tí mo ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní Belgium, mo ti láǹfààní láti rí àwọn ti mò mọ ìgbà tí wọ́n jẹ́ ọmọdé, tí wọ́n ti ń sìn bí alàgbà àti alábòójútó àyíká. Mo sì ti rí bí nǹkan bí 1,700 àwọn olùpòkìkí Ìjọba ní orílẹ̀-èdè náà ti lé ní 27,000.
Ìbéèrè mi ni pé, “Ọ̀nà kan ha wà tí ń mú ìbùkún wá nínú ìgbésí ayé ju sísin Jèhófà lọ bí?” Kò tí ì fìgbà kan sí rí, kò sí nísinsìnyí, kí yóò sì sí títí láé. Àdúrà mi ni pé kí Jèhófà máa bá a nìṣó ní títọ́ èmi àti aya mi sọ́nà, kí ó sì máa bá a nìṣó ní bíbùkún wa, kí a lè máa bá a nìṣó ní sísìn ín títí láé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti aya mi kété lẹ́yìn ìgbéyàwó wa ní ọdún 1958
-
-
“Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”Ilé Ìṣọ́—1998 | January 1
-
-
“Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
“NÍTORÍ náà ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọkùnrin àti ti ẹ̀mí mímọ́.” Bí Ìtumọ̀ Ayé Titun ṣe tú àṣẹ Jésù tí ó wà nínú Mátíù 28:19 nìyí. Ṣùgbọ́n, a ti ṣe lámèyítọ́ ọ̀nà tí a gbà tú u yìí. Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìléwọ́ kékeré ti ìsìn kan sọ pé: “Ìtumọ̀ kan ṣoṣo tí ẹsẹ Gíríìkì náà fàyè gbà ni: ‘Sọ gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn!’” Òtítọ́ ha ni èyí bí?
Ìtumọ̀ yí, “Sọ gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” fara hàn nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì, ó sì jẹ́ títú èdè Gíríìkì lọ́nà ṣangiliti. Nítorí náà, ìdí wo ni ó wà fún títú u sí, “Sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn”? Àyíká ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni. Gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà, “ẹ máa batisí wọn” tọ́ka sí àwọn ènìyàn ní kedere, kì í ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ara Germany náà, Hans Bruns, sọ pé: “[Ọ̀rọ̀] náà, ‘wọn’ kò tọ́ka sí àwọn orílẹ̀-èdè (ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà fi ìyàtọ̀ hàn kedere), bí kò ṣe sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè.”
Síwájú sí i, ó yẹ kí a gbé ọ̀nà tí a gbá mú àṣẹ Jésù ṣẹ yẹ̀ wò. Nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ní Déébè, ìlú kan ní Éṣíà Kékeré, a kà pé: “Lẹ́yìn pípolongo ìhìn rere fún ìlú ńlá yẹn àti sísọ àwọn púpọ̀ díẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n pa dà sí Lísírà àti Íkóníónì àti sí Áńtíókù.” (Ìṣe 14:21) Kíyè sí i pé kì í ṣe ìlú Déébè ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sọ di ọmọ ẹ̀yìn, bí kò ṣe díẹ̀ lára àwọn ènìyàn Déébè.
Bákan náà, ní ti ọjọ́ ìkẹyìn, ìwé Ìṣípayá kò sọ tẹ́lẹ̀ pé gbogbo orílẹ̀-èdè yóò wá sin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” ni yóò ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìṣípayá 7:9) Nípa báyìí, Ìtumọ̀ Ayé Titun fi hàn gbangba pé òun jẹ́ ìtumọ̀ tí ó ṣeé gbára lé ti ‘gbogbo Ìwé Mímọ́, tí Ọlọ́run mí sí.’—Tímótì Kejì 3:16.
-