ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 2/15 ojú ìwé 25-28
  • Mímú Ìmọ́lẹ̀ Wá Sí Awọn Ibi Jíjìnnà ni Bolivia

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mímú Ìmọ́lẹ̀ Wá Sí Awọn Ibi Jíjìnnà ni Bolivia
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Ẹ̀rí Ìdarísọ́nà Angẹli
  • Wiwaasu Ni Àárín Gbungbun Ilẹ Olóoru
  • Àìfararọ lórí awọn Odo Ilẹ-olooru
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 2/15 ojú ìwé 25-28

Mímú Ìmọ́lẹ̀ Wá Sí Awọn Ibi Jíjìnnà ni Bolivia

NI ÀRÍWÁ ati ìlà-oòrùn awọn oke giga fiofio ti Bolivia ni awọn ilẹ rírẹlẹ̀ pẹrẹsẹ ti ilẹ olóoru wà, ti o kun fun eweko. Awọn wọnyi ni a pín sọtọọtọ nipasẹ awọn odò ti ńrugùdù ti wọn ṣan kọ́lọkọ̀lọ la awọn igbo ẹgàn ati pampas [ilẹ pẹrẹsẹ ti o ni eweko ni gúúsù America] kọja. Bawo ni o ti ri lati waasu ihinrere Ijọba naa ni iru agbegbe jíjìnnà bẹ́ẹ̀?

Iwọ rò ó wò ná pe o wà ninu ọkọ oju omi nla kan, ti a gbẹ́ jade lati inu ìtì igi ti a si nfi ẹrọ ti a ṣe si ẹhin rẹ wà. Eyi ni ìrírí awọn ojiṣẹ alakooko-kikun mẹfa lati Trinidad, ilu kan ni apá-ìhà El Beni ni Bolivia. Wọn wéwèé irin-ajo kukuru yii ki wọn ba le jẹrii ni awọn ilu ti a tẹdo lẹba odo ti a kò ì tí mu “ihinrere Ijọba yii” de ọdọ wọn ri. (Matiu 24:14) Lẹhin kikọja omi mimọ gaara kan ti o lọ salalu, ọkọ wọn bẹrẹ sii kọri si ẹri tóóró kan ni ìhà Odo Mamoré.

Ẹnikan ninu awujọ naa rohin pe: “A ti fẹrẹẹ de Mamoré ki a to ri pe opin ẹri naa gbẹ. Ni sisọkalẹ kuro ninu ọkọ, a rì sinu ẹrọ̀fọ̀ ti o mù wá dé itan! Aya mi padanu awọn bata rẹ nibiti o ti ńgbìyànjú lati yọ jade. Ṣugbọn pẹlu iranlọwọ awọn ẹni ti nkọja, o ṣeeṣe lati wọ́ ọkọ oju omi wíwúwo naa jade kuro ninu àbàtà naa sori ilẹ ti o tubọ le. Lẹhin wakati meji oníṣẹ́ aṣekara, a dé Mamoré.

“Nigba naa ni a wa fi ìrọ̀rùn tukọ̀ jákè odo naa, eyi ti igbó kìjikìji ilẹ olóoru ati etídò giga wà ni ẹ̀gbẹ́ ọtun ati osi rẹ̀. Nitori dídún ẹ̀rọ agbọ́kọ̀rìn naa, awọn ìjàpá òkun titobi nla bẹ kuro lori igi ti o lefo lójú odo naa, nigba ti awọn lámùsóò [dolphin] rírẹwà ga ẹ̀hìn jade ninu omi nigbamiran. Èéfín dudu lati inu ina ti a da lẹba odo lati le awọn kòkòrò sẹhin ni o mu wa duro fun ìgbà akọkọ. Lẹhin ti a so ọkọ wa mọ́ àárín awọn ẹka igi wọ́nganwọ̀gan, a sọrọ nipa awọn ibukun Ijọba ti nbọ fun awọn ẹni bi ọrẹ. Pẹlu imọriri wọn dì ẹrù eso ati ẹyin pupọ fun wa.

“Gẹgẹbi ọjọ naa ti nkọja lọ, a tun duro ni awọn ibomiran lati gbin irúgbìn otitọ pupọ sii. Ilẹ ti ṣú nigba ti a fi maa de San Antonio. Awọn ara abule ti lọ sun. Sibẹ, gẹgẹ bi ọrọ naa ti tan kalẹ pe aworan sinima kan ni a o fi han, awọn eniyan bẹrẹsii tàn àtùpà. Ẹṣin ati kẹ̀kẹ́-ẹrù ni a so pọ lati gbe ohun-eelo wa wa sinu ilu. Ọpọlọpọ eniyan di ojúlùmọ̀ awọn Ẹlẹrii Jehofa nipa aworan sinima ati ní ojúkojú.

“Ni ọjọ ti o tẹle e a nbaa lọ lati ṣe ìbẹ̀wò si awọn ibi titun miiran. Ni etídò giga kan, awọn obinrin nfọ awọn aṣọ wọn, wọn si nwẹ ọmọ-ọwọ paapaa ninu awọn ìkarawun kàǹkà-kanka ti ijapa okun. Wọn ko tii gbọ́ awọn ihin-iṣẹ Bibeli wa ri. Ni ibi kan awọn ìṣín ẹja fò soke jade kuro ninu omi lẹgbẹẹ ọkọ oju omi naa, ọpọlọpọ si bọ sinu ọkọ. Nitori naa, lẹhin fifi aworan sinima naa hàn, a jẹ ẹja yíyan ki a to lọ sùn. Nigba ti irin ajo naa fi maa wá sopin, iwe-ìkẹ́kọ̀ọ́ pupọ ni a ti fi sode ni agbegbe jíjìnnà yii, a sì ni ìtẹ́lọ́rùn lati ran ọpọlọpọ lọwọ lati gbọ ihinrere fun igba akọkọ.”—Fiwe Roomu 15:20, 21.

Ẹ̀rí Ìdarísọ́nà Angẹli

Nisinsinyi fi ara rẹ si ipo ẹni ti a ran niṣẹ lati wa ẹnikan ri ninu ilu ti o ni eniyan 12,000 ninu, ti iwọ nbẹwo fun igba akọkọ. Iwọ ko mọ nkankan nipa rẹ àyàfi orukọ rẹ̀. Iyẹn ni ìpèníjà ti o dojukọ awọn ojiṣẹ alakooko-kikun meji ti wọn dé si Guayaramerín pẹlu ireti lati ri ẹnikan ti o ti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tẹlẹri ti o si ti lọ si awọn ipade ni ilu miiran ṣugbọn ti o ti ṣi lọ si ilu yii. Lẹhin ti wọn ríbi wọ̀ sí, tọkọtaya aṣaaju-ọna naa pinnu lati rìn ìrìn gbẹ̀fẹ́ lọ si ibi ọjà, nibi ti ọpọlọpọ awọn eniyan wà yala ti wọn korajọ sidii tabili ounjẹ tabi ti wọn wulẹ̀ njumọsọrọpọ. O fẹrẹẹ jẹ́ lọgan ni ọkunrin kan wá sọdọ tọkọtaya naa o si da ijumọsọrọpọ kan silẹ. Wọn beere lọwọ rẹ bi oun ba mọ obinrin naa ti wọn nwa. “Bẹẹkọ,” ni ọkunrin naa wi, “ṣugbọn ìyá iyawo mi jẹ ọkan lara awọn Ẹlẹrii Jehofa.” Niwọnbi wọn ko ti mọ pe Ẹlẹrii eyikeyii wà ninu ilu naa, wọn ro pe o le ma yé e.

Bi o ti wu ki o ri, ni ọjọ keji wọn bẹ obinrin agbalagba yii wo, ẹni ti ko le dide lori ibusun nitori ẹsẹ rẹ ti o dá. “Emi jẹ ọkan lara awọn Ẹlẹrii Jehofa, ṣugbọn emi ko ti ṣe baptisi,” ni oun wi. Ni bibeere ẹni ti o kọ́ ọ lẹkọọ otitọ, o tọka si aworan ọmọbinrin ọmọ rẹ lara ogiri o si wipe: “Oun ni o kọ mi.” Wọn fẹrẹ le ma gba ohun ti wọn rí gbọ! O jẹ ọdọbinrin naa ti wọn ńwá! “Eeṣe ti ọkọ ọmọ rẹ ṣe sẹ́ pe oun ko mọ̀ ọ́n?” ni wọn beere.” Óò, oun ti lọkọ nisinsinyi, o si mọ kìkì orukọ ọkọ rẹ,” ni o dahun pada. Ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ naa ko si nitosi ni akoko naa, ṣugbọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ni a dari nipasẹ ifiweranṣẹ lẹhin naa. Ki ni ìyọrísí rẹ? Oun ati iya rẹ agba tẹsiwaju dé ipo ṣiṣe baptism. Ile wọn ni a lo gẹgẹbi Gbọngan Ijọba fun ijọ kan ti npọ niye sii, ati gẹgẹbi ojiṣẹ alakooko kikun kan, ọdọbinrin naa ti dari ọpọlọpọ sinu eto-ajọ Jehofa.

Wiwaasu Ni Àárín Gbungbun Ilẹ Olóoru

Lẹ́ẹ̀kan sí i, ronu pe ọkọ ofuurufu rẹ nbalẹ sori papa ìbalẹ̀sí kan ni San Joaquín, láàárín gbùngbùn ilẹ olóoru ti Bolivia. Iwọ nimọlara àìfọkàn balẹ nigba ti o bá ronu nipa àrùn abàmì kan ti o ti pa ìdá marun-un awọn eniyan ti wọn ngbe inu ilu yii ni ọdun meji sẹhin.

Tọkọtaya aṣaaju-ọna naa ti wọn dé lati Trinidad nipasẹ ọkọ ofuurufu tọ́ ẹmi ìgbanilálejò awọn eniyan naa wò. Ọkọ naa rohin pe: “Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Bibeli ti a ṣe ni akoko ìrìn ajo inu ọkọ ofuurufu wa yọrisi ìkésíni lati wá wọ̀ sí ile àdáni kan lọfẹẹ. Awọn olùgbani lálejò wa tilẹ tun pese ounjẹ fun wa ni ẹ̀dínwó, ti o mu ki o ṣeeṣe fun wa lati lo gbogbo akoko wa ninu iṣẹ́ ìwàásù wa. Laipẹ lẹhin ti a de, sọ fun wa lati wa sí bárékè ologun ni kíákíá. Nigba ti ijoye-oṣiṣẹ naa mọ pe awa kii ṣe awọn oníyìípadà tegbòtigaga ṣugbọn pe a jẹ Ẹlẹrii Jehofa, oun fi ifẹ ti o yatọ hàn o si gba Bibeli kan, ati iwe-ikẹkọọ Bibeli ati àsansílẹ̀ owó fun awọn iwe-irohin Ilé-ìṣọ́nà ati Ji! Lẹhin ìgbà naa, o fẹrẹẹ jẹ gbogbo eniyan ilu naa ni wọn tẹ́tí sílẹ̀ daradara si ìlérí Bibeli ti ìlera pipe ni ọjọ ọla ti ko jìnnà.”—Iṣipaya 21:4.

Awọn ojiṣẹ alakooko kikun mẹrin lati San Joaquín fẹ lati lọ si San Ramón, ṣugbọn ohun ìrìnnà kanṣoṣo ti o wàlárọ̀ọ́wọ́tó ni kẹ̀kẹ́ ti maluu nfà. Wọn lo awọn páálí ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ fun ìjókòó. Awọn wọnyi ni a tẹ̀ wó laipẹ nitori iṣe jàgàjàgà ati ìmì jìgìjìgì kẹkẹ ti a bò naa, ti o ni àgbá onigi giga. Ani awọn òròmọdìyẹ ti a gbé sinu kẹkẹ naa ni o han gbangba pe oju wọn ńpòòyì nitori aisan irinna ọkọ.

Lẹhin ìrìn oní jàgàjìgì fun wakati mẹwaa la abẹ́ igbo já, wọn dé ibì kan ti wọn ko ti ri ipa ọna mọ, ilẹ sì ti ńṣú. Awakọ mu awọn awujọ naa tagìrì nipa wiwipe, “o dabii ẹni pe a ti ṣìnà!” Wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹrẹsii ṣe kayeefi pe ‘bawo ni awa ṣe le duro ninu igbo ti ejo pọ ninu rẹ ti awọn ẹran elewu si wà nibẹ yii?’ nigba ti awakọ naa fi kun un pe, “Ṣugbọn ẹ má dààmú. Awọn ẹran naa ti rin irin ajo yii ri tẹlẹ.” Bẹẹ ni o ri. Láàárín wakati kan wọn jade kuro ninu igbo naa si San Ramón gan-an!

Nibi yii, pẹlu, ni wọn ti lo ọpọlọpọ ọjọ ni kikede Paradise ti nbọ fun awọn ti ko ti gbọ́ ọ rí ṣaaju. Ko si awọn Ẹlẹrii kankan ti ngbe nihin-in; sibẹ ohun kan ṣẹlẹ ti o yi iyẹn pada.

Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan ti o jẹ Katoliki ti ntẹle awọn Ẹlẹrii gẹgẹ bi wọn ti nlọ lati ile de ile. Lọna kan ṣaa wọn pade rẹ lairo tẹlẹ wọn si rii ninu ile ti o tẹle e. Bi ẹmi ọ̀rẹ́ ti o fihan ti yà wọn lẹnu, wọn fi iwe naa Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye silẹ fun un. Bi o tilẹ jẹ pe oun funraarẹ ko ni ojulowo ifẹ, o fi iwe naa fun aburo ọkọ rẹ obinrin, ẹni ti o ka ohun ti o wa ninu rẹ patapata, o kẹkọọ siwaju sii o si di Ẹlẹrii ti a baptisi lẹhin naa.

Àìfararọ lórí awọn Odo Ilẹ-olooru

Wo ara rẹ nidi itukọ ninu ọkọ oju omi nla kan ti o ńtukọ̀ la awọn omi elewu, ti ńrugùdù kọja. Awọn apata ti o farasin, awọn bèbè ẹ̀lẹ́rọ̀fọ̀, ati awọn ìtí igi, papọ pẹlu ìrọ́yípo omi nla lojiji, wulẹ̀ jẹ iwọnba diẹ lara awọn ewu naa. Awọn ẹja piranha, ẹja ògbó [electric eel], ati ẹja afìrùṣoró [stingray] pọ̀ yanturu ninu omi wọnyi. Iru eyi ni ipenija ti o dojukọ awọn ara ni Riberalta ti wọn ni iṣẹ jíjẹ́rìí fun awọn olùgbé eti odo ni agbegbe naa.

Lati de ibi àdádó wọnyi, wọn kan ọkọ oju omi ńlá kan ti a npe ni Luz de los Ríos (Ìmọ́lẹ̀ awọn Odò). Nigba ìbẹ̀wò awọn alaboojuto àgbègbè ati àyíká, a pinnu lati gbidanwo ọkọ oju omi nla naa. Gbogbo nnkan nlọ deede titi di igba ti òrùlé rẹ há sara ẹka igi titobi ti o nà jade loke. Ìṣàn omi alágbára bi ọkọ̀ oju omi ńlá náà lu igi kan ti o wo lulẹ. Gẹgẹ bi idà kan, ẹka ṣóńṣó kan ti o dá lu ẹgbẹ ọkọ naa já sinu—o fẹrẹẹ gún aya alabojuto agbegbe naa mọ ara ọkọ! Omi rọ wọle, ọkọ oju omi nla naa dojúdé, o si da awọn èrò rẹ sinu agbábú omi. Alaboojuto agbegbe ati aya rẹ ko si lúwẹ̀ẹ́! Pẹlu iranlọwọ awọn wọnni ti wọn lúwẹ̀ẹ́, wọn dori ilẹ laisewu. Ṣugbọn ọkọ oju omi ńlá naa pòórá patapata. Ni ọpọ ọjọ lẹhin naa a ri i ni ibùsọ̀ mẹta si isalẹ odo. Gbogbo awọn ohun ìní papọ pẹlu 20 páálí ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́, ti sọnu.

Awọn Ọmọ-ogun Oju-omi Bolivia ṣeranlọwọ lati mú un léfòó pada, ati lẹhin atunṣe fun ọpọlọpọ ọsẹ, ọkọ ojú omi ńlá naa ti ṣetan lẹ́ẹ̀kan sii lati pari ìrìn ajo oju omi akọkọ rẹ. Ìrìn ajo aláìfararọ naa bẹrẹ pẹlu oju ọjọ ti ko dara ati wahala ẹrọ.

Ni ibi akọkọ ti awọn ara da ọkọ duro si, awujọ Ajihinrere kan ko wọn loju, ti wọn sì ṣẹlẹya pe: “Ọkọ oju omi yin kekere ko dara fun odo yii!” Ìgbìdánwò lati fi aworan slide han nibẹ ni o foríṣánpọ́n nitori ẹrọ iná mànàmáná ti o niyọnu. Pada sori odo lẹ́ẹ̀kan sii, awọn Ẹlẹrii naa gbọ pe awọn ọkọ oju omi ńlá miiran ti wá pẹlu awọn gbohùngbohùn ni kikilọ nipa dide “awọn wolii eke.” Ni kedere, eyi jẹ iṣẹ awọn Ajihinrere naa. Bi o ti wu ki o ri, o wulẹ̀ mu ìtọpinpin awọn eniyan naa ga sii ni.

Bi o tilẹ jẹ pe ìbẹ̀wò yii fopin si ìtànkálẹ̀ eke lati ọ̀dọ̀ awọn wolii eke gidi naa, awọn ara nimọlara àìfararọ nitori wọn ṣi ni ìrìn àjò ọlọjọ 21 niwaju wọn lati de Fortaleza.

Lójú ọ̀nà, wọn jẹrii fun oloye ẹ̀yà àdádó kan; oun fetisilẹ dardara. Nipa àwíyé Bibeli ti ọkan lara awọn aṣaaju-ọna naa sọ, awujọ kan ti ọfọ ṣẹ̀ tí wọn wà ni ibi àdádó kan ni a tù ninu pẹlu ireti tootọ fun awọn òkú. Ọkunrin agbalagba kan ti o ni ìrùngbọ̀n funfun gigun sọ imọriri atọkanwa rẹ̀ jade, o si beere bi oun ṣe le san àsansílẹ̀ owó fun ìwé irohin wa fun ọdun mẹwa! Ni Fortaleza, 120 eniyan jere lati inu ìtòlẹ́sẹẹsẹ aworan slide ti Society.

Bawo ni awọn aṣaaju-ọna wọnyi ti nimọlara ìtẹ́lọ́rùn to lati mu ìmọ́lẹ̀ otitọ lọ si awọn ibi jíjìnnà! Dajudaju, ko tun si ọna aláìléwu eyikeyii ti nmu itẹlọrun wà ti a le gba lo iwalaaye ẹni ju lati ṣiṣẹsin Ẹlẹdaa iwalaaye funraarẹ, Jehofa Ọlọrun.—Saamu 63:3, 4.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

BOLIVIA

Guayaramerín

Riberalta

Fortaleza

San Joaquín

San Ramón

Trinidad

San Antonio

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́