-
Ìrẹ̀lẹ̀ Lakooko Ìrékọjá IkẹhinỌkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
-
-
Láìpẹ́ Jesu ati ẹgbẹ́ rẹ̀ dé sí ìlú naa wọn sì ba ọ̀nà wọn lọ sí ilé naa nibi ti wọn yoo ti ṣayẹyẹ Ìrékọjá. Wọn goke ajà pẹ̀tẹ́ẹ̀sì naa lọ sí iyàrá ńlá loke, nibi ti wọn ti bá gbogbo ìpèsè tí wọn ṣe fun ayẹyẹ abẹ́lé Ìrékọjá wọn. Jesu ti ńwọ̀nà fun àkókò yii, gẹgẹ bi oun ti wi: “Emi ti fẹ́ gidigidi lati jẹ ìrékọjá yii pẹlu yin kí emi tó jìyà.”
Gẹgẹ bi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, ife ọti waini mẹrin ni awọn olùkópa ninu Ìrékọjá maa ńmu. Lẹhin títẹ́wọ́gbà ohun tí ó han gbangba pe ó jẹ́ ife kẹta, Jesu dupẹ ó sì wipe: “Ẹ gba eyi kí ẹ sì gbé e lati ọ̀dọ̀ ẹnikan sí ẹlomiran laaarin araayin; nitori mo sọ fun yin, Lati isinsinyi lọ emi kì yoo tún mu lati inu èso àmújáde àjàrà títí ijọba Ọlọrun yoo fi dé.”
Lakooko kan laaarin ounjẹ naa, Jesu dìde dúró, o fi ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó mú aṣọ ìnura, o sì fi omi kún bàsíà kan. Bi o ti saba maa nri, olùgbàlejò kan yoo ri sii pe ẹsẹ̀ àlejò kan ni a wẹ̀. Ṣugbọn niwọn bi ó ti jẹ́ pe kò sí olùgbàlejò kankan níbẹ̀ ní àkókò yii, Jesu bojuto iṣẹ́-ìsìn àṣefúnni yii. Eyikeyii ninu awọn apọsiteli naa ti lè gbá àǹfààní naa mú lati ṣe e; síbẹ̀síbẹ̀, o han gbangba pe nitori ìbánidíje ti o ṣì wà láàárín wọn sibẹ, kò sí ẹni tí ó ṣe e. Nisinsinyi ojú tì wọn bí Jesu ti bẹ̀rẹ sí i fọ̀ ẹsẹ̀ wọn.
Nigba ti Jesu dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Peteru ṣàtakò: “Dajudaju iwọ kì yoo wẹ̀ ẹsẹ̀ mi láé.”
“Àyàfi bí mo bá wẹ̀ ọ, iwọ kò ní ipa kankan lọ́dọ̀ mi,” ni Jesu wi.
“Oluwa,” ni Peteru dahunpada, “kìí ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan, bikoṣe ọwọ mi ati orí mi pẹlu.”
“Ẹni tí ó ti wẹ̀,” ni Jesu dáhùn, “kò nílò ju kí ó wẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ó mọ́tónítóní lodidi. Ẹyin ọkunrin wọnyi sì mọ́tónítóní, ṣugbọn kìí ṣe gbogbo yin.” Oun sọ eyi nitori ó mọ̀ pé Judasi Isikariọtu ńwéwèé lati dà oun.
Nigba ti Jesu ti fọ̀ ẹsẹ̀ gbogbo awọn 12 naa, títíkàn ẹsẹ̀ ẹni tí yoo fi i hàn, Judasi, ó wọ̀ awọn ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ ó sì rọ̀gbọ̀kú nídìí tabili lẹẹkan sii. Lẹhin naa ó beere pe: “Ǹjẹ́ ẹyin mọ ohun tí mo ṣe sí yin? Ẹyin ńpè mi ní, ‘Olukọ,’ ati, ‘Oluwa,’ ẹyin sì sọ̀rọ̀ lọ̀nà tí ó tọ̀nà, nitori iru bẹẹ ni mo jẹ́. Nitori naa, bí emi, tí mo jẹ́ Oluwa ati Olukọ, bá fọ̀ ẹsẹ̀ yin, ó yẹ kí ẹyin pẹlu maa fọ̀ ẹsẹ̀ araayin ẹnikiini keji. Nitori mo fi àwòkọ́ṣe lélẹ̀ fun yin, pe, gan-an gẹgẹ bi bí mo ti ṣe sí yin, ni ẹyin nilati maa ṣe pẹlu. Loootọ dajudaju ni mo wi fun yin, Ẹrú kò tóbi jù ọ̀gá rẹ̀, bẹẹni ẹni tí a rán jade kò tobi ju ẹni tí ó rán an. Bí ẹyin bá mọ̀ awọn nǹkan wọnyi aláyọ̀ ni yin bí ẹ bá ńṣe wọn.”
Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ẹlẹ́wà wo ni eyi jẹ́ ninu iṣẹ́-ìsìn onírẹ̀lẹ̀! Awọn apọsiteli naa kò nilati maa wá ibi àkọ́kọ́ kiri, ní ríronú pe wọn ṣe pataki tobẹẹ tí awọn ẹlomiran fi nilati maa ṣiṣẹsin wọn nigba gbogbo. Wọn nilati tẹ̀lé apẹẹrẹ tí Jesu filélẹ̀. Eyi kìí ṣe ti fífọ̀ ẹsẹ̀ lọna àṣà. Bẹẹkọ, ṣugbọn ó jẹ ọ̀kan tí ó jẹ́ ti ìmúratán lati ṣiṣẹsin láìsí ìṣègbè, láìkà bí iṣẹ́ naa ti lè jẹ́ yẹpẹrẹ ati aláìgbádùnmọ́ni tó. Matiu 26:20, 21; Maaku 14:17, 18; Luuku 22:14-18; 7:44; Johanu 13:1-17.
-
-
Àsè Alẹ́ Ìṣe-ìrántíỌkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
-
-
Orí 114
Àsè Alẹ́ Ìṣe-ìrántí
LẸHIN tí Jesu wẹ̀ ẹsẹ̀ awọn apọsiteli rẹ̀, ó fa ọ̀rọ̀ iwe mimọ tí ó wà ní Saamu 41:9 yọ, ní wiwi pe: “Ẹni tí ó ti maa ńjẹ ounjẹ mi tẹ́lẹ̀rí ti gbé gìgìísẹ̀ rẹ̀ soke lodisi mi.” Lẹhin naa, bí ìdààmú ti bá ẹ̀mí rẹ̀, ó ṣalaye pe: “Ọ̀kan ninu yin yoo da mí.”
Awọn apọsiteli naa bẹ̀rẹ̀ sí i ní ẹ̀dùn ọkàn wọn sì ńsọ fun Jesu ọkan tẹle omiran pe: “Kìí ṣe emi, àbí emi ni bi?” Koda Judasi Isikariọtu darapọ ninu bibeere bẹẹ. Johanu, ẹni tí ó wà nílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jesu nibi tabili, fẹhinti Jesu ó sì beere pe: “Oluwa, ta ni?”
“Ọ̀kan ninu awọn mejila naa ni, ẹni tí ńtọwọ́bọ̀ inu àwo pẹlu mi,” ni Jesu dahun. “Loootọ, Ọmọkunrin eniyan ńlọ, gan-an gẹgẹ bi a ti kọwe nipa rẹ̀, ṣugbọn ègbé ní fun ọkunrin yẹn nipasẹ ẹni tí a dà Ọmọkunrin eniyan! Ìbá ti ṣe rere ju fun ọkunrin yẹn bí a kò bá ti bí i.” Lẹhin iyẹn, Satani tún wọ inú Judasi lẹkan sii, ní lílò ibi tí ó ṣisilẹ ninu ọkàn-àyà, rẹ̀ tí o ti di buburu lọna àìtọ́ fun èrè. Nigba ti ó ṣe ni òru yẹn, lọna yíyẹ ni Jesu pe Judasi ní “ọmọkunrin ìparun.”
Jesu nisinsinyi sọ fun Judasi pe: “Ohun tí iwọ ńṣe tubọ yára ṣe e kíákíá.” Kò sí eyikeyii ninu awọn apọsiteli yooku tí ó loye ohun tí Jesu ní lọ́kàn. Awọn kan ronú pe niwọn bi àpótí owó ti wà lọwọ Judasi, Jesu ńsọ fun un pe: “Ra awọn nǹkan tí a nílò fun àjọ-àríyá naa,” tabi pe kí oun lọ fi nǹkan fun awọn òtòṣì.
Lẹhin tí Judasi ti lọ́ kuro, Jesu mú àṣeyẹ, tabi ìṣè-ìrántí kan wọlé dé tí ó jẹ́ titun patapata, pẹlu awọn apọsiteli rẹ̀ olùṣòtítọ́. Ó mú ìṣù kan, ó gbà adura ìdúpẹ́, ó bù ú, o fi i fun wọn, ni wiwi pe: “Ẹ gbà, ẹ jẹ́.” Ó ṣalaye pe: “Eyi tumọsi ará mi tí a ó fi funni nítori yin. Ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi.”
Nigba ti olukuluku ti jẹ́ burẹdi naa, Jesu mú ife ọti waini kan, dajudaju ife kẹrin tí a lò ninu iṣẹ́-ìsìn Ìrékọjá. Pẹlupẹlu oun gbà adura ọpẹ́ sori rẹ̀, ó gbé e fun wọn, o sọ fun wọn pe kí wọn mu lati inú rẹ̀, ó sì wipe: “Ife yii tumọsi májẹ̀mú titun nipa agbára ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ó tú jáde nitori yin.”
Nitori naa eyi, niti tootọ, jẹ́ ìṣe-ìrántí ikú Jesu. Ní ọdọọdun ní Nisan 14 ni a ó maa ṣe àtúnṣe rẹ̀, gẹgẹ bi Jesu ti sọ, ní ìrántí rẹ̀. Yoo pè padà sinu iyè ìrántí awọn olùṣàṣeyẹ naa ohun tí Jesu ati Baba rẹ̀ ọ̀run ti ṣe lati pèsè àsálà fun ìran aráyé kuro ninu ìdálẹ́bi ikú. Fun awọn Juu tí wọn di ọmọlẹhin Kristi, ìṣàṣeyẹ naa yoo rọ́pò Ìrékọjá.
Májẹ̀mú titun naa, eyi tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nipasẹ ẹ̀jẹ́ Jesu tí a tasílẹ̀, rọ́pò májẹ̀mú Òfin ti láéláé. A ṣalárinà rẹ̀ nipasẹ Jesu Kristi laaarin awọn olùlọ́wọ́sí meji—ní ọwọ́ kan Jehofa Ọlọrun, ní ọwọ́ keji, 144,000 awọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí. Yàtọ̀ sí pípèsè fun idariji awọn ẹ̀ṣẹ̀, májẹ̀mú naa yọnda fun ìdásílẹ̀ orilẹ-ede awọn ọba-oun-alufaa kan ti ọ̀run. Matiu 26:21-29; Maaku 14:18-25; Luuku 22:19-23; Johanu 13:18-30; 17:12; 1 Kọrinti 5:7.
▪ Asọtẹlẹ Bibeli wo ni Jesu fayọ nipa alábàákẹ́gbẹ́ kan, ìfisílo wo ni oun sì ṣe nipa rẹ̀?
▪ Eeṣe tí awọn apọsiteli naa fi ní ẹ̀dùn ọkàn jíjinlẹ̀, kí sì ní ohun tí olukuluku wọn beere?
▪ Ki ni Jesu sọ fun Judasi lati ṣe, ṣugbọn bawo ni awọn apọsiteli yooku ṣe tumọ awọn itọni wọnyi?
▪ Àṣeyẹ wo ni Jesu mú wọlé lẹhin tí Judasi ti lọ kuro, ète wo ni ó sì ṣiṣẹ fun?
▪ Awọn wo ni olùlọ́wọ́sí májẹ̀mú titun naa, ki ni májẹ̀mú naa si ṣàṣeparí rẹ̀?
-
-
Ìjiyàn kan Bẹ SilẹỌkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
-
-
Orí 115
Ìjiyàn kan Bẹ Silẹ
ṢAAJU ní alẹ́ naa, Jesu kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ẹlẹ́wà kan tí ó niiṣe pẹlu iṣẹ́-ìsìn onírẹ̀lẹ̀ nipasẹ wíwẹ ẹsẹ̀ awọn apọsiteli rẹ̀. Lẹhin naa, ó nasẹ̀ Iṣe-iranti ikú rẹ̀ tí ó sunmọle. Nisinsinyi, pàápàá ní pàtàkì lójú ìwòye ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ ojiji kan wáyé. Awọn apọsiteli rẹ̀ kówọnú ìjiyàn gbígbóná kan lórí ta ni ẹni naa ninu wọn tí ó tóbi jùlọ! Ní kedere, eyi jẹ́ apákan aáwọ̀ tí ó ti ńbáa nìṣó.
Rántí pe lẹhin tí a ti pa Jesu láradà lórí òkè naa, awọn apọsiteli jiyàn lórí ta ni ẹni tí ó tóbi jùlọ láàárín wọn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jakọbu ati Johanu beere fun awọn ipò ọlá ninu Ijọba naa, eyi tí ó yọrísí àríyànjiyàn siwaju sí i láàárín awọn apọsiteli. Nisinsinyi, ní òru rẹ̀ tí ó kẹhin pẹlu wọn, ẹ wo bí inú Jesu ti gbọdọ bàjẹ́ tó lati rí wọn tí wọn tún ńṣaáwọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i! Ki ni oun ṣe?
Kàkà kí ó bá awọn apọsiteli naa wí fun ìhùwàsí wọn, lẹẹkan sí i Jesu fi pẹlu sùúrù fọ̀rọ̀wérọ̀ pẹlu wọn: “Awọn ọba awọn orílẹ̀-èdè maa ńjẹgàba lórí wọn, awọn wọnni tí wọn sì ní ọlá-àṣẹ lórí wọn ni a ńpè ní Olóore. Ṣugbọn, ẹyin kò nilati rí bí eyiini. . . . Nitori ewo ni ó tóbi jù, ẹni naa tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì tabi ẹni tí ńṣèránṣẹ́? Kìí ha ṣe ẹni naa tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì?” Lẹhin naa, ni rírán wọn létí apẹẹrẹ tirẹ̀, ó wipe: “Ṣugbọn emi wà láàárín yin gẹgẹ bi ẹni naa tí ńṣèránṣẹ́.”
Láìka àìpé wọn sí, awọn apọsiteli ti rọ̀ mọ́ Jesu lákòókò awọn àdánwò rẹ̀. Nitori naa ó wipe: “Mo sì dá majẹmu kan pẹlu yin, gan-an gẹgẹ bi Baba mi ti dá majẹmu kan pẹlu mi, fun ijọba kan.” Majẹmu ara-ẹni yii láàárín Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ adúróṣinṣin so wọn papọ̀ pẹlu rẹ̀ lati ṣàjọpín àṣẹ kábíyèsí rẹ̀. Kìkì iye tí ó láàlà ti 144,000 ni a mú wọlé nikẹhin sínú majẹmu yii fun Ijọba kan.
Bí ó tilẹ jẹ́ pe a gbé ìrètí yíyanilẹ́nu ti ṣíṣàjọpín pẹlu Kristi ninu iṣakoso Ijọba kalẹ̀ fun awọn apọsiteli naa, wọn jẹ́ aláìlera nipa tẹ̀mí nisinsinyi. “Gbogbo yin ni yoo kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹlu mi ní alẹ́ yii,” ni Jesu wí. Bí o ti wu ki o ri, ní sísọ fun Peteru pe Oun ti gbàdúrà nitori rẹ̀, Jesu rọ̀ ọ́ pe: “Kété lẹhin ti o bá ti padà, fun awọn arakunrin rẹ lókun.”
“Ẹyin ọmọ kéékèèké,” ni Jesu ṣàlàyé, “emi wà pẹlu yin fun ìgbà diẹ sí i. Ẹyin yoo wá mi; gan-an gẹgẹ bi mo sì ti wí fun awọn Juu, ‘Ibi tí emi ńlọ ẹyin kò lè wá,’ ni mo wí fun un yin pẹlu nisinsinyi. Emi ńfún yin ní òfin titun kan, pe kí ẹ nífẹ̀ẹ́ araayin; gan-an gẹgẹ bi emi ti nífẹ̀ẹ́ yin, pe kí ẹyin pẹlu nífẹ̀ẹ́ araayin. Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ̀ pe ẹyin jẹ́ ọmọ-ẹhin mi, bí ẹyin bá ní ìfẹ́ láàárín araayin.”
“Oluwa, nibo ni iwọ ńlọ?” ni Peteru beere.
“Ibi tí emi ńlọ iwọ kò lè bá mi lọ nisinsinyi,” ni Jesu fèsìpadà, “ṣugbọn iwọ yoo tọ̀ mi wá nikẹhin.”
“Oluwa, eeṣe tí emi kò fi lè bá ọ lọ nisinsinyi?” ni Peteru fẹ́ lati mọ̀. “Emi yoo fi ọkàn mi lélẹ̀ nitori rẹ.”
“Iwọ yoo ha fi ọkàn rẹ lélẹ̀ nitori mi?” ni Jesu beere. “Lóòótọ́ ni mo wí fun ọ, Iwọ lonii, bẹẹni, ní alẹ́ yii, kí àkùkọ tó kọ lẹẹmeji, àní iwọ yoo sẹ́ mi ní ìgbà mẹta.”
“Àní bí mo bá tilẹ nilati bá ọ kú,” ni Peteru ṣàtakò, “emi kì yoo sẹ́ ọ́ lọnakọna.” Nigba ti awọn apọsiteli yooku sì darapọ̀ ninu sísọ ohun kan naa, Peteru fọ́nnu pe: “Àní bí gbogbo awọn yooku kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹlu rẹ, emi kì yoo kọsẹ̀ lae!”
Ní títọ́kasí àkókò naa nigba ti oun rán awọn apọsiteli naa jáde fun ìrìn àjò iwaasu kan ní Galili láìsí àsùnwọ̀n ati àpò ounjẹ, Jesu beere pe: “Ẹ kò ṣe aláìní ohunkohun, ẹ ṣe bẹẹ bí?”
“Bẹẹkọ!” ni èsì wọn.
“Ṣugbọn nisinsinyi jẹ́ kí ẹni tí ó ní àsùnwọ̀n mú un, bẹẹ gẹ́gẹ́ sì ni àpò ounjẹ,” ni ó wí, “sì jẹ́ kí ẹni tí kò ní idà ta ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ kí ó sì ra ọ̀kan. Nitori mo sọ fun un yin pe eyi tí a kọ ni a gbọdọ ṣeparí ninu mi, eyiini ni, ‘A sì kà á kún awọn aláìlófin.’ Nitori eyiini tí ó kàn mi ńní àṣeparí.”
Jesu ntọkasi sí àkókò naa nigba ti a o kàn án mọ́gi pẹlu awọn olùṣe buburu, tabi awọn aláìlófin. Oun tún ńfihàn pẹlu pe awọn ọmọlẹhin oun yoo dojúkọ inúnibíni mímúná lẹhin ìgbà naa. “Oluwa, wò ó! idà meji niyii níhìn-ín,” ni wọn wí.
“Ó ti tó,” ni ó dáhùn. Gẹgẹ bi awa yoo ti rí, níní awọn idà naa pẹlu wọn yoo yọnda fun Jesu láìpẹ́ lati kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ ṣíṣe pàtàkì miiran. Matiu 26:31-35; Maaku 14:27-31; Luuku 22:24-38; Johanu 13:31-38, NW; Iṣipaya 14:1-3.
▪ Eeṣe tí ìjiyàn awọn apọsiteli naa fi yanilẹ́nu?
▪ Bawo ni Jesu ṣe mójútó ìjiyàn naa?
▪ Ki ni majẹmu naa tí Jesu dá pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣaṣepari rẹ̀?
▪ Òfin titun wo ni Jesu fifúnni, bawo ni ó sì ti ṣe pàtàkì tó?
▪ Ìgbọ́kànlé ara-ẹni jù wo ni Peteru fihàn, ki ni ohun tí Jesu sì sọ?
▪ Eeṣe tí awọn ìtọ́ni Jesu nipa gbígbé àsùnwọ̀n ati àpò ounjẹ fi yàtọ̀ sí iwọnyi tí oun fúnni ní iṣaaju?
-
-
Mimura Awọn Apọsiteli Silẹ fun Igberalọ Rẹ̀Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
-
-
Orí 116
Mimura Awọn Apọsiteli Silẹ fun Igberalọ Rẹ̀
OUNJẸ iṣe-iranti ti pari, ṣugbọn Jesu ati awọn apọsiteli rẹ̀ ṣì wà ní iyara oke naa sibẹsibẹ. Bi o tilẹ jẹ pe Jesu yoo lọ laipẹ, oun ṣì ní ọpọlọpọ nǹkan lati sọ sibẹsibẹ. “Ẹ maṣe jẹ ki ọkan-aya yin wahala daamu,” ni oun tù wọn ninu. “Ẹ mu igbagbọ lò ninu Ọlọrun.” Ṣugbọn o fikun un pe: “Ẹ mu igbagbọ lò ninu mi pẹlu.”
“Ninu ile Baba mi ọpọ ibujokoo ni nbẹ,” ni Jesu nbaa lọ. “Emi nba ọna mi lọ lati pese aye silẹ fun yin . . . pe nibi ti mo bá wà ki ẹyin pẹlu lè wà nibẹ. Ibi ti emi si nlọ ẹyin mọ ọna naa.” Awọn apọsiteli ko mọ̀ pe Jesu nsọrọ nipa lilọ si ọrun, nitori naa, Tọmasi beere pe: “Oluwa, awa kò mọ ibi ti iwọ nlọ. Bawo ni a o ṣe mọ ọna naa?”
“Emi ni ọna ati otitọ ati iye,” ni Jesu dahun. Bẹẹni, kiki nipasẹ titẹwọgba a ati ṣiṣafarawe ipa ọna igbesi aye rẹ̀ ni ẹnikẹni fi le wọnu ile ọrun ti Baba naa nitori pe, gẹgẹ bi Jesu ti sọ: “Ko si ẹnikan ti o wa sọdọ Baba bikoṣe nipasẹ mi.”
“Oluwa, fi Baba naa han wa,” ni Filipi beere, “o sì tó fun wa.” O han gbangba pe Filipi nfẹ ki Jesu pese ifarahan Ọlọrun ti o ṣeeri, iru eyi ti a yọnda funni ni akoko igbaani ninu awọn iran fun Mose, Elija, ati Aisaya. Ṣugbọn, niti gidi, awọn apọsiteli naa ni ohun kan ti o san lọpọlọpọ ju awọn iran ifihan iru yẹn, gẹgẹ bi Jesu ti ṣalaye: “Emi ha ti wa pẹlu ẹyin eniyan fun akoko pipẹ tobẹẹ, sibẹsibẹ, Filipi, iwọ kò sì tii wa mọ mi. Ẹni ti o ba ti ri mi ti ri Baba pẹlu.”
Jesu fi animọ Baba rẹ̀ hàn lọna pipe tobẹẹ tí gbigbe pẹlu rẹ̀ ati ṣiṣakiyesi i, nitootọ, dabi riri Baba naa niti tootọ. Sibẹsibẹ, Baba naa ga lọla ju Ọmọkunrin rẹ̀, gẹgẹ bi Jesu ṣe sọ: “Awọn ohun ti mo wi fun ẹyin eniyan ni emi ko sọ lati inu apilẹṣe ti araami.” Jesu fi gbogbo iyin ọla fun Baba rẹ ọrun lọna ti o tọna fun awọn ikọni rẹ̀.
Bawo ni o ti gbọdọ funni ni iṣiri to fun awọn apọsiteli naa lati gbọ ti Jesu nsọ fun wọn pe nisinsinyi: “Ẹni ti o ba mu igbagbọ lo ninu mi, ẹni yẹn pẹlu yoo ṣe iṣẹ ti emi ṣe; yoo sì ṣe awọn iṣẹ titobi ju iwọnyi”! Jesu kò ní in lọkan pe awọn ọmọlẹhn rẹ̀ yoo ṣe iṣẹ iyanu alagbara ju eyi ti oun ṣe lọ. Bẹẹkọ, ṣugbọn oun ní in lọkan pe wọn yoo maa ba iṣẹ ojiṣẹ naa niṣo fun akoko pipẹ pupọ sii, kari ayika titobi ju, ati fun awọn eniyan pupọ ju.
Jesu ki yoo pa awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ ti lẹhin tí ó bá lọ. “Ohun yoowu ki o jẹ ti ẹyin ba beere ni orukọ mi,” ni o ṣeleri, “Emi yoo ṣe eyi.” Siwaju sii, o wipe: “Emi yoo beere lọwọ Baba oun yoo sì fun yin ni oluranlọwọ miiran lati wà pẹlu yin titilae, ẹmi otitọ naa.” Lẹhin igba naa, lẹhin ti o ti goke re ọrun, Jesu tu ẹmi mimọ jade sori awọn ọmọ ẹhin rẹ̀, oluranlọwọ miiran yii.
Igberalọ Jesu ti sunmọle, gẹgẹ bi oun ti sọ: “Nigba diẹ sí i aye ki yoo sì ri mi mọ.” Jesu yoo jẹ́ ẹda ẹmi kan ti ẹda eniyan kankan kò lè rí. Ṣugbọn lẹẹkan sii Jesu ṣeleri fun awọn apọsiteli rẹ̀ oloootọ pe: “Ẹyin yoo ri mi, nitori emi walaaye ẹyin yoo si walaaye.” Bẹẹni, kii ṣe kiki pe Jesu yoo farahan fun wọn ni aworan irisi ẹda eniyan lẹhin ajinde rẹ̀ nikan ni ṣugbọn bi akoko ti nlọ oun yoo ji wọn dide si iwalaaye pẹlu rẹ̀ ninu ọrun gẹgẹ bi ẹda ẹmi.
Jesu nisinsinyi sọ ofin idiwọn rirọrun naa: “Ẹni naa ti o ni awọn ofin aṣẹ mi tí ó sì npa wọn mọ, ẹni naa ni ẹni ti o nifẹẹ mi. Ẹni naa ti o bá sì nifẹẹ mi ni Baba mi yoo nifẹẹ rẹ̀, emi yoo sì nifẹẹ rẹ̀ emi yoo sì fi araami han kedere fun un.”
Lori koko yii apọsiteli Judasi, ẹni naa ti a tun npe ni Tadausi, dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹnu: “Oluwa, ki ni ṣẹlẹ ti iwọ fi ngbero lati fi araàrẹ han kedere fun wa ti kii sii ṣe fun aye?”
“Bi ẹnikẹni ba nifẹẹ mi,” ni Jesu fesi, “oun yoo pa ọrọ mi mọ, Baba mi yoo sì nifẹẹ rẹ̀ . . . Ẹni ti kò nifẹẹ mi ko pa ọrọ mi mọ.” Laidabi awọn ọmọlẹhin rẹ onigbọran, aye ṣaifiyesi awọn ẹkọ Kristi. Nitori naa oun kò ṣi araarẹ̀ paya fun wọn.
Lakooko iṣẹ ojiṣẹ rẹ̀ lori ilẹ aye, Jesu ti kọ́ awọn apọsiteli rẹ̀ ni ohun pupọ. Bawo ni wọn yoo ṣe ranti gbogbo rẹ̀, paapaa niwọn bi o ti jẹ pe, koda titi di akoko isinsinyi, wọn kuna lati moye ọpọlọpọ nǹkan? Bi o ti munilayọ, Jesu ṣeleri pe: “Oluranlọwọ naa, ẹmi mimọ, eyi ti Baba yoo ran ni orukọ mi, iyẹn ni yoo kọ́ yin lẹkọọ ohun gbogbo yoo sì mu gbogbo awọn ohun ti mo sọ fun yin pada wa si iranti yin.”
Ni titu wọn ninu lẹẹkan sii, Jesu wipe: “Mo fi alaafia silẹ fun yin, mo fi alaafia mi fun yin. . . . Ẹ maṣe jẹ ki ọkan-aya yin wahala.” Loootọ, Jesu ngberalọ, ṣugbọn o ṣalaye pe: “Bi ẹyin ba nifẹẹ mi, ẹyin yoo yọ̀ pe emi nba ọna mi lọ sọdọ Baba, nitori Baba tobi ju mi lọ.”
Akoko ti o ṣẹku fun Jesu lati lò pẹlu wọn kuru. “Emi ki yoo ba yin sọrọ pupọ mọ,” ni o wi, “nitori oluṣakoso aye nbọ. Oun kò sì ni agbara kankan lori mi.” Satani Eṣu, ẹni naa ti o lagbara iṣe lati wọnu Judasi ti o sì ni agbara lori rẹ̀, ni oluṣakoso aye naa. Ṣugbọn ko si ailera ẹ̀ṣẹ̀ ninu Jesu ti Satani le ṣiṣẹ le lori lati yí i da kuro ninu ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun.
Gbigbadun Ipo Ibatan Timọtimọ Kan
Tẹle ounjẹ iṣe iranti, Jesu ti nfun awọn apọsiteli rẹ̀ ni iṣiri pẹlu ọrọ ifinukonu alaijẹ bi àṣà. Akoko ti le rekọja ọganjọ oru. Nitori naa Jesu rọ̀ wọn pe: “Ẹ dide, ẹ jẹ ki a lọ kuro nihin-in.” Bi o ti wu ki o ri, ṣaaju ki wọn to lọ, bi ifẹ Jesu ti sun un fun wọn, ó nbaa lọ ni sisọrọ, ni pipese akawe ti nsunni ṣiṣẹ kan.
“Emi ni àjàra tootọ, Baba mi sì ni oloko,” ni oun bẹrẹ. Oloko Nla naa, Jehofa Ọlọrun, gbin àjàrà afamiṣapẹẹrẹ yii nigba ti o fòróróyàn Jesu pẹlu ẹmi mimọ lasiko baptisi rẹ̀ ni igba ikore 29 C.E. Ṣugbọn Jesu nbaa lọ lati fihan pe àjàrà naa ṣapẹẹrẹ ju oun nikan lọ, ni ṣiṣalaye pe: “Olukuluku ẹka ninu mi ti kii so eso ni oun mu kuro, olukuluku eyi ti nso eso ni oun sọdi mimọ tonitoni, ki o lè so eso pupọ sii. . . . Gan-an gẹgẹ bi ẹka kò ti lè so eso fun araarẹ̀ ayafi bi o ba duro ninu àjàrà, ni ọna kan naa ẹyin kò lè ṣe bẹẹ, ayafi bi ẹyin ba duro ninu irẹpọ pẹlu mi. Emi ni ajara, ẹyin ni ẹka.”
Nigba Pẹntikọsi, ọjọ 51 lẹhin igba naa, awọn apọsiteli ati awọn miiran di awọn ẹka àjàrà naa nigba ti a tu ẹmi mimọ jade sori wọn. Ni asẹhinwa asẹhinbọ, 144,000 eniyan wa di ẹka igi eso àjàrà afamiṣapẹẹrẹ naa. Papọ pẹlu ìtí ájàrà naa, Jesu Kristi, awọn wọnyi parapọ jẹ àjàrà afamiṣapẹẹrẹ ti nmu awọn eso Ijọba Ọlọrun jade.
Jesu ṣalaye kọ́kọ́rọ́ naa fun mimu eso jade: “Ẹni ti o ba duro ninu irẹpọ pẹlu mi, ati emi ni irẹpọ pẹlu rẹ̀, ẹni yii nso eso pupọ; nitori laisi, ẹyin kò lè ṣe ohunkohun rara.” Bi o ba ṣẹlẹ pe, ẹnikan kùnà lati mu eso jade, Jesu wipe, “a sọ ọ sita gẹgẹ bi ẹka kan oun a sì gbẹ; awọn eniyan a sì kó ẹka wọnni jọ wọn a sì sọ wọn sinu ina, wọn a sì jóná.” Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, Jesu ṣeleri pe: “Bi ẹyin ba duro ninu irẹpọ pẹlu mi ti awọn ọrọ mi sì duro ninu yin, ẹ beere ohun yoowu ti ẹ fẹ yoo sì ri bẹẹ fun yin.”
Siwaju sii, Jesu sọ fun awọn apọsiteli rẹ̀ pe: “Baba mi ni a yin logo ninu eyi, pe ki ẹ maa so eso pupọ ki ẹ sì fi araayin hàn ni ọmọ ẹhin mi.” Eso naa ti Ọlọrun fẹ lati ọ̀dọ̀ awọn ẹka naa ni ki wọn maa fi awọn iwa bii ti Kristi hàn, paapaa ni pataki ifẹ. Ju bẹẹ lọ, niwọn bi Kristi ti jẹ olupokiki Ijọba Ọlọrun, eso ti a fọkanfẹ naa tun ni ninu pẹlu igbokegbodo wọn ti sisọ awọn eniyan di ọmọ ẹhin gẹgẹ bi oun ti ṣe.
“Ẹ duro ninu ifẹ mi,” ni Jesu rọ̀ wọn nisinsinyi. Sibẹsibẹ, bawo ni awọn apọsiteli rẹ̀ ṣe le ṣe bẹẹ? “Bi ẹyin ba pa awọn ofin aṣẹ mi mọ,” ni oun wi, “ẹyin yoo duro ninu ifẹ mi,” Ni bibaa lọ, Jesu ṣalaye pe: “Eyi ni ofin aṣẹ mi, pe ki ẹ nifẹẹ araayin gan-an gẹgẹ bi mo ti nifẹẹ yin. Ko si ẹnikan ti o nifẹẹ ti o tobi ju eyi, pe ẹnikan nilati fi ẹmi rẹ̀ lelẹ nitori awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.”
Ni iwọnba wakati diẹ sii, Jesu yoo fi ifẹ titayọ yii han nipa fifi iwalaaye rẹ̀ lelẹ fun ire awọn apọsiteli rẹ̀ ati pẹlu gbogbo awọn ẹlomiran ti yoo mu igbagbọ lò ninu rẹ̀. Apẹẹrẹ tirẹ̀ nilati sun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati ni ifẹ ifara ẹni rubọ kan naa fun araawọn ẹnikinni ẹnikeji. Ifẹ yii yoo fi wọn han yatọ, bi Jesu ti sọ ṣaaju: “Nipa eyi ni gbogbo eniiyan yoo fi mọ̀ pe ẹyin jẹ ọmọ ẹhin mi, bi ẹyin ba ni ifẹ laaarin araayin.”
Ni didafi awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ han, Jesu wipe: “Ọ̀rẹ́ mi ni yin bi ẹyin ba ṣe ohun ti mo palaṣẹ fun yin. Emi kò pè yin ni ẹrú mọ, nitori ẹru kò mọ ohun ti ọ̀gá rẹ̀ nṣe. Ṣugbọn mo ti pe yin ni ọ̀rẹ́, nitori ohun gbogbo ti mo ti gbọ lati ọ̀dọ̀ Baba mi ni mo ti sọ di mimọ fun yin.”
Ibatan ṣiṣeyebiye wo ni eyi jẹ́ lati ni—lati jẹ awọn ọ̀rẹ́ Jesu timọtimọ! Ṣugbọn lati maa baa lọ lati gbadun ipo ibatan yii, awọn ọmọlẹhin rẹ̀ gbọdọ “maa baa lọ lati so eso.” Bi wọn ba ṣe bẹẹ, Jesu wipe, “ohun yoowu ti ẹ ba beere lọwọ Baba ni orukọ mi oun [yoo] fi i fun yin.” Dajudaju, iyẹn jẹ ere titobilọla fun siso eso Ijọba naa! Lẹhin ti o tun rọ̀ awọn apọsiteli rẹ̀ lẹẹkan sii lati “nifẹẹ araawọn ẹnikinni ẹnikeji,” Jesu ṣalaye pe aye yoo koriira wọn. Sibẹsibẹ, o tù wọn ninu pe: “Bi aye ba koriira yin, ẹ mọ̀ pe o ti koriira mi ṣaaju ki o to koriira yin.” Tẹle eyi Jesu ṣipaya idi ti aye fi koriira awọn ọmọlẹhin rẹ̀, ni wiwi pe: “Nitori pe ẹyin kii ṣe apakan aye, ṣugbọn mo ti yan yin jade kuro ninu aye, nititori eyi ni aye ṣe koriira yin.”
Ni ṣiṣalaye siwaju sii nipa idi ti aye fi koriira wọn, Jesu nbaa lọ: “Wọn yoo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi lodisi yin nititori orukọ mi, nitori wọn kò mọ ẹni [Jehofa Ọlọrun] ti o ran mi.” Awọn iṣẹ iyanu Jesu, niti tootọ, da awọn wọnni ti wọn koriira rẹ lẹbi, gẹgẹ bi oun ti wi: “Bi emi kò bá ti ṣe awọn iṣẹ ti ẹlomiran ko ṣe ri laaarin wọn, wọn ki ba ti ni ẹ̀ṣẹ̀; ṣugbọn nisinsinyin wọn ti rii wọn sì ti koriira ati emi ati Baba mi pẹlu.” Nipa bayii, gẹgẹ bi Jesu ti sọ, iwe mimọ ni a muṣẹ: “Wọn koriira mi laini idi.”
Gẹgẹ bi oun ti ṣe ṣaaju, Jesu tù wọn ninu lẹẹkan sii nipa ṣiṣeleri lati ran oluranlọwọ naa, ẹmi mimọ, eyi ti o jẹ ipa agbekankanṣiṣẹ alagbara ti Ọlọrun. “Iyẹn ni yoo jẹrii nipa mi; ti ẹyin, ni tiyin, yoo jẹrii.”
Iṣileti Siwaju Sii Nigba Gbigberalọ
Jesu ati awọn apọsiteli ti ṣetan lati fi iyara oke naa silẹ. “Nǹkan wọnyi ni mo ti sọ fun yin, ki a ma baa mu yin kọsẹ,” ni o nbaa lọ. Lẹhin naa o funni ni ikilọ titẹwọn naa: “Wọn yoo yọ yin kuro ninu sinagọgu: ani, akoko nbọ, ti ẹnikẹni ti o ba pa yin, yoo rò pe oun nṣe isin fun Ọlọrun.”
Bi o ti han gbangba, idaamu jijinlẹ ba awọn apọsiteli naa nipa ikilọ yii. Bi o tilẹ jẹ pe Jesu ti sọ tẹlẹtẹlẹ pe aye yoo koriira wọn, oun kò tii ṣipaya ni ṣako pe a o pa wọn. “Emi ko sọ nǹkan wọnyi fun yin lati ipilẹṣẹ wa,” ni Jesu ṣalaye, “nitori ti mo wà pẹlu yin.” Sibẹ, bawo ni o ti dara to lati mu wọn gbaradi pẹlu isọfunni yii ṣaaju ki o to gberalọ!
“Ṣugbọn nisinsinyi,” Jesu nbaa lọ, “emi nlọ sọdọ ẹni ti o ran mi; ko si si ẹnikan ninu yin ti o bi mi leere pe, ‘Nibo ni iwọ nlọ?’” Ṣaaju ni irọlẹ naa, wọn ti wadii nipa ibi ti o nlọ, ṣugbọn nisinsinyi ohun ti o sọ mu wọn gbọnriri tobẹẹ ti wọn fi kuna lati beere siwaju sii nipa eyi. Gẹgẹ bi Jesu ti wi: “Ṣugbọn nitori mo sọ nǹkan wọnyi fun yin, ibinujẹ kun ọkan yin.” Awọn apọsiteli naa ní ẹdun ọkan kii ṣe kiki nitori pe wọn ti kẹkọọ pe wọn yoo jiya inunibini bibanilẹru ti a o sì pa wọn nikan ni ṣugbọn nitori pe Ọ̀gá wọn nfi wọn silẹ.
Nitori naa Jesu ṣalaye: “Anfaani ni yoo jẹ fun yin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò bá lọ, Olùtùnú ki yoo tọ yin wa: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi yoo rán an si yin.” Gẹgẹ bi eniyan kan, Jesu le wa ni kiki ibi kanṣoṣo ni akoko kan, ṣugbọn nigba ti o ba wà ni ọrun, oun lè rán oluranlọwọ naa, ẹmi mimọ Ọlọrun, si awọn ọmọlẹhin rẹ̀ nibikibi ti wọn ba le wa lori ilẹ aye. Nitori naa lilọ Jesu yoo ṣanfaani.
Ẹmi mimọ naa, ni Jesu wi, “yoo fi oye ye araye niti ẹ̀ṣẹ̀, ati niti òdodo, ati niti idajọ.” Ẹ̀ṣẹ̀ aye, ikuna rẹ̀ lati mu igbagbọ lo ninu Ọmọkunrin Ọlọrun, ni a o túfó. Ni afikun, ẹri ti o daniloju nipa òdodo Jesu ni a o fihan kedere pẹlu ami nipa igoke rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Baba. Ikuna Satani ati aye buburu rẹ̀ lati ba iwatitọ Jesu jẹ sì jẹ ẹri ami didaniloju pe oluṣakoso aye yii ni a ti dalẹjọ alaibarade.
“Mo ni ohun pupọ lati sọ fun yin,” Jesu nbaa lọ, “ṣugbọn ẹ kò lè gbà wọn nisinsinyi.” Nitori naa Jesu ṣeleri pe nigba ti oun bá tú ẹmi mimọ naa jade, eyi ti nṣe ipá agbekankanṣiṣẹ Ọlọrun, yoo tọ́ wọn sọna si liloye awọn nǹkan wọnyi ni ibamu pẹlu agbara iṣe wọn lati moye wọn.
Awọn apọsiteli naa kuna ni pato lati loye pe Jesu yoo ku ati lẹhin naa yoo farahan fun wọn lẹhin ti a ba ti jí i dide. Nitori naa wọn nbeere lọwọ araawọn ẹnikinni ẹnikeji pe: “Ki ni eyi ti o nwi fun wa yii, Nigba diẹ, ẹyin ki yoo sì ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ̀, ẹyin yoo sì ri mi: ati, Nitori ti emi nlọ sọdọ Baba?”
Jesu mọ pe wọn fẹ lati bi i ni ibeere, nitori naa o ṣalaye pe: “Loootọ, lootọ ni mo wi fun yin pe, Ẹyin yoo maa sọkun ẹ o sì maa pohunrere ẹkun, ṣugbọn awọn araye yoo maa yọ̀: inu yin yoo sì bajẹ, ṣugbọn ibinujẹ yin ni yoo sì di ayọ.” Ni ọsan ọjọ ti o tẹle e, nigba ti a pa Jesu, awọn aṣaaju isin aye yọ, ṣugbọn awọn ọmọ ẹhin banujẹ. Ibanujẹ wọn yipada di ayọ̀, bi o ti wu ki o ri, nigba ti a ji Jesu dide! Ayọ̀ wọn sì nbaa lọ nigba ti o fun wọn ni agbara ni Pẹntikọsi lati di awọn ẹlẹrii rẹ̀ nipa titu ẹmi mimọ Ọlọrun jade sori wọn!
Ni ṣiṣefiwera ipo awọn ọmọ-ẹhin naa pẹlu ti obinrin kan lakooko ìrọbí, Jesu sọ pe: “Nigba ti obinrin ba nrọbi, a ni ibinujẹ, nitori ti wakati rẹ̀ de.” Ṣugbọn Jesu sọ pe obinrin naa kii ranti ipọnju rẹ̀ lẹhin ti o ba ti bi ọmọ rẹ̀, ni sisọ pe: “Nitori naa ẹyin ni ibinujẹ nisinsinyi: ṣugbọn emi yoo tún ri yin, [nigba ti mo ba jinde] ọkan yin yoo sì yọ̀, ko sì sí ẹni ti yoo gba ayọ yin lọwọ yin.”
Titi di akoko yii, awọn apọsiteli kò tii beere fun ohunkohun ni orukọ Jesu. Ṣugbọn oun sọ nisinsinyi pe: “Ohunkohun ti ẹyin ba beere lọwọ Baba ni orukọ mi, oun yoo fifun yin. . . . Nitori ti Baba tikaraarẹ fẹran yin, nitori ti ẹyin ti fẹran mi, ẹ sì ti gbagbọ pe lọdọ Ọlọrun ni emi ti jade wa. Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jade wa, mo sì wa si aye: ẹ̀wẹ̀, mo fi aye silẹ, mo sì nlọ sọdọ Baba.”
Awọn ọ̀rọ̀ Jesu jẹ iṣiri ti o ga fun awọn apọsiteli naa. “Nipa eyi ni awa gbagbọ pe, lọdọ Ọlọrun ni iwọ ti jade wa,” ni wọn sọ. “Ẹyin gbàgbọ́ wàyí?” ni Jesu beere. “Kiyesi i, wakati nbọ, ani o dé tán nisinsinyi, ti a o fọ́n yin kaakiri, olukuluku si ile rẹ̀; ẹ o sì fi emi nikan silẹ.” Bi o tilẹ dabi ohun ti ko ṣee gbagbọ, eyi ṣẹlẹ ki ilẹ̀ tó ṣú!
“Nnkan wọnyi ni mo ti sọ fun yin tẹlẹ, ki ẹyin ki o lè ni alaafia ninu mi.” Jesu pari ọ̀rọ̀ rẹ̀ pe: “Ninu aye, ẹyin yoo ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tujuka; mo ti ṣẹgun aye.” Jesu ṣẹgun aye nipa fifi pẹlu iṣotitọ ṣaṣepari ifẹ inu Ọlọrun laika gbogbo ohun ti Satani ati aye rẹ̀ gbiyanju lati ṣe lati ba iwatitọ Jesu jẹ́.
Adura Ipari Ninu Iyara Oke
Bi a ti sún un pẹlu ifẹ jijinlẹ fun awọn apọsiteli rẹ̀, Jesu ti nmura wọn silẹ fun igberalọ rẹ̀ ti o sunmọle. Nisinsinyi, lẹhin ti o ti ṣí wọn leti ti o sì ti tu wọn ninu fun ìgbà gigun, o gbe oju rẹ soke ọrun o sì beere lọdọ Baba rẹ̀: “Yin ọmọ rẹ logo, ki Ọmọ rẹ ki o le yin ọ logo pẹlu gẹgẹ bi iwọ ti fun un ni aṣẹ lori eniyan gbogbo, ki o le fi iye ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o fifun un.”
Iru ẹṣin-ọrọ arunisoke wo ni Jesu nasẹ rẹ̀—iye ainipẹkun! Bi a ti fun un ni “aṣẹ lori eniyan gbogbo,” Jesu le pin awọn anfaani ẹbọ irapada rẹ̀ fun gbogbo araye ti o nku lọ. Sibẹ oun yọnda “iye ainipẹkun” fun kiki awọn wọnni ti Baba tẹwọgba. Ni sisọrọ lori ẹṣin-ọrọ iye ainipẹkun yii, Jesu nba adura rẹ lọ:
“Iye ainipẹkun naa si ni eyi, ki wọn ki o lè mọ̀ ọ́n, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni ti iwọ ran.” Bẹẹni, igbala sinmile gbigba imọ nipa Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀ sinu. Ṣugbọn ohun ti o ju imọ ori lasan lọ ni a nilo.
Ẹnikan gbọdọ mọ wọn timọtimọ, ni mimu ibadọrẹẹ oloye dagba pẹlu wọn. Ẹnikan gbọdọ ni imọlara gẹgẹ bi wọn ti ni lori awọn koko ọran ki o sì ri awọn nǹkan gẹgẹ bi wọn ti ríi. Ati ju gbogbo rẹ lọ, ẹnikan gbọdọ làkàkà lati ṣafarawe awọn animọ alailẹgbẹ wọn ninu biba awọn ẹlomiran lò.
Jesu gbadura tẹle e: “Emi ti yin ọ logo ni aye; emi ti pari iṣẹ ti iwọ fun mi lati ṣe.” Niwọn bi o ti tipa bayii mu iṣẹ ayanfunni rẹ̀ ṣe titi de ọgangan yii tí ó sì ní igbọkanle nipa aṣeyọri si rere rẹ̀ ẹhin ọla, oun beere pe: “Baba, ṣe mi logo pẹlu araàrẹ, ogo ti mo ni pẹlu rẹ ki aye ki o to wà.” Bẹẹni, oun beere nisinsinyi pe ki a mú oun padabọ si ogo rẹ̀ iṣaaju ni ọrun, nipa ajinde.
Ni ṣiṣakopọ olori iṣẹ rẹ̀ lori ilẹ aye, Jesu sọ pe: “Emi ti fi orukọ rẹ han fun awọn eniyan ti iwọ ti fifunni lati inu aye wa: tirẹ ni wọn ti jẹ ri, iwọ si ti fi wọn fun mi; wọn sì ti pa ọrọ rẹ mọ́.” Jesu lo orukọ Ọlọrun, Jehofa, ninu iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀ o sì ṣaṣefihan bi a ṣe lè pè é lọna yiyẹ, ṣugbọn oun ṣe ju eyiini lọ lati fi orukọ Ọlọrun han kedere fun awọn apọsiteli rẹ̀. Oun tun mu imọ ati imọriri wọn fun Jehofa, animọ rẹ̀, ati awọn ète rẹ̀ gbooro siwaju.
Ni bibuyin fun Jehofa gẹgẹ bi Alagbara giga ju oun lọ, Ẹni naa ti oun nṣiṣẹsin labẹ rẹ̀, Jesu fi tirẹlẹtirẹlẹ jẹwọgba pe: “Nitori ọrọ ti iwọ fifun mi, emi ti fifun wọn, wọn sì ti gbà á, wọn sì ti mọ nitootọ pe, lọdọ rẹ ni mo ti jade wa, wọn sì gbagbọ pe iwọ ni o ran mi.”
Ni fifi iyatọ han laaarin awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ati iyoku araye, Jesu gbadura tẹle e pe: “Emi kò gbadura fun araye, ṣugbọn fun awọn ti iwọ ti fifun mi: . . . Nigba ti mo wà pẹlu wọn ní aye, mo pa wọn mọ́ . . . , mo ti pa wọn mọ, ẹnikan ninu wọn kò sì ṣègbé bikoṣe ọmọ ègbé,” eyiini ni, Judasi Isikariọtu. Ni akoko yii gan-an, Judasi wà ni ẹnu iṣẹ buruku rẹ̀ lati da Jesu. Nipa bayii, Judasi nmu awọn Iwe Mimọ ṣẹ laimọ.
“Aye sì ti koriira wọn,” ni Jesu nba adura rẹ̀ lọ. “Emi kò gbadura pe, ki iwọ ki o mu wọn kuro ni aye, ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn mọ kuro ninu ibi. Wọn kii ṣe ti aye, gẹgẹ bi emi kii tii ṣe ti aye.” Awọn ọmọlẹhin Jesu wà ninu aye, iṣeto ẹgbẹ awujọ ẹda eniyan yii ti Satani nṣakoso, ṣugbọn wọn jẹ wọn sì gbọdọ maa wà lọtọ ni gbogbo ìgbà kuro ninu rẹ̀ ati iwa buruku rẹ̀.
“Sọ wọn di mimọ ninu otitọ,” ni Jesu nbaa lọ, “otitọ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” Nihin-in Jesu pe awọn Iwe Mimọ ti a misi lede Heberu, eyi ti oun nṣayọlo lati inu rẹ̀ leralera ni, ‘otitọ.’ Ṣugbọn ohun ti oun kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ati ohun ti wọn kọ lẹhin naa labẹ imisi gẹgẹ bi awọn Iwe Mimọ ti Kristẹni lede Giriiki bakan naa jẹ “otitọ.” Otitọ yii le sọ ẹni di mímọ́, yi igbesi aye rẹ̀ pada patapata, ki o sì sọ ọ́ di eniyan kan ti o ya sọtọ kuro ninu aye.
Jesu gbadura nisinsinyi “kii si ṣe kiki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yoo gbà [á] gbọ́ nipa ọrọ wọn.” Nitori naa Jesu gbadura fun awọn wọnni ti yoo di awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ẹni ami-ororo ati awọn ọmọ-ẹhin miiran lẹhin ọla ti a o ṣi kojọ sinu “agbo kan.” Ki ni oun beere fun awọn wọnyi?
“Ki gbogbo wọn ki o lè jẹ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o lè jẹ́ ọkan ninu wa.” Jesu ati Baba rẹ̀ kii ṣe ẹnikan ni gidi, ṣugbọn wọn wà ni iṣọkan lori ohun gbogbo. Jesu gbadura pe ki awọn ọmọlẹhin oun gbadun jijẹ ọkan kan naa ki “aye ki o lè mọ̀ pe, iwọ ni o ran mi, ati pe iwọ sì fẹran wọn gẹgẹ bi iwọ ti fẹran mi.”
Nitori awọn wọnni ti yoo di awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ẹni ami ororo, Jesu nisinsinyi beere ohun kan lọwọ Baba rẹ ọrun. Ki ni? “Nibi ti emi gbe wa; ki wọn ki o lè maa wo ògo mi, ti iwọ fifun mi: nitori iwọ saa fẹran mi ṣiwaju ipilẹṣẹ aye,” eyiini ni, ṣaaju ki Adamu ati Efa tó loyun ọmọ. Tipẹtipẹ ṣaaju akoko yẹn, Ọlọrun fẹran Ọmọkunrin bibi rẹ kanṣoṣo, ti o wa di Jesu Kristi.
Ni pipari adura rẹ̀, Jesu tẹnumọ ọn lẹẹkan sii: “Mo ti sọ orukọ rẹ di mimọ fun wọn, emi sì sọ ọ́ di mimọ: ki ifẹ ti iwọ fẹran mi, lè maa wà ninu wọn, ati emi ninu wọn.” Fun awọn apọsiteli naa, mimọ orukọ Ọlọrun ti ni ninu wiwa lẹnikọọkan lati mọ ifẹ Ọlọrun. Johanu 14:1–17:26; 13:27, 35, 36; 10:16; Luuku 22:3, 4; Ẹkisodu 24:10; 1 Ọba 19:9-13; Aisaya 6:1-5; Galatia 6:16; Saamu 35:19; 69:4, NW; Owe 8:22, 30.
▪ Nibo ni Jesu nlọ, idahun wo ni Tọmasi si ri gba nipa ọna ti o lọ sibẹ?
▪ Nipasẹ ibeere rẹ̀, ki ni o han gbangba pe Filipi fẹ ki Jesu pese?
▪ Eeṣe ti ẹni ti o ri Jesu ti fi ri Baba pẹlu?
▪ Bawo ni awọn ọmọlẹhin Jesu ṣe ṣe awọn iṣẹ titobi ju eyi ti oun ṣe lọ?
▪ Ni ero wo ni Satani ko fi ni agbara kankan lori Jesu?
▪ Nigba wo ni Jehofa gbin àjàrà afamiṣapẹẹrẹ naa, nigba wo ati bawo ni awọn ẹlomiran ṣe di apakan àjàrà naa?
▪ Ni asẹhinwa asẹhinbọ, awọn ẹka meloo ni àjàrà afamiṣapẹẹrẹ naa ni?
▪ Eso wo ni Ọlọrun fẹ lati ọ̀dọ̀ awọn ẹka naa?
▪ Bawo ni awa ṣe lè jẹ ọ̀rẹ́ Jesu?
▪ Eeṣe ti aye fi koriira awọn ọmọlẹhin Jesu?
▪ Ikilọ Jesu wo ni o yọ awọn apọsiteli rẹ̀ lẹnu?
▪ Eeṣe ti awọn apọsiteli naa fi kuna lati beere ibi ti Jesu nlọ lọwọ rẹ̀?
▪ Ki ni awọn apọsiteli naa kuna ni pato lati loye?
▪ Bawo ni Jesu ṣe ṣapejuwe pe ipo awọn apọsiteli naa yoo yipada lati ibanujẹ si ayọ̀?
▪ Ki ni Jesu sọ pe awọn apọsiteli naa yoo ṣe laipẹ?
▪ Bawo ni Jesu ṣe ṣẹgun aye?
▪ Ni ero wo ni a ti fun Jesu ni “aṣẹ lori eniyan gbogbo”?
▪ Ki ni o tumọsi lati gba imọ Ọlọrun ati ti Ọmọkunrin rẹ̀?
▪ Ni awọn ọna wo ni Jesu gbà fi orukọ Ọlọrun han?
▪ Ki ni “otitọ naa” bawo ni o sì ṣe “sọ” Kristẹni kan di “mímọ́”?
▪ Bawo ni Ọlọrun, Ọmọkunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn olusin tootọ ṣe jẹ ọkan?
▪ Nigba wo ni “ipilẹṣẹ aye naa”?
-