ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Niwaju Sanhẹdrin, Lẹhin Naa Sọdọ Pilatu
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    • Orí 121

      Niwaju Sanhẹdrin, Lẹhin Naa Sọdọ Pilatu

      Ọ̀ YẸ̀ ọjọ keji ti nla, Peteru ti sẹ́ Jesu fun igba kẹta, awọn mẹmba Sanhẹdrin sì ti ṣetan pẹlu ìgbẹ́jọ́ yẹ̀yẹ́ wọn wọ́n sì ti funka. Bi o ti wu ki o ri, kété tí ọ̀yẹ̀ owurọ Friday là, wọn pade lẹẹkan sii, ni akoko yii ni Gbọngan Sanhẹdrin wọn. O jọ bi ẹni pe ète wọn ni lati mu ki ẹjọ oru naa dabi ẹni pe o ba ofin mu. Nigba ti a mu Jesu wa siwaju wọn, wọn wi, gẹgẹ bi wọn ti ṣe ni òru naa: “Bi iwọ ba ni Kristi naa, sọ fun wa.”

      “Ani bi mo tilẹ sọ fun yin, ẹ kò ni gbà á gbọ́ rara,” Jesu dahun. “Ju bẹẹ lọ, bi mo ba bi yin leere, ẹ kò ni dahun rara.” Bi o ti wu ki o ri, Jesu fi pẹlu igboya tọka si ẹni ti oun jẹ, ni wiwi pe: “Lati isinsinyi lọ Ọmọkunrin eniyan yoo maa jokoo ni ọwọ́ ọtun agbara Ọlọrun.”

      “Nitori naa, ṣe iwọ ni Ọmọkunrin Ọlọrun?” gbogbo wọn fẹ́ lati mọ̀.

      “Ẹyin funraayin nwipe emi ni,” ni Jesu da wọn lohun.

      Fun awọn ọkunrin wọnyi ti wọn tẹ̀ siha iṣikapaniyan, idahun yii ti to. Wọn kà á si ọ̀rọ̀ òdì. “Eeṣe ti a fi nilo ẹ̀rí siwaju sii?” ni wọn beere. “Nitori awa funraawa ti gbọ́ ọ lati ẹnu oun funraarẹ.” Nitori naa wọn de Jesu, wọn sì fà á lọ kuro, wọn sì fi le gomina Roomu Pọntu Pilatu lọwọ.

      Judasi, ti o dà Jesu, ti nkiyesi igbesẹ ẹjọ naa pẹlu iṣọra. Nigba ti o ríi pe a ti dá Jesu lẹbi, o nimọlara ẹdun ẹṣẹ. Nitori naa o lọ sọdọ awọn olori alufaa ati awọn àgbà ọkunrin lati dá 30 owo fadaka naa pada, ni ṣiṣalaye: “Emi ṣẹ̀ ni eyi ti mo fi ẹ̀jẹ̀ alaiṣẹ hàn.”

      “Kò kàn wa, maa bojuto o,” ni wọn fesi pada lọna ainimọlara aanu. Nitori naa Judasi da awọn idẹ wẹ́wẹ́ naa sinu tẹmpili o sì jade lọ o gbiyanju lati pokùnso. Bi o ti wu ki o ri, ẹka ti Judasi so okùn naa mọ lọna hihan gbangba ya, ara rẹ̀ sì jabọ sori awọn àpáta nisalẹ, nibi ti o ti bẹ́ jálajàla.

      Awọn olori alufaa kò mọ̀ ohun ti wọn yoo ṣe pẹlu awọn idẹ wẹwẹ naa. “Kò ba ofin mu lati sọ wọn sinu iṣura mimọ,” ni wọn pari ero si, “nitori wọn jẹ owo ẹ̀jẹ̀.” Nitori naa, lẹhin gbigbero papọ, wọn ra pápá amọ̀kòkò pẹlu owo naa lati maa fi sinku awọn ajeji. Pápá naa tipa bayii di eyi ti a npe ni “Pápá Ẹ̀jẹ̀.”

      O ṣì jẹ kutukutu owurọ sibẹ nigba ti a mu Jesu lọ si aafin gomina. Ṣugbọn awọn Juu ti wọn baa lọ kọ̀ lati wọle nitori wọn gbagbọ pe irufẹ ibarẹ timọtimọ bẹẹ pẹlu awọn Keferi yoo sọ wọn di ẹlẹgbin. Nitori naa, lati gba wọn laaye, Pilatu jade sita. “Ẹsun ki ni ẹ muwa lodisi ọkunrin yii?” ni oun beere.

      “Bi ọkunrin yii ko ba jẹ oniwa aitọ, awa ki ba ti fi le ọ lọwọ,” ni wọn dahun.

      Bi oun kò ti fẹ lati lọwọ ninu ohunkohun, Pilatu dahunpada: “Ẹ mú un tikaraayin ki ẹ sì ṣe idajọ rẹ̀ gẹgẹ bi ofin yin.”

      Ni ṣiṣipaya èrò iṣikapaniyan wọn, awọn Juu naa kede pe: “Ko ba ofin mu fun wa lati pa ẹnikẹni.” Nitootọ, bi wọn ba pa Jesu laaarin akoko Ajọ Ariya Irekọja, o ṣeeṣe ki o ṣokunfa họ́ùhọ́ù laaarin gbogbo eniyan, niwọn bi ọpọlọpọ ti ni ọ̀wọ̀ giga fun Jesu. Ṣugbọn bi wọn ba lè mú kí awọn ara Roomu fiya iku jẹ Jesu lori ẹsun ọran oṣelu, eyi yoo tẹsi lati tu wọn silẹ kuro lọwọ ijihin niwaju awọn eniyan naa.

      Nitori naa awọn aṣaaju isin, ni ṣiṣai mẹnukan igbẹjọ wọn akọkọ lakooko eyi ti wọn ti da Jesu lẹbi fun ọ̀rọ̀ odi, nisinsinyi wọn humọ awọn ẹsun yiyatọ. Wọn fi ẹsun alápá mẹta kàn án: “Ọkunrin yii ni a ri [1] ti ndoju orilẹ ede wa dé [2] ti o sì ndanilẹkun sisan owo ori fun Kesari [3] ti o sì nsọ pe oun alara ni Kristi ọba kan.”

      Ẹsun naa pe Jesu sọ pe oun jẹ ọba ni o kan Pilatu. Nitori naa, ó wọnu aafin lẹẹkan sii, o pe Jesu sọdọ rẹ̀, o si beere pe: “Iwọ ha ni ọba awọn Juu bi?” Ni èdè miiran, iwọ ha ti ru ofin nipa pipolongo araarẹ̀ bii ọba ni atako si Kesari?

      Jesu fẹ́ lati mọ̀ bi Pilatu ti gbọ nipa oun to ṣaaju akoko yẹn, nitori naa o beere: “Njẹ lati inu apilẹṣe araàrẹ ni iwọ ti wi eyi, tabi awọn ẹlomiran sọ fun ọ nipa mi?”

      Pilatu jẹwọ aimọkan nipa rẹ̀ ati ifẹ ọkan lati mọ otitọ. “Emi iṣe Juu bi?” ni oun fesipada. “Awọn orilẹ-ede rẹ, ati awọn olori alufaa ni o fà ọ le emi lọwọ: ki ni iwọ ṣe?”

      Jesu kò gbidanwo lọnakọna lati yẹ ariyanjiyan naa silẹ, eyi ti o jẹ ti ipo ọba. Idahun ti Jesu fun un nisinsinyi laisi iyemeji ya Pilatu lẹnu. Luuku 22:66–23:3; Matiu 27:1-11; Maaku 15:1; Johanu 18:28-35; Iṣe 1:16-20.

      ▪ Fun ète wo ni Sanhẹdrin ṣe pade lẹẹkan sii ni owurọ?

      ▪ Bawo ni Judasi ṣe ku, ki ni a sì ṣe pẹlu 30 owo fadaka naa?

      ▪ Kaka ki wọn pa a funraawọn, eeṣe ti awọn Juu fi fẹ ki awọn ara Roomu pa Jesu?

      ▪ Awọn ẹsun wo ni awọn Juu fi kan Jesu?

  • Lati Ọ̀dọ̀ Pilatu Sọdọ Hẹrọdu A sì Tún Rán an Pada
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    • Orí 122

      Lati Ọ̀dọ̀ Pilatu Sọdọ Hẹrọdu A sì Tún Rán an Pada

      BI O tilẹ jẹ pe Jesu kò gbidanwo lati fi jijẹ ọba rẹ̀ pamọ, o ṣalaye pe ijọba oun kii ṣe ihalẹ si Roomu. “Ijọba mi kii ṣe apakan aye yii,” ni Jesu sọ fun Pilatu. “Bi ijọba mi ba jẹ apakan aye yii, awọn iranṣẹ mi iba ti jà ki a ma baa fi mi le awọn Juu lọwọ. Ṣugbọn gẹgẹ bi o ti ri, ijọba mi kii ṣe lati orisun yii.” Jesu tipa bayii fihan ni igba mẹta pe oun ní Ijọba kan, bi o tilẹ jẹ pe kii ṣe ti orisun ilẹ aye.

      Sibẹ, Pilatu rọ̀ ọ́ siwaju sii: “Tóò, nigba naa, ọba ni ọ bi?” Iyẹn ni pe, njẹ ọba ni iwọ ani bi o tilẹ jẹ pe Ijọba rẹ kii ṣe ti apakan aye yii.

      Jesu jẹ ki Pilatu mọ pe o ti de ipari ero titọna, ni didahun: “Iwọ tikaraarẹ wipe ọba ni mi. Nitori eyi ni a si ṣe bi mi, ati nitori eyi ni mo ti ṣe wa sinu aye, ki emi baa lè jẹrii si otitọ naa. Olukuluku ẹni ti o wa ni iha otitọ nfetisilẹ si ohùn mi.”

      Bẹẹni, wiwa Jesu lori ilẹ aye jẹ lati jẹrii si “otitọ,” ni gidi pato otitọ naa nipa Ijọba rẹ̀. Jesu ti murasilẹ lati jẹ olóòótọ́ si otitọ yii ani bi o tilẹ ná an ni iwalaaye rẹ̀ paapaa. Bi o tilẹ jẹ pe Pilatu beere: “Ki ni otitọ?” oun kò duro fun alaye siwaju sii. Oun ti gbọ́ ohun ti o tó lati ṣe idajọ.

      Pilatu pada sọdọ awọn ogunlọgọ ti wọn duro lẹhin ode aafin naa. Lọna hihan gbangba pẹlu Jesu ni ẹgbẹ rẹ̀, oun sọ fun awọn olori alufaa ati awọn wọnni ti nbẹ pẹlu wọn: “Emi kò ri ariwisi kankan ninu rẹ̀.”

      Bi ipinnu naa ti bi wọn ninu, awọn ogunlọgọ naa bẹrẹ sii tẹpẹlẹ mọ́ ọn: “O nru awọn eniyan soke nipa kikọni jakejado gbogbo Judia, ani ni bibẹrẹ lati Galili titi de ihin.”

      Igbonara ẹhanna alainironu awọn Juu ti gbọdọ ya Pilatu lẹnu. Nitori naa bi awọn olori alufaa ati awọn àgbà ọkunrin ti nbaa lọ ni kikigbe, Pilatu yipada si Jesu o si beere pe: “Iwọ kò ha gbọ bi wọn ti njẹrii pupọ lodisi ọ?” Sibẹ, Jesu kò gbidanwo lati dahun. Iparọrọ rẹ̀ ni oju awọn ẹsun ẹlẹhanna naa mu ki ẹnu ya Pilatu.

      Ni mimọ pe Jesu jẹ ara Galili, Pilatu ri ọna àbáyọ kuro ninu ijihin. Oluṣakoso Galili, Hẹrọdu Antipa (ọmọkunrin Hẹrọdu Nla naa), wà ni Jerusalẹmu fun Irekọja, nitori naa Pilatu rán Jesu lọ sọdọ rẹ̀. Ni iṣaaju, Hẹrọdu Antipa ti bẹ́ Johanu Arinibọmi lori, ati lẹhin naa Hẹrọdu ni jinnijinni ba nigba ti o gbọ nipa awọn iṣẹ agbayanu ti Jesu nṣe, ni bibẹru pe Jesu niti tootọ ni Johanu ti o ti ji dide lati inu oku.

      Nisinsinyi, inu Hẹrọdu dun dẹhin si ireti riri Jesu. Eyi kii ṣe nitori pe oun daniyan nipa alaafia Jesu tabi pe oun fẹ lati ṣe igbidanwo tootọ gidi eyikeyii lati mọ̀ boya awọn ẹsun ti a fikan an jẹ ootọ tabi bẹẹkọ. Kaka bẹẹ, oun wulẹ nifẹẹ itọpinpin o sì ni ireti lati ri ki Jesu mu awọn iṣẹ iyanu diẹ ṣe.

      Bi o ti wu ki o ri, Jesu kọ̀ lati tẹ́ ifẹ itọpinpin Hẹrọdu lọrun. Niti tootọ, bi Hẹrọdu ti nbi i ni ibeere, oun kò sọ ọrọ kan. Nitori a já a kulẹ, Hẹrọdu ati awọn ẹsọ ọmọ ogun rẹ̀ fi Jesu ṣe yẹ̀yẹ́. Wọn fi aṣọ titan yẹbẹyẹbẹ wọ̀ ọ́ wọn sì fi i ṣe ẹlẹya. Lẹhin naa wọn rán an pada lọ sọdọ Pilatu. Gẹgẹ bi iyọrisi, Hẹrọdu ati Pilatu, ti wọn ti jẹ ọ̀tá tẹlẹri, di ọ̀rẹ́ daradara.

      Nigba ti Jesu pada, Pilatu pe awọn olori alufaa, awọn oluṣakoso Juu ati awọn eniyan papọ o sì wipe: “Ẹ mu ọkunrin yii wa sọdọ mi gẹgẹ bi ẹni kan ti nru awọn eniyan soke lati dìtẹ̀, ẹ sì wòó! mo yẹ̀ ẹ́ wò niwaju yin ṣugbọn emi ko ri ipilẹ kankan ninu ọkunrin yii fun awọn ẹsun ti ẹyin mu wa lodisi i. Niti tootọ, bẹẹ ni Hẹrọdu kò ṣe bẹẹ, nitori o ran an pada si wa; ẹ sì wòó! ko si ohun ti o yẹ si iku ti oun ti ṣe. Nitori naa emi yoo jẹ ẹ́ níyà lọna lilekoko emi yoo sì tú u silẹ.”

      Nipa bayii, Pilatu ti polongo Jesu ni alaimọwọ mẹsẹ lẹẹmeji. Oun nharagaga lati tú u silẹ. Nitori oun mọ pe o jẹ kiki nitori ìlara ni awọn alufaa fi fa a le oun lọwọ. Ṣugbọn bi Pilatu ti nbaa lọ ninu igbiyanju rẹ̀ lati tu Jesu silẹ, ó rí isunniṣe ti o tubọ lagbara sii lati ṣe bẹẹ. Nigba ti oun ṣì wà lori ijokoo idajọ rẹ̀, aya rẹ̀ fi ihin iṣẹ kan ranṣẹ sii, ni rírọ̀ ọ́ pe: “Maṣe ni ohunkohun lati ṣe pẹlu ọkunrin olododo yẹn, nitori mo jiya pupọ lonii loju àlá [ti o han gbangba pe o ni ipilẹṣẹ atọrunwa] nitori rẹ.”

      Sibẹ, bawo ni Pilatu ṣe lè tú ọkunrin alaimọwọmẹsẹ yii silẹ, gẹgẹ bi oun ti mọ̀ pe ó yẹ ki oun ṣe? Johanu 18:36-38; Luuku 23:4-16; Matiu 27:12-14, 18, 19; 14:1, 2; Maaku 15:2-5.

      ▪ Bawo ni Jesu ṣe dahun ibeere nipa ipo ọba rẹ̀?

      ▪ Ki ni “otitọ naa” nipa eyi ti Jesu lo igbesi-aye rẹ̀ lori ilẹ-aye ni jijẹrii si?

      ▪ Ki ni idajọ Pilatu, bawo ni awọn eniyan ṣe dahunpada, ki si ni Pilatu ṣe pẹlu Jesu?

      ▪ Ta ni Hẹrọdu Antipa, eeṣe ti inu rẹ̀ fi dun lati ri Jesu, ki ni o sì ṣe pẹlu rẹ̀?

      ▪ Eeṣe ti Pilatu fi ni iharagaga lati da Jesu silẹ lominira?

  • “Ẹ Wò Ó! Ọkunrin Naa!”
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    • Orí 123

      “Ẹ Wò Ó! Ọkunrin Naa!”

      BI A ti ṣí i lórí nipa ọ̀nà ìhùwà Jesu ti o si ri àìmọwọ́mẹsẹ̀ rẹ̀, Pilatu wa ọ̀nà miiran lati tú u silẹ. “Ẹyin ní àṣà kan,” ni oun sọ fun awọn ogunlọgọ naa, “pe kí emi ki o da ọ̀kan silẹ fun yin nigba àjọ ìrékọjá.”

      Baraba, òṣìkàpànìyàn olókìkí burúkú kan, ni a tún mú gẹgẹ bi ẹlẹ́wọ̀n, nitori naa Pilatu beere pe: “Ta ni ẹyin nfẹ́ kí emi dá sílẹ̀ fun yin? Baraba, tabi Jesu tí a ńpè ní Kristi?”

      Bi o ti jẹ pe awọn olórí alufaa ti yí wọn lérò padà tí wọn sì ti ru wọn sókè, awọn ènìyàn naa beere fun ìtúsílẹ̀ Baraba ati fun pípa Jesu. Láìjuwọ́sílẹ̀, Pilatu dáhùnpadà, ní bibeere lẹẹkan síi: “Ninu awọn mejeeji, ewo ni ẹyin fẹ́ kí emi da silẹ fun yin?”

      “Baraba,” ni wọn kígbe.

      “Kini emi yoo ha ṣe sí Jesu ẹni tí a ńpè ní Kristi?” Pilatu beere ninu ìdààmú oun ibẹru.

      Pẹlu ìkéramúramù adinilétí kan, wọn dahun pe: “Jẹ́ kí ó di kíkàn mọ́gi!” “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”

      Ní mímọ̀ pe wọn ńbéèrè ikú ọkunrin aláìmọwọ́mẹsẹ̀ kan, Pilatu jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pe: “Eeṣe, búburú ki ni ọkunrin yii ṣe? emi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nitori naa emi yoo nà án, emi a sì jọwọ rẹ lọwọ lọ.”

      Láìka awọn ìgbìdánwò rẹ̀ sí, ogunlọgọ oníbìínú naa tí awọn aṣaaju isin wọn rusoke ńbá kíkérara lọ: “Jẹ́ kí ó di kíkàn mọ́ igi!” Bi awọn alufaa ti mú wọn ní ìgbónára ewèlè, ogunlọgọ naa ńfẹ́ ẹ̀jẹ̀. Kí a ronu nipa rẹ̀ ná, kìkì ọjọ́ márùn-ún ṣaaju, diẹ ninu wọn ni ó ṣeeṣe kí wọn ti wà lára awọn tí wọn kí Jesu káàbọ̀ sí Jerusalẹmu gẹgẹ bi Ọba! Ni gbogbo àkókò naa, awọn ọmọ-ẹhin Jesu, bí wọn bá wà níbẹ̀, wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, a kò sì lè kiyesi wọn.

      Ní ríri i pe ìfọ̀rànlọ̀ oun kò ṣe rere kankan ṣugbọn, kàkà bẹ́ẹ̀, irukerudo ni ó bẹsilẹ, Pilatu bu omi ó sì fọ ọwọ́ rẹ̀ niwaju ogunlọgọ naa, ó sì wipe: “Ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ̀ ènìyàn olóòótọ́ yii: ẹ maa bójútó o.” Ní bayii, awọn ènìyàn naa dáhùn pe: “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà ní orí wa, ati ní orí awọn ọmọ wa.”

      Nitori naa, ní ìbámu pẹlu ohun ti wọn béèrè—ati fífẹ́ lati tẹ́ ogunlọgọ naa lọ́rùn ju lati ṣe ohun tí ó tọ̀nà—Pilatu tú Baraba silẹ fun wọn. Oun mú Jesu ó sì jẹ́ kí wọn bọ́ aṣọ rẹ̀ ki wọn sì nà án lọ́rẹ́ lẹhin naa. Eyi kii ṣe nínà ní pàṣán ṣákálá. The Journal of the American Medical Association ṣàpèjúwe àṣà ìnanilọ́rẹ́ awọn ará Roomu:

      “Ohun èèlò ti a saba maa nlo ni pàṣán tẹ́ẹ́rẹ́ (flagrum tabi flagellum) kòbókò awọ ẹlẹ́yọ kọọkan melookan tabi alahunpọ tí gígùn wọn kò báradọ́gba, ti a wa so awọn irin ródóródó kéékèèké tabi awọn egungun àgùtàn wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ mímú mọ́ kaakiri. . . . Bí awọn ọmọ-ogun Roomu ti ńna ẹ̀hìn òjìyà naa léraléra pẹlu ipá, awọn irin ródóródó naa yoo fa awọn ìdáranjẹ̀ jíjìn, kòbókò aláwọ naa ati awọn egungun àgùtàn yoo sì bẹ́ awọ ara naa ati awọn ẹran isalẹ awọ. Nigba naa, bí ìnàlọ́rẹ́ naa ti nbaa lọ, ara ti ńbẹ́ naa yoo fàya kan awọn iṣu-ẹran ti wọn wà lara egungun yoo sì sọ ẹran ara di ẹlẹ́jẹ̀ jálajàla.”

      Lẹhin nínà onídàálóró yii, wọn mú Jesu wọnú ààfin gómìnà lọ, wọn si pe gbogbo ẹgbẹ ọmọ-ogun jọ. Nibẹ ni awọn ọmọ-ogun ti hàn án léèmọ̀ siwaju sí i nipa híhun adé ẹ̀gún kan tí wọn sì tì í bọ orí rẹ̀. Wọn fi esùsú bọ ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, wọn sì wọ̀ ọ́ láṣọ elése àlùkò, irú eyi tí awọn ọlọ́ba maa ńwọ̀. Nigba naa ni wọn wí fun un lọna ìfiniṣẹlẹ́yà pe: “Kábíyèsí ọba awọn Júù.” Wọn tún tutọ́ sí i lára wọn sì gbá a lójú pẹlu. Ni bibọ èsùsú líle naa ní ọwọ́ rẹ̀, wọn lò ó lati fi lù ú ní orí, ní fífi awọn ẹ̀gún mímú ti o wà ninu “adé” atẹ́nilógo rẹ̀ gún un siwaju sí i pẹlu.

      Iyì ọlá ati okun pípẹtẹrí Jesu lójú ìfojú ẹni gbolẹ̀ yii wú Pilatu lórí tobẹẹ tí a fi sún un lati ṣe ìgbìdánwò miiran lati tún un ràpadà. “Wòó, mo mú un jáde tọ̀ yin wá, kí ẹyin ki o lè mọ̀ pe, emi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀,” ni oun sọ fun awọn ogunlọgọ naa. Ó ṣeeṣe kí ó wòye pe ìrísí ipò ìdálóró Jesu yoo rọ awọn ènìyàn naa lọkan. Bí Jesu ti dúró niwaju àwùjọ àwọn ènìyànkénìyàn aláìláàánú naa, ni wíwọ adé ẹlẹ́gùn-ún ati ẹwu elésè àlùkò pẹlu ojú rẹ̀ tí ńṣẹ̀jẹ̀ ninu ìrora, Pilatu pòkìkí pe: ‘Ẹ wò ó! Ọkunrin naa!’

      Bí ó tilẹ jẹ́ pe a dọgbẹ sii lara ti a si ti han an leemọ ika, níhìn-ín ni sàràkí ẹ̀dá títayọ julọ ninu gbogbo ìtàn dúró, ọkunrin títóbi jùlọ nitootọ tí ó tíì gbé láyé rí! Bẹẹni, Jesu fi iyì-ọlá dídákẹ́rọ́rọ́ ati ìparọ́rọ́ han tí ó tọka si ìtóbilọ́lá kan tí Pilatu pàápàá gbọdọ jẹ́wọ́, nitori awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọna tí ó hàn gbangba jẹ́ ìdàpọ̀mọ́ra ọ̀wọ̀ ati ìkáàánú. Johanu 18:39–19:5; Matiu 27:15-17, 20-30, NW; Maaku 15:6-19; Luku 23:18-25.

      ▪ Ní ọ̀nà wo ni Pilatu fi gbìdánwò lati tú Jesu silẹ?

      ▪ Bawo ni Pilatu ṣe gbìyànjú lati tú araarẹ̀ silẹ kuro lọwọ ẹrù-iṣẹ́?

      ▪ Ki ni ìnàlọ́rẹ́ ní ninu?

      ▪ Bawo ni a ṣe fi Jesu ṣẹlẹ́yà lẹhin tí a ti nà án lọ́rẹ́?

      ▪ Ìgbìdánwò siwaju sí i wo ni Pilatu ṣe lati tú Jesu silẹ?

  • A Fà Á Lé Wọn Lọwọ Wọn Si Mu Un Lọ
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    • Orí 124

      A Fà Á Lé Wọn Lọwọ Wọn Si Mu Un Lọ

      NIGBA ti Pilatu, ẹni ti ìwà jẹ́jẹ́ Jesu ti a ti daloro wú lori, gbiyanju lẹẹkan sii lati tú u silẹ, ibinu awọn olori alufa tún peleke sii. Wọn ti pinnu lati maṣe jẹ ki ohunkohun ṣedilọwọ fun ète buruku wọn. Nitori naa wọn tun bẹrẹ ariwo yèè lẹẹkan sii: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”

      Pilatu dahunpada pe: “Ẹ mú un funra yin ki ẹ si kàn án mọ́gi.” (Ni odikeji si ohun ti wọn sọ ni iṣaaju, awọn Juu le ni aṣẹ lati fiya iku jẹ awọn ọdaran fun awọn ẹṣẹ ti o jẹmọ ijọsin ti iwuwo rẹ̀ pọ dé ààyè kan.) Lẹhin naa, fun o keretan igba karun-un, Pilatu sọ ni gbangba pe Jesu jẹ alaiṣẹ alairo, ni wiwi pe: “Emi ko ri ariwisi eyikeyii ninu rẹ.”

      Awọn Juu, ni ririi pe awọn ẹ̀sùn oṣelu wọn ti kuna lati mu eso jade, yipada si ẹ̀sùn ọrọ odi nipa isin tí wọn ti lo ni ọpọlọpọ wakati ṣaaju nibi ìgbẹ́jọ́ Jesu niwaju awọn Sanhẹdrin. Wọn wipe, “Awa ni ofin kan, ati ni ibamu pẹlu ofin naa oun yẹ si iku, nitori pe oun fi araarẹ ṣe ọmọkunrin Ọlọrun.”

      Ẹ̀sùn yi jẹ titun si Pilatu, o si mu ki o bẹru. Nisinsinyi oun mọ daju pe Jesu kii ṣe eniyan lasan, ani gẹgẹ bi àlá aya rẹ ati bi agbara animọ ara ọtọ ti Jesu ni ti fihan. Ṣugbọn “ọmọkunrin Ọlọrun” kẹ̀? Pilatu mọ pe Jesu wa lati Galili. Sibẹ, o ha le ṣeeṣe pe oun ti walaaye ṣaaju bi? Ni mimu un pada sinu aafin lẹẹkan sii, Pilatu beere pe: “Nibo ni iwọ ti wa?”

      Jesu dakẹ jẹẹ. Ṣaaju isinsinyi oun ti sọ fun Pilatu pe ọba ni oun, ṣugbọn pe ijọba oun kii ṣe apakan aye yii. Nisinsinyi alaye eyikeyii siwaju sii ki yoo ṣiṣẹ fun ète wiwulo kankan. Bi o ti wu ki o ri, abuku ba ọ̀wọ̀ ara ẹni Pilatu nipa aidahun naa, ibinu rẹ̀ si ru si Jesu pẹlu awọn ọrọ naa: “Iwọ ko ha ni ba mi sọrọ bi? Iwọ ko ha mọ pe emi ni aṣẹ lati tu ọ silẹ mo si ni aṣẹ lati kan ọ mọgi?”

      Jesu dahun tọwọtọwọ pe: “Iwọ ki yoo ni aṣẹ eyikeyii lodisi mi ayafi bi a ba ti yọnda fun ọ lati oke wa.” Oun ntọkasi aṣẹ ti Ọlọrun yọnda fun awọn oluṣakoso ẹda-eniyan lati bojuto awọn àlámọ̀rí lori ilẹ-aye. Jesu fikun un pe: “Idi niyi ti ọkunrin naa ti o fa mi le ọ lọwọ fi ni ẹṣẹ giga ju.” Nitootọ, alufaa agba naa Kaifa ati awọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati Judasi Iskariọtu ru ẹrù wiwuwo ju ti Pilatu fun iwa ti ko ba idajọ-ododo mu ti wọn hù si Jesu.

      Bí Jesu ti tubọ wú u lórí ti o si kun fun ibẹru pe Jesu le ni ipilẹṣẹ atọrunwa, Pilatu sọ awọn isapa rẹ lati tú U silẹ dọtun. Bi o ti wu ki o ri, awọn Juu kọ̀ fun Pilatu. Wọn tun ẹ̀sùn oṣelu wọn sọ, ni hihalẹ lọna arekereke pe: “Bi iwọ ba tu ọkunrin yii silẹ, iwọ kii ṣe ọrẹ Kesari. Olukuluku ẹni ti o nsọ ara rẹ di ọba sọrọ lodisi Kesari.”

      Laika ewu ńláǹlà naa si, Pilatu mu Jesu jade lẹẹkan sii “Ẹ woo! Ọba yin!” ni oun tun sọ fun wọn lẹẹkan sii.

      “Mu un lọ! Mu un lọ! Kàn án mọgi!”

      “Ṣe ki emi kan ọba yin mọgi?” Pilatu beere pẹlu ìgbékútà.

      Awọn Juu ti ṣaini itẹlọrun labẹ iṣakoso awọn ara Roomu. Nitootọ, wọn koriira ijẹgaba Roomu tẹgantẹgan! Sibẹ, pẹlu àgàbàgebè awọn olori alufa wipe: “Awa ko ni ọba kan bikoṣe Kesari.”

      Ni bibẹru ipo oṣelu ati ifusi rẹ, Pilatu juwọsilẹ labẹ awọn ibeere dandangbọn aláìsimi awọn Juu. Oun fa Jesu le wọn lọwọ. Awọn ọmọ-ogun bọ aṣọ elese-aluko lọrun Jesu wọn si fi ẹwu àwọ̀lékè rẹ wọ̀ọ́. Bi wọn ti ńmú Jesu lọ lati kan an mọgi, wọn mu ki o ru igi idaloro ti oun funrarẹ.

      Ṣugbọn nisinsinyi o ti di ìyálẹ̀ta ọjọ Friday, Nisan 14; boya ọjọ́kanrí ti nsunmọ. Jesu kò sùn rárá lati kutukutu owurọ ọjọ Thursday, oun si ti jiya iriri onirora kan tẹ̀lé omiran. Bi o ti lè yéni, okun rẹ tan laipẹ labẹ ẹru igi naa. Nitori naa ẹnikan ti nkọja lọ, Simoni kan bayii ara Kirene ni Africa, ni wọn fipá mu wọnú iṣẹ-isin lati bá a rù ú. Bi wọn ti nlọ, ọpọ awọn eniyan tẹle wọn, ti o ni-ninu ọpọlọpọ awọn obinrin ti wọn nlu ara wọn ninu ẹdun ọkan ti wọn si ńpohùnréré ẹkun nitori Jesu.

      Ni yiyiju si awọn obinrin naa Jesu wipe: “Ẹyin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ẹ dakẹ sisunkun fun mi. Dipo bẹẹ, ẹ sunkun fun ara yin ati fun awọn ọmọ yin; nitori pe, woo! ọjọ nbọ ninu eyi ti awọn eniyan yoo wipe, ‘Alayọ ni awọn obinrin ti wọn yàgàn, ati awọn ile-ọlẹ ti ko bimọ ati ọmu ti ko fi ọyàn fun ọmọ mu!’ . . . Nitori pe bi wọn ba ṣe awọn nǹkan wọnyi nigba ti igi jẹ tutu, ki ni yoo waye nigba ti o ba gbẹ?”

      Jesu ntọkasi igi orilẹ-ede Juu, tí ọ̀rinrin iwalaaye ṣi nbẹ ninu rẹ nitori wiwanibẹ Jesu ati ti awọn aṣẹku ti wọn gbagbọ ninu rẹ̀. Ṣugbọn nigba ti a ba mu awọn wọnyi jade kuro ninu orilẹ-ede naa, kiki igi kan ti o ti kú nipa tẹmi ni yoo ṣẹ́kù, bẹẹni, eto-ajọ orilẹ-ede kan ti o ti gbẹ. Óò, iru idi fun sisunkun wo ni yoo wa nigba ti awọn ọmọ-ogun Roomu, ti wọn nṣiṣẹ gẹgẹ bi awọn olùmúdàájọ́ ṣẹ Ọlọrun, ba pa orilẹ-ede Juu run patapata! Johanu 19:6-17; 18:31; Luku 23:24-31; Matiu 27:31, 32; Maaku 15:20, 21, NW.

      ▪ Ẹ̀sùn wo lodisi Jesu ni awọn aṣaju isin fisun nigba ti awọn ẹ̀sùn oṣelu wọn kuna lati mu eso jade?

      ▪ Eeṣe ti Pilatu fi tubọ kun fun ibẹru sii?

      ▪ Ta ni o ru ẹṣẹ titobi ju fun ohun ti o ṣẹlẹ si Jesu?

      ▪ Nikẹhin bawo ni awọn alufa ṣe mu ki Pilatu fa Jesu le wọn lọwọ fun ìyà ikú?

      ▪ Ki ni Jesu sọ fun awọn obinrin ti wọn nsunkun fun un, ki ni oun si ni lọkan nipa titọkasi igi naa gẹgẹ bi eyi ti o “tutu” ati lẹhin naa gẹgẹ bi eyi ti o “gbẹ”?

  • Ijẹrora Lori Òpó-igi
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    • Orí 125

      Ijẹrora Lori Òpó-igi

      PAPỌ pẹlu Jesu awọn ọlọṣa meji ni a mú jade lọ lati jiya iku. Nibi ti ko jinna si ilu naa, itolọwọọwọ naa duro ni ibikan ti a npe ni Goligota, tabi Ibi Agbárí.

      Awọn ẹlẹwọn naa ni a bọ́ aṣọ wọn. Lẹhin naa ni a pese waini ti a po pẹlu òjíá. O jọ pe awọn obinrin Jerusalẹmu ni o ṣe é, awọn ara Roomu si yọnda àpòpọ̀ aparora yii fun awọn wọnni ti a ńkàn mọ́gi. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti Jesu tọ́ ọ wo, ó kọ̀ lati mú ninu rẹ̀. Eeṣe? Lọna ti o han gbangba oun fẹ lati ṣakoso gbogbo agbara ero ori rẹ lẹkun-unrẹrẹ nigba idanwo igbagbọ rẹ gigajulọ yii.

      Jesu ni a nà sori opó igi nisinsinyi pẹlu awọn ọwọ rẹ lókè ori rẹ. Lẹhin naa awọn ọmọ-ogun kàn ìṣó titobi wọ inu awọn ọwọ ati ẹsẹ rẹ. Oun jà pẹlu irora bi awọn ìṣó naa ti gun ẹran ati iṣan wọnu. Nigba ti wọn gbe opo igi naa nàró, irora naa buru jai, nitori ìwọ̀n iwuwo ara fa oju ọgbẹ́ ìṣó naa ya. Sibẹ, dipo kí ó halẹ, Jesu gbadura fun awọn ọmọ ogun Roomu naa: “Baba, dariji wọn; nitori ti wọn ko mọ ohun ti wọn nṣe.”

      Pilatu ti kàn àmì kan sara opó igi ti o ka pe: “Jesu ti Nasarẹti Ọba awọn Juu.” O jọ pe, o kọ eyi kii ṣe kiki nitori pe oun bọwọ fun Jesu nikan ni ṣugbọn nitori pe oun korira awọn alufaa Júù fun fifipa mú un ṣedajọ iku fun. Ki gbogbo eniyan ba le ka ami naa, Pilatu kọ ọ ni ede mẹta—ni Heberu, ni Latin ti a fi aṣẹ yàn, ati ni Giriiki ti o wọpọ.

      Awọn olori alufa, papọ pẹlu Kaifa ati Anasi, ni irẹwẹsi bá. Ipokiki olojurere yii ba wakati ayọ iṣẹgun wọn jẹ. Nitori naa wọn ṣatako pe: “Maṣe kọ ọ́ pe, Ọba awọn Juu; ṣugbọn pe oun wipe, Emi ni Ọba awọn Juu.” Ni fifi ibinu han fun ṣiṣiṣẹ gẹgẹ bi irinṣẹ lati mu ete awọn alufaa ṣẹ, Pilatu dahun pẹlu ifidimulẹ gbọnyin pe: “Ohun ti mo ti kọ tan, mo ti kọ ọ na.”

      Awọn alufaa, papọ pẹlu ọpọlọpọ ero, korajọ nisinsinyi si ibi ifiya iku jẹni naa, awọn alufaa si gbiyanju lati tako ẹ̀rí àmì naa. Wọn ṣatunsọ ẹri eke ti wọn sọ ni iṣaaju nibi ìgbẹ́jọ́ Sanhẹdrin. Nitori naa ko yanilẹnu pe awọn ti nkọja bẹrẹsii sọ ọrọ eebu, ti wọn nmi ori wọn ni ṣiṣẹlẹya wipe: “Óò iwọ ti yoo wo tẹmpili palẹ ti yoo si kọ́ ọ ni ọjọ mẹta, gba ara rẹ la! Bi iwọ ba jẹ ọmọkunrin Ọlọrun, sọkalẹ kuro lori opo-igi idaloro!”

      “Awọn miiran ni oun gbala; oun ko le gba araarẹ la!” Awọn olori alufa ati awọn ọrẹ kòríkòsùn wọn onisin jalu ọrọ naa. “Ọba Isirẹli ni oun; ẹ jẹ ki o sọkalẹ kuro lori opo-igi idaloro nisinsinyi awa yoo si ni igbagbọ ninu rẹ. Oun ti fi igbẹkẹle rẹ̀ sinu Ọlọrun; ẹ jẹ ki O gbà á silẹ nisinsinyi bi Oun ba fẹ ẹ, nitori oun wipe, ‘Ọmọkunrin Ọlọrun ni emi.’”

      Bi ẹmi naa ti ràn wọn, awọn ọmọ-ogun pẹlu darapọ ninu fifi Jesu ṣe yẹyẹ. Wọn pese ọtí kíkan fun un lati fi ṣe ẹlẹya, ti o jọ pe wọn gbe e soke rekọja awọn ètè rẹ ti o ti gbẹ. Wọn ṣáátá pe, “Bi iwọ ba jẹ ọba awọn Júù, gba ara rẹ la.” Ani awọn ọlọṣa naa paapaa—wọn kan ọkan si apa ọtun Jesu ati ekeji si apa osi—pẹgan rẹ. Rò ó wò na! Ọkunrin titobilọla julọ ti o tii gbe aye rí, bẹẹni, ẹni naa ti o ṣajọpin pẹlu Jehofa Ọlọrun ninu dida ohun gbogbo, jiya gbogbo eebu yii pẹlu iṣotitọ!

      Awọn ọmọ-ogun mu awọn ẹwu awọleke Jesu wọn si pin si apa mẹrin. Wọn ṣẹ́ kèké lati mọ ti ta ni iwọnyi yoo jẹ. Bi o ti wu ki o ri, ẹwu awọtẹlẹ rẹ ko ni oju rírán, ni jijẹ ojulowo didaraju. Nitori naa awọn ọmọ-ogun naa wi fun ara wọn pe: “Ẹ maṣe jẹ ki a fa a ya, ṣugbọn ki a ṣẹ́ kèké nitori rẹ ti ẹni ti yoo jẹ.” Nipa bayi, laimọ, wọn mu iwe mimọ ṣẹ ti o wipe: “Wọn pin aṣọ mi laaarin araawọn, wọn si ṣẹ́ kèké le aṣọ ileke mi.”

      Laipẹ ọkan lara awọn ọlọṣa wa mọriri pe Jesu nitootọ gbọdọ jẹ ọba kan. Nitori naa, ni bíbá ẹlẹgbẹ rẹ wi, oun wipe: “Iwọ ko bẹru Ọlọrun, ti iwọ wa ninu ẹbi kan naa? Niti wa, wọn jare nitori ere ohun ti awa ṣe ni awa njẹ: ṣugbọn ọkunrin yi ko ṣe ohun buburu kan.” Lẹhin naa oun ba Jesu sọrọ ni taarata, ni bibẹbẹ pe: “Ranti mi nigba ti iwọ ba de ijọba rẹ.”

      Jesu fesi pe, ‘Loootọ ni mo wi fun ọ lonii, iwọ yoo wa pẹlu mi ni Paradise.’ Ileri yii ni a o muṣẹ nigba ti Jesu ba nṣakoso gẹgẹ bi Ọba ni ọrun ti o si ji oluṣe buburu aronúpìwàdà yii dide si iye lori ilẹ-aye ninu Paradise ti awọn olùla Amagẹdọn ja ati awọn alabaakẹgbẹ wọn yoo ni anfaani lati mú gbilẹ̀. Matiu 27:33-44, NW; Maaku 15:22-32; Luku 23:27, 32-43; Johanu 19:17-24.

      ▪ Eeṣe ti Jesu fi kọ̀ lati mu waini ti a po pẹlu òjíá?

      ▪ Ki ni o jọ pe o jẹ idi ti a fi gbe àmì sori opo igi Jesu, ifọrọwerọ wo ni eyi si tun mu wa laaarin Pilatu ati awọn olori alufaa?

      ▪ Eebu siwaju sii wo ni Jesu gba lori opo igi, ki ni o si fa a lọna hihan gbangba?

      ▪ Bawo ni asọtẹlẹ ṣe ni imuṣẹ nipa ohun ti o ṣẹlẹ si awọn ẹwu Jesu?

      ▪ Iyipada wo ni ọkan lara awọn ọlọṣa naa ṣe, bawo si ni Jesu yoo ṣe mu ibeere rẹ̀ ṣẹ?

  • “Dajudaju Ọmọkunrin Ọlọrun Ni Eyi”
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    • Orí 126

      “Dajudaju Ọmọkunrin Ọlọrun Ni Eyi”

      JESU ko tii pẹ lori opo-igi nigba ti, ni ọjọ́kanrí, abàmì okunkun oni wakati mẹta kan ṣú. Imuṣokunkun oṣupa kọ ni ó fà á niwọn bi eyi ti maa nwaye kiki ni akoko oṣupa titun, oṣupa si ti yọ jade tan lakooko Irekọja. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìmúṣókùnkùn oṣupa kii pẹ ju iwọnba iṣẹju diẹ lọ. Nitori naa okunkun naa ní ipilẹṣẹ atọrunwa! O ṣeeṣe ki o pa awọn wọnni ti nfi Jesu ṣẹlẹya lẹnumọ fun ìgbà diẹ, ani ki o tilẹ dá ipẹgan wọn duro.

      Bí àrà meriyiiri akojinnijinni bani naa ba ṣẹlẹ ṣaaju ki oluṣe buburu naa tó ba ẹlẹgbẹ rẹ wi ti o si bẹ Jesu lati ranti oun, o le jẹ ìdí fun ironupiwada rẹ. O ṣeeṣe ki o jẹ pe laaarin okunkun naa ni awọn obinrin mẹrin, ti wọn jẹ, iya Jesu ati Salome arabinrin rẹ, Maria Magidaleni, ati Maria iya apọsiteli Jakọbu Kekere, ti wa ọna de ìtòsí opo-igi idaloro naa. Johanu, apọsiteli aayo olufẹ Jesu, wà pẹlu wọn nibẹ.

      Bawo ni ọkan iya Jesu ti ‘gbọgbẹ́’ tó bi oun ti nwo ọmọkunrin rẹ ti oun tọ́ ti oun si bọ́ dagba ti a gbe kọ́ ninu irora! Sibẹ, Jesu ko ronu nipa irora tirẹ funraarẹ, ṣugbọn nipa ipo alaafia iya rẹ. Pẹlu isapa nlanla, o mi ori si Johanu o si wi fun iya rẹ pe: “Ìyá, wòó! Ọmọkunrin rẹ!” Lẹhin naa, ni mimi ori siha Maria, o wi fun Johanu pe: “Wòó! Iya rẹ!”

      Jesu tipa bayi fi itọju iya rẹ, ẹni ti o jẹ opó lọna ti o han gbangba nisinsinyi le apọsiteli rẹ ti oun nifẹẹ lọna akanṣe lọwọ. Oun ṣe eyi nitori pe awọn ọmọkunrin Maria miiran ko tii fi igbagbọ han ninu rẹ sibẹ. Oun tipa bayii fi apẹẹrẹ rere lelẹ ti ṣiṣe ipese kii ṣe kiki fun aini iya rẹ̀ nipa ti ara nikan ṣugbọn fun aini tẹmi rẹ̀ pẹlu.

      Ni nǹkan bi agogo mẹta ọsan, Jesu wipe: “Oungbẹ ngbẹ mi.” Jesu nimọlara pe Baba rẹ ti, bii pe o ri bẹẹ nitootọ, fa ọwọ́ aabo sẹhin kuro lọdọ rẹ̀ ki a ba le dán iwatitọ rẹ̀ wò de gongo. Nitori naa o ke jade pẹlu ohùn rara pe: “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, eeṣe ti iwọ fi kọ mi silẹ?” Ni gbigbọ eyi awọn kan ti wọn duro nitosi kigbe soke pe: “Wòó! oun npe Elija.” Lọ́gán ọkan ninu wọn sare ó sì mu kàn-ìnkàn-ìn ti a ti rì bọnu ọti kikan ní ipẹkun pòròpórò hisopu kan, o fun un ni ohun mimu. Ṣugbọn awọn miiran wipe: “Ẹ jẹ ki o ku! Ẹ jẹ ki a ri boya Elija yoo wa lati sọ ọ kalẹ.”

      Nigba ti Jesu gba ọti kikan naa, o kigbe jade pe: “O pari!” Bẹẹni, oun ti pari ohun gbogbo ti Baba rẹ ti ran an wa si ilẹ-aye lati ṣe. Nikẹhin, oun wipe: “Baba, ni ọwọ rẹ ni mo fi ẹmi mi le.” Jesu tipa bayi fi ipá iwalaaye rẹ̀ le Ọlọrun lọwọ pẹlu igbọkanle pe Ọlọrun yoo mú un pada bọsipo fun oun lẹẹkan sii. Lẹhin naa o tẹri ara rẹ ba o si ku.

      Lakooko ti Jesu mi èémí rẹ ikẹhin, isẹlẹ buburu kan waye, ti o ṣi awọn apata ràbàtàràbàtà silẹ. Isẹlẹ naa lagbara tobẹẹ gẹẹ ti awọn iboji iranti lẹhin ode Jerusalẹmu fi fọ, ara awọn oku ni a si gbe sọ sita kuro ninu wọn. Awọn ti nkọja lọ, ti wọn ri awọn ara oku naa ti o wà ni gbangba, wọ inu ilu lọ wọn si rohin rẹ̀.

      Siwaju sii pẹlu, ni akoko ti Jesu ku, ìkélé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ ti o pin ibi Mimọ kuro lara ibi Mimọ Julọ ninu tẹmpili Ọlọrun ni o faya si meji, lati oke delẹ. Yoo fẹrẹẹ jẹ pe, ìkélé ti a ṣe lọṣọọ daradara yi jẹ nǹkan bi ẹsẹ bata 60 lóòró o si wuwo gan-an! Kii ṣe kìkì pe àgbàyanu Iṣẹ-iyanu naa fi ibinu Ọlọrun han lodisi awọn ti o pa Ọmọkunrin Rẹ nikan ni, ṣugbọn o fihan pe wiwọle sinu ibi Mimọ Julọ naa, ọrun funraarẹ, ni a mu ki o ṣeeṣe nisinsinyi nipasẹ iku Jesu.

      O dara, nigba ti awọn eniyan nimọlara isẹlẹ naa ti wọn si ri ohun ti nṣẹlẹ, ẹru ba wọn gidigidi. Ijoye oṣiṣẹ ti o wa nidii ifiya iku jẹni naa fi ogo fun Ọlọrun. “Dajudaju Ọmọkunrin Ọlọrun ni eyi,” ni oun polongo. O ṣeeṣe ki oun ti wa nibẹ nigba ti a jiroro jijẹ ọmọkunrin atọrunwa nibi igbẹjọ Jesu niwaju Pilatu. Nisinsinyi oun ni idaniloju pe Jesu ni Ọmọkunrin Ọlọrun, bẹẹni, pe oun nitootọ ni ọkunrin titobilọla julọ ti o tíì gbe aye ri.

      Awọn miiran pẹlu ni awọn iṣẹlẹ agbayanu wọnyi já láyà, wọn si bẹrẹsii pada si ile wọn ni lílu àyà wọn, gẹgẹ bi ifaraṣapejuwe ìbànújẹ́ ati ìtìjú mímúná. Ọpọlọpọ awọn obinrin ti wọn jẹ ọmọ-ẹhin Jesu ni a sun lọna jijinlẹ nipa awọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wọnyi bi wọn ti nkiyesi iran apewo yii lati okeere. Apọsiteli Johanu wà nibẹ pẹlu. Matiu 27:45-56, NW; Maaku 15:33-41; Luuku 23:44-49; 2:34, 35; Johanu 19:25-30.

      ▪ Eeṣe ti ìmúṣókùnkùn òṣùpá ko fi lè jẹ́ idi fun òkùnkùn oni wákàtí mẹta naa?

      ▪ Ní kete ṣaájú ikú rẹ̀, apẹẹrẹ rere wo ni Jesu pèsè fun awọn wọnni ti wọ́n ní awọn obi ọlọ́jọ́lórí?

      ▪ Ki ni awọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ mẹrin ti Jesu sọ kẹhin ṣaaju iku rẹ̀?

      ▪ Ki ni ìsẹ̀lẹ̀ naa ṣàṣeparí rẹ̀, ki si ni ìjẹ́pàtàkì ìkélé tẹmpili ti o fàya si meji?

      ▪ Bawo ni awọn iṣẹlẹ naa ṣe nípalórí ìjòyè òṣìṣẹ́ ti o wa nidii ìfìyà ikú jẹni naa?

  • A Sin ín ni Friday—Iboji Rẹ̀ Ṣofo ni Sunday
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    • Orí 127

      A Sin ín ni Friday—Iboji Rẹ̀ Ṣofo ni Sunday

      NISINSINYI o ti di ọjọ́rọ̀ ni Friday, Sabaati Nisan 15 yoo sì bẹrẹ nigba ti oorun bá wọ̀. Oku Jesu sorọ̀ jọwọlọ lori opo igi naa, ṣugbọn awọn ọlọṣa meji tí ó wà lẹgbẹ rẹ̀ ṣì walaaye. Ọsan Friday ni a ńpè ni Ipalẹmọ nitori akoko yii ni awọn eniyan maa nṣe ounjẹ ti wọn sì maa npari iṣẹ kanjukanju miiran eyikeyii ti a kò le dá dúró di ẹhin Sabaati.

      Sabaati ti yoo bẹrẹ laipẹ kii ṣe kiki Sabaati ti a nṣe deedee (ni ọjọ keje ọsẹ) ṣugbọn o tun jẹ Sabaati onipele meji, tabi “nla.” A pe e lọna yii nitori pe Nisan 15, eyi ti o jẹ ọjọ akọkọ Ajọdun ọlọjọ meje ti awọn Akara Aiwu (o si saba maa njẹ Sabaati kan, laika ọjọ ti o ba bọ si laaarin ọsẹ), bọ si ọjọ kan naa gẹgẹ bi Sabaati ti a nṣe deedee.

      Gẹgẹ bi Ofin Ọlọrun ti wi, òkú ni a ko nilati fi silẹ ni sisorọ sori òpó igi di igba ti ilẹ ba mọ́. Nitori naa awọn Juu beere lọwọ Pilatu pe ki a tètè mu iku awọn wọnni ti a nfiya iku jẹ yara kankan nipa dida ẹsẹ wọn. Nitori naa, awọn ọmọ ogun da ẹsẹ awọn ọlọṣa mejeeji. Ṣugbọn niwọn bi Jesu ti farahan bi ẹni ti o ti ku, ẹsẹ rẹ̀ ni a ko dá. Eyi mu asọtẹlẹ iwe mimọ ṣẹ pe: “A ki yoo dá egungun rẹ̀ kankan.”

      Bi o ti wu ki o ri, lati mu iyemeji yii kuro pe Jesu ti ku nitootọ, ọkan lara awọn ọmọ ogun naa fi ọ̀kọ̀ gún ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ọ̀kọ̀ naa gun un lọ si apa iha ọkan rẹ̀, lẹsẹkẹsẹ ẹ̀jẹ̀ ati omi si jade wa. Apọsiteli Johanu, ẹni ti ọ̀ràn ṣoju rẹ̀, rohin pe eyi mu iwe mimọ miiran ṣẹ pe: “Wọn yoo maa wo Ẹni naa ti wọn gún lọ́kọ̀.”

      Ẹni ti o tun wa nibi ifiya iku jẹni naa ni Josẹfu lati ilu Arimatia, mẹmba Sanhẹdrin kan ti o ni orukọ rere. Oun kọ̀ lati fọwọsi igbesẹ alaiba idajọ ododo mu ti ile-ẹjọ giga lodisi Jesu. Josẹfu jẹ ọmọ ẹhin Jesu nitootọ, bi o tilẹ jẹ pe oun ti bẹru lati fi ara rẹ̀ hàn gẹgẹ bi ọ̀kan. Bi o ti wu ki o ri, nisinsinyi oun lo igboya o si lọ sọdọ Pilatu lati beere fun oku Jesu. Pilatu ranṣẹ pe ijoye oṣiṣẹ ologun ti o wa ni abojuto, lẹhin ti ijoye oṣiṣẹ naa sì ti mú un daju pe Jesu ti ku, Pilatu jẹ ki a fa oku naa lé e lọwọ.

      Josẹfu gbe oku naa o sì fi aṣọ fẹlẹfẹlẹ mimọtonitoni wé e ni imurasilẹ fun isinku. Nikodemu, mẹmba Sanhẹdrin miiran, ràn án lọwọ. Nikodemu pẹlu ti kuna lati jẹwọ igbagbọ rẹ̀ ninu Jesu ni gbangba nitori ibẹru pipadanu ipo rẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyi o mu àkápọ̀ kan ti o ni òjíá ninu ti ìwọ̀n rẹ̀ to nǹkan bii pound ọgọrun-un ati aloe olowo iyebiye wá. Ara Jesu ni a fi aṣọ ti a fi ndi ọgbẹ́ ti o ni awọn oorun didun wọnyi wé, gan-an gẹgẹ bi àṣà ti awọn Juu gbà nmura oku silẹ fun sísin.

      Lẹhin eyi ara naa ni a tẹ́ sinu iboji iranti titun ti Josẹfu ti a gbẹ sinu apata ninu ọgbà nitosi. Nikẹhin, okuta nla kan ni a yi bo iwaju iboji naa. Lati ṣaṣepari sisin oku naa ṣaaju Sabaati, ipalẹmọ ara oku naa jẹ kanjukanju. Nitori naa, Maria Magidaleni ati Maria iya Jakọbu Kekere, awọn ti o ṣeeṣe ki wọn ti maa ṣe itilẹhin ninu imurasilẹ naa, yara lọ si ile lati pese ohun oloorun didun ati òróró lọ́fíndà si i. Lẹhin Sabaati, wọn ṣeto lati tọju ara oku Jesu siwaju sii lati pa a mọ laidibajẹ fun saa akoko gigun kan.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́