ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Sin ín ni Friday—Iboji Rẹ̀ Ṣofo ni Sunday
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    • Ni kutukutu owurọ Sunday Maria Magidaleni, Maria iya Jakọbu, papọ pẹlu Salomẹ, Joanna, ati awọn obinrin miiran, mu awọn ohun oloorun didun wá sibi iboji naa lati tọju ara oku Jesu. Loju ọna wọn sọ fun araawọn pe: “Ta ni yoo yi okuta kuro lẹnu ilẹkun iboji iranti fun wa?” Ṣugbọn nigba ti wọn de ibẹ, wọn rii pe isẹlẹ kan ti ṣẹlẹ angẹli Jehofa sì ti yi okuta naa kuro. Awọn oluṣọ ti lọ, iboji naa sì ṣofo! Matiu 27:57–28:2; Maaku 15:42–16:4; Luuku 23:50–24:3, 10; Johanu 19:14, Joh 19:31–20:1; Joh 12:42; Lefitiku 23:5-7; Deutaronomi 21:22, 23; Saamu 34:20; Sẹkaraya 12:10.

  • Jesu Walaaye!
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    • Orí 128

      Jesu Walaaye!

      NIGBA ti awọn obinrin naa ri iboji Jesu ti o ṣofo, Maria Magidaleni sare lọ lati sọ fun Peteru ati Johanu. Bi o ti wu ki o ri, o han gbangba pe awọn obinrin yooku duro si ibi iboji naa. Laipẹ, angẹli kan farahan o sì kesi wọn wọle.

      Nihin-in awọn obinrin naa tun ri angẹli miiran, ọkan lara awọn angẹli naa sì wi fun wọn pe: “Ẹ maṣe bẹru, nitori mo mọ̀ pe ẹyin nwa Jesu ẹni ti a kàn mọgi. Oun kò si nihin-in, nitori a ti ji i dide, gẹgẹ bi o ti wi. Ẹ wa, ẹ wo ibi ti o ti dubulẹ si. Ẹ lọ kiakia ki ẹ sì sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe a ti gbe e dide kuro ninu oku.” Nitori naa pẹlu ibẹru ati ayọ, awọn obinrin wọnyi sare lọ pẹlu.

      Ni akoko yii, Maria ti ri Peteru ati Johanu, o sì rohin fun wọn pe: “Wọn ti gbe Oluwa lọ kuro ninu iboji iranti, awa kò sì mọ ibi ti wọn tẹ ẹ si.” Lọ́gán awọn apọsiteli mejeeji bẹrẹ eré sisa. Johanu jẹ ẹlẹ́sẹ̀ ehoro—o han gbangba pe oun ni o kere jù—o si de iboji naa ṣaaju. Ni akoko yii awọn obinrin naa ti lọ, nitori naa ko si ẹni kankan ni ayika. Ni bibẹrẹ mọlẹ, Johanu bẹjuwo inu iboji naa o sì ri awọn ọ̀já ìdìkú, ṣugbọn o duro sita.

      Nigba ti Peteru de, oun kò jáfara ṣugbọn o wọnu iboji lọ. Oun ri awọn ọ̀já ìdìkú ti wọn wà nílẹ̀ nibẹ ati awọn aṣọ ti a fi di ori Jesu. A yí i pọ si oju kan. Nisinsinyi Johanu pẹlu wọ inu iboji naa, o sì gba irohin Maria gbọ. Ṣugbọn yala Peteru tabi Johanu ko loye pe Jesu ni a ti ji dide, ani bi o tilẹ jẹ pe Oun ti fi igba gbogbo sọ fun wọn pe oun yoo ji dide. Awọn mejeeji pada sile pẹlu kayefi, ṣugbọn Maria, ẹni ti o ti pada sibi iboji naa, duro nibẹ.

      Laaarin akoko naa, awọn obinrin yooku nyara lọ lati sọ fun awọn ọmọ-ẹhin pe Jesu ti ji dide, gẹgẹ bi awọn angẹli naa ti paṣẹ fun wọn lati ṣe. Nigba ti wọn nsare lọ loju ọna bi wọn ti lè ṣe to, Jesu pade wọn o sì wipe: “Ẹ pẹlẹ o!” Ni wiwolẹ sibi ẹsẹ rẹ̀, wọn wárí fun un. Nigba naa Jesu wipe: “Ẹ ma bẹru! Ẹ lọ, ẹ rohin fun awọn arakunrin mi, ki wọn lè lọ si Galili; nibẹ ni wọn yoo sì ri mi.”

      Ṣaaju, nigba ti ìsẹ̀lẹ̀ sẹ ti awọn angẹli naa sì farahan, awọn ọmọ ogun ti wọn ńṣọ́ ẹ̀ṣọ́ ni jìnnìjìnnì bá wọn sì dabi oku eniyan. Lẹhin ti ara wọn ti kọ́fẹ, wọn lọ sinu ilu naa lọgan wọn sì sọ ohun ti o ti ṣẹlẹ fun awọn olori alufaa. Lẹhin fifi ikùn lukùn pẹlu “awọn àgbà ọkunrin” awọn Juu, ipinnu ni wọn ṣe lati gbiyanju lati maṣe jẹ ki awọn eniyan mọ̀ nipa ọran naa nipa fifun awọn ọmọ ogun naa ni àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Wọn fun wọn ni itọni pe: “Ẹ wipe, ‘Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá ni òru wọn sì jí i gbe nigba ti awa nsun.’”

      Niwọn bi o ti jẹ pe awọn ọmọ ogun Roomu ni a lè fiya iku jẹ fun sisun ni ẹnu iṣẹ wọn, awọn alufaa ṣeleri pe: “Bi eyi [irohin pe ẹ sun] ba sì de etí gomina, awa yoo yí i lọkan pada yoo sì da yin silẹ lominira kuro ninu wahala.” Niwọn bi iye owo abẹtẹlẹ naa ti pọ̀ lọna ti o tẹrun, awọn ọmọ ogun naa ṣe gẹgẹ bi a ti fun wọn ni itọni. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, irohin eke nipa jíjí okú Jesu gbé di eyi ti o tankalẹ lọna gbigbooro laaarin awọn Juu.

      Maria Magidaleni, ẹni ti o duro sẹhin nibi iboji naa, ni ẹ̀dùn ọkàn bò mọlẹ. Nibo ni Jesu le wa? Ni títẹ̀ba siwaju lati wo inu iboji naa, oun ri awọn angẹli meji ninu aṣọ funfun, ti wọn ti tun farahan! Ọkan jokoo nibi ori ati ekeji nibi ẹsẹ nibi ti a ti tẹ́ ara Jesu si. “Obinrin, eeṣe ti iwọ fi nsunkun?” ni wọn beere.

      Maria dahun pe: “Wọn ti gbe Oluwa mi lọ, emi kò sì mọ ibi ti wọn tẹ́ ẹ si.” Lẹhin naa oun yipada o si ri ẹnikan ti o tun ibeere naa beere pe: “Obinrin, eeṣe ti iwọ fi nsunkun?” Ẹni yii tun beere pe: “Ta ni iwọ nwa?”

      Ni riro pe ẹni yii jẹ́ olùtọ́jú iboji naa, o sọ fun un pe: “Alagba, bi iwọ ba ti gbe e kuro, sọ ibi ti iwọ tẹ ẹ si fun mi, emi yoo sì gbe e lọ.”

      Ẹni naa wipe: “Maria!” Lọ́gán oun sì mọ pe Jesu ni, nipa ọna ti oun mọ̀ daadaa ti ẹni naa gbà sọrọ si i. Ó sì ké jade pe: “Rab·boʹni!” (ti o tumọsi “Olukọ!”) Ati pẹlu ayọ ti kò láàlà, o gbá a mu. Ṣugbọn Jesu wipe: “Dẹkun rírọ̀ mọ mi. Nitori emi kò tii goke lọ sọdọ Baba sibẹ. Ṣugbọn mu ọna rẹ pọ̀n lọ si ọ̀dọ̀ awọn arakunrin mi ki o sì wi fun wọn pe, ‘Emi ngoke lọ sọdọ Baba mi ati Baba yin ati sọdọ Ọlọrun mi ati Ọlọrun yin.’”

      Nisinsinyi Maria sare lọ si ibi ti awọn apọsiteli ati awọn ọmọ-ẹhin ẹlẹgbẹ rẹ̀ ti korajọ si. O fi irohin tirẹ̀ kun irohin tí awọn obinrin yooku ti sọ nipa riri Jesu ti a ji dide. Sibẹ, awọn ọkunrin wọnyi, ti wọn kò gba awọn obinrin akọkọ gbọ́, lọna ti o han gbangba ko gba Maria gbọ́ pẹlu. Matiu 28:3-15, NW; Maaku 16:5-8; Luuku 24:4-12; Johanu 20:2-18, NW.

      ▪ Lẹhin biba iboji naa ni ṣiṣofo, ki ni Maria Magidaleni ṣe, iriri wo sì ni awọn obinrin yooku naa ni?

      ▪ Bawo ni Peteru ati Johanu ṣe huwapada ni rírí iboji tí ó ṣófo naa?

      ▪ Ki ni awọn obinrin yooku ba pade loju ọna nigba ti wọn nlọ lati rohin ajinde Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin?

      ▪ Ki ni o ti ṣẹlẹ si ẹṣọ ọmọ ogun, ki sì ni ihuwapada si irohin wọn fun awọn alufaa?

      ▪ Ki ni o ṣẹlẹ nigba ti Maria Magidaleni dá nikan wà nibi iboji naa, ki sì ni iṣarasihuwa awọn ọmọ-ẹhin si irohin awọn obinrin naa?

  • Awọn Ifarahan Siwaju Sii
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
    • AWỌN ọmọ-ẹhin ṣi rẹwẹsi sibẹ. Wọn ko loye ijẹpataki iboji ṣiṣofo naa, bẹẹ si ni wọn kò gba irohin awọn obinrin naa gbọ́. Nigba ti o ya ni ọjọ Sunday, Kleopa ati ọmọ-ẹhin miiran fi Jerusalẹmu silẹ lọ si Ẹmausi, nibi ti o jinna tó nǹkan bii ibusọ meje.

      Ní oju ọna, nigba ti wọn njiroro awọn iṣẹlẹ ọjọ naa, ajeji kan darapọ mọ́ wọn. O beere pe, “Ki ni kókó ọrọ wọnyi ti ẹ njiyan le lori laaarin araayin bi ẹ ti nrin lọ?”

      Awọn ọmọ-ẹhin naa duro, oju wọn rẹwẹsi, Kleopa si fesipada pe: “Iwọ ha ngbe ní iwọ nikan gẹgẹ bi atipo ní Jerusalẹmu nipa bẹẹ tí o kò mọ awọn nǹkan ti wọn ti ṣẹlẹ ninu rẹ̀ ni awọn ọjọ wọnyi?” O beere pe, “Awọn nǹkan wo?”

      “Awọn nǹkan nipa Jesu ti Nasarẹti,” ni wọn dahun. “Awọn olori alufaa wa ati awọn oluṣakoso fi í lé idajọ iku lọwọ tí wọn sì kàn án mọ́gi. Ṣugbọn awa nreti pe ọkunrin yii ni ẹni naa ti a kadara lati dá Isirẹli nídè.’

      Kleopa ati alabaakẹgbẹ rẹ̀ ṣalaye awọn iṣẹlẹ ayanilẹnu ọjọ naa—irohin nipa iran ti o ga ju ti ẹda lọ ti awọn angẹli ati iboji ṣiṣofo—ṣugbọn lẹhin naa wọn jẹwọ iyalẹnu jijinlẹ wọn nipa itumọ awọn nǹkan wọnyi. Ajeji naa ba wọn wipe: “Óò ẹyin alailoye ti ẹ si lọra ni ọkan lati gba gbogbo ohun ti awọn wolii sọ gbọ! Ko ha jẹ́ ọranyan fun Kristi lati jiya nǹkan wọnyi ki o si wọ inú ogo rẹ̀?” Lẹhin naa oun tumọ awọn ayọka lati inú ọrọ ẹsẹ iwe mímọ́ ti o niiṣe pẹlu Kristi fun wọn.

      Nikẹhin wọn de eti Ẹmausi, ajeji naa ṣe bii ẹni ti o ṣi nba irin àjò niṣo. Ni fifẹ lati gbọ sii, awọn ọmọ-ẹhin naa rọ̀ ọ́ pe: “Duro pẹlu wa, nitori o ti nsunmọ alẹ.” Nitori naa o duro fun ounjẹ. Bi o ti gbadura ti o si bu akara ti o si nà án si wọn, wọn mọ̀ daju pe oun niti gidi ni Jesu ti o gbé ara ẹda eniyan wọ. Ṣugbọn lẹhin naa oun nù mọ́ wọn loju.

      Nisinsinyi wọn loye idi ti ajeji naa fi mọ pupọ tobẹẹ! Wọn beere pe, “Ọkan aya wa kò ha gbina bi o ti nba wa sọrọ ni oju ọna, ti o si nṣi awọn Iwe Mimọ payá fun wa ni kikun?” Laijafara, wọn dide wọn sì yara pada lọ si Jerusalẹmu, nibi ti wọn ti ri awọn apọsiteli ati awọn wọnni tí wọn pejọ pẹlu wọn. Ṣaaju ki Kleopa ati ẹnikeji rẹ̀ tó le sọ ohun kan, awọn yooku rohin pẹlu irusoke pe: “Niti tootọ Oluwa ti ji dide o si fi ara han Simoni!” Lẹhin naa awọn meji naa rohin bi Jesu ti farahan wọn pẹlu. Eyi jẹ́ igba kẹrin laaarin ọjọ naa ti oun ti farahan awọn ẹni ọtọọtọ laaarin awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

      Jesu lojiji ṣe ifarahan karun-un, ani bi o tilẹ jẹ pe awọn ilẹkun ni a tipa nitori pe awọn ọmọ-ẹhin wà ninu ibẹru awọn Juu, ó wọle, ó sì duro laaarin wọn gan-an, o si wipe: “Alaafia fun yin.” A dáyà já wọn, ni riro pe wọn ti ri ẹmi kan. Nitori naa, ni ṣiṣalaye pe oun kii ṣe ìran abàmì, Jesu wipe: “Eeṣe ti ẹ fi ńdààmú, eesitiṣe ti iyemeji fi dide ninu ọkan-aya yin? Ẹ wo awọn ọwọ́ mi ati awọn ẹsẹ̀ mi, pe emi funraami ni; ẹ fọwọba mi ki ẹ si ri, nitori ẹmi kò ni ẹran ati egungun gan-an gẹgẹ bi ẹ ti ri pe emi ni.” Sibẹ, wọn lọra lati gbagbọ.

      Lati ran wọn lọwọ lati loye pe oun ni Jesu nitootọ, o beere pe: “Ẹ ni ohun kan nibẹ lati jẹ bí?” Lẹhin titẹwọgba ègé ẹja sísè ti o si jẹ ẹ, o wipe: “Iwọnyi ni ọrọ mi ti mo sọ fun yin nigba ti mọ ṣi wa pẹlu yin [ṣaaju iku mi], pe gbogbo nǹkan ti a ti kọ sinu ofin Mose ati ninu awọn Wolii ati awọn Saamu nipa mi ni a gbọdọ múṣẹ.”

      Nitootọ, ni biba ohun ti o jásí ikẹkọọ Bibeli lọ pẹlu wọn, Jesu kọ wọn pe: “Ni ọ̀nà yii ni a ti kọ ọ́ pe Kristi yoo jiya yoo si dide laaarin awọn oku ni ọjọ kẹta, ati lori ipilẹ orukọ rẹ a o waasu ironupiwada fun idariji ẹṣẹ ninu gbogbo awọn orilẹ-ede—bẹrẹ lati Jerusalẹmu, ẹyin yoo jẹ́ ẹlẹrii awọn nǹkan wọnyi.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́