-
Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Agbo Ilé RẹÀṣírí Ayọ̀ Ìdílé
-
-
ORÍ KỌKÀNLÁ
Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Agbo Ilé Rẹ
1. Kí ni àwọn nǹkan tí ó lè fa ìpínyà nínú ìdílé?
ALÁYỌ̀ ni àwọn tí ó jẹ́ apá kan àwọn ìdílé tí ìfẹ́, ìfòyebánilò, àti àlàáfíà wà. A retí pé, irú ìyẹn ni ìdílé rẹ jẹ́. Ó bani nínú jẹ́ pé, àìmọye ìdílé kùnà láti bá àpèjúwe yẹn mu, wọ́n sì pínyà fún ìdí kan tàbí òmíràn. Kí ní ń pín agbo ilé níyà? Nínú orí yìí, a óò jíròrò ohun mẹ́ta. Nínú àwọn ìdílé kan, àwọn mẹ́ḿbà kì í ṣe onísìn kan náà. Nínú àwọn ìdílé mìíràn, ó lè jẹ́ pé kì í ṣe àwọn òbí kan náà ni ó bí àwọn ọmọ. Nínú àwọn mìíràn ẹ̀wẹ̀, wàhálà àtirí oúnjẹ òòjọ́ tàbí ìfẹ́ ọkàn fún ohun ìní ti ara púpọ̀ sí i, dà bí èyí tí ń pín àwọn mẹ́ḿbà ìdílé níyà. Síbẹ̀, àwọn àyíká ipò tí ń pín agbo ilé kan níyà lè ṣàìnípa lórí òmíràn. Kí ní ń fa ìyàtọ̀ náà?
2. Níbo ni àwọn kan ń yíjú sí fún ìtọ́sọ́nà nínú ìgbésí ayé ìdílé, ṣùgbọ́n kí ni orísun dídára jù lọ fún irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀?
2 Ojú ìwòye jẹ́ kókó kan. Bí o bá fi tọkàntọkàn gbìyànjú láti lóye ojú ìwòye ẹnì kejì, ó ṣeé ṣe kí o fòye mọ bí o ṣe lè pa agbo ilé tí ó wà níṣọ̀kan mọ́. Orísun ìtọ́sọ́nà rẹ jẹ́ kókó kejì. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, àwọn aládùúgbò wọn, àwọn akọ̀rọ̀ nínú ìwé ìròyìn, tàbí àwọn amọ̀nà míràn tí ẹ̀dá ènìyàn gbé kalẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn kan ti rí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ nípa ipò wọn, wọ́n sì ti lo ohun tí wọ́n kọ́. Báwo ni ṣíṣe èyí ṣe lè ran ìdílé lọ́wọ́ láti jẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú agbo ilé?—2 Timoteu 3:16, 17.
BÍ ỌKỌ RẸ BÁ NÍ ÌGBÀGBỌ́ TÍ Ó YÀTỌ̀
3. (a) Kí ni ìmọ̀ràn Bibeli nípa ṣíṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀? (b) Àwọn ìlànà pàtàkì wo ni ó ṣeé fi sílò tí ẹnì kan nínú ìgbéyàwó bá jẹ́ onígbàgbọ́ tí ẹnì kejì sì jẹ́ aláìgbàgbọ́?
3 Bibeli fún wa nímọ̀ràn gidigidi lòdì sí ṣíṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹnì kan tí ó ní ìgbàgbọ́ ìsìn tí ó yàtọ̀. (Deuteronomi 7:3, 4; 1 Korinti 7:39) Ṣùgbọ́n, ó lè jẹ́ pé, o kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láti inú Bibeli lẹ́yìn ìgbéyàwó rẹ, ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ni ṣíṣe? Dájúdájú, ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó náà ṣì fìdí múlẹ̀. (1 Korinti 7:10) Bibeli tẹnu mọ́ ìwàpẹ́títí ìdè ìgbéyàwó, ó sì fún àwọn tí ó ti ṣègbéyàwó níṣìírí láti wá ọ̀nà láti yanjú aáwọ̀ wọn dípò yíyẹ̀ wọ́n sílẹ̀. (Efesu 5:28-31; Titu 2:4, 5) Ṣùgbọ́n, bí ọkọ rẹ bá fi àtakò gidigidi hàn sí ṣíṣe tí o ń ṣe ìsìn tí ó bá Bibeli mu ńkọ́? Ó lè gbìyànjú láti dí ọ lọ́wọ́ lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, tàbí ó lè sọ pé òun kò fẹ́ kí aya òun máa ya ojúlé kiri, láti máa sọ̀rọ̀ nípa ìsìn. Kí ni ìwọ yóò ṣe?
4. Ní ọ̀nà wo ni aya kan fi lè fi ẹ̀mí ìfọ̀ràn-rora-ẹni-wò hàn bí ọkọ rẹ̀ kò bá ṣàjọpín ìgbàgbọ́ rẹ̀?
4 Bí ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ní ń mú kí ọkọ mi hùwà bí ó ṣe ń hùwà?’ (Owe 16:20, 23) Bí kò bá lóye ohun tí o ń ṣe ní tòótọ́, ó lè máa dààmú nípa rẹ? Tàbí ó lè wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan, nítorí pé o kò tún bá wọn lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà kan tí wọ́n kà sí pàtàkì. Ọkọ kan wí pé: “Fífi èmi nìkan sílẹ̀ nínú ilé ń mú kí n nímọ̀lára pé a ti pa mí tì.” Ọkùnrin yìí rò pé ìsìn ń gba aya mọ òun lọ́wọ́. Síbẹ̀, ìgbéraga kò mú kí ó gbà pé òún dá nìkan wà. Ọkọ rẹ lè nílò ìdánilójú pé, ìfẹ́ rẹ fún Jehofa kò túmọ̀ sí pé, ó kò nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ nísinsìnyí tó bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Rí i pé o ń lo àkókò pẹ̀lú rẹ̀.
5. Ìwàdéédéé wo ni aya tí ọkọ rẹ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí ó yàtọ̀ ní láti dì mú?
5 Ṣùgbọ́n, o gbọ́dọ̀ gbé ohun kan tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì yẹ̀ wò, bí o bá fẹ́ kojú ipò náà pẹ̀lú ọgbọ́n. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun rọ àwọn aya pé: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún awọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ ninu Oluwa.” (Kolosse 3:18) Nípa báyìí, ó kìlọ̀ lòdì sí ẹ̀mí dáńfó gedegbe. Ní àfikún sí i, nípa sísọ pé “gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ ninu Oluwa,” ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí fi hàn pé ìtẹríba fún ọkọ ẹni, ní láti gbé ìtẹríba fún Oluwa yẹ̀ wò pẹ̀lú. Ó gbọ́dọ̀ wà déédéé.
6. Àwọn ìlànà wo ni ó yẹ kí Kristian aya fi sọ́kàn?
6 Lójú Kristian kan, lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ àti jíjẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìgbàgbọ́ ẹni, tí a gbé karí Bibeli, jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́ tí a kò gbọdọ̀ fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. (Romu 10:9, 10, 14; Heberu 10:24, 25) Nígbà náà, kí ni ìwọ yóò ṣe, bí ẹ̀dá ènìyàn kan bá pàṣẹ fún ọ ní tààràtà láti má ṣe tẹ̀ lé ohun kan pàtó tí Ọlọrun béèrè fún? Àwọn aposteli Jesu Kristi polongo pé: “Awa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Àpẹẹrẹ wọ́n pèsè àwòṣe kan tí ó ṣeé mú lò nínú ọ̀pọ̀ ipò nínú ìgbésí ayé. Ìfẹ́ fún Jehofa yóò ha sún ọ láti fún un ní ìfọkànsìn tí ó tọ́ sí i bí? Lọ́wọ́ kan náà, ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí o ní fún ọkọ rẹ yóò ha mú kí o gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọ̀nà kan tí kì yóò bí ọkọ rẹ nínú bí?—Matteu 4:10; 1 Johannu 5:3.
7. Ìpinnu wo ni Kristian aya gbọ́dọ̀ ní?
7 Jesu sọ pé, èyí kò lè fìgbà gbogbo ṣeé ṣe. Ó kìlọ̀ pé, nítorí àtakò sí ìjọsìn tòótọ́, àwọn mẹ́ḿbà tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ nínú àwọn ìdílé kan yóò nímọ̀lára pé a ti pín àwọn níyà, bíi pé idà kan ti pín àwọn àti ìyókù ìdílé wọn níyà. (Matteu 10:34-36) Obìnrin kan ní Japan nírìírí èyí. Ọdún 11 ni ọkọ rẹ̀ fi ta kò ó. Ó hùwà rírorò sí i, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó sì tì í mọ́ta. Ṣùgbọ́n ó forí tì í. Àwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ Kristian ràn án lọ́wọ́. Ó gbàdúrà láìdábọ̀, ó sì rí ọ̀pọ̀ ìṣírí láti inú 1 Peteru 2:20. Ó dá obìnrin Kristian yìí lójú pé, bí òún bá dúró ṣinṣin, lọ́jọ́ kan ṣáá, ọkọ òun yóò dara pọ̀ mọ́ òun nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa. Ọkọ rẹ̀ sì ṣe bẹ́ẹ̀.
8, 9. Báwo ni aya kan ṣe lè yẹra fún gbígbé àwọn ohun ìdènà tí kò pọn dandan síwájú ọkọ rẹ̀?
8 Ọ̀pọ̀ àwọn ohun gbígbéṣẹ́ ń bẹ tí o lè ṣe tí ó lè nípa lórí ìṣarasíhùwà alábàáṣègbéyàwó rẹ. Fún àpẹẹrẹ, bí ọkọ rẹ bá ta ko ìsìn rẹ, má ṣe fún un ní ìdí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún ṣíṣàwáwí ní àwọn agbègbè míràn. Jẹ́ kí ilé wà ní mímọ́ tónítóní. Máa tún ìrísí ara rẹ ṣe. Máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ àti ìmọrírì lóòrèkóòrè. Dípò ṣíṣe lámèyítọ́, jẹ́ alátìlẹ́yìn. Fi hàn pé, o ń wò ó gẹ́gẹ́ bí olórí. Má ṣe gbẹ̀san bí o bá nímọ̀lára pé ó ti ṣẹ̀ ọ́. (1 Peteru 2:21, 23) Fàyè sílẹ̀ fún àìpé ẹ̀dá ènìyàn, bí aáwọ̀ bá sì ṣẹlẹ̀, jẹ́ ẹni tí yóò kọ́kọ́ tọrọ àforíjì tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀.—Efesu 4:26.
9 Má ṣe jẹ́ kí lílọ sí àwọn ìpàdé jẹ́ ìdí tí oúnjẹ rẹ̀ yóò fi pẹ́ délẹ̀. O tún lè yàn láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian nígbà míràn tí ọkọ rẹ kò bá sí nílé. Ó bọ́gbọ́n mu fún Kristian aya kan láti yàgò fún wíwàásù fún ọkọ rẹ̀, nígbà tí kò bá nífẹ̀ẹ́ sí èyí. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun yóò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn aposteli Peteru pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún awọn ọkọ tiyín, kí ó baà lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ naa, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà awọn aya wọn, nitori jíjẹ́ tí wọ́n ti jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí ìwà mímọ́ yín papọ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Peteru 3:1, 2) Àwọn Kristian aya ń ṣiṣẹ́ lórí bí wọn yóò ṣe túbọ̀ fi àwọn èso tẹ̀mí Ọlọrun hàn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.—Galatia 5:22, 23.
NÍGBÀ TÍ AYA KÌ Í BÁ ṢE KRISTIAN
10. Báwo ni ọkọ kan tí ó jẹ́ onígbàgbọ́ ṣe yẹ kí ó hùwà sí aya rẹ̀ bí aya rẹ̀ bá ní èrò ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀?
10 Bí ọkọ bá jẹ́ Kristian ńkọ́, tí aya kì í sì í ṣe Kristian? Bibeli fúnni ní ìtọ́sọ́nà fún irú ipò bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Bí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tí kò gbàgbọ́, síbẹ̀ tí obìnrin naa sì faramọ́ bíbá a gbé, kí oun máṣe fi obìnrin naa sílẹ̀.” (1 Korinti 7:12) Ó tún gba àwọn ọkọ níyànjú pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ awọn aya yín.”—Kolosse 3:19.
11. Báwo ni ọkọ kan ṣe lè fi ìfòyemọ̀ hàn, kí ó sì fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ lo ipò orí lórí aya rẹ̀, bí aya náà kì í bá ṣe Kristian?
11 Bí ìwọ́ bá jẹ́ ọkọ, tí aya rẹ sì ní ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀ sí tìrẹ, rí i dájú pé o bọ̀wọ̀ fún aya rẹ, o sì gba ìmọ̀lára rẹ̀ rò. Gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà, ó yẹ fún òmìnira dé ìwọ̀n àyè kan láti ṣe ìsìn tí ó bá àwọn èrò ìgbàgbọ́ rẹ̀ mu, àní bí o kò tilẹ̀ fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú wọn. Ní ìgbà àkọ́kọ́ tí o bá bá a sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ, má ṣe retí pé kí ó pa gbogbo èrò ìgbàgbọ́ tí ó ti dì mú tipẹ́tipẹ́ tì, fún ohun kan tí ó jẹ́ tuntun. Dípò sísọ pé èké lásán ni ìsìn tí òun àti ìdílé rẹ̀ ti ṣìkẹ́ fún ìgbà pípẹ́, fi sùúrù sakun láti bá a fèrò wérò láti inú Ìwé Mímọ́. Ó lè jẹ́ pé, ó ń rò pé o ti pa òun tì, nítorí tí o ya èyí tí ó pọ̀ jù nínú àkókò rẹ sọ́tọ̀ fún àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Ó lè ta ko àwọn ìsapá rẹ láti ṣiṣẹ́ sin Jehofa, síbẹ̀ ohun tí ó ń dọ́gbọ́n sọ lè wulẹ̀ jẹ́: “Mo nílò díẹ̀ sí i nínú àkókò rẹ!” Ní sùúrù. Pẹ̀lú ìfẹ́ onígbatẹnirò rẹ, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, o lè ràn án lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́.—Kolosse 3:12-14; 1 Peteru 3:8, 9.
TÍTỌ́ ÀWỌN ỌMỌ
12.Àní bí ọkọ kan àti aya rẹ̀ bá ní ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀, báwo ni a ṣe lè lo àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ nínú títọ́ àwọn ọmọ?
12 Nínú agbo ilé kan tí kò wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọsìn, ìtọ́ni ìsìn tí a óò fún àwọn ọmọ máa ń di ọ̀ràn àríyànjiyàn nígbà míràn. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a lo àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́? Bibeli yan olórí ẹrù iṣẹ́ ti fífún àwọn ọmọ ní ìtọ́ni fún bàbá, ṣùgbọ́n ìyá pẹ̀lú ní ipa pàtàkì láti kó. (Owe 1:8; fi wé Genesisi 18:19; Deuteronomi 11:18, 19.) Àní bí bàbá náà kò bá tilẹ̀ tẹ́wọ́ gba ipò orí Kristi, òun ṣì ni olórí ìdílé náà.
13, 14. Bí ọkọ bá ka mímú àwọn ọmọ lọ sí àwọn ìpàdé Kristian tàbí kíkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn léèwọ̀ fún aya rẹ̀, kí ni aya lè ṣe?
13 Àwọn bàbá kan tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ kì í ṣàtakò bí màmá bá ń fún àwọn ọmọ ní ìtọ́ni lórí ọ̀ràn ìsìn. Àwọn mìíràn sì máa ń ṣàtakò. Bí ọkọ rẹ bá kọ̀ láti gbà ọ́ láyè láti mú àwọn ọmọ lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ tàbí tí ó tilẹ̀ kà á léèwọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn nínú ilé ńkọ́? Wàyí o, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ojúṣe wà tí o ní láti mú wà déédéé—ojúṣe rẹ sí Jehofa Ọlọrun, sí ọkọ tí ó jẹ́ orí rẹ, àti sí àwọn ọmọ rẹ àyànfẹ́. Báwo ni o ṣe lè mú ìwọ̀nyí wà déédéé?
14 Dájúdájú, ìwọ yóò gbàdúrà lórí ọ̀ràn náà. (Filippi 4:6, 7; 1 Johannu 5:14) Ṣùgbọ́n ní àbárèbábọ̀, ìwọ ni o gbọ́dọ̀ pinnu ipa ọ̀nà tí ìwọ yóò tọ̀. Bí o bá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ní mímú un ṣe kedere sí ọkọ rẹ pé, kì í ṣe pé o ń pe ipò orí rẹ̀ níjà, àtakò rẹ̀ lè rọlẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Kódà, bí ọkọ rẹ bá kà á léèwọ̀ fún ọ láti mú àwọn ọmọ rẹ lọ sí àwọn ìpàdé tàbí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn, ìwọ́ ṣì lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Nípa ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ rẹ ojoojúmọ́ àti àpẹẹrẹ rere rẹ, gbìyànjú láti gbin ìwọ̀n ìfẹ́ fún Jehofa, ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀wọ̀ fún àwọn òbí—títí kan bàbá wọn—àníyàn onífẹ̀ẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn, àti ìmọrírì fún àṣà ṣíṣiṣẹ́ tọkàntọkàn, sí wọn lọ́kàn. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, bàbá náà lè ṣàkíyèsí àwọn ìyọrísí rere náà, ó sì lè mọrírì bí àwọn ìsapá rẹ ṣe níyelórí tó.—Owe 23:24.
15. Kí ni ẹrù iṣẹ́ bàbá tí ó jẹ́ onígbàgbọ́ nínú kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́?
15 Bí o bá jẹ́ ọkọ kan tí ó jẹ́ onígbàgbọ́, tí aya rẹ kì í sì í ṣe onígbàgbọ́, nígbà náà, o gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ títọ́ àwọn ọmọ rẹ “ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.” (Efesu 6:4) Síbẹ̀, bí o ṣe ń ṣe èyí, o ní láti fi inú rere, ìfẹ́, àti òye bá aya rẹ lò.
BÍ ÌSÌN RẸ BÁ YÀTỌ̀ SÍ TI ÀWỌN ÒBÍ RẸ
16, 17. Àwọn ìlànà Bibeli wo ni àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ rántí bí wọ́n bá tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀ sí ti àwọn òbí wọn?
16 Kì í ṣe ohun tuntun mọ́ fún àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá láti tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye ìsìn tí ó yàtọ̀ sí ti àwọn òbí wọn. O ha ti ṣe ìyẹn bí? Bí o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, Bibeli ní ìmọ̀ràn fún ọ.
17 Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí awọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Oluwa, nitori èyí jẹ́ òdodo: ‘Bọlá fún baba rẹ ati ìyá rẹ.’” (Efesu 6:1, 2) Ìyẹ́n ní ọ̀wọ̀ tí ó gbámúṣé fún àwọn òbí nínú. Ṣùgbọ́n, bí ìgbọràn sí àwọn òbí tilẹ̀ ṣe pàtàkì, a kò gbọdọ̀ ṣe é láìka Ọlọrun tòótọ́ sí. Nígbà tí ọmọ kan bá dàgbà tó láti bẹ̀rẹ̀ sí í dápinnu ṣe, ó ń tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ sí i fún àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀. Kì í ṣe nínú ọ̀ràn òfin ayé nìkan ni èyí ti jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n, ní pàtàkì, nínú òfin àtọ̀runwá pẹ̀lú. Bibeli sọ pé: “Olúkúlùkù wa ni yoo ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọrun.”—Romu 14:12.
18, 19. Bí àwọn ọmọ bá ní ìsìn tí ó yàtọ̀ sí ti àwọn òbí wọn, báwo ni wọ́n ṣe lè ran àwọn òbí wọn lọ́wọ́ láti lóye ìgbàgbọ́ wọn dáradára sí i?
18 Bí èrò ìgbàgbọ́ rẹ bá mú kí o ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé rẹ, gbìyànjú láti lóye ojú ìwòye àwọn òbí rẹ. Ó ṣeé ṣe kí inú wọ́n dùn, bí kíkọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli àti fífi wọ́n sílò, bá ti yọrí sí sísọ ọ́ di ẹni tí ó túbọ̀ ń bọ̀wọ̀ fúnni, tí ó túbọ̀ jẹ́ onígbọràn, tí ó túbọ̀ jẹ́ aláápọn sí i nínú ohun tí wọ́n bá ní kí o ṣe. Ṣùgbọ́n, bí ìgbàgbọ́ rẹ tuntun bá tún mú kí o kọ àwọn èrò ìgbàgbọ́ àti àṣà tí àwọn fúnra wọn ṣìkẹ́ sílẹ̀, wọ́n lè rò pé o ń ta ogún tí wọ́n fẹ́ láti fi lé ọ lọ́wọ́ nù. Wọ́n tún lè máa bẹ̀rù nípa ire rẹ, bí ohun tí o ń ṣe kò bá wọ́pọ̀ ní àwùjọ náà tàbí bí ó bá yí àfiyèsí rẹ kúrò nínú àwọn ìlépa tí àwọ́n rò pé ó lè mú ọ láásìkí nípa ti ara. Ìgbéraga pẹ̀lú lè jẹ́ ìdènà kan. Wọ́n lè rò pé, ohun tí o ń dọ́gbọ́n sọ ni pé, ìwọ ni o tọ̀nà, àwọn ni àwọ́n kùnà.
19 Nítorí náà, bí ó ba ti lè tètè yá tó, gbìyànjú láti mú àwọn òbí rẹ mọ díẹ̀ lára àwọn alàgbà tàbí àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn tí wọ́n dàgbà dénú, láti inú ìjọ àdúgbò. Fún àwọn òbí rẹ níṣìírí láti bẹ Gbọ̀ngàn Ìjọba wò, kí wọ́n sì fetí ara wọn gbọ́ ohun tí a ń jíròrò, kí wọ́n sì fúnra wọn rí irú ènìyàn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ìṣarasíhùwà àwọn òbí rẹ lè tutù pẹ̀sẹ̀. Àní nígbà tí àwọn òbí bá ranrí pátápátá, tí wọ́n run àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, tí wọ́n sì ka lílọ sí àwọn ìpàdé Kristian léèwọ̀ fún àwọn ọmọ wọn, àǹfààní máa ń wà láti kàwé níbòmíràn, láti bá àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni sọ̀rọ̀, àti láti jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn kí a sì ràn wọ́n lọ́wọ́ lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà. O sì tún lè gbàdúrà sí Jehofa. Àwọn ọ̀dọ́ kan ní láti dúró títí di ìgbà tí wọ́n bá dàgbà tó láti gbé lẹ́yìn òde ilé ìdílé, kí wọ́n tó lè ṣe púpọ̀ sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun yòówù tí ipò inú ilé lè jẹ́, má ṣe gbàgbé láti “bọlá fún baba rẹ ati ìyá rẹ.” Ṣe ipa tìrẹ láti mú kí àlàáfíà wà nínú ilé. (Romu 12:17, 18) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọrun.
ÌPÈNIJÀ JÍJẸ́ ÒBÍ NÍNÚ ÌGBÉYÀWÓ ÀTÚNṢE
20. Àwọn ìmọ̀lára wo ni àwọn ọmọ́ lè ní, bí bàbá wọn tàbí ìyá wọn bá jẹ́ òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe?
20 Nínú ọ̀pọ̀ ilé, ipò tí ń mú ìpènijà títóbi jù lọ wá kì í ṣe ọ̀ràn ìsìn bí kò ṣe ti ìṣòro ìdílé ìgbéyàwó àtúnṣe. Ọ̀pọ̀ agbo ilé lónìí ní àwọn ọmọ tí wọ́n wá láti inú ìgbéyàwó ìṣáájú ti ọ̀kan lára àwọn òbí tàbí ti àwọn òbí méjèèjì. Nínú irú ìdílé bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ lè máa jowú, wọ́n lè má di kùnrùngbùn tàbí kí wọ́n tilẹ̀ má mọ ibi àátẹ̀sí. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, wọ́n lè fojú tín-ín-rín ìsapá àtọkànwá tí òbí inú ìgbéyàwó àtúnṣe náà ń ṣe, láti jẹ́ bàbá rere tàbí ìyá rere. Kí ni ó lè ṣèrànwọ́ láti mú kí ìdílé onígbèéyàwó àtúnṣe yọrí sí rere?
21. Láìka àyíká ipò àrà ọ̀tọ̀ wọn sí, èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe yíjú sí àwọn ìlànà tí a rí nínú Bibeli fún ìrànlọ́wọ́?
21 Mọ̀ pé, láìka wí pé àwọn àyíká ipò wọ̀nyí jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ sí, àwọn ìlànà Bibeli tí ń mú àṣeyọrí wá nínú agbo ilé mìíràn ṣeé mú lò níhìn-ín pẹ̀lú. Fún ìgbà díẹ̀, ṣíṣàìka àwọn ìlànà wọ̀nyẹn sí lè dà bíi pé ó dín ìṣòro kù, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí ó yọrí sí ìrora ọkàn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. (Orin Dafidi 127:1; Owe 29:15) Mú ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ dàgbà—ọgbọ́n láti fi àwọn ìlànà Ọlọrun sílò pẹ̀lú àǹfààní pípẹ́ títí lọ́kàn, àti òye láti mọ ìdí tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé fi ń sọ ohun kan, tí wọ́n sì ń ṣe ohun kan. Ó tún yẹ kí o ní ẹ̀mí ìfọ̀rànrora-ẹni-wò.—Owe 16:21; 24:3; 1 Peteru 3:8.
22. Èé ṣe tí ó fi lè ṣòro fún àwọn ọmọ láti tẹ́wọ́ gba òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe?
22 Bí o bá jẹ́ òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe, o lè rántí pé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ ìdílé náà, àwọn ọmọ náà tẹ́wọ́ gbà ọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí o di òbí wọn nínú ìgbéyàwó àtúnṣe, ìṣarasíhùwà wọ́n lè ti yí padà. Ní rírántí òbí tí ó bí wọn gan-an tí kò gbé pẹ̀lú wọn mọ́, àwọn ọmọ náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìṣòro àìmọ ibi àátẹ̀sí, bóyá kí wọ́n máa nímọ̀lára pé o fẹ́ já ìfẹ́ni tí wọ́n ní fún òbí tí kò sí lọ́dọ̀ wọn mọ́ gbà mọ́ àwọn lọ́wọ́. Nígbà míràn, wọ́n lè rán ọ létí láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé, ìwọ kì í ṣe bàbá àwọn tàbí ìyá àwọn. Irú àwọn gbólóhùn bẹ́ẹ̀ máa ń dunni gan-an. Síbẹ̀, “má ṣe yára ní ọkàn rẹ láti bínú.” (Oniwasu 7:9) O ní láti lo ìfòyemọ̀ àti ìfọ̀rànrora-ẹni-wò láti lè kojú èrò ìmọ̀lára àwọn ọmọ wọ̀nyẹn.
23. Báwo ni a ṣe lè lo ìbáwí nínú ìdílé tí ó ní àwọn ọmọ láti inú ìgbéyàwó ìṣáájú?
23 Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ṣe pàtàkì nígbà tí a bá ń báni wí. Ìbáwí tí ó ṣe déédéé, ṣe pàtàkì. (Owe 6:20; 13:1) Níwọ̀n bí àwọn ọmọ kò sì ti rí bákan náà, ìbáwí lè yàtọ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan sí òmíràn. Àwọn òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe kan rí i pé, ó kéré tán, ní ìbẹ̀rẹ̀, ó lè sàn jù fún òbí tí ó bí wọn gan-an láti bójú tó apá yìí. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì pé, kí àwọn òbí méjèèjì fohùn ṣọ̀kan lórí ìbáwí náà, kí wọ́n sì fara mọ́ ọn, kì í ṣe kí wọ́n máa fojú rere hàn sí ọmọ tiwọn ju ọmọ inú ìgbéyàwó ìṣáájú lọ. (Owe 24:23) Ìgbọràn ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n a ní láti máa fàyè sílẹ̀ fún àìpé. Má ṣe hùwà padà lọ́nà tí ó ré kọjá ààlà. Fi ìfẹ́ báni wí.—Kolosse 3:21.
24. Kí ni ó lè ṣèrànwọ́ láti yẹra fún àwọn ìṣòro ìwà híhù láàárín àwọn mẹ́ḿbà ẹ̀yà òdì kejì nínú ìdílé onígbèéyàwó àtúnṣe?
24 Àwọn ìjíròrò ìdílé lè ṣe púpọ̀ láti dènà wàhálà. Ìwọ̀nyí lè ran ìdílé lọ́wọ́ láti pa àfiyèsí pọ̀ sórí àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé. (Fi wé Filippi 1:9-11.) Wọ́n tún lè ran ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti rí ipa tí òun lè sà nínú lílé àwọn góńgó ìdílé bá. Ní àfikún sí i, àwọn ìjíròrò ìdílé láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ lè yẹ àwọn ìṣòro ọ̀nà ìwà híhù sílẹ̀. Ó yẹ kí àwọn ọmọbìnrin mọ bí a ṣe ń múra, àti bí a ṣe ń hùwà bí ọmọlúwàbí sí ọkọ ìyá wọn àti sí àwọn ọmọkùnrin tí ọkọ ìyá wọn ti bí tẹ́lẹ̀, àwọn ọmọkùnrin sì nílò ìmọ̀ràn lórí ìwà tí ó tọ́ sí aya bàbá wọn àti sí àwọn ọmọbìnrin tí aya bàbá wọn ti bí tẹ́lẹ̀.—1 Tessalonika 4:3-8.
25. Àwọn ànímọ́ wo ni ó lè ṣèrànwọ́ láti mú kí àlàáfíà wà nínú ìdílé onígbèéyàwó àtúnṣe?
25 Ní kíkojú ìpènijà àrà ọ̀tọ̀ ti jíjẹ́ òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe, jẹ́ onísùúrù. Ó ń gba àkókò láti mú ipò ìbátan tuntun dàgbà. Jíjèrè ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ àwọn ọmọ tí kì í ṣe ìwọ ni o bí wọn lè jẹ́ òpò tí ń kani láyà. Ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe. Ọkàn-àyà ọlọgbọ́n àti onífòyemọ̀, pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn lílágbára láti ṣe ohun tí ó dùn mọ́ Jehofa nínú, ni kọ́kọ́rọ́ sí àlàáfíà nínú ìdílé ìgbéyàwó àtúnṣe. (Owe 16:20) Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ipò míràn.
ÌLÉPA ỌRỌ̀ ÀLÙMỌ́NÌ HA Ń PÍN ÌDÍLÉ RẸ NÍYÀ BÍ?
26. Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn ìṣòro àti ìṣarasíhùwà ní ti ọrọ̀ àlùmọ́nì ṣe lè pín ìdílé kan níyà?
26 Àwọn ìṣòro àti ìṣarasíhùwà ní ti ọrọ̀ àlùmọ́nì lè pín ìdílé níyà ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà. Ó bani nínú jẹ́ pé, ìjiyàn lórí owó àti ìfẹ́ ọkàn fún ọrọ̀—tàbí ó kéré tán láti lè ní ọrọ̀ díẹ̀ sí i—ti dá wàhálà sílẹ̀ nínú àwọn ìdílé kan. Ìpínyà lè jẹ yọ nígbà tí àwọn alábàáṣègbéyàwó méjèèjì bá ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tí wọ́n sì mú ìṣarasíhùwà “owó tèmi nìyí, owó tìrẹ nìyẹn” dàgbà. Àní bí wọ́n bá tilẹ̀ yẹra fún ìjiyàn pàápàá, bí àwọn alábàáṣègbéyàwó méjèèjì bá ń ṣiṣẹ́, wọ́n lè rí i pé àyè díẹ̀ ní àwọn ní fún èkíní kejì. Ìtẹ̀sí tí ń wọ́pọ̀ sí i nínú ayé ni kí àwọn bàbá máa gbé ibi tí ó jìnnà sí àwọn ìdílé wọn fún sáà gígùn—ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọdún pàápàá—láti baà lè rí owó púpọ̀ sí i ju èyí tí wọ́n lè rí ní ilé lọ. Èyí lè yọrí sí ìṣòro ńláǹlà.
27. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìlànà tí ó lè ṣèrànwọ́ fún ìdílé kan tí ó ní ìṣòro ìṣúnná owó?
27 A kò lè gbé òfin kalẹ̀ fún bíbójú tó àwọn ipò wọ̀nyí, níwọ̀n bí àwọn ìdílé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ní láti kojú àwọn pákáǹleke àti àìní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Síbẹ̀, ìmọ̀ràn Bibeli lè ṣèrànwọ́. Fún àpẹẹrẹ, Owe 13:10 (NW) fi hàn pé a lè yẹra fún aáwọ̀ nípa “fífikùn lukùn.” Kì í wulẹ̀ ṣe sísọ ojú ìwòye tẹni nìkan ni èyí ní nínú, ṣùgbọ́n wíwá ìmọ̀ràn àti wíwádìí bí ẹnì kejì ṣe rí ọ̀ràn náà sí. Síwájú sí i, gbígbé ìwéwèé ètò ìnáwó tí ó ṣe déédéé kalẹ̀ lè ṣèrànwọ́ láti mú ìsapá ìdílé wà ní ìṣọ̀kan. Nígbà míràn ó pọn dandan—bóyá fún ìgbà díẹ̀—fún àwọn alábàáṣègbéyàwó méjèèjì láti ṣiṣẹ́ lẹ́yìn òde ilé, láti lè bójú tó àwọn àfikún ìnáwó, ní pàtàkì, nígbà tí àwọn ọmọ tàbí àwọn mìíràn tí ó gbójú lé wọn bá wà. Nígbà tí ọ̀ràn bá rí báyìí, ọkọ náà lè fi aya rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé, òún ṣì ní àkókò fún un. Ọkọ náà pẹ̀lú àwọn ọmọ lè fi tìfẹ́tìfẹ́ ran aya lọ́wọ́ láti ṣe nínú iṣẹ́ tí òun nìkan ì bá ti dá ṣe.—Filippi 2:1-4.
28. Àwọn ìránnilétí wo ni ìdílé kan lè máa fi sọ́kàn, tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wà ní ìṣọ̀kan?
28 Bí ó ti wù kí ó rí, fi í sọ́kàn pé bí owó tilẹ̀ jẹ́ kò-ṣeé-mánìí nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí, kì í mú ayọ̀ wá. Ó sì dájú pé, kò lè mú ìwàláàyè wá. (Oniwasu 7:12) Ní tòótọ́, dídarí àfiyèsí tí ó pọ̀ jù sórí ọrọ̀ àlùmọ́nì lè fa ìparun nípa tẹ̀mí àti ti ọ̀nà ìwà híhù. (1 Timoteu 6:9-12) Ẹ wo bí ó ti dára jù tó láti kọ́kọ́ wá Ìjọba Ọlọrun àti òdodo rẹ̀, pẹ̀lú ìdánilójú pé òun yóò bù kún ìsapá wa láti ní àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí ìgbésí ayé! (Matteu 6:25-33; Heberu 13:5) Nípa fífi ire tẹ̀mí ṣáájú àti kíkọ́kọ́ lépa àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọrun, ìwọ́ lè rí i pé agbo ilé rẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àyíká ipò kan lè pín in níyà, yóò di ọ̀kan tí ó wà ní ìṣọ̀kan ní tòótọ́ ní àwọn ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . ÀWỌN MẸ́ḾBÀ ÌDÍLÉ LÁTI MÚ KÍ ÀLÀÁFÍÀ WÀ NÍNÚ ILÉ?
Ó yẹ kí àwọn Kristian mú ìfòyemọ̀ dàgbà.—Owe 16:21; 24:3.
Ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí tọkọtaya ń fi hàn nínú ìgbéyàwó kò sinmi lórí pé wọ́n jọ jẹ́ mẹ́ḿbà ìsìn kan náà.—Efesu 5:23, 25.
Kristian kì yóò mọ̀ọ́mọ̀ ru òfin Ọlọrun láé.—Ìṣe 5:29.
Ẹlẹ́mìí àlàáfíà ni àwọn Kristian.—Romu 12:18.
Má ṣe yára bínú.—Oniwasu 7:9.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 139]
ÌGBÉYÀWÓ TÍ Ó TỌ́ Ń MÚ ỌLÁ ÀTI ÀLÀÁFÍÀ WÁ
Ní òde òní, ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin ń gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya láìjẹ́jẹ̀ẹ́ àdéhùn kankan lábẹ́ òfin. Ẹnì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ lè dojú kọ irú ipò yìí. Nínú àwọn ipò kan, ẹgbẹ́ àwùjọ tàbí àṣà ìbílẹ̀ lè fọwọ́ sí àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n kò bófin mu. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pá ìdiwọ̀n Bibeli béèrè fún ìgbéyàwò tí a fi orúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà tí ó tọ́, lábẹ́ òfin. (Titu 3:1; Heberu 13:4) Fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ nínú ìjọ Kristian, Bibeli tún pàṣẹ pé, ọkọ kan àti aya kan péré ni ó gbọ́dọ̀ wà nínú àjọṣepọ̀ ìgbéyàwó kan. (1 Korinti 7:2; 1 Timoteu 3:2, 12) Títẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n yìí ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ sí níní àlàáfíà nínú ilé rẹ. (Orin Dafidi 119:165) Àwọn ohun tí Jehofa ń béèrè fún kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe tàbí ohun tí ń dẹ́rù pani. Ó ṣètò ohun tí ó fi kọ́ wa láti ṣe wá láǹfàání.—Isaiah 48:17, 18.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 130]
Gbìyànjú láti lóye ojú ìwòye ẹnì kejì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 138]
Yálà o jẹ́ òbí ní tààràtà tàbí ti ìgbéyàwó àtúnṣe, gbára lé Bibeli fún ìtọ́sọ́nà
-
-
Ìwọ́ Lè Borí Àwọn Ìṣòro Tí Ń Ṣe Ìdílé Lọ́ṣẹ́Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
-
-
ORÍ KEJÌLÁ
Ìwọ́ Lè Borí Àwọn Ìṣòro Tí Ń Ṣe Ìdílé Lọ́ṣẹ́
1. Àwọn ìṣòro fífara sin wo ní ń bẹ nínú àwọn ìdílé kan?
AṢẸ̀ṢẸ̀ parí fífọ̀ àti nínu ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà ni. Lójú àwọn tí ń kọjá lọ, ó ń dán gbinrin, àfi bí agánrán. Ṣùgbọ́n lábẹ́nú, ara ọkọ̀ náà ti ń dípẹtà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn ṣe rí nínú àwọn ìdílé kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ìrísí òde, gbogbo rẹ̀ rí rèterète, ojú tí ń mú ẹ̀rín músẹ́ jáde bo ìbẹ̀rù àti ìrora mọ́lẹ̀. Níbi tí ojú àwọn ará ìta kò tó, àlàáfíà ìdílé ti ń dípẹtà. Àwọn ìṣòro méjì tí ó lè ní àbájáde yìí ni ìmukúmu àti ìwà ipá.
ỌṢẸ́ TÍ ÌMUKÚMU Ń ṢE
2. (a) Kí ni ojú ìwòye Bibeli nípa mímu ọtí? (b) Kí ni ìmukúmu?
2 Bibeli kò sọ pé mímu ọtí ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì burú, ṣùgbọ́n, ó sọ pé ó burú láti jẹ́ ọ̀mùtí. (Owe 23:20, 21; 1 Korinti 6:9, 10; 1 Timoteu 5:23; Titu 2:2, 3) Àmọ́, jíjẹ́ onímukúmu tún burú ju jíjẹ́ ọ̀mùtí lọ; ó jẹ́ mímu ọtí ní àmuyíràá nígbà gbogbo, àti àìlè ṣàkóso ara ẹni nítorí mímu ún. Àwọn onímukúmu lè jẹ́ àgbàlagbà. Ó bani nínú jẹ́ pé, wọ́n tún lè jẹ́ ọ̀dọ́.
3, 4. Ṣàpèjúwe àbájáde tí ìmukúmu ń ní lórí alábàáṣègbéyàwó onímukúmu náà àti àwọn ọmọ rẹ̀.
3 Tipẹ́tipẹ́ ni Bibeli ti fi hàn pé, ọtí àmujù lè ba àlàáfíà ìdílé jẹ́. (Deuteronomi 21:18-21) Gbogbo ìdílé látòkè délẹ̀ ni ń nímọ̀lára àbájáde búburú tí ìmukúmu ń mú wá. Aya lè kó wọ inú ìsapá láti mú kí ọkọ rẹ̀ jáwọ́ nínú mímùmukúmu ọtí tàbí láti kojú àwọn ìwà ọkọ rẹ̀ tí a kò lè sọ bí yóò ti rí.a Ó lè gbìyànjú láti máa gbé ọtí náà pamọ́, kí ó dà á nù, kí ó fi owó ọkọ rẹ̀ pamọ́, kí ó sì máa bẹ ọkọ rẹ̀ láti ro ti ìdílé, láti ro ìwàláàyè rẹ̀, kí ó sì tún máa fi Ọlọrun bẹ̀ ẹ́ pàápàá—ṣùgbọ́n kí onímukúmu náà ṣì máa gbà á pé. Bí ìsapá rẹ̀ léraléra láti ṣàkóso ọtí mímu ọkọ rẹ̀ ti ń já sí pàbó, yóò máa nímọ̀lára ìjákulẹ̀ àti àìtóótun. Ẹ̀rù lè bẹ̀rẹ̀ sí í bà á, kí inú máa bí i, kí ó bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára ẹ̀bi, kí ara rẹ̀ máà lélẹ̀, kí ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn, kí ó máà sì ní ọ̀wọ̀ ara ẹni.
4 Àbájáde ìmukúmu òbí kò yọ àwọn ọmọ sílẹ̀. A ń ṣe àwọn mìíràn léṣe. A ń fi ìbálòpọ̀ fìtínà àwọn mìíràn. Wọ́n tilẹ̀ lè dá ara wọn lẹ́bi fún bí òbí kan ṣe ń mu ọtí nímukúmu. Léraléra, ìwà ségesège onímukúmu náà ń ba ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú àwọn ẹlòmíràn jẹ́. Nítorí pé, wọn kò lè fara balẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé, àwọn ọmọ náà lè kọ́ láti pa ìmọ̀lára wọn mọ́, èyí tí ó sì sábà ń ní àbájáde burúkú nípa ti ara. (Owe 17:22) Irú ìwà àìnígbọkànlé nínú ara ẹni tàbí àìní ọ̀wọ̀ ara ẹni yìí lè bá àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ dàgbà.
KÍ NI ÌDÍLÉ NÁÀ LÈ ṢE?
5. Báwo ni a ṣe lè bójú tó ìmukúmu, èé sì ti ṣe tí èyí fi ṣòro?
5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ amòye sọ pé ìmukúmu kò gbóògùn, ọ̀pọ̀ jù lọ fohùn ṣọ̀kan pé, ìkọ́fẹpadà dé ìwọ̀n àyè kan ṣeé ṣe pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yíyàgò pátápátá. (Fi wé Matteu 5:29.) Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnú dùn ún ròfọ́, agada ọwọ́ sì ṣeé bẹ́ gẹdú ni ọ̀rọ̀ mímú kí onímukúmu kan tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́, níwọ̀n bí òun yóò ti máa fìgbà gbogbo sẹ́ ìṣòro tí ó ní. Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé bá gbé ìgbésẹ̀ láti kojú ọ̀nà tí ìmukúmu náà ti gbà ní ipa lórí wọn, onímukúmu náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé òún ní ìṣòro. Oníṣègùn kan tí ó ti ní ìrírí nínú ríran àwọn onímukúmu àti ìdílé wọn lọ́wọ́ wí pé: “Mo rò pé ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kí ìdílé náà máa bá ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́ lọ lọ́nà tí ó lè ṣàǹfààní fún wọn jù lọ. Onímukúmu náà yóò túbọ̀ máa rí i bí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín òun àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé yòókù ti gbòòrò tó.”
6. Kí ni orísun ìmọ̀ràn dídára jù lọ fún àwọn ìdílé tí wọ́n ní mẹ́ḿbà tí ó jẹ́ onímukúmu?
6 Bí onímukúmu bá wà nínú ìdílé rẹ, ìmọ̀ràn Bibeli tí a mí sí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé lọ́nà tí ó ṣàǹfààní jù lọ. (Isaiah 48:17; 2 Timoteu 3:16, 17) Gbé àwọn ìlànà kan yẹ̀ wò tí ó ti ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ láti kojú ìmukúmu pẹ̀lú àṣeyọrí.
7. Bí mẹ́ḿbà kan bá jẹ́ onímukúmu, ta ni ó jẹ̀bi?
7 Dáwọ́ títẹ́wọ́ gba gbogbo ẹ̀bi náà dúró. Bibeli sọ pé: “Olúkúlùkù ni yoo ru ẹrù ti ara rẹ̀,” pẹ̀lúpẹ̀lù, “olúkúlùkù wa ni yoo ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọrun.” (Galatia 6:5; Romu 14:12) Onímukúmu náà lè gbìyànjú láti di ẹ̀bi náà lè ìdílé rẹ̀ lórí. Fún àpẹẹrẹ, ó lè sọ pé: “Ká ní ẹ ti bá mi lò lọ́nà tí ó dára ni, n kì bá mu ọtí.” Bí àwọn mìíràn bá gbà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń fún un níṣìírí láti máa bá mímu ọtí nìṣó. Kódà, bí ó bá jẹ́ àyíká ipò tàbí àwọn ènìyàn míràn ni ó nípa lórí wa, gbogbo wa pátá—títí kan àwọn onímukúmu—ni yóò jíhìn fún ohun tí a bá ṣe.—Fi wé Filippi 2:12.
8. Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo ni a lè gbà ran onímukúmu náà lọ́wọ́ láti kojú àwọn àbájáde ìṣòro rẹ̀?
8 Má ṣe rò pé ìgbà gbogbo ni ìwọ yóò máa dáàbò bo onímukúmu náà lọ́wọ́ àbájáde ọtí mímu rẹ̀. Òwe Bibeli nípa ẹnì kan tí ń bínú lè ṣeé lò lọ́nà kan náà fún onímukúmu náà pé: “Bí ìwọ bá gbà á, síbẹ̀ ìwọ óò tún ṣe é.” (Owe 19:19) Jẹ́ kí onímukúmu náà jìyà àbájáde ọtí mímu rẹ̀. Jẹ́ kí ó fúnra rẹ̀ fọ ẹ̀gbin tí ó ti ṣe mọ́ tónítóní tàbí kí ó tẹ ẹni tí ó gbà á síṣẹ́ láago ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì tí ọ̀ran ọtí mímu rẹ̀ ṣẹlẹ̀.
9, 10. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn ìdílé ẹni tí ó jẹ́ onímukúmu náà tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́, ìrànlọ́wọ́ àwọn wo ni wọ́n ní láti wá ní pàtàkì?
9 Tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Owe 17:17 sọ pé: “Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n arákùnrin ni a bí fún ìgbà ìpọ́njú.” Nígbà tí onímukúmu bá wà nínú ìdílé rẹ, ìrora ọkàn ń bẹ. O nílò ìrànlọ́wọ́. Má ṣe lọ́ra láti gbára lé ‘àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́’ fún ìrànlọ́wọ́. (Owe 18:24) Bíbá àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n lóye ìṣòro náà, tàbí tí wọ́n ti dojú kọ irú ipò kan náà sọ̀rọ̀, lè pèsè àwọn àbá gbígbéṣẹ́ fún ọ, lórí ohun tí o lè ṣe àti ohun tí o kò gbọdọ̀ ṣe. Ṣùgbọ́n wà déédéé. Bá àwọn tí o gbẹ́kẹ̀ lé sọ̀rọ̀, àwọn tí yóò pa “ọ̀rọ̀ àṣírí” rẹ mọ́.—Owe 11:13.
10 Kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn Kristian alàgbà. Àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristian lè jẹ́ orísun ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n dàgbà dénú wọ̀nyí ní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun dáradára, wọ́n sì jáfáfá nínú bí a ṣeé ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. Wọ́n lè jẹ́ “ibi ìlùmọ́ kúrò lójú ẹ̀fúùfù, àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì; bí odò omi ní ibi gbígbẹ, bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.” (Isaiah 32:2) Kì í ṣe kìkì pé àwọn Kristian alàgbà ń dáàbò bo ìjọ lódindi kúrò lọ́wọ́ àwọn agbára ìdarí aṣeniléṣe nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún ń tuni nínú, wọ́n ń tuni lára, wọ́n sì ń ní ọkàn-ìfẹ́ ara ẹni nínú àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ní ìṣòro. Lo àǹfààní ìrànlọ́wọ́ wọn dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.
11, 12. Ta ní ń pèsè ìrànlọ́wọ́ títóbi jù lọ fún àwọn ìdílé tí wọ́n ní onímukúmu, báwo sì ni a ṣe ń pèsè ìrànlọ́wọ́ náà?
11 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, gba okun láti ọ̀dọ̀ Jehofa. Bibeli fi tìfẹ́tìfẹ́ mú un dá wa lójú pé: “Oluwa ń bẹ létí ọ̀dọ̀ àwọn tí í ṣe oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí í ṣe onírora ọkàn là.” (Orin Dafidi 34:18) Bí o bá nímọ̀lára ìròbínújẹ́ ọkàn tàbí tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ nítorí pákáǹleke ti bíbá mẹ́ḿbà ìdílé tí ó jẹ́ onímukúmu gbé pọ̀, mọ̀ pé ‘Oluwa ń bẹ létí ọ̀dọ̀ rẹ.’ Ó lóye bí ipò ìdílé rẹ ti nira tó.—1 Peteru 5:6, 7.
12 Gbígba ohun tí Jehofa sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àníyàn. (Orin Dafidi 130:3, 4; Matteu 6:25-34; 1 Johannu 3:19, 20) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀ ń mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti rí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun gbà, tí ó lè fún ọ ní “agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” láti lè máa fara dà á láti ọjọ́ dé ọjọ́.—2 Korinti 4:7.b
13. Ìṣòro kejì wo ni ó ń ṣe ọ̀pọ̀ ìdílé lọ́ṣẹ́?
13 Mímu ọtí ní àmujù lè yọrí sí ìṣòro mìíràn tí ń ṣe ọṣẹ́ nínú ìdílé—ìwà ipá abẹ́lé.
ỌṢẸ́ TÍ ÌWÀ IPÁ ABẸ́LÉ Ń ṢE
14. Nígbà wo ni ìwà ipá abẹ́lé bẹ̀rẹ̀, báwo sì ni ipò náà ti rí lónìí?
14 Ìṣẹ̀lẹ̀ ìwà ipá abẹ́lé kan láàárín tẹ̀gbọ́n tàbúrò, Kaini àti Abeli, ni ìwà ipá àkọ́kọ́ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. (Genesisi 4:8) Láti ìgbà náà wá, onírúurú ìwà ipá abẹ́lé ti ń pọ́n aráyé lójú. Àwọn ọkọ tí ń lu aya wọn ní àlùbolẹ̀ ń bẹ, àwọn aya tí ń gbéjà ko ọkọ wọ́n wà, àwọn òbí tí ń lu àwọn ọmọ wọn kéékèèké bí ẹní máa kú wà, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọmọ tí wọ́n ti dàgbà tí wọ́n ń hùwà ìkà sí àwọn òbí wọn àgbàlagbà.
15. Báwo ni ìwà ipá abẹ́lé ṣe ń nípa lórí èrò ìmọ̀lára àwọn mẹ́ḿbà ìdílé?
15 Ọṣẹ́ tí ìwà ipá abẹ́lé ń ṣe ré kọjá àwọn àpá ti a lè fojú rí fíìfíì. Obìnrin kan tí a máa ń lù ní àlùbolẹ̀ wí pé: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀bi àti ìtìjú ń bẹ tí o ní láti kojú. Ní òwúrọ̀ púpọ̀ jù lọ, ìwọ yóò wulẹ̀ fẹ́ láti wà lórí ibùsùn, ní rírò pé àlá burúkú lásán ni.” Àwọn ọmọdé tí wọ́n fojú rí ìwà ipá abẹ́lé tàbí tí wọ́n nírìírí rẹ̀ lè jẹ́ oníwà ipá nígbà tí wọ́n bá dàgbà, tí àwọn náà sì ní ìdílé tiwọn fúnra wọn.
16, 17. Kí ni ṣíṣeni léṣe ní ti èrò ìmọ̀lára, báwo sì ni ó ṣe ń nípa lórí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé?
16 Ìwà ipá abẹ́lé kò mọ sórí ṣíṣeni léṣe nípa ti ara nìkan. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìkọlù náà lè jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ ẹnu. Owe 12:18 sọ pé: “Àwọn kan ń bẹ tí ń yára sọ̀rọ̀ lásán bí ìgúnni idà.” Àwọn ‘ohun tí ń gúnni’ wọ̀nyí tí a fi ń dá ìwà ipá abẹ́lé mọ̀, ní nínú, pípeni lórúkọ burúkú àti pípariwo léni lórí, bákan náà sì ni ṣíṣe lámèyítọ́ ẹni nígbà gbogbo, ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí, àti fífi ìwà ipá wuni léwu. Àwọn ọgbẹ́ ìwà ipá ní ti èrò ìmọ̀lára kò ṣeé fojú rí, àwọn ẹlòmíràn kì í sì í sábà kíyè sí i.
17 Èyí tí ó bani nínú jẹ́ ní pàtàkì jù lọ ni ṣíṣe ọmọdé léṣe ní ti èrò ìmọ̀lára—ṣíṣe lámèyítọ́ nígbà gbogbo àti fífojú kéré agbára ìṣe tí ọmọ kan ní, fífojú kéré òye rẹ̀, tàbí bí ó ṣe ṣeyebíye tó gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Irú ọ̀rọ̀ èébú bẹ́ẹ̀ lè pa ẹ̀mí ọmọdé kan run. Òtítọ́ ni pé, gbogbo ọmọdé nílò ìbáwí. Ṣùgbọ́n Bibeli fún àwọn bàbá ní ìtọ́ni pé: “Ẹ máṣe máa dá awọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má baà soríkodò.”—Kolosse 3:21.
BÍ A ṢE LÈ YẸRA FÚN ÌWÀ IPÁ ABẸ́LÉ
18. Níbo ni ìwà ipá abẹ́lé ti ń bẹ̀rẹ̀, kí sì ni Bibeli fi hàn pé ó jẹ́ ọ̀nà tí a lè gbà kiwọ́ rẹ̀ bọlẹ̀?
18 Ìwà ipá abẹ́lé ń bẹ̀rẹ̀ nínú ọkàn-àyà àti èrò inú; bí a ṣe ń hùwà ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú bí a ṣe ń ronú. (Jakọbu 1:14, 15) Láti kiwọ́ ìwà ipá náà bọlẹ̀, ẹni tí ń hùwà ìkà síni náà ní láti yí bí ó ṣe ń ronú padà. (Romu 12:2) Èyí ha ṣeé ṣe bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní agbára láti yí àwọn ènìyàn padà. Ó lè fa àwọn ojú ìwòye aṣekúpani “tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in-gbọn-in” tu pàápàá. (2 Korinti 10:4; Heberu 4:12) Ìmọ̀ pípéye nípa Bibeli lè ṣèrànwọ́ láti mú ìyípadà pátápátá bá àwọn ènìyàn, débi tí a óò fi lè sọ pé wọ́n gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.—Efesu 4:22-24; Kolosse 3:8-10.
19. Ojú wo ni ó yẹ kí Kristian kan fi wo alábàáṣègbéyàwó rẹ̀, báwo sì ni ó ṣe yẹ kí ó máa bá a lò?
19 Ojú tí a fi ń wo alábàáṣègbéyàwó ẹni. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wí pé: “Ó yẹ kí awọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ awọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara awọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.” (Efesu 5:28) Bibeli tún sọ pé ọkọ ní láti fún aya rẹ̀ ní “ọlá . . . gẹ́gẹ́ bí fún ohun-ìlò aláìlerató.” (1 Peteru 3:7) A ṣí àwọn aya létí “lati nífẹ̀ẹ́ awọn ọkọ wọn,” kí wọ́n sì ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” fún wọn. (Titu 2:4; Efesu 5:33) Ó dájú pé, kò sí ọkọ kan tí ó bẹ̀rù Ọlọrun tí yóò fi tòótọ́tòótọ́ sọ pé, òun ń bọlá fún aya òun ní tòótọ́, bí òún bá ń ṣe é léṣe tàbí tí òún ń bú u. Kò sì sí aya kan tí ń pariwo lé ọkọ rẹ̀ lórí, tàbí tí ń fi ọ̀rọ̀ aṣa bá a sọ̀rọ̀, tàbí tí ń bá a jà nígbà gbogbo tí ó lè sọ ní tòótọ́ pé, òún nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, òún sì ń bọ̀wọ̀ fún un.
20. Ta ni àwọn òbí yóò jíhìn fún lórí àwọn ọmọ wọn, èé sì ti ṣe tí kò fi yẹ kí àwọn òbí fojú kéré agbára ìṣe àwọn ọmọ wọn?
20 Ojú ìwòye tí ó tọ́ nípa àwọn ọmọ. Ìfẹ́ àti àfíyèsí àwọn òbí tọ́ sí àwọn ọmọ, àní, wọ́n nílò rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pe àwọn ọmọ ní “ìní Oluwa” àti “èrè rẹ̀.” (Orin Dafidi 127:3) Ẹrù iṣẹ́ àwọn òbí ni níwájú Jehofa láti bójú tó ogún ìní yẹn. Bibeli sọ̀rọ̀ nípa “awọn ọ̀nà ìhùwà ìkókó” àti “ìwà òmùgọ̀” ìgbà ọmọdé. (1 Korinti 13:11; Owe 22:15, NW) Kò yẹ kí ó ya àwọn òbí lẹ́nu bí wọ́n bá dojú kọ ìwà òmùgọ̀ tí ń bẹ nínú àwọn ọmọ wọn. Àwọn ògowẹẹrẹ kì í ṣe àgbàlagbà. Kò yẹ kí àwọn òbí béèrè ju ohun tí ọjọ́ orí ọmọ kan, ipò àtilẹ̀wá ìdílé, àti ohun tí agbára rẹ̀ gbé lọ.—Wo Genesisi 33:12-14.
21. Ojú wo ni ó bá ìfẹ́ Ọlọrun mú láti fi wo àwọn òbí tí wọ́n ti dàgbà àti láti bá wọn lò?
21 Ojú tí a fi ń wo àwọn òbí tí wọ́n ti dàgbà. Lefitiku 19:32 sọ pé: “Kí ìwọ kí ó sì dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì bọ̀wọ̀ fún ojú arúgbó.” Òfin Ọlọrun tipa báyìí fún ọ̀wọ̀ àti ìkàsí ńláǹlà fún àwọn àgbàlagbà níṣìírí. Èyí lè jẹ́ ìpènijà nígbà tí ó bà dà bíi pé òbí kan tí ó ti dàgbà ń béèrè ju ohun tí agbára ẹní gbé lọ tàbí tí ó ń ṣàìsàn, bóyá tí kì í yára rìn tàbí yára ronú. Síbẹ̀, a rán àwọn ọmọ létí láti “máa san ìsanfidípò yíyẹ fún awọn òbí wọn.” (1 Timoteu 5:4) Èyí yóò túmọ̀ sí bíbá wọn lò pẹ̀lú ọlá àti ọ̀wọ̀, bóyá pípèsè fún wọn ní ti ọ̀ràn ìnáwó pàápàá. Híhùwà ìkà nípa ti ara sí àwọn òbí tí wọ́n ti dàgbà tàbí híhùwà ìkà sí wọn lọ́nà míràn ta ko bí Bibeli ṣe ní kí á hùwà pátápátá.
22. Kí ni ànímọ́ pàtàkì nínú bíborí ìwà ipá abẹ́lé, báwo sì ni a ṣe lè lò ó?
22 Mú ìkóra-ẹni-níjàánu dàgbà. Owe 29:11 sọ pé: “Aṣiwèrè a sọ gbogbo inú rẹ̀ jáde: ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n a pa á mọ́ di ìgbà ìkẹyìn.” Báwo ni o ṣe lè ṣàkóso ẹ̀mí rẹ? Dípò jíjẹ́ kí ìbínú gbèrú nínú lọ́hùn-ún, tètè yanjú àwọn ìṣòro tí ó bá dìde. (Efesu 4:26, 27) Fi ibẹ̀ sílẹ̀ bí o bá nímọ̀lára pé o kò lè ṣàkóso ara rẹ mọ́. Gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun láti mú kí o ní ìkóra-ẹni-níjàánu. (Galatia 5:22, 23) Dídọ́gbẹ̀ẹ́rẹ́ tàbí lílọ́wọ́ nínú àwọn eré ìmárale kan lè ṣèrànwọ́ láti ṣàkóso èrò ìmọ̀lára rẹ. (Owe 17:14, 27) Sakun láti “lọ́ra láti bínú.”—Owe 14:29.
PÍPÍNYÀ TÀBÍ GBÍGBÉ PA PỌ̀?
23. Kí ni ó lè ṣẹlẹ̀ bí mẹ́ḿbà kan nínú ìjọ Kristian bá ń hu ìwà ipá onírufùfù ìbínú léraléra, láìronú pìwà dà, bóyá tí ó tún ń ṣe ìdílé rẹ̀ léṣe nípa ti ara?
23 Bibeli ka “ìṣọ̀tá, gbọ́nmisi-omi-ò-to, . . . ìrufùfù ìbínú,” mọ́ àwọn iṣẹ́ tí Ọlọrun kò fọwọ́ sí, ó sì sọ pé “awọn wọnnì tí ń fi irúfẹ́ awọn nǹkan báwọ̀nyí ṣèwàhù kì yoo jogún ìjọba Ọlọrun.” (Galatia 5:19-21) Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé òún jẹ́ Kristian tí ó sì ń hu ìwà ipá onírufùfù ìbínú léraléra, láìronú pìwà dà, bóyá tí ó tún ń ṣe alábàáṣègbéyàwó tàbí àwọn ọmọ léṣe, ni a lè yọ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristian. (Fi wé 2 Johannu 9, 10.) Ní ọ̀nà yìí, a óò mú kí ìjọ wà ní mímọ́ tónítóní kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ń hùwà ìkà síni.—1 Korinti 5:6, 7; Galatia 5:9.
24. (a) Báwo ni àwọn alábàáṣègbéyàwó tí a ti ṣe léṣe ṣe lè yàn láti hùwà padà? (b) Báwo ni àwọn alàgbà àti àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n bìkítà ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn alábàáṣègbéyàwó tí a ti ṣe léṣe, ṣùgbọ́n kí ni kò yẹ kí wọ́n ṣe?
24 Àwọn Kristian tí alábàáṣègbéyàwó wọn ń lù ní àlùbolẹ̀ nísinsìnyí ńkọ́, tí kò sì fi àmì ìyípadà kankan hàn? Àwọn kan ti yàn láti dúró ti alábàáṣègbéyàwó tí ń ṣe wọ́n léṣe náà, fún ìdí kan tàbí òmíràn. Àwọn mìíràn ti yàn láti kó jáde, ní níní ìmọ̀lára pé, ìlera wọn nípa ti ara, ti èrò orí, àti tẹ̀mí—àní bóyá ìwàláàyè wọn pàápàá—wà nínú ewu. Ohun tí ẹnì kan tí ó jìyà ìwà ipá abẹ́lé bá yàn láti ṣe nínú àwọn àyíká ipò wọ̀nyí jẹ́ ìpinnu ara ẹni níwájú Jehofa. (1 Korinti 7:10, 11) Àwọn ọ̀rẹ́ afẹ́nifẹ́re, àwọn ẹbí, tàbí àwọn Kristian alàgbà lè fẹ́ láti ṣèrànwọ́, kí wọ́n sì fúnni ní ìmọ̀ràn, ṣùgbọ́n wọn kò ní láti fipá mú òjìyà kan láti gbé ìgbésẹ̀ kan pàtó. Ìpinnu ti ara rẹ̀ nìyẹn.—Romu 14:4; Galatia 6:5.
ÒPIN ÀWỌN ÌṢÒRO TÍ Ń ṢỌṢẸ́
25. Kí ni ète Jehofa fún ìdílé?
25 Nígbà tí Jehofa so Adamu àti Efa pọ̀ nínú ìgbéyàwó, kò fìgbà kankan pète pé àwọn ìṣòro tí ń ṣọṣẹ́, irú bí ìmukúmu tàbí ìwà ipá, yóò máa ba ìdílé jẹ́ díẹ̀díẹ̀. (Efesu 3:14, 15) Ó fẹ́ kí ìdílé jẹ́ ibi tí ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò ti gbilẹ̀, tí a óò sì bójú tó àìní mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan ní ti èrò orí, èrò ìmọ̀lára, àti nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó yọjú, ìgbésí ayé ìdílé jó àjórẹ̀yìn kíámọ́sá.—Fi wé Oniwasu 8:9.
26. Ọjọ́ ọ̀la wo ni ó dúró de àwọn tí wọ́n ń gbìyànjú láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí Jehofa béèrè fún?
26 Ó múni láyọ̀ pé, Jehofa kò tí ì pa ète rẹ̀ fún ìdílé tì. Ó ṣèlérí láti mú ayé tuntun alálàáfíà kan wá nínú èyí tí àwọn ènìyàn “yóò wà ní àlàáfíà ẹnikẹ́ni kì yóò sì dẹ́rù bà wọ́n.” (Esekieli 34:28) Ní àkókò yẹn, ìmukúmu, ìwà ipá abẹ́lé, àti gbogbo àwọn ìṣòro mìíràn tí ń ṣe ìdílé lọ́ṣẹ́ lónìí, yóò di ohun àtijọ́. Àwọn ènìyàn yóò rẹ́rìn-ín músẹ́, kì í ṣe láti fi bo ìbẹ̀rù àti ìrora wọn mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí pé, wọ́n ń rí “inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Orin Dafidi 37:11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tọ́ka sí i pé ọkùnrin ni onímukúmu náà, àwọn ìlànà tí ó wà níhìn-ín tún ṣeé mú lò bí onímukúmu náà bá jẹ́ obìnrin.
b Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n ní àwọn ibùdó ìtọ́jú, ilé ìwòsàn, àti àwọn ètò ìkọ́fẹpadà, tí ó wà fún ríran àwọn onímukúmu àti ìdílé wọn lọ́wọ́. Yálà láti wá irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ tàbí láti má ṣe wá a, jẹ́ ìpinnu ara ẹni. Watch Tower Society kò fàṣẹ sí ọ̀nà ìtọ́jú kan ní pàtó. Bí ó ti wù kí ó rí, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ó má baà jẹ́ pé, ní wíwá ìrànlọ́wọ́ kiri, ẹnì kan yóò tibẹ̀ lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tí ń fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ báni dọ́rẹ̀ẹ́.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . ÀWỌN ÌDÍLÉ LÁTI YẸRA FÚN ÀWỌN ÌṢÒRO TÍ Ó LÈ ṢỌṢẸ́ RÍRINLẸ̀?
Jehofa kò fọwọ́ sí mímu ọtí ní àmujù.—Owe 23:20, 21.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni yóò jíhìn fún àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.—Romu 14:12.
Láìsí ìkóra-ẹni-níjàánu a kò lè ṣiṣẹ́ sin Ọlọrun lọ́nà tí ó tẹ́wọ́ gbà.—Owe 29:11.
Àwọn ojúlówó Kristian ń bọlá fún àwọn òbí wọn tí wọ́n ti dàgbà.—Lefitiku 19:32.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 146]
Àwọn Kristian alàgbà lè jẹ́ orísun ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà nínú yíyanjú àwọn ìṣòro ìdílé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 151]
Àwọn tọkọtaya Kristian tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn, yòó gbé ìgbésẹ̀ kíámọ́sá láti yanjú aáwọ̀
-
-
Bí Ìgbéyàwó Bá Wà ní Bèbè ÀtitúkáÀṣírí Ayọ̀ Ìdílé
-
-
ORÍ KẸTÀLÁ
Bí Ìgbéyàwó Bá Wà ní Bèbè Àtitúká
1, 2. Nígbà tí ìgbéyàwó bá wà lábẹ́ másùnmáwo, ìbéèrè wo ni ó yẹ kí á béèrè?
NÍ 1988, obìnrin ará Itali kan, tí ń jẹ́ Lucia, soríkọ́ gidigidi.a Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá, ìgbéyàwó rẹ̀ forílé àtiforíṣánpọ́n. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó ti gbìyànjú láti parí ìjà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, ṣùgbọ́n òtúbáńtẹ́ ló ń já sí. Nítorí náà, ó pínyà, nítorí àìbára-ẹni-mu, ó sì wá dojú kọ dídánìkan gbọ́ bùkátà lórí àwọn ọmọbìnrin méjì. Ní wíwẹ̀yìn padà sí àkókò yẹn, Lucia rántí pé: “Mo ní ìdánilójú, nígbà yẹn lọ́hùn-ún pé, kò sí ohun tí ó lè gba ìgbéyàwó wa là.”
2 Bí o bá ń dojú kọ ìṣòro nínú ìgbéyàwó rẹ, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti lóye ìmọ̀lára Lucia. Ìgbéyàwó rẹ lè kún fún ìṣòro, kí o sì máa ṣe kàyéfì bí ohunkóhun bá lè gbà á là. Bí ó bá jẹ́ bí ọ̀ràn ti rí nìyẹn, yóò ṣàǹfààní fún ọ láti gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò: Mo ha ti tẹ̀ lé gbogbo ìmọ̀ràn rere tí Ọlọrun fi fúnni nínú Bibeli láti ran ìgbéyàwó lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí?—Orin Dafidi 119:105.
3. Bí ìkọ̀sílẹ̀ tilẹ̀ wọ́pọ̀, ìhùwàpadà wo ni a ròyìn rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn tí ó ti ṣèkọ̀sílẹ̀ àti àwọn ìdílé wọn?
3 Nígbà tí pákáǹleke bá ga láàárín ọkọ àti aya, títú ìgbéyàwó náà ká lè dà bí ìgbésẹ̀ tí ó rọrùn jù lọ láti gbé. Ṣùgbọ́n, bí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti ń rí ìbísí kíkàmàmà nínú ìdílé tí ń tú ká, ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin tí ó ti ṣèkọ̀sílẹ̀ ní ń kábàámọ̀ ìtúká náà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ń jìyà ìṣòro ìlera, ti ara àti ti ọpọlọ, ju àwọn tí kò tú ìgbéyàwó wọn ká. Ìdàrú ọkàn àti àìláyọ̀ àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn ti kọ ara wọn sílẹ̀ máa ń pẹ́ kí ó tó san. Àwọn òbí àti àwọn ọ̀rẹ́ ìdílé títúká ń jìyà pẹ̀lú. Ojú tí Ọlọrun, Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó, fi ń wo ipò náà ńkọ́?
4. Báwo ni ó ṣe yẹ kí á bójú tó àwọn ìṣòro nínú ìgbéyàwó?
4 Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú àwọn orí tí ó ṣáájú, Ọlọrun pète pé kí ìgbéyàwó jẹ́ ìdè wíwà pẹ́ títí. (Genesisi 2:24) Nígbà náà, kí ni ìdí tí ọ̀pọ̀ jaburata ìgbéyàwó fi ń forí ṣánpọ́n? Ó lè má ṣẹlẹ̀ lójijì. Lọ́pọ̀ ìgbà, àmì ìkìlọ̀ máa ń wà ṣáájú. Àwọn ìṣòro pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ìgbéyàwó lè gbèrú di ńlá títí tí wọn yóò fi dà bí èyí tí kò ṣeé yanjú. Ṣùgbọ́n, bí a bá tètè bójú tó àwọn ìṣòro wọ̀nyí, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Bibeli, kò ní sí ìdí fún ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó láti tú ká.
NÍ OJÚ ÌWÒYE TÒÓTỌ́
5. Ipò jíjóòótọ́ wo ni ó yẹ kí a dojú kọ nínú ìgbéyàwó èyíkéyìí?
5 Ohun kan tí ó sábà ń ṣamọ̀nà sí ìṣòro ni ìfojúsọ́nà tí kò jóòótọ́ tí alábàáṣègbéyàwó kan tàbí àwọn méjèèjì ní. Àwọn ìwé ìtàn eléré ìfẹ́, àwọn ìwé ìròyìn gbígbajúmọ̀, ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, àti àwọn sinimá lè ru ìrètí àti àlá asán, tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé sókè. Nígbà tí àwọn àlá wọ̀nyí kò bá ṣẹ, ẹnì kan lè ronú pé a ti rẹ́ òun jẹ, a kò tẹ́ òun lọ́rùn, ó sì lè ní ìkorò ọkàn pẹ̀lú. Bí ó ti wù kí ó rí, báwo ni àwọn aláìpé méjì ṣe lè rí ayọ̀ nínú ìgbéyàwó? Ó ń béèrè ìsapá kí ọwọ́ tó lè tẹ ìbátan aláṣeyọrí.
6. (a) Ojú ìwòye wíwà déédéé wo nípa ìgbéyàwó ni Bibeli fúnni? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tí ń fa àìfohùnṣọ̀kan nínú ìgbéyàwó?
6 Bibeli gbéṣẹ́. Ó sọ nípa ìdùnnú tí ń bẹ nínú ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n, ó tún kìlọ̀ pé, àwọn tí ó ṣègbéyàwó “yoo ní ìpọ́njú ninu ẹran-ara wọn.” (1 Korinti 7:28) Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ní ìṣáájú, tọkọtaya náà jẹ́ aláìpé, wọ́n sì lè dẹ́ṣẹ̀. Èrò orí, èrò ìmọ̀lára àti ìgbésí ayé àtilẹ̀wá àwọn méjèèjì yàtọ̀ síra. Àwọn tọkọtaya nígbà míràn kì í fohùn ṣọ̀kan nípa owó, ọmọ, àti àwọn àna. Àìsí àkókò tó láti jọ ṣe nǹkan pọ̀ àti àwọn ìṣòro ìbálòpọ̀ takọtabo tún lè jẹ́ orísun ìforígbárí.b Ó ń gba àkókò láti bójú tó irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n, mọ́kàn le! Ọ̀pọ̀ jù lọ tọkọtaya ni ó ti ṣeé ṣe fún láti kojú irú ìṣòro wọ̀nyí, wọ́n sì ti pèsè ojútùú tí àwọn méjèèjì fara mọ́.
Ẹ JÍRÒRÒ AÁWỌ̀ YÍN
7, 8. Bí ìmúbínú tàbí èdè àìyedè bá wà láàárín tọkọtaya, ọ̀nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni ó yẹ kí a gbà yanjú wọn?
7 Ó máa ń nira fún ọ̀pọ̀ ènìyàn láti sinmẹ̀dọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sọ ohun tí ó bí wọn nínú, èdè àìyedè, tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tí a ṣẹ̀ wọ́n. Kàkà kí ó sọ ní tààràtà pé: “O ṣì mí lóye,” alábàáṣègbéyàwó kan lè bínú, kí ó sì fẹ ìṣòro náà lójú ju bí ó ti yẹ lọ. Ọ̀pọ̀ yóò wí pé: “Ti ara rẹ nìkan ni o mọ̀,” tàbí, “O kò nífẹ̀ẹ́ mi.” Láìfẹ́ kó wọnú àríyànjiyàn, ẹnì kejì rẹ̀ lè kọ̀ láti fèsì.
8 Ọ̀nà tí ó dára jù láti tẹ̀ lé jẹ́ láti fetí sí ìmọ̀ràn Bibeli náà pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má sì ṣe ṣẹ̀; ẹ máṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín ninu ipò ìtánnísùúrù.” (Efesu 4:26) A bi tọkọtaya kan, tí ń ṣe ayẹyẹ ọgọ́ta ọdún ìgbéyàwó wọn, ní àṣírí ìgbéyàwó wọn aláṣeyọrí. Ọkọ náà sọ pé: “A kọ́ láti má ṣe lọ sùn láìyanjú àwọn aáwọ̀ wa, láìka bí wọ́n ti lè kéré tó sí.”
9. (a) Kí ni Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ó jẹ́ apá ṣíṣe kókó kan nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀? (b) Kí ni tọkọtaya ní láti ṣe lọ́pọ̀ ìgbà, bí èyí tilẹ̀ ń béèrè ìgboyà àti ìrẹ̀lẹ̀?
9 Nígbà tí èdè àìyedè bá ṣẹlẹ̀ láàárín tọkọtaya kan, olúkúlùkù wọ́n ní láti “yára nipa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nipa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nipa ìrunú.” (Jakọbu 1:19) Lẹ́yìn fífetí sílẹ̀ kínníkínní, àwọn méjèèjì lè rí ìdí láti tọrọ àforíjì. (Jakọbu 5:16) Fífi tinútinú sọ pé, “Máà bínú fún ìpalára tí mo ṣe fún ọ,” ń béèrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgboyà. Ṣùgbọ́n, yíyanjú aáwọ̀ lọ́nà yìí yóò gbéṣẹ́ gidigidi ní ríran tọkọtaya lọ́wọ́, kì í ṣe láti yanjú ìṣòro wọn nìkan, ṣùgbọ́n láti mú ẹ̀mí ọ̀yàyà àti ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí, tí yóò mú kí wọ́n túbọ̀ gbádùn ìbáṣepọ̀ wọn dáradára sí i, dàgbà.
FÍFI Ẹ̀TỌ́ ÌGBÉYÀWÓ FÚNNI
10. Ààbò wo tí Paulu dámọ̀ràn fún àwọn Kristian ní Korinti ni ó lè kan Kristian lónìí?
10 Nígbà tí aposteli Paulu kọ̀wé sí àwọn ará Korinti, ó dámọ̀ràn ìgbéyàwó “nitori ìgbòdekan àgbèrè.” (1 Korinti 7:2) Ayé òde òní burú bíi Korinti ìgbàanì, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. Àwọn ọ̀rọ̀ oníwà pálapàla tí àwọn ènìyàn ayé ń sọ ní gbangba, ọ̀nà tí kò bójú mu tí wọ́n ń gbà múra, àwọn ìtàn ìṣekúṣe tí a ń gbé jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé mìíràn, lórí tẹlifíṣọ̀n, àti nínú sinimá, gbogbo wọ́n ń para pọ̀ láti ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè. Fún àwọn ará Korinti tí ń gbé nínú irú àyíká bẹ́ẹ̀, aposteli Paulu sọ pé: “Ó sàn lati gbéyàwó ju kí ìfẹ́ onígbòónára máa mú ara-ẹni gbiná.”—1 Korinti 7:9.
11, 12. (a) Gbèsè kí ni ọkọ àti aya jẹ ara wọn, irú ẹ̀mí wo ni ó sì yẹ kí wọ́n fi san án fún ara wọn? (b) Báwo ni ó ṣe yẹ kí á bójú tó ipò náà, bí a óò bá du ara wa ní ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó fún ìgbà kúkúrú?
11 Nítorí náà, Bibeli pàṣẹ fún àwọn tọkọtaya Kristian pé: “Kí ọkọ máa fi ohun ẹ̀tọ́ aya rẹ̀ fún un; ṣugbọn kí aya pẹlu ṣe bákan naa fún ọkọ rẹ̀.” (1 Korinti 7:3) Kíyè sí i pé orí fífúnni ni ìtẹnumọ́ náà wà—kì í ṣe orí fífagbára béèrè. Ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí nínú ìgbéyàwó ń tẹ́ni lọ́rùn ní tòótọ́, kìkì bí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìgbéyàwó bá ń ṣàníyàn nípa ire ẹnì kejì rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Bibeli pàṣẹ fún ọkọ láti bá ìyàwó rẹ̀ lò “ní ìbámu pẹlu ìmọ̀.” (1 Peteru 3:7) Èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì nínú fífúnni àti gbígba ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó. Bí a kò bá fi jẹ̀lẹ́ńkẹ́ bá aya kan lò, ó lè ṣòro fún un láti gbádùn ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí yìí nínú ìgbéyàwó.
12 Àwọn ìgbà kán máa ń wà tí àwọn tọkọtaya lè ní láti fi ohun ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó du ara wọn. Èyí lè jẹ́ òtítọ́ nípa aya ní àwọn àkókò kan láàárín oṣù tàbí nígbà tí ó bá rẹ̀ ẹ́ gan-an. (Fi wé Lefitiku 18:19.) Ó lè jẹ́ òtítọ́ nípa ọkọ nígbà tí ó bá ń dojú kọ ìṣòro ńlá kan níbi iṣẹ́, tí èrò ìmọ̀lára rẹ̀ sì ti fàro. Irú fífi ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó duni fún ìgbà kúkúrú bẹ́ẹ̀, ní a lè bójú tó dáradára jù lọ bí àwọn méjèèjì bá jọ jíròrò ipò náà, láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, tí wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan nípasẹ “ìjọ́hẹn tọ̀túntòsì.” (1 Korinti 7:5) Èyí yóò ṣèdènà fún èyíkéyìí nínú àwọn méjèèjì láti dórí ìpinnu tí kò tọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, bí aya kan bá mọ̀-ọ́nmọ̀ fi du ọkọ rẹ̀, tàbí bí ọkọ kan bá dìídì kùnà láti fi ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó fún aya rẹ̀ ní ọ̀nà onífẹ̀ẹ́, ó lè ṣí ẹnì kejì rẹ̀ payá sí ìdẹwò. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ìṣòro lè jẹ yọ nínú ìgbéyàwó.
13. Báwo ni àwọn Kristian ṣe lè ṣiṣẹ́ láti pa ìrònú wọn mọ́ ní mímọ́ tónítóní?
13 Gẹ́gẹ́ bíi gbogbo Kristian, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè, tí ó lè ru ìfẹ́ ọkàn tí kò mọ́, tí kò sì bá ti ẹ̀dá mu sókè. (Kolosse 3:5) Wọ́n tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ èrò àti ìwà wọn nígbà tí wọ́n bá ń bá gbogbo mẹ́ḿbà ẹ̀yà kejì lò. Jesu kìlọ̀ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan lati ní ìfẹ́ onígbòónára sí i ti ṣe panṣágà pẹlu rẹ̀ ná ninu ọkàn-àyà rẹ̀.” (Matteu 5:28) Nípa fífi ìmọ̀ràn Bibeli lórí ìbálòpọ̀ takọtabo sílò, ó yẹ kí ó ṣeé ṣe fún tọkọtaya láti yẹra fún kíkó sínú ìdánwò, àti ṣíṣe panṣágà. Wọ́n lè máa bá a lọ láti gbádùn ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí dídùn mọ́ni nínú ìgbéyàwó tí a ti ka ìbálòpọ̀ takọtabo sí ẹ̀bùn gbígbámúṣé láti ọ̀dọ Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó, Jehofa.—Owe 5:15-19.
ÀWỌN ÌPÌLẸ̀ TÍ BIBELI FỌWỌ́ SÍ FÚN ÌKỌ̀SÍLẸ̀
14. Ipò bíbani nínú jẹ́ wo ni ó máa ń jẹ yọ nígbà míràn? Èé ṣe?
14 Lọ́nà tí ń múni láyọ̀, nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ìgbéyàwó Kristian, a lè yanjú ìṣòro èyíkéyìí tí ó bá yọjú. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà míràn, ọ̀ràn kì í rí bẹ́ẹ̀. Nítorí aláìpé ni wá, tí a sì ń gbé nínú ayé ẹlẹ́ṣẹ̀, tí ó wà lábẹ́ ìdarí Satani, àwọn ìgbéyàwó kan máa ń dé bèbè àtitúká. (1 Johannu 5:19) Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn Kristian bójú tó irú ipò dídánniwò bẹ́ẹ̀?
15. (a) Kí ni ìpìlẹ̀ kan ṣoṣo tí Ìwé Mímọ́ fúnni fún ìkọ̀sílẹ̀, pẹ̀lú ṣíṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn? (b) Èé ṣe tí àwọn kan fi yàn láti má ṣe kọ alábàáṣègbéyàwó wọn aláìṣòótọ́ sílẹ̀?
15 Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án nínú Orí 2 ìwé yìí, àgbèrè nìkan ni ìpìlẹ̀ kan ṣoṣo tí Ìwé Mímọ́ fúnni fún ìkọ̀sílẹ̀, pẹ̀lú ṣíṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn.c (Matteu 19:9) Bí o bá ní ẹ̀rí gúnmọ́ pé ẹnì kejì rẹ nínú ìgbéyàwó ti hùwà àìṣòótọ́, nígbà náà, o dojú kọ ìpinnu nínira. Ìwọ yóò ha máa bá ìgbéyàwó náà lọ tàbí ìwọ yóò ṣèkọ̀sílẹ̀? Kò sí òfin kan tí ó dè é. Àwọn Kristian kan ti forí ji ẹnì kejì wọn tí ó ronú pìwà dà tinútinú, tí ìgbéyàwó tí a pa mọ́ náà sì yọrí sí rere. Àwọn mìíràn kò ṣèkọ̀sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ.
16. (a) Kí ni díẹ̀ lára ìdí tí ó sún àwọn kan láti kọ alábàáṣègbéyàwó wọn tí ó ṣẹ̀ sílẹ̀? (b) Nígbà tí aláìmọwọ́mẹsẹ̀ nínú ìgbéyàwó bá pinnu láti ṣèkọ̀sílẹ̀ tàbí láti má ṣèkọ̀sílẹ̀, èé ṣe tí kò fi yẹ kí ẹnikẹ́ni ṣe lámèyítọ́ ìpinnu ẹni náà?
16 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìwà ẹ̀ṣẹ̀ náà ti lè yọrí sí oyún tàbí àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré. Tàbí bóyá a ní láti dáàbò bo àwọn ọmọ lọ́wọ́ òbí tí ń bọ́mọ ṣèṣekúṣe. Ní kedere, a ní láti gbé ohun púpọ̀ yẹ̀ wò kí a tó ṣèpinnu. Bí ó ti wù kí ó rí, bí o bá gbọ́ nípa àìṣòtítọ́ ẹnì kejì rẹ, tí o sì ní ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́yìn náà, o tipa báyìí fi hàn pé o ti forí ji alábàáṣègbéyàwó rẹ, o sì fẹ́ máa bá ìgbéyàwó náà lọ. Ìpìlẹ̀ fún ìkọ̀sílẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn, lọ́nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, kò sí níbẹ̀ mọ́. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọjúràn, kí ó sì gbìyànjú láti nípa lórí ìpinnu rẹ, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ ṣe lámèyítọ́ ìpinnu tí o bá ṣe. Ìwọ yóò ní láti tẹ́wọ́ gba àbájáde ìpinnu tí o ṣe. “Olúkúlùkù ni yoo ru ẹrù ti ara rẹ̀.”—Galatia 6:5.
ÀWỌN ÌPÌLẸ̀ FÚN ÌPÍNYÀ
17. Bí kò bá sí àgbèrè, ìkálọ́wọ́kò wo ni Ìwé Mímọ́ gbé ka ìpínyà tàbí ìkọ̀sílẹ̀?
17 Àwọn ipò kan ha wà tí ó lè mú kí ìpínyà tàbí ìkọ̀sílẹ̀ pàápàá, kúrò lọ́dọ̀ alábàáṣègbéyàwó ẹní tọ̀nà, àní bí ẹni tọ̀hún kò bá ṣàgbèrè pàápàá? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, Kristian kan kò lómìnira láti bá ẹlòmíràn dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ète fífẹ́ ẹ. (Matteu 5:32) Bí Bibeli tilẹ̀ yọ̀ǹda fún irú ìpínyà bẹ́ẹ̀, ó fi lélẹ̀ pàtó pé ẹni tí ń pínyà náà ní láti “wà láìlọ́kọ [tàbí láìláya] bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó parí aáwọ̀ pẹlu ọkọ [tàbí aya] rẹ̀.” (1 Korinti 7:11) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ipò lílégbákan tí ó lè mú kí ìpínyà dà bí ohun tí ó bọ́gbọ́n mu?
18, 19. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ipò lílé kenkà tí ó lè sún alábàáṣègbéyàwó kan láti gbé àǹfààní tí ń bẹ nínú ìpínyà tàbí ìkọ̀sílẹ̀ tí ó bófin mu yẹ̀ wò, bí kò bá tilẹ̀ ṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn?
18 Ó dára, ìdílé lè di aláìní nítorí ìwà ọ̀lẹ paraku àti àwọn àṣà burúkú ọkọ.d Ó lè máa náwó ìdílé dànù sórí tẹ́tẹ́ tàbí kí ó máa ná an sórí ìlòkulò oògùn tàbí ìmukúmu ọtí. Bibeli sọ pé: “Bí ẹni kan kò bá pèsè fún . . . awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà agbo ilé rẹ̀, oun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Timoteu 5:8) Bí irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ bá kùnà láti yí ọ̀nà rẹ̀ padà, bóyá kí ó tilẹ̀ máa mú lára owó aya rẹ̀ láti ná sórí àwọn àṣà burúkú rẹ̀, aya náà lè yàn láti dáàbò bo ire rẹ̀ àti ti àwọn ọmọ rẹ̀ nípa pípínyà lọ́nà òfin.
19 A tún lè gbé irú ìgbésẹ̀ tí ó bófin mu bẹ́ẹ̀ bí alábàáṣègbéyàwó kan bá jẹ́ ẹni tí ń hùwà ipá sí ẹnì kejì rẹ̀, bóyá ó máa ń lu ẹni tọ̀hún débi pé ìlera àti ẹ̀mí rẹ̀ pàápàá wà nínú ewu. Ní àfikún sí i, bí alábàáṣègbéyàwó kan bá ń gbìyànjú ní gbogbo ìgbà láti fipá mú ẹnì kejì rẹ̀ rú òfin Ọlọrun ní ọ̀nà kan, ẹni tí a ń halẹ̀ mọ́ náà lè ronú nípa pípínyà, pàápàá bí ọ̀ràn bá dórí ibi tí a ti fi ìwàláàyè rẹ̀ nípa tẹ̀mí sínú ewu. Alábàáṣègbéyàwó tí ó wà nínú ewu náà lè dórí ìpinnu pé, ọ̀nà kan ṣoṣo láti “ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn” jẹ́ láti pínyà lábẹ́ òfin.—Ìṣe 5:29.
20. (a) Nínú ọ̀ràn ìwólulẹ̀ ìdílé, kí ni àwọn ọ̀rẹ́ tí ó dàgbà dénú àti àwọn alàgbà lè fi fúnni, kí sì ni kò yẹ kí wọ́n fi fúnni? (b) Àwọn tọkọtaya kò gbọdọ̀ lo àwọn ìtọ́ka Bibeli sí ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwáwí láti ṣe kí ni?
20 Nínú gbogbo ọ̀ràn ìwà oníkà lílé kenkà ti alábàáṣègbéyàwó kan, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fagbára mú aláìmọwọ́mẹsẹ̀ nínú ìgbéyàwó náà yálà láti pínyà tàbí láti dúró ti ẹnì kejì rẹ̀. Bí àwọn ọ̀rẹ́ tí ó dàgbà dénú àti àwọn alàgbà tilẹ̀ lè fúnni ní ìtìlẹ́yìn àti ìmọ̀ràn tí a gbé karí Bibeli, àwọn wọ̀nyí kò lè mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí ń lọ láàárín ọkọ àti aya. Jehofa nìkan ṣoṣo ni ó lè rí èyí. Àmọ́ ṣáá o, Kristian aya kò bọlá fún ètò ìgbéyàwó tí Ọlọrun ṣe, bí ó bá ń lo àwọn àwáwí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí ipò líléwu gidi kan bá ń bá a lọ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe lámèyítọ́ rẹ̀ bí ó bá yàn láti pínyà. A lè sọ ohun kan náà nípa Kristian ọkọ kan tí ó fẹ́ pínyà. “Gbogbo wa ni yoo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọrun.”—Romu 14:10.
BÍ A ṢE GBA ÌGBÉYÀWÓ TÍ Ó TI FẸ́RẸ̀Ẹ́ TÚKÁ LÀ
21. Ìrírí wo ni ó fi hàn pé ìmọ̀ràn Bibeli lórí ìgbéyàwó ń múná dóko?
21 Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí Lucia, tí a mẹ́nu kàn ní ìṣáájú, pínyà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, ó ṣalábàápàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn. Ó ṣàlàyé pé: “Sí ìyàlẹ́nu mi gíga jù lọ, Bibeli pèsè àwọn ojútùú gbígbéṣẹ́ sí ìṣòro mi. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan péré tí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́, mo hára gàgà láti bá ọkọ mi làjà. Lónìí, mo lè sọ pé, Jehofa mọ bí a ti ń gba àwọn ìgbéyàwó tí ó wà nínú yánpọnyánrin sílẹ̀, nítorí pé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ń ṣèrànwọ́ fún tọkọtaya láti mọ bí wọ́n ṣe ní láti buyì fún ara wọn. Kì í ṣe òótọ́, bí àwọn kan ti ń sọ, pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń pín ìdílé níyà. Nínú ọ̀ràn tèmi, òdì kejì ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” Lucia kọ́ láti lo ìlànà Bibeli nínú ìgbésí ayé rẹ̀.
22. Nínú kí ni ó yẹ kí gbogbo tọkọtaya ní ìgbọkànlé?
22 Ọ̀ràn Lucia kì í ṣe àrà ọ̀tọ̀. Ó yẹ kí ìgbéyàwó jẹ́ ìbùkún, kì í ṣe ẹrù ìnira. Nítorí ìdí yìí, Jehofa ti pèsè orísun ìmọ̀ràn ìgbéyàwó dídára jù lọ tí a tíì kọ rí—Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣíṣeyebíye. Bibeli lè sọ “òpè di ọlọgbọ́n.” (Orin Dafidi 19:7-11) Ó ti gba ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó tí ó wà ní bèbè àtitúká là, ó sì ti mú ọ̀pọ̀ míràn, tí ó ní ìṣòro wíwúwo rinlẹ̀, sunwọ̀n sí i. Ǹjẹ́ kí gbogbo tọkọtaya ní ìgbọkànlé kíkún nínú ìmọ̀ràn ìgbéyàwó tí Jehofa Ọlọrun ń pèsè. Ó ń ṣiṣẹ́ gan-an!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ padà.
b A ti mójú tó díẹ̀ lára àwọn ìṣòro wọ̀nyí nínú àwọn orí tí ó ṣáájú.
c Ọ̀rọ̀ Bibeli náà tí a tú sí “àgbèrè,” kan panṣágà, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, ìbẹ́ranko-lòpọ̀, àti àwọn ìwà àìbófinmu mìíràn, tí a mọ̀-ọ́nmọ̀ hù, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú lílo àwọn ẹ̀yà ìbímọ.
d Èyí kò kan àwọn ipò nínú èyí tí kò ṣeé ṣe fún ọkọ, bí òún tilẹ̀ ní ète rere lọ́kàn, láti pèsè fún ìdílé rẹ̀ nítorí àwọn ìdí tí ó ré kọjá agbára rẹ̀, irú bí àìsàn tàbí àìníṣẹ́lọ́wọ́.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ . . . LÁTI YẸRA FÚN ÌWÓLULẸ̀ ÌGBÉYÀWÓ?
Ìgbéyàwó jẹ́ orísun ìdùnnú àti ìpọ́njú.—Owe 5:18, 19; 1 Korinti 7:28.
A gbọ́dọ̀ bójú tó aáwọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.—Efesu 4:26.
Nínú ìjíròrò, sísọ̀rọ̀ kò ṣe pàtàkì ju fífetí sílẹ̀.—Jakọbu 1:19.
A gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ ìgbéyàwó fúnni pẹ̀lú ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan àti oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.—1 Korinti 7:3-5.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 154]
Ẹ tètè yanjú àwọn ìṣòro yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìtánnísùúrù
-
-
Dídàgbà Pọ̀Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
-
-
ORÍ KẸRÌNLÁ
Dídàgbà Pọ̀
1, 2. (a) Àwọn ìyípadà wo ní ń wáyé bí ènìyàn ti ń sún mọ́ ọjọ́ ogbó? (b) Báwo ni àwọn ènìyàn oníwà-bí-Ọlọ́run ní àkókò tí a kọ Bibeli ṣe rí ìtẹ́lọ́rùn ní ọjọ́ ogbó?
Ọ̀PỌ̀ ìyípadà máa ń wáyé bí a ti ń dàgbà. Àìlera ara ń tán wa lókun. Ìrísí ẹni nínú dígí ń fi ìhunjọ àkọ̀tun àti ìyípadà díẹ̀díẹ̀ nínú àwọ̀ irun—títí kan ìpàdánù irun pàápàá, hàn. A lè di ẹni tí ń tètè gbàgbé nǹkan. A máa ń mú ìbátan tuntun dàgbà nígbà tí àwọn ọmọ bá ṣègbéyàwó, àti nígbà tí a bá ní àwọn ọmọ-ọmọ. Fún àwọn kan, ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ń yọrí sí ìlànà ìṣiṣẹ́ déédéé ojoojúmọ́ tí ó yàtọ̀ nínú ìgbésí ayé.
2 Ní tòótọ́, dídarúgbó jẹ́ àdánwò ńlá. (Oniwasu 12:1-8) Síbẹ̀, ronú nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní àwọn àkókò tí a kọ Bibeli. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n jèrè ọgbọ́n àti òye, tí ó mú ìtẹ́lọ́rùn ńlá wá fún wọn ní ọjọ́ ogbó. (Genesisi 25:8; 35:29; Jobu 12:12; 42:17) Báwo ni wọ́n ṣe ṣàṣeyọrí nínú dídarúgbó tayọ̀tayọ̀? Dájúdájú, ó jẹ́ nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tí àwa lónìí rí àkọsílẹ̀ wọn nínú Bibeli.—Orin Dafidi 119:105; 2 Timoteu 3:16, 17.
3. Ìmọ̀ràn wo ni Paulu fún àwọn àgbà ọkùnrin àti obìnrin?
3 Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí Titu, aposteli Paulu fún àwọn àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí ní ìmọ̀ràn yíyè kooro. Ó kọ̀wé pé: “Kí awọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ninu àṣà-ìhùwà, oníwà-àgbà, ẹni tí ó yèkooro ní èrò-inú, onílera ninu ìgbàgbọ́, ninu ìfẹ́, ninu ìfaradà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ kí awọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí ní ọ̀wọ̀ onífọkànsìn ninu ìhùwàsí, kì í ṣe afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n máṣe di ẹrú fún ọ̀pọ̀ ọtí-wáìnì, kí wọ́n jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere.” (Titu 2:2, 3) Kíkọbiara sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìpènijà dídàgbà.
Ẹ MÚ ARA YÍN BÁ ÒMÌNIRA ÀWỌN ỌMỌ YÍN MU
4, 5. Báwo ni ọ̀pọ̀ òbí ṣe ń hùwà padà nígbà tí àwọn ọmọ wọ́n bá fi ilé sílẹ̀, báwo sì ni àwọn kan ṣe ń mú ara wọn bá ipò tuntun náà mu?
4 Yíyí ẹrù iṣẹ́ padà ń béèrè fún ìmọwọ́ọ́yípadà. Ẹ wo bí èyí ti já sí òtítọ́ tó nígbà tí àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà bá fi ilé sílẹ̀ láti ṣègbéyàwó! Fún ọ̀pọ̀ òbí, èyí jẹ́ ìránnilétí àkọ́kọ́ pé wọ́n ti ń dàgbà. Bí wọ́n tilẹ̀ dunnú pé àwọn ọmọ wọn ti dàgbà, àwọn òbí sábà máa ń ṣàníyàn nípa bóyá wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti múra àwọn ọmọ sílẹ̀ fún wíwà lómìnira. Ojú sì lè máa ro wọ́n.
5 Ó yéni pé àwọn òbí ṣì máa ń ṣàníyàn nípa ire àwọn ọmọ wọn, àní lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ti fi ilé sílẹ̀ pàápàá. Ìyá kan sọ pé: “Bí ó bá kàn tilẹ̀ jẹ́ pé mo ń gbúròó wọn déédéé, láti fọkàn mi balẹ̀ pé gbogbo nǹkan ń lọ déédéé fún wọn—inú mi ì bá dùn.” Bàbá kan ròyìn pé: “Nígbà tí ọmọbìnrin wa fi ilé sílẹ̀, kò rọrùn fún wa rárá. Ó ṣí àlàfo ńlá sílẹ̀ nínú ìdílé wa, nítorí pé a jọ máa ń ṣe gbogbo nǹkan pọ̀ ni.” Báwo ni àwọn òbí wọ̀nyí ṣe kojú àìsí àwọn ọmọ wọn nílé? Lọ́pọ̀ ọ̀ràn, nípa ṣíṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn àti ríràn wọ́n lọ́wọ́.
6. Kí ní ń ṣèrànwọ́ láti pa ipò ìbátan ìdílé mọ́ sí àyè tí ó yẹ ẹ́?
6 Nígbà tí àwọn ọmọ bá ṣègbéyàwó, ẹrù iṣẹ́ àwọn òbí máa ń yí padà. Genesisi 2:24 sọ pé: “Nítorí náà ni ọkùnrin yóò ṣe máa fi bàbá òun ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fi ara mọ́ aya rẹ̀: wọn ó sì di ara kan.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Títẹ́wọ́ gba ìlànà Ọlọrun nípa ipò orí àti ètò nǹkan yóò ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye yíyẹ nípa àwọn nǹkan.—1 Korinti 11:3; 14:33, 40.
7. Ìṣarasíhùwà dídára wo ni bàbá kan mú dàgbà nígbà tí àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ fi ilé sílẹ̀ láti ṣègbéyàwó?
7 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọbìnrin méjèèjì tí tọkọtaya kan ní ṣègbéyàwó, tí wọ́n sì fi ilé sílẹ̀, tọkọtaya náà nímọ̀lára àlàfo ṣíṣí sílẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn. Lákọ̀ọ́kọ́, ọkọ kórìíra àwọn ọkọ àwọn ọmọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí ó ti ń ronú lórí ìlànà ipò orí, ó lóye pé àwọn ọkọ àwọn ọmọbìnrin òun ni wọ́n ni ojúṣe bíbójú tó agbo ilé wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, nígbà tí àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ béèrè ìmọ̀ràn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn nípa èrò àwọn ọkọ wọn, ó sì rí i dájú pé òún ti èrò àwọn ọkọ wọn lẹ́yìn bí ó ti lè ṣeé ṣe tó. Nísinsìnyí, àwọn ọkọ àwọn ọmọ rẹ̀ kà á sí ọ̀rẹ́, wọ́n sì ń tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn rẹ̀.
8, 9. Báwo ni àwọn òbí kan ṣe mú ara wọn bá òmìnira àwọn ọmọ wọn tí ó ti dàgbà mu?
8 Bí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ara wọn níyàwó, bí wọn kò tilẹ̀ ṣe ohun tí ó lòdì sí Ìwé Mímọ́, bá kùnà láti ṣe ohun tí àwọn òbí wọ́n rò pé ó dára jù lọ ńkọ́? Tọkọtaya kan, tí wọ́n ní àwọn ọmọ tí ó ti ṣègbéyàwó, ṣàlàyé pé: “A máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà gbogbo láti mọ ojú ìwòye Jehofa, ṣùgbọ́n bí a kò bá tilẹ̀ fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ìpinnu wọn, a máa ń tẹ́wọ́ gbà á, a sì máa ń tì wọ́n lẹ́yìn, a sì ń fún wọn níṣìírí.”
9 Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Asia, ó máa ń ṣòro gidigidi fún àwọn ìyá kan láti tẹ́wọ́ gba òmìnira àwọn ọmọ wọn ọkùnrin. Bí ó ti wù kí ó rí, bí wọ́n bá bọ̀wọ̀ fún ètò àti ipò orí Kristian, wọ́n máa ń rí i pé gbún-úngbùn-ùngbún pẹ̀lú àwọn ìyàwó àwọn ọmọ wọn máa ń dín kù. Kristian obìnrin kan rí i pé fífi tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi ilé sílẹ̀ ti jẹ́ “orísun ìmoore tí ń pọ̀ sí i.” Inú rẹ̀ dùn láti rí ìtóótun wọn láti bójú tó agbo ilé wọn tuntun. Èyí sì ti túmọ̀ sí mímú ẹrù ti ara àti ti èrò orí tí òun àti ọkọ rẹ̀ ní láti gbé bí wọ́n ti ń dàgbà sí i fúyẹ́.
FÍFÚN ÌDÈ ÌGBÉYÀWÓ YÍN LÓKUN LẸ́Ẹ̀KAN SÍ I
10, 11. Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ wo ni yóò ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti yẹra fún díẹ̀ lára àwọn ọ̀fìn àkókò ìgòkè àgbà?
10 Onírúurú ọ̀nà ni àwọn ènìyàn ń gbà hùwà bí wọ́n ti ń gòkè àgbà. Àwọn ọkùnrin kan máa ń múra yàtọ̀ nínú ìgbìdánwò wọn láti fara hàn bí ọ̀dọ́. Ọ̀pọ̀ obìnrin ń dààmú nípa àwọn ìyípadà tí ìmọ́wọ́dúró nǹkan oṣù ń mú wá. Lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́, àwọn kan tí ń gòkè àgbà máa ń mú alábàáṣègbéyàwó wọn bínú tàbí jowú nípa títage pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà kejì tí ó kéré púpọ̀ sí wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọkùnrin àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí, tí wọ́n jẹ́ oníwà-bí-Ọlọ́run, jẹ́ ẹni tí ó “yèkooro ní èrò-inú,” tí ń ki ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bọṣọ. (1 Peteru 4:7) Àwọn obìnrin adàgbàdénú pẹ̀lú ń ṣiṣẹ́ kára láti pa ìdúróṣinṣin ìgbéyàwó wọn mọ́, nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ọkọ wọn àti ìfẹ́ láti wu Jehofa.
11 Lábẹ́ ìmísí, Ọba Lemueli ṣàkọsílẹ̀ ìyìn fún “obìnrin oníwà rere,” tí ó san ẹ̀san “rere” fún ọkọ rẹ̀ “kì í ṣe búburú ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Kristian ọkọ kan kò ní kùnà láti mọyì bí aya rẹ̀ ṣe ń làkàkà láti kojú àwọn ìdààmú èrò ìmọ̀lára èyíkéyìí tí ó ń nírìírí rẹ̀ bí ó ti ń gòkè àgbà. Ìfẹ́ rẹ̀ yóò sún un láti “fi ìyìn fún un.”—Owe 31:10, 12, 28.
12. Báwo ni tọkọtaya ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí bí ogbó ṣe ń dé?
12 Ní àwọn ọdún títọ́ ọmọ, tí ọwọ́ há gádígádí, ẹ̀yin méjèèjì lè ti fi tayọ̀tayọ̀ pa lílépa àwọn ohun tí ẹ fọkàn fẹ́ tì láti bójú tó àwọn àìní àwọn ọmọ yín. Nísinsìnyí tí wọ́n ti fi ilé sílẹ̀, ó ti tó àkókò láti yí ìgbésí ayé ìgbéyàwó yín padà. Ọkọ kan sọ pé: “Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin mi fi ilé sílẹ̀, mo tún aya mi gbé.” Ọkọ mìíràn sọ pé: “A mójú tó ìlera ara wa lẹ́nì kíní-kejì, a sì ń rán ara wa létí àǹfààní eré ìmárale.” Nítorí kí wọ́n má baà nímọ̀lára ìdánìkanwà, òun àti aya rẹ̀ fi aájò àlejò hàn fún àwọn mẹ́ḿbà yòókù nínú ìjọ. Bẹ́ẹ̀ ni, fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn ń mú ìbùkún wá. Síwájú sí i, ó dùn mọ́ Jehofa nínú.—Filippi 2:4; Heberu 13:2, 16.
13. Ipa wo ni òtítọ́ inú àti àìlábòsí ń kó bí tọkọtaya kan ti ń dàgbà pọ̀?
13 Má ṣe jẹ́ kí àlàfo wà nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láàárín ìwọ àti alábàáṣègbéyàwó rẹ. Ẹ tú inú yín jáde fún ara yín. (Owe 17:27) Ọkọ kan sọ pé: “A túbọ̀ ń lóye ara wa sí i nípa ṣíṣe aájò ara wa lẹ́nì kíní-kejì àti nípa gbígba ti ara wa rò.” Aya rẹ̀ gbà pẹ̀lú rẹ̀, ní sísọ pé: “Bí a ti ń dàgbà sí i, a ti wá gbádùn mímu tíì pa pọ̀, jíjíròrò, àti fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wa.” Jíjẹ́ olótìítọ́ inú àti aláìlábòsí lè ṣèrànwọ́ láti mú ìdè ìgbéyàwó yín lókun sí i, ní fífún un ní agbára láti dojú àtakò Satani, olùba ìgbéyàwó jẹ́, bolẹ̀.
GBÁDÙN ÀWỌN ỌMỌ-ỌMỌ RẸ
14. Ipa ṣíṣe kedere wo ni ìyá-ìyá Timoteu kó nínú ìdàgbàsókè Timoteu gẹ́gẹ́ bíi Kristian kan?
14 Àwọn ọmọ-ọmọ jẹ́ “adé” àwọn àgbàlagbà. (Owe 17:6) Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àwọn ọmọ-ọmọ lè gbádùn mọ́ni gidigidi—kí ó múni lórí yá, kí ó sì tuni lára. Bibeli sọ̀rọ̀ dáradára nípa Loide, ìyá àgbà kan tí òun àti ọmọbìnrin rẹ̀, Eunike, ṣàjọpín ìgbàgbọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ọmọ rẹ̀ jòjòló, Timoteu. Ọmọdé yìí dàgbà pẹ̀lú ìmọ̀ náà pé ìyá rẹ̀ àti ìyá-ìyá rẹ̀ ka òtítọ́ Bibeli sí pàtàkì.—2 Timoteu 1:5; 3:14, 15.
15. Ní ti àwọn ọmọ-ọmọ, ipa ṣíṣeyebíye wo ni àwọn òbí àgbà lè kó, ṣùgbọ́n kí ni wọ́n ní láti yẹra fún?
15 Nígbà náà, níhìn-ín ni ibi tí àwọn òbí àgbà ti lè kópa tí ó ga lọ́lá. Ẹ̀yin òbí àgbà, ẹ ti ṣàjọpín ìmọ̀ yín nípa àwọn ète Jehofa pẹ̀lú àwọn ọmọ yín. Ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí pẹ̀lú ìran mìíràn! Inú ọ̀pọ̀ ọmọdé máa ń dùn láti gbọ́ àwọn ìtàn Bibeli lẹ́nu àwọn òbí wọn àgbà. Dájúdájú, ìwọ kò gba ẹrù iṣẹ́ tí bàbá ní láti gbin òtítọ́ Bibeli sínú àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́ ọn lọ́wọ́. (Deuteronomi 6:7) Kàkà bẹ́ẹ̀, o ń ṣe kún un. Ǹjẹ́ kí àdúrà rẹ jẹ́ ti onipsalmu pé: “Nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo hewú, Ọlọrun má ṣe kọ̀ mí; títí èmi óò fi fi ipá rẹ hàn fún ìran yìí, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn ará ẹ̀yìn.”—Orin Dafidi 71:18; 78:5, 6.
16. Báwo ni àwọn òbí àgbà ṣe lè yẹra fún jíjẹ́ okùnfà aáwọ̀ tí ń jẹ yọ nínú ìdílé wọn?
16 Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn òbí àgbà kan máa ń kẹ́ àwọn ọmọdé bà jẹ́, débi pé pákáǹleke ń dìde láàárín àwọn òbí àgbà náà àti àwọn ọmọ wọn tí ó ti dàgbà. Àmọ́ ṣáá o, inú rere àtọkànwá rẹ lè mú kí ó rọrùn fún àwọn ọmọ-ọmọ rẹ láti finú hàn ọ́, nígbà tí wọn kò bá nítẹ̀sí láti ṣí àwọn ọ̀ràn payá fún àwọn òbí wọn. Nígbà míràn, àwọn ọmọdé máa ń retí pé àwọn òbí wọn àgbà, tí ó gbọ̀jẹ̀gẹ́, yóò gbè sẹ́yìn wọn lòdì sí àwọn òbí wọn. Kí ni ó yẹ kí o ṣe? Lo ọgbọ́n, kí o sì fún àwọn ọmọ-ọmọ rẹ níṣìírí láti tú ọkàn wọn jáde fún àwọn òbí wọn. O lè ṣàlàyé pé èyí ń dùn mọ́ Jehofa nínú. (Efesu 6:1-3) Bí ó bá pọn dandan, o lè fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọmọdé náà nípa bíbá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀. Má fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fún àwọn ọmọ-ọmọ rẹ nípa àwọn ohun tí o ti kọ́ láti àwọn ọdún yìí wá. Ìwà àìlábòsí àti òtítọ́ inú rẹ lè ṣàǹfààní fún wọn.
YÍWỌ́ PADÀ BÍ O TI Ń DARÚGBÓ
17. Irú ìpinnu tí onipsalmu ṣe wo ni ó yẹ kí àwọn Kristian àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí ṣe?
17 Bí o ti ń dàgbà sí i, ìwọ yóò rí i pé o kò lè ṣe gbogbo ohun tí o máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ tàbí gbogbo ohun tí o fẹ́ láti ṣe. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè ko dídarúgbó lójú? Nínú èrò inú rẹ, o lè rò pé ọmọ 30 ọdún ni ọ́, ṣùgbọ́n ìrísí rẹ lójú dígí ń fi hàn kedere pé o dàgbà ju ìyẹn lọ fíìfíì. Ma ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Onipsalmu náà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jehofa pé: “Má ṣe ṣá mi tì nígbà ogbó; má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí agbára mi bá yẹ̀.” Pinnu láti ṣe irú ìpinnu kan náà tí onipsalmu ṣe. Ó sọ pé: “Èmi óò máa retí nígbà gbogbo, èmi óò sì máa fi ìyìn kún ìyìn rẹ.”—Orin Dafidi 71:9, 14.
18. Báwo ni Kristian tí ó dàgbà dénú kan ṣe lè lo àkókò ìfẹ̀yìntì rẹ̀ lọ́nà tí ó ṣeyebíye?
18 Ọ̀pọ̀ ti múra sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú láti fi kún ìyìn wọn sí Jehofa lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́. Bàbá kan, tí ó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, sọ pé: “Mo wéwèé ṣáájú nípa ohun tí n óò ṣe nígbà tí ọmọbìnrin wa bá parí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Mo pinnu pé n óò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún, mo sì ta òwò mi kí n lè lómìnira láti sin Jehofa ní kíkún sí i. Mo gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Ọlọrun.” Bí o bá ti ń sún mọ́ ọdún tí ìwọ yóò fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, rí ìtùnú nínú ìpolongo Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa pé: “Àní títí dé ogbó Èmi náà ni; àní títí dé ewú ni èmi óò rù yín.”—Isaiah 46:4.
19. Ìmọ̀ràn wo ni a fún àwọn tí ń darúgbó?
19 Mímú ara ẹni bá ipò ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ mu lè má rọrùn. Aposteli Paulu gba àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí nímọ̀ràn láti jẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ninu àṣà-ìhùwà.” Èyí ń béèrè fún ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo, láìjuwọ́sílẹ̀ fún ìtẹ̀sí wíwá ìgbésí ayé gbẹ̀fẹ́. Àìní tí ó túbọ̀ ga lè wà fún ìlànà ìṣiṣẹ́ déédéé ojoojúmọ́ àti ìbára-ẹni-wí lẹ́yìn ìfẹ̀yìntì ju ṣáájú rẹ̀ lọ. Nígbà náà, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí, ‘kí o máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ lati ṣe nígbà gbogbo ninu iṣẹ́ Oluwa, ní mímọ̀ pé òpò rẹ kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹlu Oluwa.’ (1 Korinti 15:58) Mú ìgbòkègbodò rẹ gbòòrò síwájú sí i láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. (2 Korinti 6:13) Ọ̀pọ̀ Kristian ń ṣe èyí nípa fífi tìtaratìtara wàásù ìhìn rere bí agbára ọjọ́ ogbó wọn ti yọ̀ǹda fún wọn tó. Bí o ti ń dàgbà sí i, jẹ́ “onílera ninu ìgbàgbọ́, ninu ìfẹ́, ninu ìfaradà.”—Titu 2:2.
KÍKOJÚ ÀDÁNÙ ALÁBÀÁṢÈGBÉYÀWÓ RẸ
20, 21. (a) Nínú ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan ìsinsìnyí, kí ni yóò pín tọkọtaya níyà nígbẹ̀yìngbẹ́yín? (b) Báwo ni Anna ṣe pèsè àpẹẹrẹ dídára fún àwọn alábàáṣègbéyàwó tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀?
20 Ó ń bani nínú jẹ́, ṣùgbọ́n òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro ni pé, nínú ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan ìsinsìnyí, ikú ń pín àwọn tọkọtaya níyà, nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Àwọn Kristian tí wọ́n pàdánù alábàáṣègbéyàwó wọ́n mọ̀ pé àwọn olólùfẹ́ wọn ń sùn, wọ́n sì ní ìdánilójú pé wọn yóò padà rí wọn. (Johannu 11:11, 25) Ṣùgbọ́n àdánù náà ń múni kẹ́dùn síbẹ̀. Báwo ni ẹni náà tí ó kù lẹ́yìn ṣe lè kojú rẹ̀?a
21 Rírántí ohun tí ẹnì kan nínú Bibeli ṣe yóò ṣàǹfààní. Anna di opó lẹ́yìn ọdún méje péré tí ó wọlé ọkọ, ó sì ti pé ọmọ ọdún 84 nígbà tí a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. A lè ní ìdánilójú pé ó kẹ́dùn nígbà tí ó pàdánù ọkọ rẹ̀. Báwo ni ó ṣe kojú rẹ̀? Ó ń ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí Jehofa Ọlọrun nínú tẹ́ḿpìlì, tọ̀sán-tòru. (Luku 2:36-38) Láìsí àníàní, ìgbé ayé iṣẹ́ ìsìn Anna, tí ó kún fún àdúrà, jẹ́ egbòogi fún ìbànújẹ́ àti ìdánìkanwà tí ó mọ̀ lára gẹ́gẹ́ bí opó kan.
22. Báwo ni àwọn opó kan ṣe kojú ìdánìkanwà?
22 Obìnrin ọlọ́dún 72, tí ó di opó ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ṣàlàyé pé: “Ìpèníjà gíga jù lọ fún mi jẹ́ àìní ẹnì kejì láti bá sọ̀rọ̀. Ọkọ mi mọ bí a ti ń fetí sílẹ̀. A máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìjọ àti ìpín wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian.” Opó mìíràn sọ pé: “Bí àkókò tilẹ̀ ń woni sàn, mo ti rí i pé ó túbọ̀ pé pérépéré láti sọ pé, ohun tí ènìyàn fi àkókò rẹ̀ ṣe ní ń ran ènìyàn lọ́wọ́ láti sàn. O wà ní ipò tí ó túbọ̀ dára láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.” Opó ọlọ́dún 67 kan gbà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí, ní sísọ pé: “Ọ̀nà dídára kan láti gbà kojú ọ̀fọ̀ jẹ́ láti fí ara rẹ fún àwọn ẹlòmíràn ní títù wọ́n nínú.”
ỌLỌRUN MỌYÌ WỌN NÍ ỌJỌ́ OGBÓ
23, 24. Ìtùnú ńlá wo ni Bibeli fún àwọn arúgbó, pàápàá àwọn opó?
23 Bí ikú tilẹ̀ mú alábàáṣègbéyàwó ààyò olùfẹ́ ẹni lọ, Jehofa jẹ́ adúrótini tí ó dájú. Ọba Dafidi ìgbàanì sọ pé: “Ohun kan ni èmi ń tọrọ ní ọ̀dọ̀ Oluwa, òun náà ni èmi óò máa wá kiri: kí èmi kí ó lè máa gbé inú ilé Oluwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi kí ó lè máa wo ẹwà Oluwa, kí èmi kí ó sì máa fi inú dídùn wo tẹ́ḿpìlì rẹ̀.”—Orin Dafidi 27:4.
24 Aposteli Paulu rọni pé: “Bọlá fún awọn opó tí wọ́n jẹ́ opó níti gàsíkíá.” (1 Timoteu 5:3) Ìmọ̀ràn tí ó tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, fi hàn pé àwọn opó yíyẹ, tí kò ní àwọn mọ̀lẹ́bí tí ó sún mọ́ wọn, lè ti nílò ìtìlẹ́yìn nípa ti ara láti ọ̀dọ̀ ìjọ. Bí ó ti wù kí ó rí, èrò tí ó wà nídìí ìtọ́ni náà láti “bọlá fún” ní èrò mímọyì wọn nínú. Ẹ wo irú ìtùnú tí àwọn opó lè rí gbà láti inú mímọ̀ pé Jehofa mọyì wọn, yóò sì tì wọ́n lẹ́yìn!—Jakọbu 1:27.
25. Góńgó wo ni ó ṣì wà fún àwọn arúgbó?
25 Ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun mí sí polongo pé: “Ẹwà àwọn arúgbó ni ewú.” Ó jẹ́ ‘adé ògo, bí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.’ (Owe 16:31; 20:29) Nígbà náà, yálà alábàáṣègbéyàwó rẹ ṣì wà láàyè tàbí o ti padà sí ipò àpọ́n, máa bá a nìṣó láti fi iṣẹ́ ìsìn Jehofa ṣe àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ. Ìwọ yóò tipa báyìí ṣe orúkọ rere pẹ̀lú Ọlọrun nísinsìnyí, ìwọ yóò sì ní ìrètí ìyè ayérayé nínú ayé kan tí ìrora ọjọ́ ogbó kì yóò ti sí mọ́.—Orin Dafidi 37:3-5; Isaiah 65:20.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìjíròrò kíkún lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . TỌKỌTAYA BÍ WỌ́N TI Ń DARÚGBÓ?
Àwọn ọmọ-ọmọ jẹ́ “adé” àwọn arúgbó.—Owe 17:6.
Ọjọ́ ogbó lè mú àfikún àǹfààní wá láti sin Jehofa.—Orin Dafidi 71:9, 14.
A rọ àwọn àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí láti jẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ninu àṣà-ìhùwà.”—Titu 2:2.
Bí àwọn tí ó pàdánù alábàáṣègbéyàwó wọn tilẹ̀ ń kẹ́dùn, wọ́n lè rí ìtùnú nínú Bibeli.—Johannu 11:11, 25.
Jehofa mọyì àwọn arúgbó tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́.—Owe 16:31.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 166]
Bí ẹ ti ń dàgbà, ẹ mú ìfẹ́ tí ẹ ni fún ara yín dá ara yín lójú
-
-
Bíbọlá fún Àwọn Òbí Wa ÀgbàlagbàÀṣírí Ayọ̀ Ìdílé
-
-
ORÍ KẸẸ̀Ẹ́DÓGÚN
Bíbọlá fún Àwọn Òbí Wa Àgbàlagbà
1. Gbèsè kí ni a jẹ àwọn òbí wa, nítorí èyí, báwo ni ó ṣe yẹ kí a nímọ̀lára, kí a sì hùwà sí wọn?
ỌKÙNRIN ọlọgbọ́n ìgbàanì gbani nímọ̀ràn pé: “Fetí sí ti bàbá rẹ tí ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí ó bá gbó.” (Owe 23:22) Ìwọ lè sọ pé, ‘Èmi ki yóò ṣe ìyẹn láé!’ Dípò gígan ìyá wa—tàbí bàbá wa—ọ̀pọ̀ nínú wa ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún wọn. A mọ̀ pé a jẹ wọ́n ní gbèsè ohun púpọ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn òbí wa fún wa ní ìwàláàyè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa ni Orísun ìwàláàyè, láìsí àwọn òbí wa, a kì bá tí wà láàyè. Kò sí ohun tí a lè fún àwọn òbí wa tí ó lè ṣeyebíye tó ìwàláàyè fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ronú nípa ìfara-ẹni-rúbọ, aájò alánìíyàn, ìnáwó, àti àbójútó onífẹ̀ẹ́ tí títọ́ ọmọ láti ọmọdé jòjòló di àgbàlagbà ń náni. Ẹ wo bí ó ti lọ́gbọ́n nínú tó nígbà náà, pé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbani nímọ̀ràn pé: “Bọlá fún baba rẹ ati ìyá rẹ . . . kí nǹkan lè lọ dáadáa fún ọ kí iwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀-ayé”!—Efesu 6:2, 3.
MÍMỌ ÀWỌN ÀÌNÍ TI ÈRÒ ÌMỌ̀LÁRA
2. Báwo ni àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ṣe lè san “ìsanfidípò yíyẹ” fún àwọn òbí wọn?
2 Aposteli Paulu kọ̀wé sí àwọn Kristian pé: “Kí [awọn ọmọ tabi awọn ọmọ-ọmọ] kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ lati máa fi ìfọkànsin Ọlọrun ṣèwàhù ninu agbo ilé tiwọn kí wọ́n sì máa san ìsanfidípò yíyẹ fún awọn òbí wọn ati awọn òbí wọn àgbà, nitori tí èyí ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọrun.” (1 Timoteu 5:4) Àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ń pèsè “ìsanfidípò yíyẹ” yìí nípa fífi ìmọrírì hàn fún àwọn ọdún onífẹ̀ẹ́, oníṣẹ́ àṣekára, àti aláájò tí àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà ti lò lé wọn lórí. Ọ̀nà kan tí àwọn ọmọ lè gbà ṣe èyí jẹ́ nípa mímọ̀ pé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yòókù, àwọn àgbàlagbà nílò ìfẹ́ àti ìmúdánilójú—gidigidi gan-an. Gẹ́gẹ́ bíi gbogbo wa, wọ́n ní láti mọ̀ pé a kà wọ́n sí pàtàkì. Wọ́n ní láti nímọ̀lára pé ìgbésí ayé wọn nítumọ̀.
3. Báwo ni a ṣe lè bọlá fún àwọn òbí wa àti àwọn òbí wa àgbà?
3 Nítorí náà, a lè bọlá fún àwọn òbí wa àti àwọn òbí wa àgbà nípa jíjẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. (1 Korinti 16:14) Bí àwọn òbí wa kì í bá bá wa gbé, a gbọ́dọ̀ rántí pé gbígbúròó wa ṣe pàtàkì púpọ̀ fún wọn. Lẹ́tà amóríyá gágá, ìkésíni lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù, tàbí ìbẹ̀wò lè dá kún ayọ̀ wọn gidigidi. Miyo, tí ń gbé ní Japan, kọ̀wé nígbà tí ó wà ní ẹni ọdún 82 pé: “Ọmọbìnrin mi [tí ọkọ rẹ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn àjò] máa ń sọ fún mi pé: ‘Màmá, jọ̀wọ́ bá wa “rìnrìn àjò.”’ Ó ń fi orúkọ ìjọ àti nọ́ḿbà tẹlifóònù ibi tí mo ti lè kàn sí wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ránṣẹ́ sí mi. Mo lè ṣí àwòrán ilẹ̀ tí mo ní, kí n sì sọ pé: ‘Ibí yìí ni wọ́n wà nísinsìnyí!’ Gbogbo ìgbà ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún fífi irú ọmọ báyìí ta mí lọ́rẹ.”
ṢÍṢÈRÀNWỌ́ NÍPA BÍBÓJÚ TÓ ÀWỌN ÀÌNÍ TI ARA
4. Báwo ni òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn àwọn Júù ṣe fún ìwà ìkà gbáà sí àwọn òbí àgbàlagbà níṣìírí?
4 Bíbọlá fún àwọn òbí ẹni ha kan bíbójú tó àwọn àìní wọn nípa ti ara pẹ̀lú bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ó kàn án. Ní ọjọ́ Jesu, àwọn aṣáájú ìsìn Júù gbé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ náà lárugẹ pé, bí ẹnì kan bá sọ kedere pé owó tàbí ohun ìní òún jẹ́ “ẹ̀bùn tí a yàsímímọ́ fún Ọlọrun,” kò sí lábẹ́ ojúṣe lílò ó láti bójú tó àwọn òbí rẹ̀ mọ́. (Matteu 15:3-6) Ẹ wo irú ìwà ìkà gbáà tí èyí jẹ́! Ní ti gidi, ń ṣe ni àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn ń ki àwọn ènìyàn láyà láti ṣàìbọlá fún àwọn òbí wọn, ṣùgbọ́n láti fojú tín-ínrín wọn nípa fífi ìmọtara-ẹni-nìkan sẹ́ ipò àìní wọn. Àwa kò fẹ́ ṣe èyí láé!—Deuteronomi 27:16.
5. Láìka ìpèsè tí ìjọba ṣe ní àwọn orílẹ̀-èdè kan sí, èé ṣe tí bíbọlá fún àwọn òbí ẹni fi kan gbígbọ́ bùkátà lórí wọn nígbà míràn?
5 Ní ọ̀pọ̀ órílẹ̀-èdè lónìí, àwọn ètò ìṣètìlẹ́yìn tí ìjọba dá sílẹ̀ ń bójú tó díẹ̀ lára àwọn ohun ti ara tí àwọn àgbàlagbà ṣaláìní, irú bí oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé. Ní àfikún sí ìyẹn, ó ti lè ṣeé ṣe fún àwọn àgbàlagbà náà fúnra wọn láti tọ́jú àwọn ohun ti ara díẹ̀ pamọ́ fún ọjọ́ ogbó wọn. Ṣùgbọ́n bí àwọn ìpèsè wọ̀nyí bá tán tàbí bí wọ́n bá ṣàìtó, àwọn ọmọ ń bọlá fún àwọn òbí wọn nípa ṣíṣe ohun tí wọ́n lè ṣe láti bójú tó àwọn àìní àwọn òbí wọn. Ní ti gidi, bíbójú tó àwọn òbí ọlọ́jọ́lórí jẹ́ ẹ̀rí ìfọkànsin Ọlọrun, ìyẹn ni pé, ìfọkànsìn ẹni sí Jehofa Ọlọrun, Olùdásílẹ̀ ètò ìdílé.
ÌFẸ́ ÀTI ÌFARA-ẸNI-RÚBỌ
6. Àwọn ètò ibùgbé wo ni àwọn kan ti ṣe láti lè bójú tó àìní àwọn òbí wọn?
6 Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ti fi pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfara-ẹni-rúbọ bójú tó àìní àwọn òbí wọn tí ó ṣaláìlera. Àwọn kan ti mú àwọn òbí wọn wá láti gbé pẹ̀lú wọn tàbí ṣí lọ sí ìtòsí wọn. Àwọn mìíràn ti ṣí lọ sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, irú ètò bẹ́ẹ̀ ti já sí ìbùkún fún àwọn òbí àti àwọn ọmọ.
7. Èé ṣe tí ó fi dára láti má ṣe tètè sáré ṣèpinnu jù nínú ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn òbí àgbàlagbà?
7 Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà míràn, irú ìṣílọ bẹ́ẹ̀ kì í yọrí sí rere. Èé ṣe? Bóyá nítorí pé a ti tètè sáré ṣèpinnu jù tàbí pé orí ìmọ̀lára nìkan ni a gbé ìpinnu náà kà. Pẹ̀lú ọgbọ́n, Bibeli kìlọ̀ pé: “Amòye ènìyàn wo ọ̀nà ara rẹ̀ rere.” (Owe 14:15) Fún àpẹẹrẹ, ká sọ pé ìyá rẹ, àgbàlagbà, níṣòro dídágbé, tí o sì rò pé ó lè ṣe é láǹfààní láti wá gbé pẹ̀lú rẹ. Bí o ti ń fi òye wo ọ̀nà ara rẹ, o lè gbé àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò: Kí ni àwọn àìní rẹ̀ ní ti gidi? Àwọn ìṣètò àdáni tàbí ti ìjọba, tí ó pèsè ojútùú àfirọ́pò ṣíṣètẹ́wọ́gbà ha wà bí? Òún ha fẹ́ láti ṣí lọ bí? Bí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni èyí yóò ṣe nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀? Òun yóò ha ní láti fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ sẹ́yìn bí? Báwo ni èyí yóò ṣe nípa lórí èrò ìmọ̀lára rẹ̀? O ha ti jíròrò gbogbo nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú rẹ̀ bí? Báwo ni irú ìṣílọ bẹ́ẹ̀ yóò ṣe nípa lórí rẹ, lórí alábàáṣègbéyàwó rẹ, lórí àwọn ọmọ rẹ? Bí ìyá rẹ bá nílò àbójútó, ta ni yóò pèsè rẹ̀? Ẹ ha lè pín ẹrù iṣẹ́ náà bí? O ha ti jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ọ̀ràn náà kàn gbọ̀ngbọ̀n bí?
8. Àwọn wo ni ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti bá fikùn lukùn nígbà tí o bá ń pinnu bí o ṣe lè ran àwọn òbí rẹ àgbàlagbà lọ́wọ́?
8 Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé gbogbo àwọn ọmọ inú ìdílé ni ẹrù iṣẹ́ àbójútó náà já lé lórí, ó lè bọ́gbọ́n mu láti pe ìpàdé gbogbo ìdílé, kí gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé lè ṣàjọpín nínu ṣíṣe ìpinnu. Bíbá àwọn alàgbà inú ìjọ Kristian tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tí ó ti dojú kọ irú ipò kan náà sọ̀rọ̀ lè ṣèrànwọ́ pẹ̀lú. Bibeli kìlọ̀ pé: “Láìsí ìgbìmọ̀, èrò a dasán, ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìmọ̀, wọn a fi ìdí múlẹ̀.”—Owe 15:22.
JẸ́ AFỌ̀RÀN-RORA-ẸNI-WÒ ÀTI OLÓYE
9, 10. (a) Láìka ọjọ́ ogbó wọn sí, ìgbatẹnirò wo ni ó yẹ kí a fi hàn sí àwọn àgbàlagbà? (b) Láìka ìgbésẹ̀ tí ọmọ tí ó ti dàgbà gbé nítorí àwọn òbí rẹ̀ sí, kí ni ó yẹ kí ó máa fún wọn nígbà gbogbo?
9 Bíbọlá fún àwọn òbí wa àgbàlagbà ń béèrè ẹ̀mí ìfọ̀ràn-rora-ẹni-wò àti òye. Bí wàhálà ọjọ́ ogbó ti ń yọjú, ó túbọ̀ lè máa nira fún àwọn àgbàlagbà láti rìn, jẹun, àti láti rántí nǹkan. Wọ́n lè nílò ìrànlọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ máa ń ṣàníyàn jù nípa ààbò àwọn òbí wọn, wọ́n sì máa ń gbìyànjú láti pèsè ìtọ́sọ́nà. Ṣùgbọ́n, àgbàlagbà ni àwọn arúgbó, pẹ̀lú àìmọye ọdún tí wọ́n ti fi to ọgbọ́n àti ìrírí jọ pelemọ, pẹ̀lú àìmọye ọdún tí wọ́n ti fi bójú tó ara wọn, tí wọ́n sì ti dá ṣèpinnu. Iyì àti ọ̀wọ̀ ara ẹni wọn lè ti rọ̀ mọ́ ipa wọn gẹ́gẹ́ bí òbí àti àgbàlagbà kan. Àwọn òbí tí wọ́n ronú pé àwọ́n ní láti fi ara àwọn sábẹ́ àkóso àwọn ọmọ wọn lè soríkọ́ tàbí bínú. Àwọn kan máa ń kọ̀, wọ́n sì máa ń ta ko ohun tí wọ́n lè rí gẹ́gẹ́ bí ìsapá láti já òmìnira wọn gbà kúrò lọ́wọ́ wọn.
10 Kò sí ojútùú rírọrùn sí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìwà inú rere láti yọ̀ǹda fún àwọn òbí àgbàlagbà láti bójú tó ara wọn, kí wọ́n sì dá ṣèpinnu dé ìwọ̀n tí ó bá ṣeé ṣe. Kì í ṣe ìwà ọlọgbọ́n láti pinnu ohun tí ó dára jù lọ fún àwọn òbí rẹ láìkọ́kọ́ jíròrò pẹ̀lú wọn ná. Wọ́n lè ti pàdánù ohun púpọ̀ nítorí ọjọ́ ogbó. Má dù wọ́n ni ohun tí ó kù fún wọn. Ìwọ́ lè rí i pé, bí o bá ti ń yẹra tó láti ṣàkóso àwọn òbí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ipò ìbátan rẹ pẹ̀lú wọn yóò ṣe máa sunwọ̀n sí i. Inú wọn yóò dùn, inú ìwọ pẹ̀lú yóò sì dùn. Bí o tilẹ̀ ní láti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lórí àwọn nǹkan kan fún ire wọn, bíbọlá fún àwọn òbí rẹ ń béèrè pé kí o fún wọn ní iyì àti ọ̀wọ̀ tí ó yẹ wọ́n. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbani nímọ̀ràn pé: “Kí ìwọ kí ó sì dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì bọ̀wọ̀ fún ojú arúgbó.”—Lefitiku 19:32.
PÍPA Ẹ̀MÍ ÌRÒNÚ YÍYẸ MỌ́
11-13. Bí ọmọ tí ó ti dàgbà kò bá ní ipò ìbátan tí ó dára pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ láti ilẹ̀ wá, báwo ni ó ṣì ṣe lè bójú tó ìpènijà ṣíṣaájò wọn ní ọjọ́ ogbó wọn?
11 Nígbà míràn, ìṣòro tí àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ń dojú kọ nínú bíbọlá fún àwọn òbí wọn tí ó ti darúgbó ní í ṣe pẹ̀lú ipò ìbátan tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn òbí wọn nígbà tí wọ́n wà ní kékeré. Bóyá bàbá rẹ kò fi ọ̀yàyà àti ìfẹ́ hàn sí ọ, ìyá rẹ jẹ gàba lé ọ lórí, ó sì rorò. O ṣì lè ní ìjákulẹ̀, ìbínú, tàbí ìrora, nítorí wọn kì í ṣe irú òbí tí o fẹ́ kí wọ́n jẹ́. O ha lè ṣẹ́pá irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ bí?a
12 Basse, tí a tọ́ dàgbà ní Finland, ròyìn pé: “Ọkọ ìyá mi ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olóyè SS ní Nazi Germany. Ó máa ń tètè bínú, kò sì ṣeé sún mọ́ ní àkókò yìí. Ó lu ìyá mi bolẹ̀ ní àìmọye ìgbà lójú mi. Nígbà kan, nígbà tí inú rẹ̀ ru sí mi, ó fi bẹ́líìtì rẹ̀ làkàlàkà, ó sì fi irin rẹ̀ gbá mí lójú. Ó gbá mi débi pé mo tàkìtì lórí ibùsùn.”
13 Síbẹ̀, ó ní àwọn ànímọ́ mìíràn. Basse fi kún un pé: “Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó ṣiṣẹ́ kára, kò sì yẹ gbígbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀ sílẹ̀. Kò hùwà sí mi bíi bàbá rí, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé a ti ṣá a lọ́gbẹ́ nípa ti èrò ìmọ̀lára. Ní kékeré ni ìyá rẹ̀ ti tì í síta. Gbogbo ìgbà ni ó máa ń jà, ó sì wọnú ogun gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́kùnrin kan. Mo lè lóye rẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan, n kò sì dá a lẹ́bi. Nígbà tí mo dàgbà, tí ara bàbá mi kò sì yá, mo fẹ́ láti ṣèrànlọ́wọ́ fún un débi tí agbára mi mọ, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Kò rọrùn rárá, ṣùgbọ́n mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe. Mo gbìyànjú láti jẹ́ ọmọ rere títí dé òpin, mo sì rò pé ó gbà pé mo ṣe bẹ́ẹ̀.”
14. Ẹsẹ ìwé mímọ́ wo ni ó ṣeé mú lò nínú gbogbo ipò, títí kan àwọn tí ń dìde nínú bíbójú tó àwọn òbí àgbàlagbà?
14 Nínú ọ̀ràn ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú àwọn ọ̀ràn yòókù, ìmọ̀ràn Bibeli náà ṣeé mú lò pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inúrere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú, ìwàtútù, ati ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nìkínní kejì kí ẹ sì máa dáríji ara yín fàlàlà lẹ́nìkínní kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní èrèdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti dáríjì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹlu máa ṣe.”—Kolosse 3:12, 13.
ÀWỌN TÍ Ń BÓJÚ TÓNI NÍLÒ ÀBÓJÚTÓ PẸ̀LÚ
15. Èé ṣe tí bíbójú tó àwọn òbí fi ń múni soríkọ́ nígbà míràn?
15 Ṣíṣaájò òbí tí ó ṣaláìlera jẹ́ iṣẹ́ ńlá, tí ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsapá, ẹrù iṣẹ́, àti àkókò gígùn. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn nípa èrò ìmọ̀lára ni ó nira jù lọ. Ó ń soni lórí kọ́ láti máa wo àwọn òbí rẹ bí wọ́n ti ń pàdánù ìlera, agbára ìrántí, àti òmìnira wọn. Sandy, tí ó wá láti Puerto Rico, ròyìn pé: “Ìyá mi ni igi lẹ́yìn ọgbà nínú ìdílé wa. Ó ń roni lára gan-an láti rí bí ó ṣe ń jìyà, tí a sì ní láti ṣaájò rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í tiro; láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó di ẹni tí ń fi ọ̀pá rìn, lẹ́yìn náà, ó lo irin ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tí arọ ń rọ̀ lé láti fi rìn, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó di ẹni tí ń lo kẹ̀kẹ́ arọ. Láti ìgbà náà wá ipò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í burú sí i, títí tí ó fi kú. Ó ní àrùn jẹjẹrẹ inú egungun, ó sì nílò àbójútó déédéé—tọ̀sán-tòru. A máa ń wẹ̀ fún un, a ń fi oúnjẹ nù ún, a sì máa ń kàwé fún un. Kò rọrùn rárá—pàápàá ní ti èrò ìmọ̀lára. Nígbà tí ó hàn sí mi pé ìyá mi ń kú lọ, mo sunkún, nítorí pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gidi gan-an.”
16, 17. Ìmọ̀ràn wo ni ó lè ran abójútóni lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye tí ó wà déédéé nípa àwọn nǹkan?
16 Bí o bá bá ara rẹ nínú irú ipò kan náà, kí ni o lè ṣe láti kojú rẹ̀? Fífetí sí Jehofa nípa kíka Bibeli àti bíbá a sọ̀rọ̀ nínú àdúrà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ gidigidi. (Filippi 4:6, 7) Ní ọ̀nà ti ara, rí i dájú pé o ń jẹ àwọn oúnjẹ tí ó ní àwọn èròjà tí ń ṣara lóore, kí o sì máa gbìyànjú láti sùn dáadáa. Nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò wà ní ipò tí ó túbọ̀ dára, nípa ti èrò ìmọ̀lára àti ti ara, láti ṣaájò àyànfẹ́ rẹ. Bóyá o lè ṣètò láti ní ìsinmi díẹ̀ lẹ́nu ìlànà ìṣiṣẹ́ déédéé ojoojúmọ́ rẹ. Bí kò bá tilẹ̀ ṣeé ṣe fún ọ láti lọludé lọ, ó ṣì bọ́gbọ́n mu láti ṣètò àkókò díẹ̀ láti fi sinmi. Láti lè rí àyè lọ sinmi, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti ṣètò fún ẹnì kan láti dúró ti òbí rẹ tí ń ṣòjòjò náà.
17 Kò ṣàjèjì fún àwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ abójútóni láti retí ohun tí agbára wọn kò ká lọ́wọ́ ara wọn. Ṣùgbọ́n, má ṣe dá ara rẹ lẹ́bi fún ohun tí o kò lè ṣe. Ní àwọn ipò àyíká kan, o lè ní láti gbé àyànfẹ́ rẹ lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Bí o bá jẹ́ abójútóni, àwọn góńgó tí agbára rẹ lè ka ni kí o gbé kalẹ̀. O gbọ́dọ̀ wà déédéé nípa àìní àwọn ọmọ rẹ, alábàáṣègbéyàwó rẹ, àti ti ara rẹ pẹ̀lú, kì í ṣe ti àwọn òbí rẹ nìkan.
OKUN TÍ Ó RÉ KỌJÁ TI Ẹ̀DÁ
18, 19. Ìlérí ìtìlẹyìn wo ni Jehofa ṣe, ìrírí wo ni ó sì fi hàn pé ó ń pa ìlérí yìí mọ́?
18 Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, Jehofa fi tìfẹ́tìfẹ́ pèsè ìtọ́sọ́nà tí ó lè ṣèrànwọ́ gidigidi fún ẹnì kan nínú bíbojú tó àwọn òbí tí ń darúgbó, ṣùgbọ́n ìyẹn nìkan kọ́ ni ìrànlọ́wọ́ tí ó pèsè. Lábẹ́ ìmísí, onipsalmu náà kọ̀wé pé: “Oluwa wà létí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí ń ké pè é. . . . Yóò gbọ́ igbe wọn pẹ̀lú yóò sì gbà wọ́n.” Jehofa yóò gba àwọn olùṣòtítọ́, tàbí dá wọn sí, la àwọn ipò tí ó nira jù lọ pàápàá kọjá.—Orin Dafidi 145:18, 19.
19 Myrna, ní ilẹ̀ Philippines, nírìírí èyí nígbà tí ó ń ṣaájò ìyá rẹ̀, tí àrùn ẹ̀gbà sọ di aláìlèdáṣe-ohunkóhun. Myrna kọ̀wé pé: “Kò sí ohun tí ń múni soríkọ́ tó rírí àyànfẹ́ rẹ tí ń jìyà, tí kò ṣeé ṣe fún un láti sọ ibi tí ń dùn ún fún ọ. Ń ṣe ni ó dà bíi pé mo rí i tí ó ń rọra rì sínú omi, tí n kò sì lè ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń kúnlẹ̀ àdúrà tí mo sì máa ń sọ fún Jehofa nípa bí ó ti rẹ̀ mí tó. Mo ké jáde bíi Dafidi, tí ó fi taratara bẹ Jehofa láti fi omijé òun sínú ìgò, kí ó sì rántí òun. [Orin Dafidi 56:8] Gẹ́gẹ́ bí Jehofa sì ti ṣèlérí, ó fún mi ní agbára tí mo nílò. ‘Oluwa ni aláfẹ̀yìntì mi.’”—Orin Dafidi 18:18.
20. Àwọn ìlérí Bibeli wo ní ń ran àwọn abójútóni lọ́wọ́ láti pa ojú ìwòye nǹkan yóò dára mọ́, bí ẹni tí wọ́n ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀ tilẹ̀ kú?
20 A máa ń sọ pé, ṣíṣaájò àwọn òbí ọlọ́jọ́lórí jẹ́ “ìtàn tí kì í ní ìgbẹ̀yìn tí ó dára.” Láìka ìsapá tí ó dára jù lọ ní bíbójú tó wọn sí, àwọn arúgbó wa lè kú, gẹ́gẹ́ bí ìyá Myrna ti ṣe. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa mọ̀ pé ikú kì í ṣe òpin ìtàn náà. Aposteli Paulu sọ pé: “Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọrun . . . pé àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo yoo wà.” (Ìṣe 24:15) Àwọn tí ó ti pàdánù àwọn òbí wọn àgbàlagbà nínú ikú ń rí ìtùnú gbà nínú ìrètí àjíǹde pa pọ̀ pẹ̀lú ìlérí ayé tuntun aládùn kan, tí yóò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, nínú èyí tí “ikú kì yoo sì sí mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.
21. Ire wo ní ń jẹ yọ láti inú bíbọlá fún àwọn òbí wa àgbàlagbà?
21 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún àwọn òbí wọn, bí àwọn wọ̀nyí tilẹ̀ lè ti darúgbó. (Owe 23:22-24) Wọ́n ń bọlá fún wọn. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń nírìírí ohun tí òwe onímìísí náà sọ, pé: “Bàbá rẹ àti ìyá rẹ yóò yọ̀, inú ẹni tí ó bí ọ yóò dùn.” (Owe 23:25) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn tí ń bọlá fún àwọn òbí wọn àgbàlagbà ń mú inú Jehofa Ọlọrun dùn, wọ́n sì tún ń bọlá fún un.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe àwọn ipò tí àwọn òbí ti jẹ̀bi ṣíṣi agbára àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí a ní nínú wọn lò pátápátá, débi tí a lè sọ pé wọ́n jẹ̀bi ìwà ọ̀daràn, ni a ń sọ níhìn-ín.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . WA LÁTI BỌLÁ FÚN ÀWỌN ÒBÍ WA ÀGBÀLAGBÀ?
A gbọ́dọ̀ san àsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí wa àti àwọn òbí wa àgbà.—1 Timoteu 5:4.
Gbogbo àwọn àlámọ̀rí wa gbọ́dọ̀ máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́.—1 Korinti 16:14.
A kò gbọdọ̀ sáré jù láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì.—Owe 14:15.
A gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wa àgbàlagbà, àní bí wọ́n bá tilẹ̀ ń ṣàìsàn, tí wọ́n sì ń gbó lọ pàápàá.—Lefitiku 19:32.
Kì í ṣe títí gbére ni a óò máa dojú kọ dídarúgbó, kí a sì kú.—Ìṣípayá 21:4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 179]
Kì í ṣe ìwà ọlọgbọ́n láti pinnu fún òbí kan láìkọ́kọ́ bá a sọ̀rọ̀ ná
-
-
Wá Ọjọ́ Ọ̀la Wíwà Pẹ́ Títí fún Ìdílé RẹÀṣírí Ayọ̀ Ìdílé
-
-
Orí Kẹrìndínlógún
Wá Ọjọ́ Ọ̀la Wíwà Pẹ́ Títí fún Ìdílé Rẹ
1. Kí ni ète Jehofa fún ètò ìdílé?
NÍGBÀ tí Jehofa so Adamu àti Efa pọ̀ nínú ìgbéyàwó, Adamu fi ìdùnnú rẹ̀ hàn nípa kíkéwì Heberu tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ lọ́jọ́ lórí jù lọ. (Genesisi 2:22, 23) Bí ó ti wù kí ó rí, Ẹlẹ́dàá ní púpọ̀ lọ́kàn ju mímú adùn wá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn lọ. Ó fẹ́ kí tọkọtaya àti ìdílé wọn ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ó sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ pé: “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa rẹ̀, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀; kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun, àti lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, àti lórí ohun alààyè gbogbo tí ń rákò lórí ilẹ̀.” (Genesisi 1:28) Ẹ wo irú iṣẹ́ amérèwá gidi tí ìyẹn jẹ́! Ẹ sì wo bí àwọn àti àwọn ọmọ wọn ọjọ́ ọ̀la ì bá ti láyọ̀ tó ká ní Adamu àti Efa ti ṣe ìfẹ́ Jehofa nínú ìgbọràn kíkún rẹ́rẹ́!
2, 3. Báwo ni àwọn ìdílé ṣe lè rí ayọ̀ tí ó ga jù lọ lónìí?
2 Lónìí pẹ̀lú, ayọ̀ ìdílé máa ń kún nígbà tí wọ́n bá jùmọ̀ ṣiṣẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọrun. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ìfọkànsin Ọlọrun ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí ati ti èyíinì tí ń bọ̀.” (1 Timoteu 4:8) Ìdílé tí ń gbé pẹ̀lú ìfọkànsin Ọlọrun, tí ó sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jehofa, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú Bibeli, yóò rí ayọ̀ nínú “ìyè ti ìsinsìnyí.” (Orin Dafidi 1:1-3; 119:105; 2 Timoteu 3:16) Àní bí ó bá jẹ́ kìkì mẹ́ḿbà kan ṣoṣo nínú ìdílé ní ń lo àwọn ìlànà Bibeli, àwọn nǹkan máa ń dára ju ìgbà tí ẹnikẹ́ni kò bá lò ó lọ.
3 Ìwé yìí ti jíròrò ọ̀pọ̀ ìlànà Bibeli tí ń dá kún ayọ̀ ìdílé. Ó ṣeé ṣe kí o ti kíyè sí i pé díẹ̀ lára wọ́n fara hàn léraléra jálẹ̀ ìwé yìí. Èé ṣe? Nítorí wọ́n jẹ́ òtítọ́ lílágbára tí ó gbéṣẹ́ fún ire gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé ní onírúurú apá ìgbésí ayé ìdílé. Ìdílé tí ó bá là kàkà láti lo àwọn ìlànà Bibeli wọ̀nyí, yóò rí i pé ìfọkànsin Ọlọrun “ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí,” ní tòótọ́. Ẹ jẹ́ kí a wo mẹ́rin lára àwọn ìlànà pàtàkì wọ̀nyẹn lẹ́ẹ̀kan sí i.
ÀǸFÀÀNÍ ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU
4. Èé ṣe tí ìkóra-ẹni-níjàánu fi ṣe pàtàkì nínú ìgbéyàwó?
4 Ọba Solomoni sọ pé: “Ẹni tí kò lè ṣe àkóso ara rẹ̀, ó dà bí ìlú tí a wó lulẹ̀, tí kò sì ní odi.” (Owe 25:28; 29:11) ‘Ṣíṣàkóso ara ẹni,’ lílo ìkóra-ẹni-níjàánu, ṣe kókó fún àwọn tí ń fẹ́ ìgbéyàwó aláyọ̀. Jíjuwọ́ sílẹ̀ fún èrò ìmọ̀lára apanirun, irú bí ìbínú fùfù tàbí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, yóò ṣèpalára tí yóò gba ọ̀pọ̀ ọdún láti ṣàtúnṣe—bí ó bá ṣe é tún ṣe rárá.
5. Báwo ni ènìyàn aláìpé ṣe lè mú ìkóra-ẹni-níjàánu dàgbà, pẹ̀lú àwọn àǹfààní wo sì ni?
5 Àmọ́ ṣáá o, kò sí àtọmọdọ́mọ Adamu èyíkéyìí tí ó lè ṣàkóso ẹran ara rẹ̀ aláìpé délẹ̀délẹ̀. (Romu 7:21, 22) Síbẹ̀, ìkóra-ẹni-níjàánu jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èso ẹ̀mí. (Galatia 5:22, 23) Nítorí náà, ẹ̀mí Ọlọrun yóò mú ìkóra-ẹni-níjàánu jáde nínú wa bí a bá gbàdúrà fún ànímọ́ yìí, bí a bá lo ìmọ̀ràn yíyẹ, tí a rí nínú Ìwé Mímọ́, bí a bá sì kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń fi ànímọ́ yìí hàn, tí a sì yẹra fún àwọn tí kì í fi í hàn. (Orin Dafidi 119:100, 101, 130; Owe 13:20; 1 Peteru 4:7) Irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti “sá fún àgbèrè,” àní nígbà tí a bá dẹ wá wò pàápàá. (1 Korinti 6:18) A óò kọ ìwà ipá sílẹ̀, a óò sì yẹra fún ìmukúmu tàbí kí a ṣẹ́pá rẹ̀. Gbogbo wa yóò sì lè fi pẹ̀lẹ́tù kojú ìsúnnibínú àti àwọn ipò tí kò rọrùn. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa—títí kan àwọn ọmọdé—kọ́ láti mú èso ẹ̀mí ṣíṣeyebíye yìí dàgbà.—Orin Dafidi 119:1, 2.
OJÚ ÌWÒYE TÍ Ó TỌ́ NÍPA IPÒ ORÍ
6. (a) Kí ni ètò tí Ọlọrun fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ipò orí? (b) Kí ni ó yẹ kí ọkọ́ rántí bí ipò orí rẹ̀ yóò bá mú ayọ̀ wá fún ìdílé rẹ̀?
6 Mímọ ipò orí jẹ́ ìlànà kejì tí ó ṣe pàtàkì. Paulu ṣàpèjúwe ìṣètò àwọn nǹkan nígbà tí ó sọ pé: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀ orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀ orí Kristi ni Ọlọrun.” (1 Korinti 11:3) Èyí túmọ̀ sí pé ọkọ ní ń mú ipò iwájú nínú ìdílé, ìyàwó rẹ̀ ń fi ìṣòtítọ́ ṣètìlẹyìn, àwọn ọmọ sì ń ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn. (Efesu 5:22-25, 28-33; 6:1-4) Àmọ́ ṣáá o, kíyè sí i pé ipò orí ń ṣamọ̀nà sí ayọ̀ kìkì nígbà tí a bá lò ó lọ́nà tí ó yẹ. Àwọn ọkọ tí ń gbé pẹ̀lú ìfọkànsin Ọlọrun mọ̀ pé ipò orí kì í ṣe ipò apàṣẹwàá. Wọ́n ń fara wé Jesu, Orí wọn. Bí Jesu yóò tilẹ̀ jẹ́ “orí lórí ohun gbogbo,” òún “wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bíkòṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́.” (Efesu 1:22; Matteu 20:28) Ní ọ̀nà kan náà, Kristian ọkọ kan ń lo ipò orí, kì í ṣe láti fi ṣe ara rẹ̀ láǹfààní, ṣùgbọ́n láti fi bójú tó ire ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀.—1 Korinti 13:4, 5.
7. Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ni yóò ran aya kan lọ́wọ́ láti mú ipa tí Ọlọrun fún un nínú ìgbéyàwó ṣẹ?
7 Ní tirẹ̀, aya kan tí ń gbé pẹ̀lú ìfọkànsin Ọlọrun kì í bá ọkọ rẹ̀ figa gbága tàbí wá ọ̀nà láti jẹ gàba lé e lórí. Inú rẹ̀ máa ń dùn láti tì í lẹ́yìn àti láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà míràn, Bibeli máa ń sọ̀rọ̀ nípa aya gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí” ọkọ rẹ̀ “ni,” ní mímú un ṣe kedere pé ọkọ rẹ̀ ni orí rẹ̀. (Genesisi 20:3, NW) Nípasẹ̀ ìgbéyàwó, ó wá sábẹ́ “òfin ọkọ rẹ̀.” (Romu 7:2) Lọ́wọ́ kan náà, Bibeli pè é ní “olùrànlọ́wọ́” àti “àṣekún.” (Genesisi 2:20, NW) Ó ń pèsè àwọn ànímọ́ àti agbára àtilèṣe nǹkan tí ọkọ rẹ̀ ṣaláìní, ó sì ń fún ọkọ rẹ̀ ní ìtìlẹ́yìn tí ó nílò. (Owe 31:10-31) Bibeli tún sọ pé aya jẹ́ “alájọṣe,” ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú alábàáṣègbéyàwó rẹ̀. (Malaki 2:14, NW) Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí ń ran ọkọ àti aya lọ́wọ́ láti lóye ipò èkíní-kejì wọn, kí wọ́n sì fi iyì àti ọ̀wọ̀ yíyẹ hàn fún ara wọn.
“YÁRA NIPA Ọ̀RỌ̀ GBÍGBỌ́”
8, 9. Ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn ìlànà tí yóò ṣèrànwọ́ fún gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé láti mú agbára ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí wọ́n ní sunwọ̀n sí i.
8 Nínú ìwé yìí, a tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ léraléra. Èé ṣe? Nítorí pé ó máa ń rọrùn láti yanjú àwọn ìṣòro nígbà tí àwọn ènìyàn bá bá ara wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì fetí sílẹ̀ sí ara wọn ní tòótọ́. A tẹnu mọ́ ọn léraléra pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ jẹ́ sọ-sími-n-sọ-sí-ọ. Ọmọ ẹ̀yìn náà, Jakọbu, sọ ọ́ ní ọ̀nà yìí: “Olúkúlùkù ènìyàn gbọ́dọ̀ yára nipa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nipa ọ̀rọ̀ sísọ.”—Jakọbu 1:19.
9 Ó tún ṣe pàtàkì pé kí a ṣọ́ bí a ti ń sọ̀rọ̀. A kò lè ka àwọn ọ̀rọ̀ gbàkan-o-ṣubú, asọ̀, tàbí àwọn ọ̀rọ̀ rírorò sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ aláṣeyọrí. (Owe 15:1; 21:9; 29:11, 20) Bí ohun tí a sọ bá tilẹ̀ tọ̀nà, bí a bá sọ ọ́ láti pani lára, pẹ̀lú ìgbéraga, tàbí ní ọ̀nà rírorò, ó ṣeé ṣe kí ó ba nǹkan jẹ́ ju kí ó tún un ṣe lọ. Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wá jẹ́ èyí tí ó dùn létí, “tí a fi iyọ̀ dùn.” (Kolosse 4:6) Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ wá dà bí “èso igi wúrà nínú agbọ̀n fàdákà.” (Owe 25:11) Àwọn ìdílé tí ó ti kọ́ bí a ti ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ dáradára ti gbé ìgbésẹ̀ ńlá síhà jíjèrè ayọ̀.
IPA PÀTÀKÌ TÍ ÌFẸ́ Ń KÓ
10. Irú ìfẹ́ wo ni ó ṣe kókó nínú ìgbéyàwó?
10 Ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” fara hàn léraléra jálẹ̀ ìwé yìí. Ìwọ́ ha rántí irú ìfẹ́ tí a mẹ́nu kàn jù lọ? Òtítọ́ ni pé òòfà ìfẹ́ (Gíríìkì, eʹros) ń kó ipa pàtàkì nínú ìgbéyàwó, àti nínú ìgbéyàwó aláṣeyọrí, ọkọ àti ayá máa ń mú ìfẹ́ni jíjinlẹ̀ àti ìbádọ́rẹ̀ẹ́ (Gíríìkì, phi·liʹa) dàgbà fún ara wọn. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·gaʹpe, dúró fún, ni ó ṣe pàtàkì jù lọ. Ìfẹ́ yìí ni a ń fi hàn sí Jehofa, sí Jesu, àti sí aládùúgbò wa. (Matteu 22:37-39) Ìfẹ́ yìí ni Jehofa fi hàn sí ìran ènìyàn. (Johannu 3:16) Ẹ wo bí ó ti dára tó pé a lè fi irú ìfẹ́ kan náà hàn sí alábàáṣègbéyàwó wa àti àwọn ọmọ wa!—1 Johannu 4:19.
11. Báwo ni ìfẹ́ ṣe ń ṣiṣẹ́ fún ire ìgbéyàwó?
11 Nínú ìgbéyàwó, ìfẹ́ tí a gbé ga yìí jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” ní tòótọ́. (Kolosse 3:14) Ó ń so tọkọtaya pọ̀, ó sì ń mú wọn fẹ́ láti ṣe ohun tí ó dára jù lọ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. Nígbà tí àwọn ìdílé bá dojú kọ àwọn ipò líle koko, ìfẹ́ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti para pọ̀ yanjú àwọn ìṣòro. Bí tọkọtaya kan ti ń dàgbà, ìfẹ́ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ti ara wọn lẹ́yìn, àti láti máa bá a lọ láti mọyì ara wọn. “Ìfẹ́ . . . kì í wá awọn ire tirẹ̀ nìkan. . . . A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa farada ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.”—1 Korinti 13:4-8.
12. Èé ṣe tí ìfẹ́ tí tọkọtaya kan ní fún Ọlọrun fi ń fún ìgbéyàwó wọn lókun?
12 Ìdè ìgbéyàwó túbọ̀ máa ń lágbára sí i nígbà tí kì í bá ṣe ìfẹ́ láàárín tọkọtaya nìkan ni ó dè é, ṣùgbọ́n nígbà tí ìfẹ́ fún Jehofa bá jẹ́ ohun pàtàkì tí ó dè é. (Oniwasu 4:9-12) Èé ṣe? Ó dára, aposteli Johannu kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọrun túmọ̀ sí, pé kí a pa awọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (1 Johannu 5:3) Nípa báyìí, tọkọtaya kan ní láti fi ìfọkànsin Ọlọrun kọ́ àwọn ọmọ wọn, kì í ṣe kìkì nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn gan-an, ṣùgbọ́n nítorí pé èyí jẹ́ àṣẹ Jehofa. (Deuteronomi 6:6, 7) Wọ́n ní láti kọ ìwà pálapàla sílẹ̀ kì í ṣe kìkì nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan ni, ṣùgbọ́n ní pàtàkì nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jehofa, ẹni tí “yoo dá awọn àgbèrè ati awọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Heberu 13:4) Àní tí alábàáṣègbéyàwó kan bá ń fa ìṣòro ńlá nínú ìgbéyàwó, ìfẹ́ fún Jehofa yóò sún ẹnì kejì rẹ̀ láti máa bá títẹ̀ lé ìlànà Bibeli nìṣó. Aláyọ̀, ní ti gidi, ni àwọn ìdílé tí ìfẹ́ fún Jehofa ti fún ìfẹ́ fún ara wọn lókun!
ÌDÍLÉ TÍ Ń ṢE ÌFẸ́ ỌLỌRUN
13. Báwo ni ìpinnu láti ṣe ìfẹ́ Ọlọrun yóò ṣe ran ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti tẹjú mọ́ àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì ní tòótọ́?
13 Ìgbésí ayé Kristian látòkèdélẹ̀ rọ̀ mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun. (Orin Dafidi 143:10) Ohun tí ìfọkànsin Ọlọrun túmọ̀ sí nìyẹn. Ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun ń ran ìdílé lọ́wọ́ láti tẹjú mọ́ àwọn ohun ṣíṣe pàtàkì ní tòótọ́. (Filippi 1:9, 10) Fún àpẹẹrẹ, Jesu kìlọ̀ pé: “Mo wá lati fa ìpínyà, bá ọkùnrin kan lòdì sí baba rẹ̀, ati ọmọbìnrin kan lòdì sí ìyá rẹ̀, ati ọ̀dọ́ aya kan lòdì sí ìyá ọkọ rẹ̀. Nítòótọ́, awọn ọ̀tá ènìyàn yoo jẹ́ awọn ènìyàn agbo ilé oun fúnra rẹ̀.” (Matteu 10:35, 36) Gẹ́gẹ́ bí Jesu ti kìlọ̀ gan-an, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọn ti ṣe inúnibíni sí. Ẹ wo irú ipò bíbani nínú jẹ́, ríroni lára tí èyí jẹ́! Síbẹ̀, ìdè ìdílé kò gbọdọ̀ lágbára ju ìfẹ́ tí a ní fún Jehofa Ọlọrun àti fún Jesu Kristi lọ. (Matteu 10:37-39) Bí ènìyàn bá fara dà á, láìka àtakò ìdílé sí, àwọn tí ń ṣàtakò náà lè yíwà padà nígbà tí wọ́n bá rí èso rere tí ìfọkànsin Ọlọrun ń mú jáde. (1 Korinti 7:12-16; 1 Peteru 3:1, 2) Bí ìyẹn kò bá tilẹ̀ ṣẹlẹ̀, kò sí ire wíwà pẹ́ títí tí ń tìdí kíkọ iṣẹ́ ìsìn Ọlọrun sílẹ̀ nítorí àtakò wá.
14. Báwo ni ìfẹ́ ọkàn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọrun yóò ṣe ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà tí ó ṣàǹfààní jù lọ fún àwọn ọmọ wọn?
14 Ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun ń ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu títọ́. Fún àpẹẹrẹ, ní àwọn agbègbè kan, àwọn òbí nítẹ̀sí láti wo àwọn ọmọ gẹ́gẹ́ bí ìdókòwò kan, wọ́n sì gbára lé àwọn ọmọ wọn láti bójú tó wọn ní ọjọ́ ogbó wọn. Bí ó tilẹ̀ tọ̀nà, tí ó sì bójú mu fún àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà láti ṣaájò àwọn òbí wọn àgbàlagbà, irú ìgbatẹnirò bẹ́ẹ̀ kò yẹ kí ó mú kí àwọn òbí sún àwọn ọmọ wọn láti lépa ọ̀nà ìgbésí ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Àwọn òbí kò ṣe àwọn ọmọ wọn ní àǹfààní kankan bí wọ́n bá tọ́ wọn dàgbà láti ka ohun ìní ti ara sí ohun tí ó ṣe pàtàkì ju àwọn ohun tẹ̀mí lọ.—1 Timoteu 6:9.
15. Báwo ni ìyá Timoteu, Eunike, ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ òbí títayọ lọ́lá kan tí ó ṣe ìfẹ́ Ọlọrun?
15 Eunike, màmá Timoteu ọ̀dọ́, ọ̀rẹ Paulu, jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà ní ti èyí. (2 Timoteu 1:5) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìgbàgbọ́ ni ó fẹ́, Eunike, àti ìyá Timoteu àgbà, Loide, ṣe àṣeyọrí nínú títọ́ Timoteu dàgbà láti lépa ìfọkànsin Ọlọrun. (2 Timoteu 3:14, 15) Nígbà tí Timoteu dàgbà tó, Eunike yọ̀ǹda fún un láti fi ilé sílẹ̀, kí ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Paulu nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀. (Ìṣe 16:1-5) Ẹ wo bí inú rẹ̀ yóò ti dùn tó nígbà tí ọmọ rẹ̀ di míṣọ́nnárì títayọ lọ́lá kan! Ẹ̀kọ́ tí ó rí gbà ní kékeré hàn dáradára nínú ìfọkànsin Ọlọrun tí ó ní gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà kan. Dájúdájú, Eunike rí ìtẹ́lọ́rùn àti ìdùnnú nínú gbígbọ́ ìròyìn nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ adúróṣinṣin Timoteu, bí ojú tilẹ̀ lè máa ro ó.—Filippi 2:19, 20.
ÌDÍLÉ ÀTI ỌJỌ́ Ọ̀LA RẸ
16. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ, ìbìkítà yíyẹ wo ni Jesu fi hàn, ṣùgbọ́n ète ṣíṣe kí ni ó ga jù lọ lọ́kàn rẹ̀?
16 A tọ́ Jesu dàgbà nínú ìdílé oníwà-bí-Ọlọ́run, àti gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà kan, ó fi ìbìkítà yíyẹ tí ọmọ ń fi hàn sí ìyá rẹ̀ hàn. (Luku 2:51, 52; Johannu 19:26) Bí ó ti wù kí ó rí, ète ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun ni ó ga jù lọ lọ́kàn Jesu, fún un, èyí sì ní ṣíṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún aráyé láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú. Èyí ni ó ṣe nígbà tí ó fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.—Marku 10:45; Johannu 5:28, 29.
17. Ìfojúsọ́nà ológo wo ni ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́ Jesu ṣí sílẹ̀ fún àwọn tí ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun?
17 Lẹ́yìn ikú Jesu, Jehofa jí i dìde sí ìyè ní ọ̀run, ó sì fún un ní ọlá àṣẹ ńlá, ó sì fi í jẹ Ọba Ìjọba ọ̀run ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. (Matteu 28:18; Romu 14:9; Ìṣípayá 11:15) Ẹbọ Jesu mú kí ó ṣeé ṣe kí a yan àwọn ẹ̀dá ènìyàn kan láti ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba yẹn. Ó tún ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìyókù aráyé, tí ó lọ́kàn títọ́, láti gbádùn ìwàláàyè pípé nínú ayé kan tí a ti mú padà sí ipò paradise. (Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 4; 21:3-5; 22:1-4) Lónìí, ọ̀kan lára àwọn àǹfààní gíga jù lọ tí a ní jẹ́ láti sọ ìhìn rere ológo yìí fún àwọn aládùúgbò wa.—Matteu 24:14.
18. Ìránnilétí àti ìṣírí wo ni a fún àwọn ìdílé àti ẹnì kọ̀ọ̀kan?
18 Gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti fi hàn, gbígbé ìgbésí ayé onífọkànsin Ọlọrun ní ìlérí pé àwọn ènìyàn lè jogún àwọn ìbùkún nínú ìyè “tí ń bọ̀.” Dájúdájú, ọ̀nà tí ó dára jù lọ nìyí láti rí ayọ̀! Rántí pé, “ayé ń kọjá lọ bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́-ọkàn rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun ni yoo dúró títí láé.” (1 Johannu 2:17) Nípa báyìí, bóyá ọmọ ni ọ́ tàbí òbí, ọkọ tàbí aya, tàbí àgbàlagbà àpọ́n tí ó ní ọmọ tàbí tí kò ní ọmọ, là kàkà láti ṣe ìfẹ́ Ọlọrun. Àní nígbà tí o bá wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ tàbí tí o dojú kọ àwọn ìṣòro ńlá pàápàá, má ṣe gbàgbé láé pé ìránṣẹ́ Ọlọrun alààyè ni o jẹ́. Nípa báyìí, ǹjẹ́ kí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ mú ìdùnnú wá fún Jehofa. (Owe 27:11) Ǹjẹ́ kí ìwà rẹ yọrí sí ayọ̀ fún ọ nísinsìnyí àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tí ń bọ̀!
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . ÌDÍLÉ RẸ LÁTI LÁYỌ̀?
A lè mú ìkóra-ẹni-níjàánu dàgbà.—Galatia 5:22, 23.
Pẹ̀lú ojú ìwòye tí ó tọ̀nà nípa ipò orí, àti ọkọ àtiaya ń wá ire tí ó dára jù lọ fún ìdílé.—Efesu 5:22-25, 28-33; 6:4.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ní fífetí sílẹ̀ nínú.—Jakọbu 1:19.
Ìfẹ́ fún Jehofa yóò fún ìgbéyàwó lókun.—1 Johannu 5:3.
Ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun ni góńgó tí ó ṣe pàtàkì jù lọ fún ìdílé.—Orin Dafidi 143:10; 1 Timoteu 4:8.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 188]
Ẹ̀BÙN WÍWÀ NÍ ÀPỌ́N
Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ní ń ṣègbéyàwó. Kì í sì í ṣe gbogbo tọkọtaya ní ń yàn láti bímọ. Àpọ́n ni Jesu, ó sì sọ nípa wíwà ní àpọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn kan nígbà tí ó bá jẹ́ “nítìtorí ìjọba awọn ọ̀run.” (Matteu 19:11, 12) Aposteli Paulu pẹ̀lú yàn láti má ṣe gbéyàwó. Ó sọ nípa ipò wíwà ní àpọ́n àti ṣíṣègbéyàwó gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀bùn.” (1 Korinti 7:7, 8, 25-28) Nípa báyìí, bí ìwé yìí tilẹ̀ ti sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nípa àwọn ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbéyàwó àti títọ́ ọmọ dàgbà, kò yẹ kí a gbàgbé àwọn ìbùkún àti èrè tí wíwà ní àpọ́n tàbí ṣíṣègbéyàwó láìbímọ lè mú wá.
-