-
Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run àti Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lò ÓKí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
-
-
ÀFIKÚN
Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run àti Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lò Ó
BÁWO ni wọ́n ṣe túmọ̀ Sáàmù 83 ẹsẹ18 nínú Bíbélì rẹ? Bí Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe túmọ̀ rẹ̀ rèé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn pẹ̀lú túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó jọ èyí. Àmọ́, àwọn olùtumọ̀ kan kò fi orúkọ náà, Jèhófà síbẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, orúkọ oyè bíi “Olúwa” tàbí “Ayérayé” ni wọ́n fi rọ́pò rẹ̀. Kí ló yẹ kó wà nínú ẹsẹ yìí? Ṣé orúkọ oyè ló yẹ kó wà níbẹ̀ ni àbí orúkọ náà, Jèhófà?
Orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù
Orúkọ kan ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Orúkọ àrà ọ̀tọ̀ kan fara hàn nínú Sáàmù 83 ẹsẹ 18 yìí nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi èdè Hébérù kọ. Sípẹ́lì rẹ̀ ni יהוה (YHWH) ní èdè Hébérù. “Jèhófà” là ń pè é ní èdè Yorùbá. Ṣé inú ẹsẹ Bíbélì yìí nìkan ní orúkọ náà ti fara hàn ni? Rárá o. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà tó fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù!
Báwo ni orúkọ Ọlọ́run ṣe ṣe pàtàkì tó? Ìwọ wo àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tí Jésù Kristi kọ́ni. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ ni pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Nígbà tó yá, Jésù tún gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ọlọ́run sì dá a lóhùn látọ̀run pé: “Èmi ti ṣe é lógo, èmi yóò sì tún ṣe é lógo dájúdájú.” (Jòhánù 12:28) Èyí fi hàn gbangba pé orúkọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an. Kí wá ni ohun tó mú àwọn olùtumọ̀ kan yọ orúkọ yìí kúrò nínú ìtumọ̀ Bíbélì wọn, tí wọ́n wá fi orúkọ oyè rọ́pò rẹ̀?
Ó dà bíi pé ohun méjì ló mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, ọ̀pọ̀ ló sọ pé kò yẹ kéèyàn máa lo orúkọ náà nítorí pé kò sẹ́ni tó mọ bí wọ́n ṣe ń pè é ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Kò sí fáwẹ̀lì nínú èdè Hébérù tí wọ́n ń kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, kò sẹ́ni tó mọ bí wọ́n ṣe ń pe YHWH gan-an lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Àmọ́, ṣó wá yẹ kí èyí mú ká má lo orúkọ Ọlọ́run? Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Yéṣúà tàbí Yèhóṣúà ni wọ́n ń pe Jésù, kò sẹ́ni tó lè sọ bí wọ́n ṣe ń pè é gan-an nígbà yẹn. Síbẹ̀, ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń pe orúkọ Jésù bó ṣe rí lédè wọn lóde òní. Wọn ò sọ pé àwọn ò ní lo orúkọ Jésù nítorí àwọn ò mọ bí wọ́n ṣe ń pè é ní ọ̀rúndún kìíní. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, tó o bá lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, wàá rí i pé bí wọ́n á ṣe máa pe orúkọ rẹ níbẹ̀ ṣeé ṣe kó yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń pè é ní ìlú rẹ. Nítorí náà, kò yẹ ká tìtorí pé a ò mọ bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ká wá sọ pé a ò ní lò ó mọ́.
Òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù kan tó ti wà tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n sábà máa ń sọ pé ó jẹ́ ìdí kejì tí wọ́n fi yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì. Ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù wọ̀nyẹn sọ pé èèwọ̀ ni, èèyàn ò gbọ́dọ̀ pe orúkọ Ọlọ́run. Òfin kan tó wà nínú Bíbélì ni wọ́n ṣì lóye tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀. Òfin náà sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò ní láárí, nítorí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tí ó lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò ní láárí.”—Ẹ́kísódù 20:7.
Òfin yìí sọ pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Ọlọ́run nílòkulò. Àmọ́, ǹjẹ́ ó kà á léèwọ̀ pé ká má lo orúkọ Ọlọ́run tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀? Rárá, kò ní ká máà lò ó tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù (tí wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé) jẹ́ olóòótọ́ èèyàn tí wọ́n pa Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un mọ́. Síbẹ̀, lemọ́lemọ́ ni wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀ sáàmù tí ẹgbàágbèje olùjọsìn kọ lórin sí Ọlọ́run. Kódà, Jèhófà sọ pé káwọn olùjọsìn òun máa pe orúkọ òun, àwọn tó jẹ́ onígbọràn sì ṣe bẹ́ẹ̀. (Jóẹ́lì 2:32; Ìṣe 2:21) Ìdí nìyẹn táwọn Kristẹni lónìí fi ń lo orúkọ Ọlọ́run tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, bí Jésù náà ṣe lò ó tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.—Jòhánù 17:26.
Àṣìṣe ńlá làwọn olùtumọ̀ Bíbélì ṣe bí wọ́n ṣe fi orúkọ oyè rọ́pò orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì. Ńṣe ni wọ́n jẹ́ kí Ọlọ́run dà bí ẹni tó jìnnà jù tí kì í sì í ṣe ẹni gidi kan, bẹ́ẹ̀ Bíbélì rọ̀ wá pé ká ní “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.” (Sáàmù 25:14) Ìwọ ronú nípa ẹnì kan tó o pè ní ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ ná. Ǹjẹ́ o lè sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ lẹnì kan tí o kò bá mọ orúkọ rẹ̀? Bákan náà, téèyàn ò bá mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, báwo ló ṣe lè sún mọ́ ọn ní gidi? Síwájú sí i, táwọn èèyàn kì í bá lo orúkọ Ọlọ́run, wọn ò lè mọ ìtumọ̀ pàtàkì tó ní. Kí ni ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run?
Fúnra Ọlọ́run ló sọ ohun tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí fún Mósè tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tòótọ́. Nígbà tí Mósè bi Ọlọ́run pé kí lorúkọ rẹ̀, Jèhófà dá a lóhùn pé: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Bí ìtumọ̀ Bíbélì Rotherham ṣe túmọ̀ ẹsẹ náà ni pé: “Èmi yóò di ohunkóhun tí mo bá fẹ́.” Nítorí náà, Jèhófà lè di ohunkóhun láti lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe.
Ká sọ pé o lè di ohunkóhun tó o bá fẹ́, kí lò bá ṣe? Kí lò bá ṣe fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ? Tí ìkan nínú wọn bá ń ṣàìsàn, ì bá ṣeé ṣe fún ọ láti di dókítà kó o sì tọ́jú rẹ̀. Bó bá sì jẹ́ pé ńṣe lẹnì kan nínú wọn wọko gbèsè, ì bá ṣeé ṣe fún ọ láti di olówó tó ń fowó ṣàánú tí wàá sì fowó rẹ gbà á sílẹ̀. Àmọ́ ká sòótọ́, ó lójú ohun tó o lè dà. Bó sì ṣe rí fún gbogbo wa náà nìyẹn. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹnu á yà ọ́ gan-an láti rí bí Jèhófà ṣe ń di ohunkóhun kó bàa lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ó sì máa ń wù ú láti lo agbára rẹ̀ nítorí àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (2 Kíróníkà 16:9) Àmọ́ àwọn tí kò mọ orúkọ Ọlọ́run kò lè mọ nǹkan kan nípa oríṣiríṣi ànímọ́ rere tó ní, èyí tí ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ gbé yọ.
Kò sí àní-àní pé Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì. Tí a bá mọ ìtumọ̀ rẹ̀ tí a sì ń lò ó fàlàlà nínú ìjọsìn wa, á ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tó jẹ́ Bàbá wa ọ̀run.a
a Bó o bá ń fẹ́ àlàyé sí i nípa orúkọ Ọlọ́run, ìtumọ̀ rẹ̀ àti ìdí tó fi yẹ ká máa lò ó nínú ìjọsìn, ka ìwé pẹlẹbẹ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Tún wo Àfikún Ìsọfúnni Láti Lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,1.
-
-
Bí Dáníẹ́lì Ṣe Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbà Tí Mèsáyà Yóò DéKí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
-
-
ÀFIKÚN
Bí Dáníẹ́lì Ṣe Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbà Tí Mèsáyà Yóò Dé
BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé ó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún lọ tí wòlíì Dáníẹ́lì ti gbé ayé kí wọ́n tó bí Jésù, Ọlọ́run ṣí ohun kan payá fún Dáníẹ́lì tó jẹ́ kó ṣeé ṣe láti mọ ìgbà tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà tàbí Kristi. Ọlọ́run sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Kí o mọ̀, kí o sì ní ìjìnlẹ̀ òye pé láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́ títí di ìgbà Mèsáyà Aṣáájú, ọ̀sẹ̀ méje yóò wà, àti ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta.”—Dáníẹ́lì 9:25.
Láti lè mọ ìgbà tí Mèsáyà yóò dé, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ọdún tí a óò ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìgbà tí yóò dé. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ, ó jẹ́ “láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́.” Ọdún wo ni “ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà” wáyé? Nehemáyà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé, ọ̀rọ̀ náà láti tún Jerúsálẹ́mù kọ́ jáde lọ ní “ọdún ogún Atasásítà Ọba.” (Nehemáyà 2:1, 5-8) Àwọn òpìtàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọdún 474 ṣáájú Sànmánì Kristẹni (Ṣ.S.K.) ni Atasásítà pé ọdún kan lórí ìtẹ́. Nítorí náà, ọdún 455 Ṣ.S.K. ló pé ogún ọdún tó gorí ìtẹ́. Ní báyìí, a ti mọ̀ pé ọdún 455 Ṣ.S.K. la ti máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣírò ìgbà tí Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà yóò dé.
Dáníẹ́lì jẹ́ ká mọ iye ọdún tó wà láàárín ìgbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣírò ìgbà tí Mèsáyà yóò dé sí ìgbà tí Mèsáyà máa dé. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé yóò jẹ́ ‘ọ̀sẹ̀ méje [7], àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta [62],’ tí àròpọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin [69]. Báwo ni ìgbà yìí ṣe gùn tó? Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan fi hàn pé wọn kì í ṣe ọ̀sẹ̀ ọlọ́jọ́ méje-méje, àmọ́ wọ́n jẹ́ ọ̀sẹ̀ ọlọ́dún. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ọ̀sẹ̀ kan dúró fún ọdún méje. Àwọn Júù ayé ọjọ́un mọ ọ̀sẹ̀ ọlọ́dún, tàbí ọdún méje-méje tá a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń pa ọdún Sábáàtì mọ́ ní ọdún keje-kéje. (Ẹ́kísódù 23:10, 11) Nítorí náà, nínú àsọtẹ́lẹ̀ ọlọ́sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin [69] yìí, ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọdún méje-méje, àròpọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgọ́rin àti mẹ́ta [483] ọdún.
Ìṣirò ló wá kàn tá a máa ṣe báyìí. Tá a bá ka ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgọ́rin àti mẹ́ta [483] ọdún láti ọdún 455 Ṣ.S.K., yóò mú wa dé ọdún 29 Sànmánì Kristẹni (S.K.). Ọdún yẹn gan-an ni wọ́n ri Jésù bọmi tó sì di Mèsáyà!a (Lúùkù 3:1, 2, 21, 22) Ǹjẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí ṣe nímùúṣẹ ò jọ èèyàn lójú?
a Láti ọdún 455 Ṣ.S.K. sí ọdún 1 Ṣ.S.K., iye ọdún tó wà ńbẹ̀ jẹ́ Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta [454] ọdún. Ọdún kan ló wà láàárín ọdún 1 Ṣ.S.K. sí ọdún 1 S.K. (nítorí pé òǹkà kò bẹ̀rẹ̀ látorí òdo, orí oókan ló ti bẹ̀rẹ̀). Ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n ló sì wà láàárín ọdún 1 S.K. sí ọdún 29 S.K. Tá a bá ro mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí pọ̀, yóò fún wa ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgọ́rin àti mẹ́ta [483] ọdún. Àárín ọ̀sẹ̀ ọdún àádọ́rin ni wọ́n ‘ké Jésù kúrò’ tàbí tí wọ́n pa á, ìyẹn sì jẹ́ ní ọdún 33 S.K. (Dáníẹ́lì 9:24, 26) Ka orí kọkànlá ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! àti Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 899 sí 901. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé méjèèjì.
-
-
Jésù Kristi Ni Mèsáyà Tí Ọlọ́run ṢèléríKí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
-
-
ÀFIKÚN
Jésù Kristi Ni Mèsáyà Tí Ọlọ́run Ṣèlérí
JÈHÓFÀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè dá Mèsáyà tó ṣèlérí pé yóò jẹ́ Olùdáǹdè mọ̀. Bó ṣe ràn wá lọ́wọ́ ní pé ó mí sí àwọn wòlíì rẹ̀ pé kí wọ́n sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìbí Mèsáyà, iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àti ikú rẹ̀. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tá a rí nínú Bíbélì ló ṣẹ sára Jésù Kristi, kò já létí; bí wọ́n sì ṣe sọ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà yóò ṣe ṣẹ ni wọ́n ṣe ṣẹ. Kó o lè mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, jẹ́ ká wo àsọtẹ́lẹ̀ mélòó kan tó sọ nípa ìbí Jésù àti nípa ìgbà tó wà ní kékeré.
Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì. (Aísáyà 9:7) Inú ìran ìdílé Dáfídì ni wọ́n sì bí Jésù sí lóòótọ́.—Mátíù 1:1, 6-17.
Wólìí Ọlọ́run mìíràn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà” ni wọn yóò bí ọmọ yìí sí ó sì tún sọ pé yóò di olùṣàkóso lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. (Míkà 5:2) Lákòókò tí wọ́n bí Jésù, ìlú méjì ni wọ́n ń pè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ọ̀kan wà nítòsí ìlú Násárétì tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, èkejì sì wà nítòsí Jerúsálẹ́mù ní Júdà. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Éfúrátà ni wọ́n ń pe Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù. Bí àsọtẹ́lẹ̀ Míkà sì ṣe sọ, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù yìí ni wọ́n bí Jésù sí!—Mátíù 2:1.
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn sọ pé Ọlọ́run yóò pe Ọmọ rẹ̀ “láti Íjíbítì.” Nígbà tí Jésù wà ní kékeré, wọ́n gbé e lọ́ sí Íjíbítì. Àmọ́ lẹ́yìn tí ọba Hẹ́rọ́dù kú, wọ́n gbé Jésù padà láti Íjíbítì. Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ nìyẹn.—Hóséà 11:1; Mátíù 2:15.
Nínú àtẹ ìsọfúnnni tá a pe àkọ́lé rẹ̀ ní “Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà,” a to àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Mèsáyà sábẹ́ àkòrí tá a pè ní “Àsọtẹ́lẹ̀.” Jọ̀wọ́ fi àwọn ẹsẹ Bíbélì náà wé àwọn èyí tá a tò sábẹ́ àkòrí tá a pè ní “Ìmúṣẹ.” Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ tó o ní, pé òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yóò lágbára sí i.
Bó o ṣe ń gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí yẹ̀ wò, fi sọ́kàn pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù ni wọ́n ti kọ àwọn tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyẹn. Jésù sọ pé: “Gbogbo ohun tí a kọ̀wé rẹ̀ nípa mi nínú òfin Mósè àti nínú àwọn Wòlíì àti àwọn Sáàmù ni a gbọ́dọ̀ mú ṣẹ.” (Lúùkù 24:44) Bí ìwọ náà ṣe rí i kà nínú Bíbélì, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa Mèsáyà ló nímùúṣẹ, kò já létí!
-
-
Òtítọ́ Nípa Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
-
-
ÀFIKÚN
Òtítọ́ Nípa Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́
ÀWỌN tó gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́ sọ pé ẹni mẹ́ta ló para pọ̀ di Ọlọ́run. Wọ́n sọ pé àwọn ẹni mẹ́ta náà ni Baba, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́. Wọ́n tún sọ pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bára wọn dọ́gba, pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló jẹ́ olódùmarè, wọn kò sì ní ìbẹ̀rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan ń sọ ni pé, Baba jẹ́ Ọlọ́run, Ọmọ jẹ́ Ọlọ́run, Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀, Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà.
Ọ̀pọ̀ àwọn tó gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́ ló gbà pé àwọn ò lè ṣàlàyé rẹ̀. Síbẹ̀, wọ́n ṣì máa ń rò pé ẹ̀kọ́ Bíbélì ni. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀rọ̀ náà “Mẹ́talọ́kan” ò sí nínú Bíbélì rárá. Àmọ́, ṣé ohun kan wà nínú Bíbélì tó ṣeé ṣe kéèyàn rò pé Mẹ́talọ́kan ló ń tọ́ka sí ni? Láti lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, jẹ́ ká wo ẹsẹ Bíbélì kan táwọn tó gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́ sábà máa ń fi ti ẹ̀kọ́ náà lẹ́yìn.
‘ỌLỌRUN LI Ọ̀RỌ NA’
Jòhánù 1:1 sọ pé: “Li àtetekọṣe li Ọ̀rọ wà, Ọ̀rọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọ̀rọ na.” (Bibeli Mimọ) Ní ọwọ́ ìsàlẹ̀ nínú orí Bíbélì yìí kan náà, àpọ́sítélì Jòhánù fi hàn kedere pé Jésù ni “Ọ̀rọ̀ náà.” (Jòhánù 1:14) Nítorí pé Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ni Ọ̀rọ̀ náà, àwọn kan sọ pé ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ni Baba àti Ọmọ jọ wà nínú Ọlọ́run kan ṣoṣo.
Àmọ́ ṣá o, fi sọ́kàn pé èdè Gíríìkì lẹni tó kọ ẹsẹ Bíbélì yìí fi kọ ọ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn làwọn olùtumọ̀ wá túmọ̀ rẹ̀ sí àwọn èdè mìíràn. Àmọ́, àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kan túmọ̀ gbólóhùn náà, “Ọlọrun si li Ọ̀rọ na,” lọ́nà tó yàtọ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ní ìmọ̀ nípa èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Ìyẹn ló mú kí wọ́n gbà pé ó yẹ káwọn túmọ̀ gbólóhùn náà lọ́nà tó yàtọ̀. Báwo wá ni wọ́n ṣe túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó yàtọ̀? Àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé: “Logos [Ọ̀rọ̀] náà jẹ́ ẹni ti ọ̀run.” (A New Translation of the Bible) “Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ọlọ́run kan.” (The New Testament in an Improved Version) “Ọ̀rọ̀ náà wà pẹ̀lú Ọlọ́run ó sì jẹ́ ẹni ẹ̀mí bíi tirẹ̀.” (The Translator’s New Testament) Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì wọ̀nyí fi hàn pé Ọ̀rọ̀ náà kì í ṣe Ọlọ́run.a Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n pe Ọ̀rọ̀ náà ní “ọlọ́run kan” nítorí pé ipò gíga ló wà láàárín àwọn ẹ̀dá Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ náà, “ọlọ́run” táwọn olùtumọ̀ lò nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí “ẹni alágbára.”
GBÉ ÀWỌN Ẹ̀RÍ MÌÍRÀN YẸ̀ WÒ
Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò mọ èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Báwo wá lo ṣe lè mọ ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù ní lọ́kàn gan-an? Tóò, ronú nípa àpẹẹrẹ yìí ná: Ká sọ pé olùkọ́ kan kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní nǹkan kan. Ká sọ pé nígbà tó yá, òye táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní lórí ohun tí olùkọ́ wọn kọ́ wọn yìí kò dọ́gba. Kí ló yẹ kí wọ́n ṣe? Wọ́n lè padà lọ bá olùkọ́ náà pé kó túbọ̀ ṣàlàyé rẹ̀ fáwọn. Ó dájú pé tí wọ́n bá tún gbọ́ àlàyé sí i, ẹ̀kọ́ náà yóò túbọ̀ yé wọn. Bíi tàwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí, bí ìwọ náà bá fẹ́ mọ ohun tí Jòhánù 1:1 túmọ̀ sí gan-an, o lè wonú Ìhìn Rere Jòhánù fún àlàyé síwájú sí i. Tó o bá túbọ̀ rí àlàyé sí i lórí ọ̀rọ̀ Mẹ́talọ́kan, wàá lè mọ òtítọ́.
Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Jòhánù tún kọ ní Jòhánù orí 1 ẹsẹ 18. Ó kà pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run [Olódùmarè] nígbà kankan rí.” Àmọ́, àwọn èèyàn ti rí Jésù tó jẹ́ Ọmọ rí, nítorí Jòhánù sọ pé: “Ọ̀rọ na [Jésù] si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.” (Jòhánù 1:14, Bíbélì Mímọ́ ) Báwo wá ni Ọmọ ṣe lè jẹ́ apá kan Ọlọ́run Olódùmarè? Jòhánù tún sọ pé Ọ̀rọ̀ náà “wà pẹ̀lú Ọlọ́run.” Àmọ́, ṣé ó lè ṣeé ṣe pé kẹ́nì kan wà pẹ̀lú ẹnì kan kó sì tún wá jẹ́ pé òun lẹni náà? Yàtọ̀ síyẹn, ní Jòhánù 17:3, Jésù fi hàn kedere pé ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni òun àti Bàbá òun tó wà lọ́run. Ó pe Bàbá rẹ̀ ní “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.” Nígbà tí Ìhìn Rere Jòhánù sì ń parí lọ, ohun tí Jòhánù fi ṣe àkópọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ni pé: “Ìwọ̀nyí ni a ti kọ sílẹ̀ kí ẹ lè gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run.” (Jòhánù 20:31) Kíyè sí i pé Ọmọ Ọlọ́run ló pe Jésù, kì í ṣe Ọlọ́run. Àwọn àlàyé mìíràn tá a rí látinú Ìhìn Rere Jòhánù yìí fi bó ṣe yẹ ká lóye Jòhánù 1:1 hàn wá. Jésù tí Bíbélì pè ní Ọ̀rọ̀ náà jẹ́ “ọlọ́run kan” nítorí pé ipò gíga ló wà, àmọ́ òun kọ́ ni Ọlọ́run Olódùmarè.
WÁ Ẹ̀RÍ KÚN ÀWỌN Ẹ̀RÍ WỌ̀NYÍ KÓ LÈ TÚBỌ̀ DÁ Ọ LÓJÚ
Tún ronú nípa àpẹẹrẹ olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ tá a gbé yẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan. Ká sọ pé àwọn kan nínú wọn ṣì ń ṣiyè méjì lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ àlàyé sí i lẹ́nu olùkọ́ náà, kí tún ni wọ́n lè ṣe? Wọ́n lè lọ bá olùkọ́ mìíràn pé kó ṣàlàyé ẹ̀kọ́ náà síwájú sí i fáwọn. Tí olùkọ́ kejì bá lè ṣàlàyé sí i fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé òótọ́ ni ohun tí olùkọ́ wọn kọ́ wọn, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ni kò ní ṣiyè méjì mọ́. Lọ́nà kan náà, tí ohun tí Jòhánù ń sọ gan-an nípa bí Jésù àti Ọlọrun Olódùmarè ṣe jẹ́ síra wọn kò bá dá ọ lójú, wo ohun tí ẹlòmíràn tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Mátíù kọ. Ó kọ ohun tí Jésù sọ nípa òpin ètò àwọn nǹkan yìí pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36) Báwo lèyí ṣe fi hàn pé Jésù kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè?
Jésù sọ pé Bàbá mọ̀ ju Ọmọ lọ. Àmọ́ ká ní Jésù jẹ́ apá kan Ọlọ́run Olódùmarè ni, ì bá mọ gbogbo nǹkan tí Bàbá rẹ̀ mọ̀. Èyí fi hàn pé Ọmọ àti Bàbá kò bára wọn dọ́gba. Síbẹ̀, àwọn kan ṣì máa sọ pé: ‘Ẹni ẹ̀mí ni Jésù tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kó tó di èèyàn, ìgbà tó sì wà léèyàn ló sọ̀rọ̀ yìí.’ Àmọ́ ká tiẹ̀ sọ pé ohun tó ń sọ ni pé ìgbà tòun jẹ́ èèyàn nìkan lòun ò mọ ohun kan tí Bàbá òun mọ̀, ẹ̀mí mímọ́ ńkọ́? Tó bá jẹ́ pé apá kan Ọlọ́run Olódùmarè ni ẹ̀mí mímọ́, kí ló dé tí Jésù ò fi sọ pé ẹ̀mí mímọ́ mọ ohun tí Bàbá mọ̀?
Bó o ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ nìṣó, wàá máa rí àwọn ẹsẹ Bíbélì mìíràn tó sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ẹsẹ Bíbélì náà sọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọn ò bára dọ́gba.—Sáàmù 90:2; Ìṣe 7:55; Kólósè 1:15.
a Tó o bá fẹ́ mọ àwọn ìlànà èdè Gíríìkì tí wọ́n lò fún Jòhánù 1:1, wo Àpilẹ̀kọ, “Ṣé “Ọlọ́run” Ni Ọ̀rọ̀ Náà àbí Ọ̀rọ̀ Náà Jẹ́ “ọlọ́run kan”?” nínu Ilé Ìṣọ́ November 1, 2008, Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.
-