ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 2/1 ojú ìwé 8-9
  • Ìgbà Wo Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì Yóò Dé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Wo Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì Yóò Dé?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ń Ṣẹ Níṣojú Rẹ
  • Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Máa Wáyé Láìpẹ́
  • Báwo Ni Ọ̀rọ̀ Yìí Ṣe Kàn Ọ́?
  • Bí Ayé Yìí Ṣe Máa Dópin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ọba naa Jà ní Armageddoni
    “Kí Ijọba Rẹ Dé”
  • Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ìjọba Ọlọ́run Mú Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Kúrò
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 2/1 ojú ìwé 8-9

Ìgbà Wo Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì Yóò Dé?

“Mo rí, sì wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n . . . tí ó jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà.”—ÌṢÍPAYÁ 7:9, 14.

OGUN Amágẹ́dọ́nì máa tó bẹ̀rẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?

Ní báyìí, àwùjọ èèyàn kan ti wà kárí ayé, tí wọ́n ń sin Jèhófà, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere tí Bíbélì kọ́ni, ìlànà yìí ló sì dára jù lọ. Ọlọ́run ló ń mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn yẹn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti ahọ́n kóra jọ láti di ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan, tó sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ ará yìí.—Jòhánù 13:35.

Láìpẹ́, Sátánì máa kó ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ jọ, ó sì máa fi gbogbo agbára rẹ̀ gbéjà ko àwọn èèyàn àlàáfíà, tí wọ́n dà bíi aláìní ààbò àti olùgbèjà yìí. (Ìsíkíẹ́lì 38:8-12; Ìṣípayá 16:13, 14, 16) Báwo lo ṣe máa mọ̀ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí? Bíbélì sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtó kan tó jẹ́ ká mọ ìgbà tí ogun Amágẹ́dọ́nì máa dé. Ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ló ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí.

Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ń Ṣẹ Níṣojú Rẹ

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa bí àwọn èèyàn ṣe máa mọ̀ pé àwọn ti wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3) Jésù sọ fún wọn pé ní àkókò yẹn, “orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn.” Ó sì sọ pé: “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.” (Mátíù 24:7, 8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún pe àkókò náà ní “ọjọ́ ìkẹyìn,” àti pé ìgbà yẹn yóò jẹ́ “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2  Tímótì 3:1) Ǹjẹ́ o rò pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní mu lóòótọ́?

Kí nìdí tí àkókò náà fi máa le koko? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ ohun tó máa jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé “sáà àkókò kúkúrú” kan máa wà tó jẹ́ pé ayé yìí nìkan ni Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ti máa ní agbára. Bíbélì sọ pé Sátánì máa ní “ìbínú ńlá” lákòókò yẹn. (Ìṣípayá 12:7-12) Ǹjẹ́ ìwọ náà ò rí i pé ìbínú àti ìwà ipá gbòde kan láàárín àwọn èèyàn jákèjádò ayé lónìí?

Jésù tún sọ pé ní àkókò lílekoko yìí, a máa ṣe iṣẹ́ bàǹtà-banta kan. Ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba [Ọlọ́run] ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Lóde òní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè tó lé ní igba àti márùnlélọ́gbọ̀n [235], ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún lọ. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí wọ́n ń tẹ̀, èyí tí wọ́n gbé karí Bíbélì, ni ìwé ìròyìn táwọn èèyàn ń pín káàkiri jù lọ ní ayé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì tún ti túmọ̀ Bíbélì sí nǹkan bí ọgọ́rùn-ún èdè. Wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣe iṣẹ́ yìí, ọrẹ àtinúwá ni wọ́n sì fi ń bójú tó gbogbo ìnáwó iṣẹ́ náà. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé iṣẹ́ ìwàásù tó pabanbarì yìí ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ?

Bíbélì tún sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa mú kí Jèhófà Ọlọ́run bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà. Wo irú àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́ta bẹ́ẹ̀ tó máa ṣẹ.

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Máa Wáyé Láìpẹ́

Àsọtẹ́lẹ̀ Àkọ́kọ́. Bíbélì sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè ayé yóò kéde “àlàáfíà àti ààbò” lọ́nà kan tó máa hàn kedere. Wọ́n lè máa rò pé àwọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ yanjú àwọn ohun tó jẹ́ olórí ìṣòro aráyé. Àmọ́ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìkéde yẹn kì í ṣe nǹkan àlàáfíà rárá.—1 Tẹsalóníkà 5:1-3.

Àsọtẹ́lẹ̀ Kejì. Lẹ́yìn ìkéde wọnyí, àwọn ìjọba ayé yóò dojú ìjà kọ gbogbo ẹ̀sìn kárí ayé. Ẹranko ẹhànnà ni Bíbélì fi ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba ayé yẹn, ó sì fi obìnrin kan tí ó jókòó lórí ẹranko ẹhànnà náà ṣàpẹẹrẹ àwọn ìsìn èké àgbáyé. (Ìṣípayá 17:3, 15-18) Ẹranko ẹhànnà yìí yóò pa àwọn ẹ̀sìn èké run bí Ọlọ́run ṣe fẹ́, ìyẹn àwọn ẹ̀sìn tó ń sọ pé àwọn jẹ́ aṣojú Ọlọ́run, àmọ́ tó jé pé irọ́ ni wọ́n ń pa.

Àpọ́sítélì Jòhánù fi àmì ṣàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ náà báyìí pé: “Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí, àti ẹranko ẹhànnà náà, àwọn wọ̀nyí yóò kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán, wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá. Nítorí Ọlọ́run fi í sínú ọkàn-àyà wọn láti mú ìrònú òun ṣẹ.”—Ìṣípayá 17:16, 17.

Àsọtẹ́lẹ̀ Kẹta. Lẹ́yìn tí ẹranko ẹhànnà náà bá ti pa ìsìn èké run, Sátánì yóò darí àwọn orílẹ̀-èdè ayé láti gbéjà ko àwọn tó ń sin Jèhófà Ọlọ́run.—Ìṣípayá 7:14; Mátíù 24:21.

Báwo Ni Ọ̀rọ̀ Yìí Ṣe Kàn Ọ́?

Tí o kò bá tíì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, ó lè ṣòro fún ọ láti gbà pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa wáyé lóòótọ́. Àmọ́, ìdí wà tó fi yẹ kó dá wa lójú pé ohunkóhun kò ní yẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà, gbogbo rẹ̀ ló máa ṣẹ, kò sì ní pẹ́ mọ́ tí wọ́n fi máa ṣẹ. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ṣẹ ní ìṣáájú ló jẹ́ ká ní ìdánilójú yìí.a

O kò ṣe ṣètò láti ṣèwádìí lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa ohun tó jẹ́ kó dá wọn lójú pé “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” ti sún mọ́lé gan-an àti ìdí tí kò fi yẹ kó o máa bẹ̀rù nítorí ogun náà? Ní kí wọ́n ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ pé ó yẹ kó o ṣe láti lè wà lára àwọn tí Jèhófà Ọlọ́run yóò dáàbò bò. (Ìṣípayá 16:14) Ohun tó o máa kọ́ lè yí èrò rẹ nípa ọjọ́ ọ̀la pa dà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ rí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ, ka orí 2 àti 9 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Ǹjẹ́ kì í ṣe pé iṣẹ́ ìwàásù tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe yìí ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́