ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ilẹ̀ Ayé?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
    • ORÍ KẸTA

      Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ilẹ̀ Ayé?

      • Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé?

      • Báwo lẹnì kan ṣe ta ko Ọlọ́run?

      • Báwo nìgbésí ayé ṣe máa rí lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú?

      1. Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé?

      KÒ SÍ àní-àní pé ohun àgbàyanu ni Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé. Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n máa láyọ̀ kí wọ́n sì ní ìlera pípé. Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run gbin ọgbà kan ní Édẹ́nì” ó sì “mú kí olúkúlùkù igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ hù.” Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àtobìnrin àkọ́kọ, Ó fi wọ́n sínú ilé tó dára rèǹtè-rente yẹn ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:8, 9, 15) Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fáwọn èèyàn ni pé kí wọ́n bímọ, kí wọn mú kí Párádísè yẹn tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn ẹranko.

      2. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run yóò mú ohun tó ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé ṣẹ? (b) Irú àwọn èèyàn wo ni Bíbélì sọ pé yóò wà láàyè títí láé?

      2 Ǹjẹ́ o rò pé ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ní lọ́kàn fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa gbé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé yóò nímùúṣẹ? Ọlọ́run polongo pé: “Àní mo ti sọ ọ́, . . . èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.” (Aísáyà 46:9-11; 55:11) Kò sí àní-àní, Ọlọ́run á ṣe ohun tó pinnu láti ṣe fún ilẹ̀ ayé dájúdájú! Ó sọ pé oun “kò wulẹ̀ dá [ilẹ̀ ayé] lásán,” ṣùgbọ́n òun “ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Irú àwọn èèyàn wo ni Ọlọ́run fẹ́ kó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé? Ọdún mélòó ló sì fẹ́ kí wọ́n fi máa gbé níbẹ̀? Bíbélì dáhùn pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4.

      3. Àwọn ohun tí ń bani nínú jẹ́ wo ló ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé báyìí, àwọn ìbéèrè wo lèyí sì mú ká béèrè?

      3 Ó ṣe kedere sí gbogbo wa pé ìyẹn ò tíì ṣẹlẹ̀. Ní báyìí, àwọn èèyàn ń ṣàìsàn wọ́n sì ń kú; wọ́n tiẹ̀ tún ń bára wọn jà wọ́n sì ń para wọn. Nǹkan kan ló fà á. Ṣùgbọ́n ó dájú pé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ pé kí ilẹ̀ ayé rí kọ́ ló rí lónìí! Kí ló fà á? Kí nìdí tí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ò fi tíì nímùúṣẹ? Kò sí ìwé ìtàn kan téèyàn kọ tó lè sọ ìdí rẹ̀ fún wa o, nítorí pé ọ̀run ni wàhálà náà ti bẹ̀rẹ̀.

      BÍ ẸNÌ KAN ṢE DI Ọ̀TÁ

      4, 5. (a) Ta lẹni náà gan-an tó lo ejò láti fi bá Éfà sọ̀rọ̀? (b) Báwo ni èèyàn dáadáa tó jẹ́ olóòótọ́ ṣe lè yí padà di olè?

      4 Ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ nípa ẹnì kan tó di alátakò Ọlọ́run nínú ọgbà Édẹ́nì. Bíbélì pè é ní “ejò,” àmọ́ alátakò yìí kì í wulẹ̀ ṣe ejò gidi kan tó ń fàyà fà. Ìwé tó kẹ́yìn Bíbélì sọ pé òun ni “ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Ó tún pè é ní “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:1; Ìṣípayá 12:9) Áńgẹ́lì tàbí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára téèyàn ò lè rí yìí lo ejò kan láti fi bá Éfà sọ̀rọ̀. Ó ṣe èyí lọ́nà tí ẹnì kan tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí lè gbà máa sọ̀rọ̀ kí ó sì dà bí ẹni pé ẹranko kan tàbí ọmọlangidi kan ló ń sọ̀rọ̀. Ìṣojú ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára yìí kúkú ni Ọlọ́run ṣe dá ilẹ̀ ayé fún èèyàn.—Jóòbù 38:4, 7.

      5 A lè wá béèrè pé nígbà tó jẹ́ pé gbogbo ohun tí Jèhófà dá ló dára láìkù síbì kan, ta ló dá “Èṣù” tàbí “Sátánì” yìí? Ká má fọ̀pá pọ̀ọ̀lọ̀-pọọlọ pejò, ìdáhùn ìbéèrè yìí ni pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí ló sọ ara rẹ̀ di Èṣù. Báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Tóò, a mọ̀ pé èèyàn dáadáa kan tó jẹ́ olóòótọ́ lè yí padà di olè. Báwo ló ṣe lè ṣẹlẹ̀? Ẹnì náà lè jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ jọba lọ́kàn òun. Tí kò bá sì yéé rónú nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ náà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí lè lágbára lọ́kàn rẹ̀. Tó bá wá rí àǹfààní kan pẹ́nrẹ́n, ó lè ṣe ohun búburú tó ń rò lọ́kàn.—Ka Jákọ́bù 1:13-15.

      6. Báwo ni ọmọ Ọlọ́run kan tó jẹ ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ṣe di Sátánì Èṣù?

      6 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sátánì Èṣù gan-an nìyẹn. Ketekete ló ń gbọ́ nígbà tí Ọlọ́run ń sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n bímọ kí irú ọmọ wọn sì kún ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Ó dájú pé ohun tí Sátánì rò lọ́kàn ara rẹ̀ ni pé, ‘Tiẹ̀ gbọ́ ná, gbogbo àwọn èèyàn wọ̀nyí mà lè máa sìn mí dípò Ọlọ́run!’ Bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ lọ́kàn rẹ̀ nìyẹn o. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó ṣe ohun tó ń rò lọ́kàn, ló bá tan Éfà jẹ nípa píparọ́ mọ́ Ọlọ́run lọ́dọ̀ Éfà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Bó ṣe di “Èṣù,” tó túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́” nìyẹn o. Ó tún di “Sátánì,” tó túmọ̀ sí “Alátakò.”

      7. (a) Kí nìdí tí Ádámù àti Éfà fi kú? (b) Kí nìdí tí gbogbo ọmọ Ádámù fi ń darúgbó tí wọ́n sì ń kú?

      7 Sátánì lo irọ́ àti ẹ̀tàn láti fi mú kí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:6) Ìyẹn ló fà á tí wọ́n fi kú lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ nítorí Ọlọ́run ti sọ pé wọ́n á kú tí wọ́n bá ṣàìgbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Ádámù di aláìpé nígbà tó dẹ́ṣẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ rẹ̀. (Ka Róòmù 5:12) A lè fi ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn wé agolo tí wọ́n fi ń ṣe búrẹ́dì. Bí agolo yẹn bá ní àmì kan lára, báwo ni ara gbogbo búrẹ́dì tí wọ́n fi agolo yẹn ṣe á ṣe rí? Gbogbo búrẹ́dì tí wọ́n bá fi ṣe ló máa ní àmì, tàbí àléébù yẹn lára. Lọ́nà kan náà, gbogbo èèyàn ló ti jogún àmì àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù. Ìdí nìyẹn tí gbogbo èèyàn fi ń darúgbó tí wọ́n sì ń kú.—Róòmù 3:23.

      8, 9. (a) Ẹ̀sùn wo ló hàn gbangba pé Sátánì fi kan Ọlọ́run? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀?

      8 Nígbà tí Sátánì ti Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, ó tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara rẹ̀ di olórí ọlọ̀tẹ̀. Ó sọ pé bí Ọlọ́run ṣe ń ṣàkóso kò dára. Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé, Ọlọ́run kì í ṣe alákòóso rere. Ó sọ pé irọ́ ni Ọlọ́run ń pa àti pé Ọlọ́run ń fi ohun rere du àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso lé lórí ni. Ó ní kò pọn dandan káwọn èèyàn jẹ́ kí Ọlọ́run máa ṣàkóso àwọn. Ó tún sọ pé àwọn èèyàn lè pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fúnra wọn. Paríparí rẹ̀, ó sọ pé nǹkan á ṣẹnuure fáwọn èèyàn tóun bá ń ṣàkóso wọn. Kí ni kí Ọlọ́run ṣe sí ẹ̀sùn tí Sátánì fi kàn án yìí? Àwọn kan lè rò pé ṣe ló yẹ kí Ọlọ́run pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́, ṣe ìyẹn ì bá fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Ọlọ́run? Ṣé ì bá fi hàn pé ọ̀nà tó tọ́ ni Ọlọrun ń gbà ṣàkóso?

      9 Nítorí tí Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo, kò pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ mẹ́ta yẹn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó mọ̀ pé ó máa gba àkókò láti fi hàn tẹ́rùntẹ́rùn pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan òun àti láti fi hàn pé òpùrọ́ ni Èṣù. Ni Ọlọ́run bá pinnu pé òun á fàyè gba àwọn èèyàn kí wọ́n ṣàkóso ara wọn lábẹ́ Sátánì fún àkókò tó gùn díẹ̀. Ní Orí Kọkànlá ìwé yìí, a óò rí ìdí ti Ọlọ́run fi yọ̀ọ̀da àkókò tó gùn tó bẹ́ẹ̀ kó tó yanjú ọ̀ràn náà. Àmọ, jẹ́ ká ronú nípa èyí ná: Ǹjẹ́ ó tọ́ kí Ádámù àti Éfà gba Sátánì tí kò ṣe ohun rere kankan fún wọn rí gbọ́? Ṣé ó tọ́ kí wọn gbà gbọ́ pé òǹrorò àti òpùrọ́ ni Jèhófà tó fún wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n ní? Ká ní ìwọ ni, kí lò bá ṣe?

      10. Báwo lo ṣe lè wà ní ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà bí Jèhófà ṣe ń fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn Sátánì?

      10 Ó yẹ ká ronú nípa àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nítorí pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ń dojú kọ àwọn ọ̀ràn tó fara jọ ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn lónìí. O láǹfààní láti wà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà bí Jèhófà ṣe ń fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan òun. O lè gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ kó o sì fi hàn pé òpùrọ ni Sátánì. (Sáàmù 73:28; Ka Òwe 27:11) Ó bani nínú jẹ́ pé lára ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn tó wà láyé, àwọn díẹ̀ ló máa ń pinnu pé àwọn á ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn ló mú kí ìbéèrè pàtàkì kan jẹ yọ pé, Ṣé lóòótọ́ ni Bíbélì fi kọ́ni pé Sátánì ló ń ṣàkóso ayé?

      TA LÓ Ń ṢÀKÓSO AYÉ YÌÍ?

      Àwọn kan ń kọrin, àwọn kan sì ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin, wọ́n ń gbádùn ara wọn nínú ayé tuntun

      Ǹjẹ́ Sátánì á fi gbogbo ìjọba ayé lọ Jésù tó bá jẹ́ pé wọn kì í ṣe tirẹ̀?

      11, 12. (a) Báwo ni ìdẹwò tí Sátánì gbé ko Jésù lójú ṣe fi hàn pé Sátánì ni alákòóso ayé yìí? (b) Kí ló tun fi hàn pé Sátánì ni alákòóso ayé yìí?

      11 Jésù ò jiyàn rẹ̀ rí pé Sátánì ni alákòóso ayé yìí. Nígbà kan, Sátánì fi “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn” Jésù lọ́nà iṣẹ́ ìyanu. Ó wá ṣèlérí fún Jésù pé: “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú bí ìwọ bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” (Mátíù. 4:8, 9; Lúùkù 4:5, 6) Ronú nípa rẹ̀ ná. Ǹjẹ́ ohun tí Sátánì fi lọ Jésù yẹn ì bá jẹ́ ìdẹwò ká ní kì í ṣe Sátánì ló ń ṣàkóso lórí àwọn ìjọba ayé yìí? Jésù kò jiyàn pé ti Sátánì ni gbogbo ìjọba ayé yìí. Ká ní kì í ṣe Sátánì ni agbára tó wà lẹ́yìn àwọn ìjọba wọ̀nyẹn ni, ó dájú pé Jésù ì bá ti jẹ́ kó yé e pé wọn kì í ṣe tirẹ̀.

      12 Dájúdájú, Jèhófà ni Ọlọ́run Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá gbogbo àgbáyé tó lọ salalu. (Ìṣípayá 4:11) Ṣùgbọ́n kò sí ibi tí Bíbélì ti sọ pé Ọlọ́run tàbí Jésù Kristi ni alákòóso ayé yìí. Kódà, Jésù pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31; 14:30; 16:11) Bíbélì tún pe Sátánì Èṣù ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́ríǹtì 4:3, 4) Ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ nípa alátakò yìí, tàbí Sátánì, ni pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19.

      BÍ AYÉ SÁTÁNÌ YÓÒ ṢE DÀWÁTÌ

      13. Kí nìdí tá a fi nílò ayé tuntun?

      13 Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, bẹ́ẹ̀ layé ń di ibi eléwu sí i. Àwọn tí wọ́n ń jagun, àwọn olóṣèlú jẹgúdújẹrá, àwọn alágàbàgebè aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn ọ̀daràn tí wọ́n jẹ́ ọ̀dájú ló kún inú ayé. Wọ́n ti ba gbogbo nǹkan jẹ́. Bíbélì fi hàn pé àkókò ń bọ̀ tí Ọlọ́run á mú ayé búburú yìí kúrò; èyí á wáyé nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Ayé tuntun òdodo á sì rọ́pò rẹ̀.—Ìṣípayá 16:14-16.

      14. Ta ni Ọlọ́run yàn ṣe Ọba Ìjọba Rẹ̀, báwo sì ni Bíbélì ṣe sọ èyí tẹ́lẹ̀?

      14 Jésu Kristi ni Jèhófà Ọlọ́run yàn ṣe Ọba Ìjọba Rẹ̀ ọ̀run. Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkọnrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni . . . Ọmọ-Alade Alafia. Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun.” (Aísáyà 9:6, 7, Bibeli Mimọ) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà nípa ìjọba yìí pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Bá a ṣe máa rí i nínú ìwé yìí tó bá yá, Ìjọba Ọlọ́run yóò pa gbogbo ìjọba ayé yìí rún láìpẹ́, Ìjọba tirẹ̀ yóò wá rọ́pò gbogbo wọn. (Ka Dáníẹ́lì 2:44) Lẹ́yìn náà, Ìjọba Ọlọ́run yóò mú Párádísè wá sórí ilẹ̀ ayé.

      AYÉ TUNTUN Ò NÍ PẸ́ DÉ MỌ́!

      Àwọn kan ń kọrin, àwọn kan sì ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin, wọ́n ń gbádùn ara wọn nínú ayé tuntun

      15. Kí ni “ayé tuntun”?

      15 Bíbélì fi dá wa lójú pe: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13; Aísáyà 65:17) Nígbà mìíràn, tí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa “ilẹ̀ ayé,” àwọn èèyàn inú rẹ̀ ló túmọ̀ sí. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1) Nítorí náà, àwùjọ àwọn èèyàn tó rí ojú rere Ọlọ́run ni “ayé tuntun.”

      16. Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye wo ni Ọlọ́run máa fún àwọn tó bá ṣojú rere sí, kí sì la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ rí ẹ̀bùn náà gbà?

      16 Jésù ṣèlérí pé nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, awọn tó bá rí ojú rere Ọlórun yóò rí ẹ̀bùn “ìyè àìnípẹ̀kun” gbà. (Máàkù 10:30) Jọ̀wọ́, ṣí Bíbélì rẹ sí Jòhánù 3:16 àti Jòhánù 17:3, kó o sì ka ohun tí Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Àwọn tó bá kúnjú ìwọ̀n láti gba ẹ̀bùn tó ṣeyebíye tí Ọlọ́run máa fúnni yìí yóò gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún nínú Párádísè tó ń bọ̀. Ní báyìí, jẹ́ ká gbé àwọn ìbùkún náà yẹ̀ wò nínú Bíbélì.

      17, 18. Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé àlàáfíà àti ààbò á wà níbi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé?

      17 Ìwà ibi, ogun jíjà, ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá kò ní sí mọ́. “Ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 37:10, 11) Àlàáfíà yóò wà nítorí pé ‘Ọlọ́run yóò mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé.’ (Sáàmù 46:9; Aísáyà 2:4) Nígbà náà ni “olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́,” ìyẹn ni pé, àlàáfíà yóò wà títí láé!—Sáamù 72:7.

      18 Inú ààbò làwọn olùjọsìn Jèhófà yóò máa gbé. Gbogbo ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ bá gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu ní wọ́n máa ń gbé nínú ààbò. (Léfítíkù 25:18, 19) Ohun alárinrin ní yóò mà jẹ́ o, láti máa gbé nínú irú ààbò bẹ́ẹ̀ nínú Párádísè!—Ka Aísáyà 32:18; Míkà 4:4.

      19. Báwo la ṣe mọ̀ pé oúnjẹ á pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ayé tuntun Olọ́run?

      19 Kò ní sí àìtó oúnjẹ. Onísáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sáàmù 72:16) Jèhófà yóò bù kún àwọn olódodo, “ilẹ̀ ayé yóò [sì] máa mú èso rẹ̀ wá.”—Sáàmù 67:6.

      20. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé gbogbo ilẹ̀ ayé yóò di Párádísè?

      20 Gbogbo ilẹ̀ ayé yóò di Párádísè. Àwọn ilé tuntun tó jojú ní gbèsè àti ọgbà ẹlẹ́wà ni yóò wà lórí ilẹ̀ táwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí ẹ̀dá ti bà jẹ́ yìí. (Ka Aísáyà 65:21-24; Ìṣípayá 11:18) Bọ́dún ti ń gorí ọdún, àwọn ibi táwọn èèyàn ń gbé á máa gbòòrò sí i títí tí gbogbo ilẹ̀ ayé yóò fi di ẹlẹ́wà tí yóò sì lọ́ràá bí ọgbà Édẹ́nì. Ọlọ́run ò ní ṣaláì ‘ṣí ọwọ́ rẹ̀ kí ó sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.’—Sáàmù 145:16.

      21. Kí ló fi hàn pé àlàáfíà yóò wà láàárín èèyàn àtẹranko?

      21 Àlàáfíà yóò wà láàárín èèyàn àti ẹranko. Ńṣe làwọn ẹranko ẹhànnà àtàwọn ẹran ilé yóò jọ máa jẹun. Kódà nígbà yẹn, àwọn ọmọdé ò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹranko tó ń ṣèèyàn léṣe nísinsìnyí mọ́.—Ka Aísáyà 11:6-9; 65:25.

      22. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àìsàn?

      22 Àìsàn yóò pòórá. Níwọ̀n bó ti jẹ pé Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, yóò ṣe ìwòsán tó pọ̀ gan-an ju èyí tó ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 9:35; Máàkù 1:40-42; Jòhánù 5:5-9) Nígbà yẹn, “Kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24; 35:5, 6.

      23. Kí nìdí tí àjíǹde yóò fi mú wa lọ́kàn yọ̀?

      23 Àwọn èèyàn wa tó ti kú yóò jí dìde wọn yóò sì nírètí pé àwọn ò ní kú mọ́. Gbogbo àwọn tí ń sùn nínú oorun ikú, tí wọ́n sì wà nínú ìrántí Ọlọrun, yóò jí dìde. Ní tòdodo, “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15; Ka Jòhánù 5:28, 29.

      24. Báwo ni èrò gbígbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ṣe rí lára rẹ?

      24 Ọjọ́ ọ̀la tó dára rèǹtè-rente mà ló ń dúró de àwọn tó bá pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá o, tí wọ́n sì pinnu láti sìn ín! Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀ yẹn ni Jésù tọ́ka sí nígbà tó ṣèlérí fún ẹni ibi tó kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Ó ṣe pàtàkì pé ká kẹ́kọ̀ọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa Jésù, ipasẹ̀ ẹni tí gbogbo ìbùkún yìí yóò fi ṣeé ṣe.

      OHUN TÍ BÍBÉLÌ FI KỌ́NI

      • Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ni pé kí ilẹ̀ ayé di Párádísè; èyí yóò sì ní ìmúṣẹ.—Aísáyà 45:18; 55:11.

      • Sátánì ló ń ṣàkoso ayé báyìí.—Jòhánù 12:31; 1 Jòhánù 5:19.

      • Nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, Ọlọ́run yóò tú ọ̀pọ̀ ìbùkún sórí aráyé onígbọràn.—Sáàmù 37:10, 11, 29.

  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
    • ORÍ KẸJỌ

      Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

      • Kí ni Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?

      • Kí ni Ìjọba Ọlọ́run yóò gbé ṣe?

      • Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run yóò mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé?

      1. Àdúrà tó lókìkí wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?

      Ọ̀KẸ́ àìmọye èèyàn káàkiri ayé ní wọ́n mọ àdúrà tá à ń pè ní Bàbá Wa Tí Ń Bẹ ní Ọ̀run, tàbí Àdúrà Olúwa. Orúkọ méjèèjì yìí ni wọ́n fi ń pe àdúrà tó lókìkí tí Jésù kọ́ni gẹ́gẹ́ bí àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ. Àdúrà tó nítumọ̀ làdúrà yìí, tó o bá sì ṣàyẹ̀wò àwọn ohun mẹ́ta àkọ́kọ́ tí àdúrà náà béèrè, wàá túbọ̀ mọ àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an.

      2. Kí ni mẹ́ta lára àwọn ohun tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa fàdúrà béèrè?

      2 Ní ìbẹ̀rẹ̀ àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ yìí, Jésù sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’” (Mátíù 6:9-13) Kí ni ìtumọ̀ àwọn ohun mẹ́ta tí àdúrà yìí béèrè?

      3. Kí la gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?

      3 A ti kọ́ ohun púpọ̀ nípa orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà. A sì ti kọ́ ohun díẹ̀ nípa ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, ìyẹn ohun tó ti ṣe fún aráyé àtohun tó ṣì máa ṣe. Àmọ́, kí ni Jésù ń tọ́ka sí nígbà tó ní ká máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé”? Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Báwo ni dídé rẹ̀ yóò ṣe sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, tàbí yà á sí mímọ́? Ọ̀nà wo sì ni dídé Ìjọba náà gbà kan ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?

      OHUN TÍ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN JẸ́

      4. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, ta sì ni Ọba rẹ̀?

      4 Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan tí Jèhófà Ọlọ́run gbé kalẹ̀, Ọba tí Ọlọ́run yàn ló sì máa ṣàkóso ọ̀hún. Ta ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run? Jésù Kristi ni. Ipò ọba ti Jésù ga ju ti gbogbo àwọn alákòóso èèyàn lọ, nítorí òun ni Bíbélì pè ní “Ọba àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti Olúwa àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí olúwa.” (1 Tímótì 6:15) Jésù lágbára láti ṣe ohun rere ju alákòóso èyíkéyìí tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn lọ, kódà, ó lágbára láti ṣe rere ju ẹni tó ń ṣe dáadáa jù lọ lára wọn.

      5. Láti ibo ni Ìjọba Ọlọ́run yóò ti ṣàkóso, kí ni yóò sì ṣàkóso lé lórí?

      5 Láti ibo ni Ìjọba Ọlọ́run yóò ti ṣàkóso? Ó dára, ibo ni Jésù wà? O ti kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn èèyàn pa á lórí igi oró, Ọlọ́run sì jí i dìde. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀run. (Ìṣe 2:33) Nítorí náà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀run ni Jésù wà, ọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run wà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè é ní ‘ìjọba ọ̀run.’ (2 Tímótì 4:18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run wà, yóò ṣàkóso lé ilẹ̀ ayé lórí.—Ka Ìṣípayá 11:15.

      6, 7. Kí ló mú kí Jésù jẹ́ Ọba tó yàtọ̀ sáwọn tó kù?

      6 Kí ló mú kí Jésù jẹ́ Ọba tó yàtọ̀ sáwọn tó kù? Ohun kan tó mú kó yàtọ̀ ni pé kò ní kú láéláé. Nígbà tí Bíbélì ń fi Jésù wé àwọn ọba tó jẹ́ èèyàn, ó pè é ní “ẹnì kan ṣoṣo tí ó ní àìkú, ẹni tí ń gbé nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ.” (1 Tímótì 6:16) Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo nǹkan dáadáa tí Jésù bá ṣe á máa wà títí lọ ni. Ó sì dá wa lójú pé yóò ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tí yóò ṣe àwọn èèyàn rẹ̀ láǹfààní.

      7 Wo àsọtẹ́lẹ̀ yìí tí Bíbélì sọ nípa Jésù: “Ẹ̀mí Jèhófà yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ńlá, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà; ìgbádùn rẹ̀ yóò sì wà nínú ìbẹ̀rù Jèhófà. Kì yóò sì ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́. Yóò sì fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀, yóò sì fi ìdúróṣánṣán fúnni ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà nítorí àwọn ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 11:2-4) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù Ọba yóò fi òdodo àti ìyọ́nú ṣàkóso àwọn èèyàn orí ilẹ̀ ayé. Ṣé wàá fẹ́ láti ní irú alákòóso bẹ́ẹ̀?

      8. Àwọn wo ló máa bá Jésù jọba?

      8 Ohun mìíràn nípa Ìjọba Ọlọ́run ni pé: Jésù kò ní dá ṣàkóso. Àwọn mìíràn yóò bá a ṣàkóso. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Bí a bá ń bá a lọ ní fífaradà, a ó jọ ṣàkóso pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ọba.” (2 Tímótì 2:12) Pọ́ọ̀lù, Tímótì àtàwọn olóòótọ́ mìíràn tí Ọlọ́run yàn yóò ṣàkóso pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba ọ̀run. Àwọn mélòó ló máa ní àǹfààní bàǹtà-banta yẹn?

      9. Àwọn mélòó ló máa bá Jésù jọba, ìgbà wo ni Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí yàn wọ́n?

      9 Bí Orí Keje ìwé yìí ṣe fi hàn, àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan nínú èyí tó ti rí i tí “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [Jésù Kristi] dúró lórí Òkè Ńlá Síónì [tí í ṣe ipò ọba rẹ̀ ní ọ̀run], àti pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n ní orúkọ rẹ̀ àti orúkọ Baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.” Àwọn wo ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì wọ̀nyẹn? Jòhánù fúnra rẹ̀ sọ fún wa pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 14:1, 4) Wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí Ọlọ́run dìídì yàn láti bá Jésù jọba lókè ọ̀run. Lẹ́yìn ikú wọn, ìyè ti ọ̀run ni wọn yóò jí dìde sí, àwọn àti Jésù “yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:10) Látìgbà ayé àwọn àpọ́sítélì ni Ọlọ́run ti ń yan àwọn Kristẹni tòótọ́ tí yóò lọ sọ́run kí iye wọn bàa lè pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì.

      10. Báwo ni ètò tí Ọlọ́run ṣe pé kí Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ṣàkóso aráyé ṣe fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa?

      10 Ọlọ́run ṣètò pé kí Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ṣàkóso aráyé. Ètò tí Ọlọ́run ṣe yìí fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, nítorí pé Jésù ti jẹ́ èèyàn rí ó sì mọ bí ìyà ṣe máa ń rí lára. Pọ́ọ̀lù sọ pé Jésù “kì í ṣe ẹni tí kò lè báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa, bí kò ṣe ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.” (Hébérù 4:15; 5:8) Àwọn tí yóò bá a jọba náà ti jìyà nígbà tí wọ́n fi jẹ́ ẹ̀dá èèyàn wọ́n sì ti fara da ìyà. Láfikún, àìpé ti bá wọn fínra, wọ́n sì ti fara da onírúurú àìsàn. Dájúdájú, wọ́n á mọ ìṣòro tó ń kojú ọmọ aráyé!

      KÍ NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN YÓÒ GBÉ ṢE?

      11. Kí ni Jésù sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa gbà ládùúrà nípa ìfẹ́ Ọlọ́run?

      11 Nígbà tí Jésù sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yin òun máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ó tún sọ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe “gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” Ọ̀run ni Ọlọ́run wà, kò sì sígbà kan táwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ níbẹ̀. Àmọ́ ní Orí Kẹta ìwé yìí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé áńgẹ́lì búburú kan ṣíwọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ó sì sún Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀. Ní Orí Kẹwàá, a óò mọ ohun púpọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa áńgẹ́lì búburú náà tá a mọ̀ sí Sátánì Èṣù. Ọlọ́run fàyè gba Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì tí wọ́n pinnu láti tẹ̀ lé e tá à ń pè ni ẹ̀mí èṣù pé kí wọ́n wà ní ọ̀run fúngbà díẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà yẹn, gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́run kọ́ ni wọ́n ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kò ní rí bẹ́ẹ̀ mọ́ bí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Ọba tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́, ìyẹn Jésù Kristi, yóò gbógun ti Sátánì.—Ka Ìṣípayá 12:7-9.

      12. Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì méjì wo ni Ìṣípayá 12:10 mẹ́nu kàn?

      12 Àsọtẹ́lẹ̀ tó tẹ̀ lé e yìí sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé: “Mo sì gbọ́ tí ohùn rara kan ní ọ̀run wí pé: ‘Nísinsìnyí ni ìgbàlà dé àti agbára àti ìjọba Ọlọ́run wa àti ọlá àṣẹ Kristi rẹ̀, nítorí pé [Sátánì tí í ṣe] olùfisùn àwọn arákùnrin wa ni a ti fi sọ̀kò sísàlẹ̀, ẹni tí ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sán-tòru níwájú Ọlọ́run wa!’” (Ìṣípayá 12:10) Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì méjì tí ẹsẹ Bíbélì yẹn mẹ́nu kàn? Àkọ́kọ́ ni pé, Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù jẹ́ Ọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Ìkejì ni pé, Jésù ti lé Sátánì kúrò ní ọ̀run wá sórí ilẹ̀ ayé.

      13. Kí ni àbájáde lílé tí wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run?

      13 Kí ló ti jẹ́ àbájáde ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yẹn? A kà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run pé: “Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn!” (Ìṣípayà 12:12) Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tó wà lọ́run yọ̀ nítorí pé Sátánì ò sí lọ́run mọ́, gbogbo àwọn tó wá wà lọ́run báyìí ló jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run. Àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ló wà níbẹ̀. Wọ́n ti ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀run.

      Àwòrán ẹni tí ìdààmú bá, ogun, ìwà ọ̀daràn àti ìbàyíkájẹ́

      Bí wọ́n ṣe lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run mú ègbé bá ilẹ̀ ayé. Àwọn wàhálà yẹn máa tó dópin

      14. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé nítorí pé wọ́n lé Sátánì kúrò ní ọ̀run?

      14 Àmọ́, ilẹ̀ ayé ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Ohun tó ń bí Sátánì nínú ni lílé tí wọ́n lé e kúrò lọ́run àti bó ṣe jẹ́ pé àkókò kúkúrú ló kù fún un. Nínú ìbínú rẹ̀, ó ń fa “ègbé” fún ilẹ̀ ayé. A óò mọ̀ sí i nípa ègbé yẹn ní orí tó kàn. Ṣùgbọ́n tá a bá ronú lórí bí Sátánì tí wọ́n ti lé kúrò lọ́run ṣe ń mú wàhálà bá ilẹ̀ ayé, èyí lè mú ká béèrè pé: Báwo ló ṣe máa lè ṣeé ṣe kí Ìjọba Ọlọ́run mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé?

      15. Kí ni ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún ilẹ̀ ayé?

      15 Tóò, rántí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé, tó o kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Kẹta. Ní Édẹ́nì, Ọlọ́run fi hàn pé ohun tóun ní lọ́kàn tóun fi dá ilẹ̀ ayé ni pé kó di Párádísè tí àwọn èèyàn olódodo tí kò ní kú yóò kún inú rẹ̀. Sátánì mú kí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ ìyẹn kò yí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé padà, kò kàn jẹ́ kó tètè nímùúṣẹ ni. Ohun tí Jèhófà ṣì ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé ni pé: ‘Kí àwọn olódodo jogún ilẹ̀ ayé, kí wọn sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.’ (Sáàmù 37:29) Ìjọba Ọlọ́run yóò sì mú kó rí bẹ́ẹ̀. Báwo ni yóò ṣe ṣe é?

      16, 17. Kí ni Dáníẹ́lì 2:44 jẹ́ ká mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?

      16 Gbé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Dáníẹ́lì 2:44 yẹ̀ wò. Ó kà pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Kí lèyí jẹ́ ká mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?

      17 Àkọ́kọ́, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run yóò gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ “ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn,” tàbí nígbà tí àwọn ìjọba mìíràn bá ṣì ń ṣàkóso. Ìkejì, ó ń sọ fún wa pé Ìjọba Ọlọ́run yóò wà títí láé. Ìjọba mìíràn ò ní ṣẹ́gun rẹ̀, òmíràn ò sì ní rọ́pò rẹ̀. Ìkẹta, ó jẹ́ ká rí i pé ogun yóò wà láàárín Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn ìjọba ayé yìí. Ṣùgbọ́n Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣẹ́gun. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Ìjọba Ọlọ́run nìkan ni yóò máa ṣàkóso aráyé. Ìgbà náà làwọn èèyàn yóò gbádùn ìṣàkóso tó dára jù lọ tí wọn ò rírú ẹ̀ rí.

      18. Kí ni orúkọ ogun tí yóò wáyé kẹ́yìn láàárín Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn ìjọba ayé yìí?

      18 Bíbélì ní ohun púpọ̀ láti sọ nípa ogun tí yóò wáyé kẹ́yìn láàárín Ìjọba Ọlọ́run àti ìjọba èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì fi kọ́ni pé bí òpin bá ṣe ń sún mọ́lé, àwọn ẹ̀mí búburú yóò máa tan irọ́ kálẹ̀ láti fi tan “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” jẹ. Nítorí kí ni? Ó jẹ́ “láti kó wọn [ìyẹn àwọn ọba] jọpọ̀ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” Wọn yóò kó àwọn ọba ayé jọ pọ̀ sí “ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.” (Ìṣípayá 16:14, 16) Nítorí ohun tí ẹsẹ méjèèjì wọ̀nyẹn sọ, ìjà tó máa wáyé kẹ́yìn láàárín àwọn ìjọba èèyàn àti Ìjọba Ọlọ́run là ń pè ní ogun Ha-Mágẹ́dọ́nì, tàbí Amágẹ́dọ́nì.

      19, 20. Kí ni kò jẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí?

      19 Kí ni Ìjọba Ọlọ́run yóò fi ogun Amágẹ́dọ́nì gbé ṣe? Tún ronú nípa ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ fún ilẹ̀ ayé. Ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé ni pé kó kún fún àwọn èèyàn olódodo, tí wọ́n jẹ́ pípé, tí wọn yóò sì máa sìn ín nínú Párádísè. Kí nìdí tí ayé kò fi rí bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí? Ìdí kan ni pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, à ń ṣàìsàn, a sì ń kú. Ṣùgbọ́n a kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Karùn-ún pé Jésù kú fún wa ká lè wà láàyè títí láé. Ó ṣeé ṣe kó o rántí àkọsílẹ̀ tó wà nínú Ìhìn Rere Jòhánù, tó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

      20 Ìṣòro mìíràn ni pé olubi lọ̀pọ̀ èèyàn. Wọ́n ń parọ́, wọ́n ń rẹ́ni jẹ, wọ́n sì ń hùwàkiwà. Wọn ò fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Àwọn èèyàn tó ń ṣe ohun búburú yóò pa run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ka Sáàmù 37:10) Ìdí mìíràn tí ìfẹ́ Ọlọ́run kò fi tíì di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé ni pé ìjọba èèyàn kò fún àwọn tó wà lábẹ́ wọn níṣìírí láti máa ṣe é. Ọ̀pọ̀ ìjọba ni kò lágbára tó láti darí àwọn èèyàn, òǹrorò làwọn ìjọba kan, àwọn mìíràn sì ya oníwà ìbàjẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.

      21. Báwo ni Ìjọba náà yóò ṣe mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé?

      21 Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, abẹ́ ìjọba kan péré laráyé á wà, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba yẹn yóò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run yóò sì mú àwọn ìbùkún àgbàyanu wá. Bí àpẹẹrẹ, yóò mú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù kúrò lójú ọpọ́n. (Ìṣípayá 20:1-3) Ọlọ́run yóò lo agbára tó wà nínú ẹbọ ìràpadà Jésù tí àwọn èèyàn olóòótọ́ ò fi ní máa ṣàìsàn, tí wọn ò sì ní kú mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò ṣeé ṣe fún wọn láti wà láàyè títí láé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. (Ka Ìṣípayá 22:1-3) Ilẹ̀ ayé yóò di Párádísè. Nípa bẹ́ẹ̀, Ìjọba náà yóò mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sì pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo àwọn tó ń gbé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ni yóò máa bọ̀wọ̀ fún orúkọ Jèhófà.

      ÌGBÀ WO NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN YÓÒ MÚ KÍ ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN DI ṢÍṢE LÓRÍ ILẸ̀ AYÉ?

      22. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ò dé nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé tàbí ní gbàrà lẹ́yìn tó jíǹde?

      22 Nígbà ti Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé “kí ìjọba rẹ dé,” ó ṣe kedere pé Ìjọba náà ò tíì dé nígbà yẹn. Ṣé ìgbà tí Jésù lọ sí ọ̀run ni Ìjọba náà dé? Rárá o, nítorí pé àpọ́sítélì Pétérù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé lẹ́yìn tí Jésù jí dìde, àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 110:1 ṣẹ sára rẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ náà ni pé: “Àsọjáde Jèhófà fún Olúwa mi ni pé: ‘Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.’” (Ìṣe 2:32-34; Hébérù 10:12, 13) Jésù dúró fún àkókò kan.

      Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run

      23. (a) Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso? (b) Kí la óò kẹ́kọ̀ọ́ nínú orí tó kàn?

      23 Báwo ni àkókò tí Jésù fi dúró ṣe gùn tó? Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n dìídì fẹ́ mọ òtítọ́ ṣírò pé, àkókò tí Jésù fi ń dúró yóò dópin ní ọdún 1914. (Nípa déètì yìí, wo Àfikún, “Ọdún 1914—Ọdún Pàtàkì Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì”.) Àwọn ohun tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé láti ọdún 1914 fi hàn pé ìṣirò táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n dìídì fẹ́ mọ òtítọ́ wọ̀nyẹn ṣe tọ̀nà. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó nímùúṣẹ fi hàn pé ní 1914, Kristi di Ọba, Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso. Nítorí náà, “sáà àkókò kúkúrú” tó ṣẹ́ kù fún Sátánì la wà yìí. (Ìṣípayá 12:12; Sáàmù 110:2) A sì tún lè fi ìdánilójú sọ pé láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ o ka èyí sí àgbàyanu ìhìn rere? Ṣé o gbà gbọ́ pé òótọ́ ni? Orí tó kàn yóò jẹ́ kó o rí i pé òótọ́ ni Bíbélì fi àwọn ohun wọ̀nyí kọ́ni.

      OHUN TÍ BÍBÉLÌ FI KỌ́NI

      • Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba tí yóò ṣàkóso láti ọ̀run. Jésù Kristi ni Ọba rẹ̀, Ọlọ́run sì mú ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì lára aráyé láti bá a ṣàkóso nínú Ìjọba náà.—Ìṣípayá 14:1, 4.

      • Ọdún 1914 ni Ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso, àtìgbà yẹn la sì ti lé Sátánì kúrò lọ́run wá sórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 12:9.

      • Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò pa àwọn ìjọba èèyàn run, ayé yóò sì di Párádísè.—Ìṣípayá 16:14, 16.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́