-
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dúró Níwájú Ìtẹ́ Ìdájọ́?Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | October 15
-
-
15, 16. (a) Èé ṣe tí a fi sọ pé Jesu kò di Ọba Ìjọba Ọlọrun ní 33 C.E.? (b) Nígbà wo ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọrun?
15 Ṣùgbọ́n, ní àkókò yẹn, Jesu kò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Onídàájọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè. Ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọrun, ó ń dúró de àkókò náà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọrun. Paulu kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Èwo ninu awọn áńgẹ́lì ni oun wí nipa rẹ̀ rí pé: ‘Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí emi yoo fi gbé awọn ọ̀tá rẹ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpótí-ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ’?”—Heberu 1:13.
16 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti tẹ ọ̀pọ̀ ẹ̀rí jáde pé sáà dídúró Jesu ti wá sópin ní 1914, nígbà tí ó di alákòóso Ìjọba Ọlọrun nínú àwọn ọ̀run tí a kò lè fojú rí. Ìṣípayá 11:15, 18 sọ pé: “Ìjọba ayé di ìjọba Oluwa wa ati ti Kristi rẹ̀, oun yoo sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé ati láéláé.” “Ṣugbọn awọn orílẹ̀-èdè kún fún ìrunú, ìrunú tìrẹ sì dé.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn orílẹ̀-èdè fi ìrunú wọn hàn sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì nígbà Ogun Àgbáyé I. (Luku 21:24) Ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, ọ̀wọ́n oúnjẹ, àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, tí a ti ń rí láti 1914 jẹ́rìí sí i pé Jesu ń ṣàkóso nísinsìnyí nínú Ìjọba Ọlọrun, òpin ìkẹyìn ayé yìí sì ti sún mọ́lé.—Matteu 24:3-14.
17. Àwọn kókó pàtàkì wo ni a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ báyìí?
17 Láti ṣàtúnyẹ̀wò ráńpẹ́: A lè sọ pé Ọlọrun jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba, ṣùgbọ́n lọ́nà mìíràn, ó lè jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣèdájọ́. Ní 33 C.E., Jesu jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, òun sì ni Ọba Ìjọba náà nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ Jesu tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba nísinsìnyí, tún ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ bí? Èé sì ti ṣe tí èyí fi ní láti kàn wá, ní pàtàkì ní àkókò yìí?
18. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé Jesu pẹ̀lú yóò jẹ́ Onídàájọ́?
18 Jehofa, ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti yan àwọn onídàájọ́ sípò, yan Jesu gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ tí ó bá ọ̀pá ìdiwọ̀n Rẹ̀ mu. Jesu fi èyí hàn nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa kí ènìyàn wà láàyè nípa tẹ̀mí: “Baba kì í ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni rárá, ṣugbọn ó ti fi gbogbo ìdájọ́ ṣíṣe lé Ọmọkùnrin lọ́wọ́.” (Johannu 5:22) Síbẹ̀, ipa iṣẹ́ Jesu gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ lọ ré kọjá irú ìdájọ́ yẹn, nítorí pé òun jẹ́ onídàájọ́ àwọn alààyè àti àwọn òkú. (Ìṣe 10:42; 2 Timoteu 4:1) Paulu polongo nígbà kan pé: “[Ọlọrun] ti dá ọjọ́ kan ninu èyí tí oun pète lati ṣèdájọ́ ilẹ̀-ayé tí à ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan [Jesu] tí oun ti yànsípò, ó sì ti pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà kan fún gbogbo ènìyàn níti pé ó ti jí i dìde kúrò ninu òkú.”—Ìṣe 17:31; Orin Dafidi 72:2-7.
19. Èé ṣe tí o fi tọ́ láti sọ pé Jesu ń jókòó gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́?
19 Nígbà náà, ó ha tọ́ kí a parí èrò sí pé, Jesu jókòó lórí ìtẹ́ ológo rẹ̀ ní kíkó ipa pàtó gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Jesu sọ fún àwọn aposteli pé: “Ní àtúndá, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tọ̀ mí lẹ́yìn yoo jókòó fúnra yín pẹlu sórí ìtẹ́ méjìlá, ẹ óò máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà Israeli méjìlá.” (Matteu 19:28) Bí Jesu tilẹ̀ ti di Ọba Ìjọba náà nísinsìnyí, ìgbòkègbodò rẹ̀ síwájú sí i tí a mẹ́nu kàn nínú Matteu 19:28 yóò ní jíjókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ nígbà Ẹgbẹ̀rúndún nínú. Ní àkókò yẹn, òun yóò ṣèdájọ́ gbogbo aráyé, àwọn olódodo àti aláìṣòdodo. (Ìṣe 24:15) Yóò ṣèrànwọ́ láti fi èyí sọ́kàn bí a ṣe ń darí àfiyèsí wa sí ọ̀kan nínú àwọn òwe àkàwé Jesu tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àkókò wa àti ìwàláàyè wa.
Kí Ni Òwe Àkàwé Náà Sọ?
20, 21. Kí ni àwọn aposteli Jesu béèrè, tí ó jẹ mọ́ àkókò wa, ìbéèrè wo sì ni ó yọrí sí?
20 Kété ṣáájú kí Jesu tó kú, àwọn aposteli rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọnyi yoo ṣẹlẹ̀, kí ni yoo sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ ati ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan?” (Matteu 24:3) Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì lórí ilẹ̀ ayé ṣáájú kí ‘òpin tó dé.’ Kété kí òpin náà tó dé, àwọn orílẹ̀-èdè yóò “rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹlu agbára ati ògo ńlá.”—Matteu 24:14, 29, 30.
21 Ṣùgbọ́n, báwo ni nǹkan yóò ti rí fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí a ṣèwádìí nínú òwe àkàwé ti àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ náà: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn áńgẹ́lì pẹlu rẹ̀, nígbà naa ni oun yoo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ni a óò sì kó jọ níwájú rẹ̀.”—Matteu 25:31, 32.
22, 23. Àwọn kókó wo ni ó fi hàn pé òwe àkàwé nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ kò bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmúṣẹ ní 1914?
22 Òwe àkàwé yìí ha ní í ṣe pẹ̀lú 1914, nígbà tí Jesu jókòó nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ọba, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe lóye rẹ̀ tẹ́lẹ̀ bí? Tóò, Matteu 25:34 sọ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba, nítorí náà lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, òwe àkàwé náà ní í ṣe pẹ̀lú ìgbà tí Jesu ti di Ọba ní 1914. Ṣùgbọ́n ìdájọ́ wo ni ó ṣe ní kété lẹ́yìn náà? Kì í ṣe ìdájọ́ “gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn tí wọ́n ń sọ pé àwọn para pọ̀ jẹ́ “ilé Ọlọrun.” (1 Peteru 4:17) Ní ìbámu pẹ̀lú Malaki 3:1-3, Jesu, gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ Jehofa, bẹ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró tí ó ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ ayé wò láti ṣèdájọ́ wọn. Ó tún jẹ́ àkókò fún ìdájọ́ lórí Kristẹndọmu, tí ó fi èké jẹ́wọ́ pé òún jẹ́ “ilé Ọlọrun.”c (Ìṣípayá 17:1, 2; 18:4-8) Síbẹ̀, kò sí ohunkóhun tí ó fi hàn pé, nígbà náà lọ́hùn-ún, tàbí láti ìgbà náà wá, Jesu ti jókòó láti ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbẹ̀yìngbẹ́yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́.
23 Bí a bá ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ ìgbòkègbodò Jesu nínú òwe àkàwé náà, a óò rí i pé, ó ṣèdájọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Òwe àkàwé náà kò fi hàn pé irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ yóò máa bá a nìṣó fún sáà gígùn ọlọ́dún púpọ̀, bí ẹni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń kú ní àwọn ẹ̀wádún tí ó ti kọjá wọ̀nyí ni a ti ṣèdájọ́ wọn pé, wọ́n yẹ fún ikú àìnípẹ̀kun tàbí ìyè àìnípẹ̀kun. Ó dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ó ti kú ní àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́ ti lọ sí isà okú ti gbogbo aráyé. (Ìṣípayá 6:8; 20:13) Ṣùgbọ́n, òwe àkàwé náà ń ṣàpèjúwe àkókò náà nígbà tí Jesu ń ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” tí wọ́n wà láàyè nígbà náà, tí wọ́n sì dojú kọ ìmúṣẹ ìdájọ́ rẹ̀.
24. Nígbà wo ni òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ yóò ní ìmúṣẹ?
24 Ní èdè mìíràn, òwe àkàwé náà ń tọ́ka sí ọjọ́ ọ̀la, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀. Òun yóò jókòó láti ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn tí ó bá wà láàyè nígbà náà. Yóò gbé ìdájọ́ rẹ̀ karí ohun tí wọ́n ti fi hàn pé àwọn fúnra wọn jẹ́. Ní àkókò yẹn “ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni búburú” yóò ti fìdí múlẹ̀ lọ́nà ṣíṣe kedere. (Malaki 3:18) Kíkéde ìdájọ́ náà ní ti gidi àti ìmúdàájọ́ṣẹ ni a óò ṣe ní àkókò tí ó mọ níwọ̀n. Jesu yóò ṣe àwọn ìpinnu tí ó tọ́, tí a gbé karí ohun tí ó ti hàn gbangba nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan.—Tún wo 2 Korinti 5:10.
25. Kí ni Matteu 25:31 ṣàpèjúwe, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa Ọmọkùnrin ènìyàn, tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ológo?
25 Nítorí náà, èyí túmọ̀ sí pé, ‘jíjókòó tí’ Jesu ‘jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀’ fún ìdájọ́, tí a mẹ́nu kàn nínú Matteu 25:31, ní í ṣe pẹ̀lú àkókò ọjọ́ ọ̀la, nígbà tí Ọba alágbára yìí yóò jókòó láti kéde ìdájọ́, kí ó sì múdàájọ́ ṣẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè. Bẹ́ẹ̀ ni, ìran ìdájọ́ tí ó kan Jesu ní Matteu 25:31-33, 46 ṣeé fi wé ìran inú Danieli orí 7, níbi tí Ọba tí ń ṣàkóso náà, Ẹni-àgbà ọjọ́ nì, ti jókòó láti ṣe ipa tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́.
26. Àlàyé tuntun wo ní ó wá sí ojútáyé nípa òwe àkàwé náà?
26 Lílóye òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ lọ́nà yìí fi hàn pé, ṣíṣèdájọ́ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ yóò jẹ́ ní ọjọ́ ọ̀la. Yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí “ìpọ́njú ńlá” náà tí a mẹ́nu kàn ní Matteu 24:29, 30 bá bẹ́ sílẹ̀, tí Ọmọkùnrin ènìyàn sì ‘dé nínú ògo rẹ̀.’ (Fi wé Marku 13:24-26.) Nígbà náà, nígbà tí ètò ìgbékalẹ̀ búburú látòkèdélẹ̀ bá ti lọ sí òpin rẹ̀, Jesu yóò pè àpèjọ ìdájọ́, yóò ṣèdájọ́, yóò sì múdàájọ́ ṣẹ.—Johannu 5:30; 2 Tessalonika 1:7-10.
27. Kí ni a ní láti lọ́kàn ìfẹ́ sí láti mọ̀ nípa òwe àkàwé Jesu tí ó kẹ́yìn?
27 Èyí mú òye wa nípa àkókò tí òwe àkàwé Jesu náà ní ìmúṣẹ ṣe kedere, èyí tí ó fi ìgbà tí a óò ṣèdájọ́ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ hàn. Ṣùgbọ́n báwo ni ó ṣe nípa lórí àwa tí a ń fi pẹ̀lú ìtara wàásù ìhìnrere Ìjọba náà? (Matteu 24:14) Ó ha dín ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ wa kù bí, tàbí ó mú ẹrù iṣẹ́ wíwúwo sí i wá bí? Ẹ jẹ kí a wo bí ó ṣe kàn wá nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
-
-
Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | October 15
-
-
Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?
“Oun yoo sì ya awọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùtàn kan tí ń ya awọn àgùtàn sọ́tọ̀ kúrò lára awọn ewúrẹ́.”—MATTEU 25:32.
1, 2. Èé ṣe tí òwe àkàwé nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ fi ní láti ru ọkàn ìfẹ́ wa sókè?
DÁJÚDÁJÚ, Jesu Kristi ni Olùkọ́ tí ó tóbi lọ́lá jù lọ tí ó tí ì gbé ayé rí. (Johannu 7:46) Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìkọ́ni rẹ̀ ni lílo àwọn òwe àkàwé, tàbí àwọn àkàwé. (Matteu 13:34, 35) Àwọn wọ̀nyí rọrùn, síbẹ̀, wọ́n lágbára ní gbígbin àwọn ìjìnlẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ òtítọ́ nípa tẹ̀mí síni lọ́kàn.
2 Nínú òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, Jesu tọ́ka sí àkókò kan tí òun yóò gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà àkànṣe: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé ninu ògo rẹ̀, ati . . . ” (Matteu 25:31) Èyí yẹ kí ó ru ọkàn ìfẹ́ wa sókè nítorí pé, òun ni àkàwé tí Jesu fi kádìí èsì rẹ̀ sí ìbéèrè náà pé: “Kí ni yoo . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ ati ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan?” (Matteu 24:3) Ṣùgbọ́n kí ni èyí túmọ̀ sí fún wa?
3. Ṣáájú nínú ìjíròrò rẹ̀, kí ni Jesu sọ pé yóò jẹ yọ kété lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá náà bá ti bẹ̀rẹ̀?
3 Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ apàfiyèsí tí yóò ṣẹlẹ̀ “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn” ìbẹ́sílẹ̀ ìpọ́njú ńlá, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ń retí. Ó wí pé, nígbà náà ni “àmì Ọmọkùnrin ènìyàn” yóò fara hàn. Èyí yóò nípa jíjinlẹ̀ lórí “gbogbo awọn ẹ̀yà ilẹ̀-ayé” tí wọn yóò “rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹlu agbára ati ògo ńlá.” Ọmọkùnrin ènìyàn yóò wà pẹ̀lú “awọn áńgẹ́lì rẹ̀.” (Matteu 24:21, 29-31)a Kí ni nípa ti òwe àkàwé ti àwọn
-