-
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú ẹ Jìnnà Sí JèhófàIlé Ìṣọ́—2013 | January 15
-
-
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú ẹ Jìnnà Sí Jèhófà
“Ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín.”—JÓṢ. 24:15.
1-3. (a) Kí nìdí tí Jóṣúà fi jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa? (b) Kí la gbọ́dọ̀ máa rántí tá a bá ń ṣe ìpinnu?
ÀWỌN ìpinnu tá à ń ṣe ṣe pàtàkì gan-an ni. Wọ́n máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe àti bó ṣe yẹ ká gbé ìgbé ayé wa. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí ẹnì kan ń tọ òpópónà kan lọ, tó wá dé ibì kan tí ọ̀nà ti pín sí méjì. Ṣé apá ọ̀tún ló máa yà sí ni àbí apá òsì? Tó bá jẹ́ pé onítọ̀hún mọ ibi tó ń lọ, ọ̀nà tó já síbẹ̀ ló máa yà sí. Ṣùgbọ́n tó bá lọ yà sí ọ̀nà kejì yẹn, ńṣe ni yóò túbọ̀ máa rìn jìnnà sí ibi tó ń lọ.
2 Bíbélì sọ fún wa nípa ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ní láti pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Kéènì ní láti pinnu bóyá kí òun gbà kí ìbínú mú òun ṣìwà hù tàbí kí òun kápá ìbínú òun. (Jẹ́n. 4:6, 7) Jóṣúà ní láti pinnu bóyá kí òun sin Ọlọ́run òtítọ́ tàbí kí òun máa forí balẹ̀ fún àwọn òrìṣà. (Jóṣ. 24:15) Ohun tí Jóṣúà fi ṣe àfojúsùn rẹ̀ ni pé òun fẹ́ sún mọ́ Jèhófà, ó sì ṣe ìpinnu tó jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, Kéènì ò ní irú àfojúsùn bẹ́ẹ̀, èyí mú kó ṣe ìpinnu tó mú un jìnnà réré sí Jèhófà.
3 Ìgbà míì sì wà tó máa pọn dandan pé kí àwa náà ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì gan-an. Bí a bá ń ṣe irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa rántí àfojúsùn wa. A gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu tó máa fi ògo fún Jèhófà nínú ohun gbogbo, ká sì sá fún ohunkóhun tó bá máa mú ká jìnnà sí i. (Ka Hébérù 3:12.) Nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun méje tí a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó mú wa jìnnà sí Jèhófà.
IṢẸ́
4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn níṣẹ́ lọ́wọ́?
4 Ó pọn dandan pé kí àwọn Kristẹni máa ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà ara wọn àti ti ìdílé wọn. Bíbélì sọ pé bí ẹnì kan kò bá fẹ́ pèsè fún ìdílé rẹ̀, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ. (2 Tẹs. 3:10; 1 Tím. 5:8) Torí náà, ohun àìgbọ́dọ̀máṣe ni iṣẹ́ jẹ́. Àmọ́, ó gba ìṣọ́ra o! Tó o bá yan iṣẹ́ tí kò tọ́, ó lè mú kó o jìnnà sí Jèhófà. Lọ́nà wo?
5. Ká tó gba iṣẹ́ kan, kí la gbọ́dọ̀ ronú lé lórí dáadáa?
5 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé o kò níṣẹ́ lọ́wọ́, tó sì tún ṣòro láti ríṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè tó ò ń gbé ńkọ́? Ó ṣeé ṣe kó o bẹ́ mọ́ iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá rí. Àmọ́, bí iṣẹ́ náà ò bá bá ìlànà Bíbélì mu ńkọ́? Bí iṣẹ́ náà bá máa gbà ẹ́ lákòókò, tí kò ní jẹ́ kó o gbélé, tí wàá sì máa pa ìpàdé jẹ ńkọ́? Ṣé wàá ronú pé bí iṣẹ́ kan ò tiẹ̀ dáa, ó sàn ju kéèyàn má ní iṣẹ́ kankan lọ́wọ́, kó o sì torí ìyẹn gba iṣẹ́ náà? Rántí pé, tó o bá yan iṣẹ́ tí kò dára, ńṣe ló máa mú ẹ jìnnà sí Jèhófà! (Héb. 2:1) Yálà ò ń wáṣẹ́ ni o tàbí ò ń wá bó o ṣe máa yí iṣẹ́ tó ò ń ṣe pa dà, báwo lo ṣe lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání?
6, 7. (a) Kí nìdí méjì téèyàn fi lè fẹ́ láti gba iṣẹ́ kan? (b) Èwo nínú méjèèjì ni kò ní mú kó o jìnnà sí Jèhófà, kí sì nìdí?
6 Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, má ṣe gbàgbé àfojúsùn rẹ. Bi ara rẹ pé, ‘Torí kí ni mo ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí?’ Tó bá jẹ́ pé torí àtigbọ́ bùkátà ara rẹ àti ti ìdílé rẹ kẹ́ ẹ lè máa sin Jèhófà nìṣó lo ṣe ń wáṣẹ́, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Mát. 6:33) Jèhófà mọ bó ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ rẹ tàbí nígbà tí ọrọ̀ ajé bá dẹnu kọlẹ̀. (Aísá. 59:1) Ó “mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.”—2 Pét. 2:9.
7 Tó bá wá jẹ́ pé torí kó o lè di ọlọ́rọ̀ lo ṣe ń wáṣẹ́ ńkọ́? Ó ṣeé ṣe kọ́wọ́ rẹ tẹ ohun tó ò ń wá lóòótọ́. Àmọ́, ewu wà nínú kéèyàn máa ṣiṣẹ́ nítorí àtidi ọlọ́rọ̀. (Ka 1 Tímótì 6:9, 10.) Tó o bá ka owó àti iṣẹ́ sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ, ńṣe ni wọ́n máa mú ẹ jìnnà sí Jèhófà.
8, 9. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kí àwọn òbí bi ara wọn nípa iṣẹ́ wọn? Kí nìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀?
8 Ẹ̀yin òbí, ẹ má gbàgbé pé àwọn ọmọ yín ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ìpinnu tí ẹ̀ ń ṣe. Kí ni àwọn ọmọ rẹ gbà pé o kà sí pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ? Ṣé iṣẹ́ ni àbí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà? Bí wọ́n bá rí i pé bó o ṣe máa di èèyàn pàtàkì láwùjọ àti bó o ṣe máa di olówó ló gbà ẹ́ lọ́kàn jù lọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o mọ̀ pé èyí lè mú káwọn náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ kí wọ́n sì ṣe ìpinnu tí kò dára nígbà tí wọ́n bá dàgbà? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ̀ pé ìyẹn lè mú kí wọ́n má bọ̀wọ̀ fún ẹ bó ṣe yẹ mọ́? Ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé: “Látìgbà tí mo ti gbọ́njú mọ bàbá mi, iṣẹ́ ló jẹ wọ́n lógún jù lọ. Ó kọ́kọ́ dà bíi pé torí kí wọ́n lè tẹ́ wa lọ́rùn ni wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ kára, torí pé wọn ò fẹ́ kí ohunkóhun wọ́n wa. Àmọ́ nǹkan ti yí pa dà lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Iṣẹ́ ni wọ́n ń ṣe ṣáá ní gbogbo ìgbà. Wọ́n á sì ra àwọn nǹkan ìgbádùn tí kò pọn dandan wálé fún wa. Dípò káwọn èèyàn mọ̀ wá sí ìdílé tó ń fún àwọn míì níṣìírí láti sin Jèhófà, ọmọ bàbá olówó ni wọ́n mọ̀ wá sí. Dípò tí bàbá mi fi ń ṣiṣẹ́ kára láti wá owó, ohun tó wù mí jù lọ ni pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ kára láti mú kí ìdílé wa sún mọ́ Jèhófà.”
9 Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ yín mú kẹ́ ẹ jìnnà sí Jèhófà. Àpẹẹrẹ rere ni kẹ́ ẹ fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ yín. Ẹ fi hàn wọ́n pé òótọ́ lẹ gbà gbọ́ pé kéèyàn ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà ṣe pàtàkì lọ́pọ̀lọpọ̀ ju kéèyàn máa kó owó tàbí àwọn nǹkan ìní jọ.—Mát. 5:3.
10. Kí ló yẹ kí ọ̀dọ́ kan ronú lé lórí kó tó yan irú iṣẹ́ tó máa ṣe?
10 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, tó o sì ń ronú lórí irú iṣẹ́ tó o máa ṣe nígbà tó bá yá, báwo lo ṣe lè yan iṣẹ́ tó dára? Bá a ṣe ń sọ bọ̀, ohun tó o bá fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe ló máa pinnu irú iṣẹ́ tó o máa yàn. Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ lo fẹ́ kọ́, ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ á mú kó o lè fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ? Ṣé iṣẹ́ náà kò ní mú ẹ jìnnà sí Jèhófà? (2 Tím. 4:10) Ṣé o fẹ́ dà bí ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé tó jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n bá ní owó rẹpẹtẹ nìkan ni wọ́n máa ń láyọ̀? Àbí o máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bíi ti Dáfídì tó sọ pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri”? (Sm. 37:25) Má ṣe gbàgbé pé ọ̀nà méjì ló wà o! Ọ̀kan á mú kó o jìnnà sí Jèhófà. Èkejì á mú kó o gbádùn ìgbésí ayé tó dára jù lọ. (Ka Òwe 10:22; Málákì 3:10.) Èwo lo máa yàn nínú ọ̀nà méjèèjì?a
ERÉ ÌDÁRAYÁ
11. Kí ni Bíbélì sọ nípa eré ìdárayá? Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn?
11 Bíbélì kò sọ pé ó burú láti ṣeré ìdárayá, kò sì sọ pé ńṣe ni ẹni tó bá ń ṣeré ìdárayá ń fi àkókò ṣòfò. Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Eniyan a máa rí anfani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá.” (1 Tím. 4:8, Ìròhìn Ayọ̀) Bíbélì tiẹ̀ tún sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín” wà, “ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” sì tún wà. Ó sì gbà wá níyànjú pé ká máa sinmi dáadáa. (Oníw. 3:4; 4:6) Àmọ́, bí o kò bá ṣọ́ra, eré ìdárayá lè mú kó o jìnnà sí Jèhófà. Lọ́nà wo? Torí pé ó lè jẹ́ irú èyí tí kò dára lo yàn tàbí kó o máa lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí rẹ̀.
Tá a bá ṣe eré ìdárayá tó dára, tí a kò sì ṣe é ní àṣejù, a máa gbádùn rẹ̀ gan-an
12. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ronú lé tó o bá ń yan eré ìdárayá?
12 Jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa irú eré ìdárayá tó yẹ ká máa ṣe. Ohun kan tó dájú ni pé àwọn eré ìdárayá tó gbámúṣé wà dáadáa. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn eré ìdárayá tàbí ohun táwọn èèyàn kà sí eré ìnàjú nínú ayé lónìí ló dá lórí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kórìíra. Lára irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ìwà ipá, ìbẹ́mìílò àti ìṣekúṣe. Torí náà, o gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa irú eré ìdárayá tí ò ń ṣe. Bi ara rẹ pé: ‘Ipa wo ni eré ìdárayá tí mò ń ṣe ń ní lórí mi? Ṣé kì í jẹ́ kí n máa hùwà ipá tàbí kí n máa rò pé orílẹ̀-èdè tèmi ló dára jù? Ṣé kì í mú kí n máa ronú pé èmi ni mo gbọ́dọ̀ borí ní gbogbo ọ̀nà? (Òwe 3:31) Ṣé kì í ná mi lówó tó pọ̀ jù? Ṣé kò lè mú àwọn míì kọsẹ̀? (Róòmù 14:21) Èmi àti àwọn wo la jọ ń ṣe eré ìdárayá náà? (Òwe 13:20) Ṣé kì í mú kí n máa fẹ́ láti ṣe ohun tí kò tọ́?—Ják. 1:14, 15.’
13, 14. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ronú lórí bí àkókò tó o fi ń ṣe eré ìdárayá ṣe pọ̀ tó?
13 Tún ronú lórí bí àkókò tó ò ń lò nídìí eré ìdárayá ṣe pọ̀ tó. Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń lo àkókò tó pọ̀ gan-an nídìí eré ìdárayá débi pé mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè lọ sóde ẹ̀rí àti ìpàdé mọ́?’ Tó o bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí eré ìdárayá, wàá rí i pé o kò ní gbádùn wọn tó bó ṣe yẹ. Kódà, àwọn tí kì í pẹ́ jù nídìí eré ìdárayá ni wọ́n máa ń gbádùn rẹ̀ jù. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n mọ̀ pé àwọn ti kọ́kọ́ bójú tó “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” torí náà ọkàn wọn kò ní dá wọn lẹ́bi nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré ìdárayá.—Ka Fílípì 1:10, 11.
14 Ẹnì kan lè ronú pé ńṣe ni òun ń gbádùn ara òun tó bá ń fi àkókò tó pọ̀ jù ṣe eré ìdárayá, àmọ́ ńṣe ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń mú kéèyàn jìnnà sí Jèhófà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Kim mú kó gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó ní: “Gbogbo àpèjẹ tí wọ́n bá pè mí sí pátá ni mo máa ń lọ. Òde àríyá ni mo sì máa ń wà ní gbogbo ọjọ́ Friday, Saturday àti Sunday. Àmọ́ mo ti wá rí i báyìí pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ ló wà tó yẹ kí n máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ní báyìí tí mo ti di aṣáájú-ọ̀nà, agogo mẹ́fà ìdájí ni mo máa ń jí kí n lè múra òde ẹ̀rí. Torí náà, kò sí bí mo ṣe lè máa ṣe fàájì títí di aago kan tàbí aago méjì òru. Mo mọ̀ pé kò burú láti lọ síbi àríyá, àmọ́ àpọ̀jù rẹ̀ kì í jẹ́ kéèyàn lè fi àkókò ṣe nǹkan gidi. Torí náà, ó yẹ kéèyàn ṣe é níwọ̀n.”
15. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè yan ère ìdárayá tó dára?
15 Ó pọn dandan pé káwọn òbí máa pèsè jíjẹ àti mímu fún ara wọn àtàwọn ọmọ wọn. Kí wọ́n jọ máa gba ìtọ́ni látinú Bíbélì, kí wọ́n sì jọ máa gba tara wọn rò. Ó sì tún yẹ kí wọ́n máa wáyè láti ṣeré ìdárayá. Tó o bá jẹ́ òbí, má ṣe rò pé gbogbo eré ìdárayá ló burú. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ṣọ́ra fún àwọn eré ìdárayá tí kò dára. (1 Kọ́r. 5:6) Tẹ́ ẹ bá fara balẹ̀ dáadáa, ẹ lè rí eré ìdárayá tó dára tí ìdílé yín lè máa ṣe.b Nípa bẹ́ẹ̀, eré ìdárayá tí ẹ̀ ń ṣe kò ní mú kẹ́ ẹ jìnnà sí Jèhófà.
ÀJỌṢE ÌDÍLÉ
16, 17. Ohun tí kò dára wo ló ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ òbí? Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà mọ bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe rí lára wọn?
16 Àwọn òbí àtàwọn ọmọ máa ń fẹ́ràn ara wọn gan-an. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ pé òun fẹ́ràn àwọn èèyàn òun bí ìyá ṣe máa ń fẹ́ràn ọmọ rẹ̀. (Aísá. 49:15) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé bí ẹnì kan nínú ìdílé bá fi Jèhófà sílẹ̀, ó máa ń dun àwọn yòókù nínú ìdílé gan-an. Arábìnrin kan tí wọ́n yọ ọmọ rẹ̀ obìnrin lẹ́gbẹ́ sọ pé: “Ó bà mí nínú jẹ́ gan-an. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì pé: ‘Kí ló mú kó fi Jèhófà sílẹ̀?’ Ọkàn mi ò wá balẹ̀ mọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara mi lẹ́bi.”
17 Bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ó dájú pé Jèhófà mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ. Ó dun Jèhófà gan-an nígbà tí Ádámù ọmọ rẹ̀ àti èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn tó gbé láyé ṣáájú Ìkún-omi di ọlọ̀tẹ̀. (Jẹ́n. 6:5, 6) Àwọn tí irú nǹkan báyìí ò tíì ṣẹlẹ̀ sí rí lè má mọ bó ṣe máa ń dunni tó. Síbẹ̀, bí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́ nínú ìdílé yín, ó léwu gan-an tó o bá lọ jẹ́ kí ìwà àìtọ́ onítọ̀hún mú ẹ jìnnà sí Jèhófà. Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan fi Jèhófà sílẹ̀ nínú ìdílé rẹ ńkọ́? Kí lo lè ṣe tí o kò fi ní máa banú jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ?
18. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí àwọn òbí máa dá ara wọn lẹ́bi tí ọmọ wọn bá fi Jèhófà sílẹ̀?
18 Má ṣe dá ara rẹ lẹ́bi torí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ẹni tó bá ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tó sì ti ṣe ìrìbọmi ló máa ‘ru ẹrù ara rẹ̀.’ Òun ló sì máa pinnu bóyá òun á máa sin Jèhófà nìṣó. (Gál. 6:5) Torí náà, ẹni tó bá ṣẹ̀ ló máa dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ níwájú Jèhófà. Jèhófà ò ní dá ẹ lẹ́bi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíì. (Ìsík. 18:20) Bákan náà, má ṣe dá àwọn míì lẹ́bi. Fi hàn pé o ní ọ̀wọ̀ fún ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí. Má ṣe dá àwọn alàgbà tó ń dáàbò bo ìjọ lẹ́bi. Èṣù ni kó o kọjú ìjà sí. Má ṣe kọjú ìjà sí àwọn alàgbà. Má sì ṣe jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ mú kó o jìnnà sí Jèhófà.—1 Pét. 5:8, 9.
Kò burú tó o bá ní in lọ́kàn pé èèyàn rẹ kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ṣì máa pa dà wá sọ́dọ̀ Jèhófà
19, 20. (a) Kí ni òbí kan lè ṣe tí kò fi ní banú jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ nígbà tí wọ́n bá yọ ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ́? (b) Kí ló yẹ kí irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ní lọ́kàn?
19 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tó o bá lọ ń bínú sí Jèhófà nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ? Irú ìbínú bẹ́ẹ̀ lè mú ẹ jìnnà sí Jèhófà. Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà gbọ́dọ̀ rí i pé ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà pọ̀ ju èyí tó o ní fún ìdílé rẹ lọ. Kí o má bàa banú jẹ́ jù, rí i pé ohunkóhun kò bá àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. (Òwe 18:1) Gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lọ́kàn rẹ fún un. (Sm. 62:7, 8) Má ṣe máa dọ́gbọ́n wá ọ̀nà láti kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹni tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́. Má ṣe máa kàn sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, bóyá lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí lórí fóònù. (1 Kọ́r. 5:11) Iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni kó o gbájú mọ́. (1 Kọ́r. 15:58) Arábìnrin tí inú rẹ̀ bà jẹ́ torí pé wọ́n yọ ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ́ yẹn sọ pé, “Mo mọ̀ pé ọwọ́ mi gbọ́dọ̀ dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà kò sì gbọ́dọ̀ yingin. Kó lè jẹ́ pé bí ọmọ mi bá pa dà wá sọ́dọ̀ Jèhófà, ó máa ṣeé ṣe fún mi láti ràn án lọ́wọ́.”
20 Bíbélì sọ pé ìfẹ́ a “máa retí ohun gbogbo.” (1 Kọ́r. 13:4, 7) Kò burú tó o bá ní in lọ́kàn pé èèyàn rẹ kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ṣì máa pa dà wá sọ́dọ̀ Jèhófà. Ọdọọdún ni ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ ń ronú pìwà dà tí wọ́n sì ń pa dà wá sínú ètò Jèhófà. Jèhófà kì í bínú sí wọn mọ́ tí wọ́n bá ti ronú pìwà dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ‘ṣe tán láti dárí jì wọ́n.’—Sm. 86:5.
ṢE ÌPINNU TÓ BỌ́GBỌ́N MU
21, 22. Irú ìpinnu wo lo fẹ́ máa ṣe?
21 Jèhófà ti fún àwa ẹ̀dá èèyàn ní òmìnira láti yan àwọn ohun tá a bá fẹ́ láti ṣe. (Ka Diutarónómì 30:19, 20.) Àmọ́, àwọn ìpinnu tó dára ló yẹ ká máa fi òmìnira yìí ṣe. Ó yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé kì í ṣe àwọn nǹkan tó máa mú mi yà kúrò lójú ọ̀nà tó tọ́ ni mò ń ṣe? Ṣé kì í ṣe pé iṣẹ́ tí mò ń ṣe àti eré ìdárayá tí mo yàn láàyò ti mú kí n jìnnà sí Jèhófà? Ṣé àjọṣe àárín èmi àti ìdílé mi ò sì ti mú kó ṣòro fún mi láti sún mọ́ Ọlọ́run?’
22 Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí àwa èèyàn rẹ̀ kọjá àfẹnusọ. Torí náà, kò sí ohun tó lè mú wa jìnnà sí Jèhófà, àyàfi tá a bá ṣe àwọn ìpinnu tí kò dára. (Róòmù 8:38, 39) Kò sì yẹ ká jẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá. Rí i dájú pé o kò jẹ́ kí ohunkóhun mú ẹ jìnnà sí Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí ohun mẹ́rin míì tí a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó mú wa jìnnà sí Jèhófà.
a Wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bó o ṣe lè yan iṣẹ́ tó o máa ṣe ní orí 38 nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì.
b Àwọn àbá lórí bí èèyàn ṣe lè yan eré ìnàjú tó gbámúṣé wà ní ojú ìwé 62 sí 73 nínú ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.’
-
-
Túbọ̀ Sún Mọ́ JèhófàIlé Ìṣọ́—2013 | January 15
-
-
Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà
“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—JÁK. 4:8.
1, 2. (a) Báwo ni Sátánì ṣe máa ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà? (b) Kí ló máa mú ká sún mọ́ Ọlọ́run?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN dá àwa èèyàn lọ́nà tó fi jẹ́ pé ó máa ń wù wá láti sún mọ́ ọn. Síbẹ̀, Sátánì fẹ́ ká máa ronú pé a lè ṣàṣeyọrí láìfi ti Jèhófà pè. Látìgbà tí Sátánì ti purọ́ tan Éfà jẹ nínú ọgbà Édẹ́nì ló ti ń fẹ́ kí àwa èèyàn gbà pé a ò nílò ìtọ́sọ́nà Jèhófà. (Jẹ́n. 3:4-6) Látìgbà yẹn náà sì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti lérò pé àwa èèyàn lè máa dá tara wa ṣe láìfi ti Ọlọ́run pè.
2 Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Ìdí sì ni pé Bíbélì ti ṣàlàyé fún wa nípa oríṣiríṣi ọ̀nà tí Sátánì ń gbà ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. (2 Kọ́r. 2:11) Ó ń dẹ wá wò ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa mú ká jìnnà sí Jèhófà. Àmọ́, a ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́, eré ìdárayá àti àjọṣe ìdílé mú wa jìnnà sí Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun mẹ́rin mìíràn. Ìyẹn àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, ìlera, owó àti ìgbéraga. Tá a bá ṣe ìpinnu tó tọ́ nípa àwọn nǹkan mẹ́rin yìí, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti “sún mọ́ Ọlọ́run.”—Ják. 4:8.
ÀWỌN Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDÉ
3. Onírúurú ọ̀nà wo làwọn èèyàn lè gbà lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé?
3 Ibi gbogbo ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé lóde òní. Àwọn ẹ̀rọ yìí wúlò gan-an téèyàn bá lò wọ́n lọ́nà tó tọ́. Ṣùgbọ́n téèyàn bá lò wọ́n lọ́nà tí kò tọ́, wọ́n lè mú kéèyàn jìnnà sí Ọlọ́run. Ẹ wò kọ̀ǹpútà bí àpẹẹrẹ. Kọ̀ǹpútà la fi ń kọ àwọn ìwé wa, tó fi mọ́ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí, òun náà sì ni a fi ń tẹ̀ wọ́n. A lè fi kọ̀ǹpútà ṣèwádìí ká sì tún fi bára wa sọ̀rọ̀. A sì lè lò ó nígbà míì láti ṣeré ìnàjú tó gbámúṣé. Àmọ́ tá a bá fẹ́ràn àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ju bó ṣe yẹ lọ, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í run gbogbo àkókò wa lé e lórí. Àwọn tó ń polówó ọjà máa ń mú ká ronú pé a gbọ́dọ̀ máa ra àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jáde. Bí àpẹẹrẹ, ó wu ọ̀dọ́mọkùnrin kan pé kó ra kọ̀ǹpútà kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jáde débi pé ó lọ ta ọ̀kan lára àwọn kíndìnrín rẹ̀ kó lè rówó rà á. Ẹ ò rí i pé ìyẹn tún lágbára!
4. Báwo ni arákùnrin kan ṣe jáwọ́ nínú lílo kọ̀ǹpútà ní àlòjù?
4 Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù ni pé kó o jẹ́ kí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ìyẹn sì lè ṣẹlẹ̀ tó o bá ń lò wọ́n lọ́nà tí kò yẹ, tàbí tó o bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí wọn. Arákùnrin Jona tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún sọ pé: “Mo mọ̀ pé Bíbélì sọ pé ká ‘ra àkókò tí ó rọgbọ pa dà’ ká lè máa ráyè kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́, àkóbá tí mò ń ṣe fún ara mi kì í ṣe kékeré látàrí bí mo ṣe ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí kọ̀ǹpútà.” Arákùnrin yìí sábà máa ń wà nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì títí di òru. Ó tún sọ pé: “Bó ti wù kó rẹ̀ mí tó, ìgbà yẹn gan-an ni màá túbọ̀ máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà, tí màá sì máa wo àwọn fídíò kéékèèké. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé àwọn nǹkan tí kò bójú mu ni mo máa ń wò.” Kó bàa lè jáwọ́ nínú ohun tó ti di bárakú fún un yìí, ó ṣe ohun kan sórí kọ̀ǹpútà rẹ̀ táá jẹ́ kí kọ̀ǹpútà náà máa kú fúnra rẹ̀ tó bá ti di àkókò tó yẹ kó lọ sùn.—Ka Éfésù 5:15, 16.
Ẹ̀yin òbí, ẹ máa kíyè sí ohun tí àwọn ọmọ yín ń ṣe lórí kọ̀ǹpútà
5, 6. (a) Kí làwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe fún àwọn ọmọ wọn? (b) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ní ọ̀rẹ́ tó dáa?
5 Kò pọn dandan kí ẹ̀yin òbí máa rí sí gbogbo nǹkan tí àwọn ọmọ yín bá ń ṣe. Àmọ́, ó yẹ kẹ́ ẹ máa kíyè sí ohun tí wọ́n ń ṣe lórí kọ̀ǹpútà. Àwọn ìkànnì kan wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì táwọn ọmọ ti lè wo ìṣekúṣe, tí wọ́n ti lè máa gbá géèmù oníwà ipá, tí wọ́n ti lè wo fíìmù tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò tàbí èyí tí wọ́n ti lè kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́. Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n lọ sórí irú àwọn ìkànnì bẹ́ẹ̀. Tẹ́ ẹ bá gbà wọ́n láyè láti máa lọ sórí àwọn ìkànnì yìí, bóyá torí kí wọ́n má bàa dí yín lọ́wọ́, ó lè mú kí wọ́n rò pé ohun tó dára làwọn ń ṣe. Ojúṣe ẹ̀yin òbí ni pé kẹ́ ẹ máa dáàbò bo àwọn ọmọ yín, kí wọ́n má bàa ṣe ohun tó lè mú kí wọ́n jìnnà sí Jèhófà. Ó ṣe tán, bí ẹnì kan bá ta félefèle lọ́dọ̀ àwọn òròmọdìyẹ, ńṣe ni ìyá àwọn òròmọdìyẹ náà máa pa kuuru mọ́ onítọ̀hún. Bí adìyẹ bá lè dáàbò bo ọmọ rẹ̀ lọ́nà yìí, mélòó mélòó wá ni ẹ̀yin òbí. Ó yẹ kẹ́ ẹ lè dáàbò bo àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ ewu.
6 Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè máa bá àwọn àgbàlagbà àtàwọn ọmọdé tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìjọ ṣọ̀rẹ́. Ẹ má sì gbàgbé pé àwọn ọmọ yín fẹ́ kí ẹ̀yin òbí máa wá àyè láti bá àwọn ṣeré, kẹ́ ẹ jọ máa rẹ́rìn-ín, kẹ́ ẹ sì jọ máa ṣiṣẹ́. Ìyẹn á mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo yín láti jọ “sún mọ́ Ọlọ́run.”b
ÌLERA
7. Kí nìdí tó fi máa ń wu gbogbo wa pé kí ara wá dá ṣáṣá?
7 A sábà máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn pé, ‘Ṣé àlàáfíà lẹ wà?’ Gbólóhùn yìí fi hàn pé kò sẹ́ni tí kì í ṣàìsàn. Àìsàn sì ti bẹ̀rẹ̀ látìgbà tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti jẹ́ kí Sátánì mú wọn jìnnà sí Jèhófà. Inú Sátánì máa ń dùn tá a bá ń ṣàìsàn, torí pé àìsàn máa ń jẹ́ kó túbọ̀ ṣòro fún wa láti sin Jèhófà. Tá a bá sì kú, a ò ní lè sin Ọlọ́run rárá. (Sm. 115:17) Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń fẹ́ kí ara wa dá ṣáṣá.c Ó sì yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìlera àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin jẹ wá lógún.
8, 9. (a) Báwo la ṣe lè yẹra fún ṣíṣe àṣejù nítorí ọ̀rọ̀ ìlera? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí inú wa máa dùn?
8 Àmọ́, kò tún wá yẹ ká ki àṣejù bọ ọ̀rọ̀ ìlera wa o. Ìtara tí àwọn kan fi ń polówó irú oúnjẹ kan, egbòogi tàbí ohun ìṣaralóge pọ̀ ju ìtara tí wọ́n fi ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ. Òótọ́ ni pé ó lè jẹ́ pé ńṣe ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, kò yẹ ká máa ta irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, ní àwọn àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè. Kò sì yẹ ká máa polówó wọn níbẹ̀. Kí nìdí?
9 Ìdí tá a fi ń pàdé pọ̀ láwọn ibi àpéjọ wa ni pé ká lè jíròrò ohun tó wà nínú Bíbélì ká sì ní ayọ̀ tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń fúnni. (Gál. 5:22) Torí náà, kò ní bójú mu tó bá lọ jẹ́ pé ibẹ̀ la ti ń sọ fún àwọn tó béèrè lọ́wọ́ wa àtàwọn tí kò béèrè nípa ìlera àti irú egbòogi tó dáa kéèyàn lò. Ibi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìpàdé jẹ́. Tá a bá sọ ibẹ̀ di ibi ìtajà, a lè ba ayọ̀ àwọn míì jẹ́. (Róòmù 14:17) Olúkúlùkù ló máa pinnu irú ìtọ́jú tó tẹ́ òun lọ́rùn. Ó ṣe tán, kò sí èèyàn tó lè wo gbogbo àìsàn. Kódà, àwọn dókítà tó dáńgájíá jù lọ ń darúgbó, wọ́n ń ṣàìsàn, wọ́n sì ń kú. Àníyàn ò sì lè fi kún iye ọjọ́ tó yẹ ká lò láyé. (Lúùkù 12:25) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé, “ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.”—Òwe 17:22.
10. (a) Kí ló ń mú ká ṣeyebíye lójú Jèhófà? (b) Ìgbà wo làwa èèyàn ò ní ṣàìsàn mọ́?
10 Kò burú ká máa tọ́jú ara wa kí ìrísí wa lè dáa. Àmọ́, kò pọn dandan kéèyàn máa dààmú ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ torí pé ó fẹ́ dán láwọ̀ ju ọjọ́ orí rẹ̀ lọ. Bíbélì sọ pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” (Òwe 16:31) Ìwà rere wa ló ń mú ká ṣeyebíye jù lọ lójú Jèhófà, ohun tó sì yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí àwa náà nìyẹn. (Ka 1 Pétérù 3:3, 4.) Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn lọ ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ kan tó lè fi ẹ̀mí ẹni sínú ewu, tàbí kéèyàn máa lo àwọn oògùn kan tó léwu fún ara kó má bàa tètè darúgbó? Bó ti wù ká darúgbó tàbí kí ara wá dá ṣáṣá tó, “ìdùnnú Jèhófà” nìkan ló lè mú ká ní ẹwà tòótọ́. (Neh. 8:10) Inú ayé tuntun nìkan la ò ti ní ṣàìsàn mọ́ tí ara wa á sì máa jà yọ̀yọ̀. (Jóòbù 33:25; Aísá. 33:24) Títí dìgbà náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání ká sì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà. Èyí á jẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé wa nísinsìnyí, ọ̀rọ̀ ìlera ò sì ní gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ.—1 Tím. 4:8.
OWÓ
11. Báwo ni owó ṣe lè mú wa jìnnà sí Jèhófà?
11 Kò burú láti ní owó tàbí kéèyàn máa ṣe iṣẹ́ tó dára, tó sì ń mówó wọlé. (Oníw. 7:12; Lúùkù 19:12, 13) Àmọ́ “ìfẹ́ owó” lè mú wa jìnnà sí Jèhófà. (1 Tím. 6:9, 10) “Àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí,” èyí tó túmọ̀ sí pé kéèyàn máa ṣàníyàn jù nítorí jíjẹ, mímu àti ohun ìní, lè mú ká jìnnà sí Jèhófà. “Agbára ìtannijẹ ọrọ̀” tún lè mú ká jìnnà sí Ọlọ́run. Ohun tí agbára ìtannijẹ ọrọ̀ sì túmọ̀ sí ni pé kéèyàn gbà pé owó ló lè fúnni ní ayọ̀ àti ààbò tó tọ́jọ́. (Mát. 13:22) Jésù mú kó ṣe kedere pé “kò sí ẹnì kan” tó lè sìnrú fún Ọlọ́run àti ọrọ̀.—Mát. 6:24.
12. Onírúurú ọ̀nà wo làwọn èèyàn ń gbà wá owó òjijì lóde òní? Kí la lè ṣe tí a kò fi ní dà bí wọn?
12 Tá a bá rò pé owó ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn lè mú ká ṣe ohun tí kò tọ́. (Òwe 28:20) Torí pé àwọn kan fẹ́ láti di olówó òjijì, ńṣe ni wọ́n lọ fi owó wọn ta tẹ́tẹ́. Àwọn ará kan tiẹ̀ lọ́wọ́ sí àwọn okòwò tí wọ́n rò pé ó máa tètè sọ wọ́n di olówó, wọ́n sì ṣèlérí fún àwọn ará míì nínú ìjọ pé àwọn pẹ̀lú máa rí owó nídìí okòwò náà. Àwọn míì sì sọ pé káwọn ará kan nínú ìjọ yá àwọn lówó láti fi ṣòwò àti pé owó gọbọi làwọn máa fi san án pa dà fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí ìwọra mú kó o lọ ṣe òwò tó máa mú kó o kó sọ́wọ́ àwọn gbájúẹ̀! Torí náà, ṣọ́ra kó o má ṣe di oníwọra. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn ẹ́. Kò rọrùn láti tètè rí owó rẹpẹtẹ kó jọ o!
13. Èrò wo ni Jèhófà fẹ́ ká ní nípa owó?
13 Tí a kò bá jẹ́ kí iṣẹ́ wa dí wa lọ́wọ́ láti fi “ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀” sí ipò àkọ́kọ́, Jèhófà máa fún wa ní àwọn nǹkan tó jẹ́ kòṣeémáàní. (Mát. 6:33; Éfé. 4:28) Jèhófà kò fẹ́ ká máa sùn nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́ torí pé ó máa ń rẹ̀ wá nítorí iṣẹ́ àṣejù. Kò sì fẹ́ ká máa ṣàníyàn nípa owó nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tó bá gbà káwọn lè lówó. Kí ìyẹn lè jẹ́ àṣesílẹ̀ tó máa di àbọ̀wábá fún wọn nígbà tí wọ́n bá darúgbó. Ohun tí wọ́n sì máa ń sọ pé káwọn ọmọ wọn náà ṣe nìyẹn. Jésù fi hàn pé kò bọ́gbọ́n mu láti ronú lọ́nà yẹn. (Ka Lúùkù 12:15-21.) Èyí lè mú ká rántí Géhásì tó jẹ́ oníwọra, àmọ́ tó rò pé òun ṣì lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà lẹ́sẹ̀ kan náà.—2 Ọba 5:20-27.
14, 15. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti ronú pé owó ló lè mú ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan.
14 Àwọn ẹyẹ idì kan wà tí wọ́n gbé ẹja tó wúwo jù fún wọn láti gbé. Àmọ́, nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ju ẹja náà sílẹ̀, ńṣe ni wọ́n rì sínú omi. Ǹjẹ́ ohun tó jọ ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ sí àwa Kristẹni? Alàgbà kan tó ń jẹ́ Alex sọ pé: “Mo máa ń ṣọ́wó ná gan-an ni. Ó bá mi débi pé bí ọṣẹ olómi tí mo bù sọ́wọ́ látinú ike bá ti pọ̀ jù, ńṣe ni màá da díẹ̀ pa dà sínú ike náà.” Àmọ́ Alex rò pé bí òun bá lè wá díẹ̀ kún owó tó wà lọ́wọ́ òun, òun á fi iṣẹ́ tí òun ń ṣe sílẹ̀, òun á sì wọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Torí náà, ó lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ra ìpín ìdókòwò àti bí wọ́n ṣe ń tà á. Lẹ́yìn náà, ó fi gbogbo owó tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ ra ìpín ìdókòwò. Kódà, ó tún yáwó láti ra ìpín ìdókòwò púpọ̀ sí i! Àwọn ọ̀mọ̀ràn tó mọ bí wọ́n ṣe ń díwọ̀n èrè orí ìpín ìdókòwò tiẹ̀ sọ fún un pé kò ní pẹ́ rárá tí èrè orí ìpín ìdókòwò rẹ̀ á fi pọ̀ gan-an. Àmọ́, ńṣe ni èrè orí ìpín ìdókòwò já wálẹ̀ lójijì. Alex sọ pé: “Mo pinnu pé màá gba owó mi pa dà. Èrò mi ni pé, ìgbà yòówù kó jẹ́, màá dúró dìgbà tí èrè orí ìpín ìdókòwò náà bá lọ sókè.”
15 Fún ọ̀pọ̀ oṣù tí Alex fi ń dúró yìí, kò rí nǹkan míì rò mọ́ ju ìpín ìdókòwò tó rà lọ. Iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́lẹ̀, kò sì rí oorun sùn dáadáa mọ́. Àmọ́, ìpín ìdókòwò náà ò lọ sókè mọ́ o! Gbogbo owó tí Alex dà lé e lórí ló wọgbó, nǹkan sì wá le fún un débi pé ńṣe ló ta ilé rẹ̀. Ó wá sọ pé: “Ìṣòro tí ọ̀rọ̀ yìí dá sílẹ̀ nínú ìdílé mi kì í ṣe kékeré.” Àmọ́, ó sọ ẹ̀kọ́ pàtàkì tó rí kọ́. Ó ní: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé bí ẹnikẹ́ni bá gbẹ́kẹ̀ lé ayé tí Sátánì ń darí yìí pé ó máa fún òun ní ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀, ńṣe lonítọ̀hún á fi ìka àbámọ̀ bọnu gbẹ̀yìn.” (Òwe 11:28) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé owó wa tàbí ọgbọ́n tá a fi lè mówó wọlé, ńṣe là ń gbẹ́kẹ̀ lé Sátánì, tí í ṣe “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́r. 4:4; 1 Tím. 6:17) Ní báyìí, Alex ti ṣe àwọn ìyípadà tó máa mú kó lè máa lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Èyí ti mú kí òun àti ìdílé rẹ̀ láyọ̀ kí wọ́n sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.—Ka Máàkù 10:29, 30.
ÌGBÉRAGA
16. Kí ni àwa Kristẹni tòótọ́ lè máa fi yangàn? Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ?
16 Kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn máa fi ohun tó dára yangàn. Bí àpẹẹrẹ, ohun àmúyangàn ló jẹ́ pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà. (Jer. 9:24) Ìyẹn ló sì fà á tá a fi ń gbìyànjú nígbà gbogbo ká lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó dára ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ, ká má sì ṣe máa rò pé a gbọ́n ju Jèhófà lọ. Ńṣe ni irú èrò bẹ́ẹ̀ máa mú ká jìnnà sí Jèhófà.—Sm. 138:6; Róòmù 12:3.
Dípò tí wàá fi máa wá ipò nínú ìjọ, máa fayọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ nìṣó!
17, 18. (a) Irú èèyàn wo ni Bíbélì fi hàn pé Dáfídì jẹ́? Àwọn wo ni Bíbélì fi hàn pé wọ́n jẹ́ agbéraga? (b) Báwo ni arákùnrin kan kò ṣe jẹ́ kí ìgbéraga mú òun jìnnà sí Jèhófà?
17 Bíbélì sọ fún wa nípa àwọn tó jẹ́ agbéraga àtàwọn tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Onírẹ̀lẹ̀ ni Dáfídì Ọba. Ó bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà, ó sì rí ìbùkún Jèhófà. (Sm. 131:1-3) Àmọ́ Jèhófà fìyà jẹ Nebukadinésárì Ọba àti Bẹliṣásárì torí pé wọ́n jẹ́ agbéraga. (Dán. 4:30-37; 5:22-30) Láwọn ìgbà míì, àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó máa fi hàn bóyá a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tàbí agbéraga. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni Ryan, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì ni nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìjọ míì. Ó sọ pé: “Èrò mi ni pé mi ò ní pẹ́ di alàgbà tí mo bá débẹ̀. Àmọ́, ní ọdún kan lẹ́yìn tí mo débẹ̀, mi ò tíì di alàgbà.” Ṣé Ryan bínú sí àwọn alàgbà tó wà níbẹ̀ torí pé wọn kò tètè dámọ̀ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alàgbà? Ṣé ìgbéraga mú kó pa ìpàdé tì, kó sì wá kọ Jèhófà àtàwọn ará sílẹ̀? Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Ryan, kí lo máa ṣe?
18 Látàrí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, Arákùnrin Ryan sọ pé: “Mo ṣe ìwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa mo sì kà nípa ìdí tó fi dára pé kéèyàn máa ní sùúrù.” (Òwe 13:12) “Ìgbà yẹn ni mo tó wá rí i pé mo gbọ́dọ̀ ní sùúrù àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀. Mo gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Jèhófà kọ́ mi.” Látìgbà yẹn ni Ryan ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bó ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ìjọ àti lóde ẹ̀rí. Kò sì pẹ́ tó fi ní àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jíire. Ó wá sọ pé: “Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo di alàgbà ní ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn náà. Ìdí tó sì fi yà mí lẹ́nu ni pé mi ò tiẹ̀ ronú nípa rẹ̀ mọ́, torí pé mò ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn mi.”—Ka Sáàmù 37:3, 4.
DÚRÓ TI JÈHÓFÀ
19, 20. (a) Báwo la ṣe lè rí i dájú pé èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí kò mú wa jìnnà sí Jèhófà? (b) Àwọn adúróṣinṣin wo la lè fi ṣe àwòkọ́ṣe wa?
19 Kò sí èyí tó burú nínú àwọn nǹkan méje tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí àti èyí tá à ń jíròrò lọ́wọ́ yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbéraga kò dára, ohun àmúyangàn ni pé a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Ìdílé aláyọ̀ àti ìlera tó dára jẹ́ ara ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa. A mọ̀ pé tá a bá níṣẹ́ lọ́wọ́ tá a sì lówó lọ́wọ́, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti máa gbọ́ bùkátà ara wa. A mọ̀ pé eré ìdárayá máa ń tuni lára. Àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé sì wúlò gan-an. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ máa rántí pé tá a bá ṣe ohunkóhun nígbà tí kò tọ́, tá a bá ṣe é láṣejù, tàbí tá a ṣe é lọ́nà tó máa pa iṣẹ́ ìsìn wa lára, ó lè mú ká jìnnà sí Jèhófà.
Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun mú ẹ jìnnà sí Jèhófà!
20 Ohun tí Sátánì sì fẹ́ ni pé ká jìnnà sí Jèhófà. Àmọ́, o lè ṣiṣẹ́ kára láti dáàbò bo ara rẹ àti ìdílé rẹ. (Òwe 22:3) Sún mọ́ Jèhófà, má sì ṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Bíbélì sọ fún wa nípa ọ̀pọ̀ èèyàn tó jẹ́ adúróṣinṣin. Énọ́kù àti Nóà “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́n. 5:22; 6:9) Mósè “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Héb. 11:27) Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni Jésù máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà, Ọlọ́run sì tì í lẹ́yìn. (Jòh. 8:29) Fi àwọn tá a dárúkọ yìí ṣe àwòkọ́ṣe rẹ. ‘Máa yọ̀ nígbà gbogbo. Máa gbàdúrà láìdabọ̀. Máa dúpẹ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo.’ (1 Tẹs. 5:16-18) Má sì ṣe jẹ́ kí ohunkóhun mú ẹ jìnnà sí Jèhófà!
a A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.
b Wo “Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Yanjú” nínú Jí! October–December 2011.
c Wo “Ohun Márùn-ún Tó Lè Mú Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I” nínú Jí! April–June 2011.
-