ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dúró Níwájú Ìtẹ́ Ìdájọ́?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | October 15
    • Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dúró Níwájú Ìtẹ́ Ìdájọ́?

      “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn áńgẹ́lì pẹlu rẹ̀, nígbà naa ni oun yoo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀.”—MATTEU 25:31.

      1-3. Ìdí wo ni a ní fún fífojúsọ́nà fún rere ní ti ìdájọ́?

      ‘OJẸ̀BI ÀBÓÒ JẸ̀BI?’ Ọ̀pọ̀ ń tọpinpin bí wọ́n ṣe ń gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ìgbẹ́jọ́ kan. Àwọn onídàájọ́ àti àwọn mẹ́ḿbà ìgbìmọ̀ ìdájọ́ lè jẹ́ aláìlábòsí, ṣùgbọ́n òdodo ha máa ń fìgbà gbogbo lékè bí? O kò ha ti gbọ́ nípa àìṣèdájọ́ òdodo àti àìṣẹ̀tọ́ nígbà tí ìgbẹ́jọ́ bá ń lọ lọ́wọ́ bí? Irú àìṣèdájọ́ òdodo bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ohun tuntun, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú àkàwé Jesu, nínú Luku 18:1-8.

      2 Ohun yòówù kí ìrírí rẹ̀ ní ti ìdájọ́ ti ẹ̀dá ènìyàn jẹ́, ṣàkíyèsí ìparí èrò tí Jesu dé: “Ọlọrun kì yoo ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún awọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí ń ké jáde sí i tọ̀sán tòru . . . ? Mo sọ fún yín, Oun yoo mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn pẹlu ìyára kánkán. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé, oun yoo ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀-ayé níti gidi bí?”

      3 Bẹ́ẹ̀ ni, Jehofa yóò rí sí i pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rí ìdájọ́ òdodo gbà nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ó kan Jesu pẹ̀lú, ní pàtàkì nísinsìnyí, nítorí pé, a ń gbé ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò ìgbékalẹ̀ búburú ti ìsinsìnyí. Láìpẹ́, Jehofa yóò lo Ọmọkùnrin rẹ̀ alágbára láti mú ìwà búburú kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (2 Timoteu 3:1; 2 Tessalonika 1:7, 8; Ìṣípayá 19:11-16) A lóye ipa iṣẹ́ Jesu láti inú ọ̀kan lára àwọn àkàwé tí ó ṣe, tí a sábà máa ń pè ní òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́.

      4. Báwo ni a ti ṣe lóye àkókò tí òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ ní ìmúṣẹ sí tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n èé ṣe tí a óò fi fún òwe àkàwé náà ní àfiyèsí nísinsìnyí? (Owe 4:18)

      4 Tipẹ́tipẹ́ ni a ti rò pé òwe àkàwé náà ṣàpèjúwe Jesu tí ó jókòó gẹ́gẹ́ bí Ọba ní 1914, tí ó sì ti ń ṣèdájọ́ láti ìgbà náà wá—ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn ènìyàn tí wọ́n fi hàn pé àwọ́n jẹ́ ẹni bí àgùntàn, ikú àkúrun fún àwọn ewúrẹ́. Ṣùgbọ́n títún òwe àkàwé náà gbé yẹ̀wò tọ́ka sí òye kan tí a tún ṣe nípa àkókò tí ó ní ìmúṣẹ àti ohun tí ń ṣàpèjúwe. Àtúnṣe yìí fún ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ ìwàásù wa lókun àti bí ìdáhùnpadà àwọn ènìyàn ti ṣe kókó tó. Láti lè rì ìpìlẹ̀ fún òye jíjinlẹ̀ síi ní ti òwe àkàwé náà, ẹ jẹ́ kí a gbé ohun tí Bibeli fi hàn nípa Jehofa àti Jesu yẹ̀ wò, bí àwọn méjèèjì ṣe jẹ́ Ọba àti Onídàájọ́.

      Jehofa Gẹ́gẹ́ Bí Onídàájọ́ Gíga Lọ́lá Jù Lọ

      5, 6. Èé ṣe tí ó fi bá a mu wẹ́kú láti wo Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Onídàájọ́?

      5 Jehofa ń fi agbára rẹ̀ ṣàkóso lórí gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ lágbàáyé. Nítorí tí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ tí kò sì ní òpin, òun ni “Ọba ayérayé.” (1 Timoteu 1:17; Orin Dafidi 90:2, 4; Ìṣípayá 15:3) Ó ní ọlá àṣẹ láti ṣe àwọn òfin, tàbí láti pa àṣẹ, àti láti rí i pé ó múlẹ̀. Ṣùgbọ́n ọlá àṣẹ rẹ̀ ní jíjẹ́ Onídàájọ́ nínú. Isaiah 33:22 sọ pé: “Oluwa ni onídàájọ́ wa, Oluwa ni olófin wa, Oluwa ni ọba wa; òun óò gbà wá là.”

      6 Ó ti pẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ti mọ Jehofa gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ àwọn ẹjọ́ àti ọ̀ràn àríyànjiyàn. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí “Onídàájọ́ gbogbo ayé” ti wọn ẹ̀rí nípa ìwà búburú Sodomu àti Gomorra wò, ó dájọ́ pé àwọn olùgbé náà yẹ fún ìparun, ó sì rí sí i pé ìdájọ́ òdodo náà múlẹ̀. (Genesisi 18:20-33; Jobu 34:10-12) Ẹ wo bí èyí ṣe ní láti fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó, láti mọ̀ pé, Jehofa jẹ́ Onídàájọ́ òdodo, tí ó lè mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ nígbà gbogbo!

      7. Báwo ni Jehofa ti ṣe ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ ní bíbá Israeli lò?

      7 Ní Israeli ìgbàanì, nígbà mìíràn, Jehofa máa ń ṣèdájọ́ ní tààràtà. A kò ha ti ní tù ọ́ nínú nígbà náà lọ́hùn-ún, láti mọ̀ pé Onídàájọ́ pípé kan ni ń pinnu àwọn ọ̀ràn bí? (Lefitiku 24:10-16; Numeri 15:32-36; 27:1-11) Ọlọrun tún pèsè “àwọn òfin” tí ó dára látòkèdélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n fún ṣíṣe ìdájọ́. (Lefitiku 25:18, 19; Nehemiah 9:13; Orin Dafidi 19:9, 10; 119:7, 75, 164; 147:19, 20) Òun ni “Onídàájọ́ gbogbo ayé,” nítorí náà, gbogbo wa ni ó kàn.—Heberu 12:23.

      8. Ìran tí ó jẹ mọ́ ọn wo ní Danieli rí?

      8 A ni ẹ̀rí “ẹni tí ọ̀ran ṣojú rẹ̀” tí ó jẹ́rìí sí ọ̀ràn yìí. A fi ìran àwọn ẹranko ẹhànnà rírorò tí wọ́n dúró fún àwọn ìjọba tàbí ilẹ̀ ọba han wòlíì Danieli. (Danieli 7:1-8, 17) Ó fi kún un pé: ‘A sọ àwọn ìtẹ́ wọnnì kalẹ̀ títí Ẹni-àgbà ọjọ́ náà fi jókòó, aṣọ ẹni tí ó fún gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.’ (Danieli 7:9) Ṣàkíyèsí pé Danieli rí àwọn ìtẹ́ tí “Ẹni-àgbà ọjọ́ náà [Jehofa] fi jókòó.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ ti wa.) Bí ara rẹ léèrè pé: ‘Danieli níhìn-ín ha ń rí bí Ọlọrun ṣe ń di Ọba bí?’

      9. Kí ni ìtumọ̀ kan fún ‘jíjókòó’ lórí ìtẹ́? Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ.

      9 Tóò, nígbà tí a bá kà pé ẹnì kan “jókòó” lórí ìtẹ́, a lè rò pé ó ń di ọba, nítorí pé, nígbà mìíràn, Bibeli máa ń lo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ: “Nígbà tí [Simri] bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, bí ó ti jókòó ní orí ìtẹ́ rẹ̀, ó . . . ” (1 Ọba 16:11; 2 Ọba 10:30; 15:12; Jeremiah 33:17) Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Messia sọ pé: “Yóò sì jókòó yóò sì jọba lórí ìtẹ́ rẹ̀.” (Ìkọ̀wé wínníwinní jẹ́ ti wa.) Nítorí náà, láti ‘jókòó lórí ìtẹ́’ lè túmọ̀ sí dídi ọba. (Sekariah 6:12, 13) A ṣàpèjúwe Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́. (1 Ọba 22:19; Isaiah 6:1; Ìṣípayá 4:1-3) Òun ni “Ọba ayérayé.” Síbẹ̀, níwọ̀n bí ó ti fi ìtẹnumọ́ kéde apá tuntun kan ní ti ipò ọba aláṣẹ, a lè sọ pé ó ti di Ọba, bí ẹni pé ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ lákọ̀tun.—1 Kronika 16:1, 31; Isaiah 52:7; Ìṣípayá 11:15-17; 15:3; 19:1, 2, 6.

      10. Kí ni olórí iṣẹ́ àwọn ọba Israeli? Ṣàpèjúwe.

      10 Ṣùgbọ́n kókó pàtàkì kan rèé: Olórí iṣẹ́ àwọn ọba ìgbàanì ni, láti máa gbẹ́jọ́, kí wọ́n sì máa ṣèdájọ́. (Owe 20:8; 29:14) Rántí ìdájọ́ ọlọ́gbọ́n tí Solomoni ṣe nígbà tí àwọn obìnrin méjì ń jà lórí ọmọ kan náà. (1 Ọba 3:16-28; 2 Kronika 9:8) Ọ̀kan lára àwọn ilé ìjọba rẹ̀ ni “ìloro ìtẹ́ níbi ti yóò máa ṣe ìdájọ́,” tí a sì tún ń pè ní “ìloro ìdájọ́.” (1 Ọba 7:7) A ṣàpèjúwe Jerusalemu gẹ́gẹ́ bí ibi tí “a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀” sí. (Orin Dafidi 122:5) Ó ṣe kedere pé, ‘jíjókòó lórí ìtẹ́’ tún lè túmọ̀ sí lílo ọlá àṣẹ ìdájọ́.—Eksodu 18:13; Owe 20:8.

      11, 12. (a) Kí ni ìjẹ́pàtàkì jíjókòó tí Jehofa jókòó, tí a mẹ́nu kàn nínú Danieli orí 7? (b) Báwo ni àwọn ẹsẹ mìíràn ṣe jẹ́rìí sí i pé Jehofa jókòó láti ṣèdájọ́?

      11 Wàyí o, ẹ jẹ́ kí a padà sí ìran náà, níbi tí Danieli ti rí “Ẹni-àgbà ọjọ́ náà tí ó jókòó.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ ti wa.) Danieli 7:10 fi kún un pé: “Àwọn onídàájọ́ jókòó, a sì ṣí ìwé wọnnì sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, Ẹni-àgbà ọjọ́ náà jókòó láti ṣèdájọ́ nípa ìjẹgàba lórí ayé àti láti ṣèdájọ́ Ọmọkùnrin ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ẹni náà tí ó yẹ kí ó ṣàkóso. (Danieli 7:13, 14) Lẹ́yìn náà, a kà pé “Ẹni-àgbà ọjọ́ nì . . . dé, . . . a sì fi ìdáláre fún àwọn ènìyàn mímọ́,” àwọn tí a ṣèdájọ́ wọn pé, wọ́n yẹ láti ṣàkóso pẹ̀lú Ọmọkùnrin ènìyàn. (Danieli 7:22, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ ti wa.) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín “àwọn onídàájọ́ jókòó,” wọ́n sì ṣèdájọ́ mímúná lórí agbára ayé tí ó kẹ́yìn.—Danieli 7:26.a

      12 Nítorí náà, rírí tí Danieli rí Ọlọrun tí ó ‘jókòó lórí ìtẹ́’ túmọ̀ sí bíbọ̀ Rẹ̀ láti ṣèdájọ́. Dafidi ti kọrin ṣáájú pé: “Ìwọ [Jehofa] ni ó ti mú ìdájọ́ mi àti ìdí ọ̀ràn mi dúró; ìwọ ni ó jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń ṣe ìdájọ́ òdodo.” (Orin Dafidi 9:4, 7) Joeli sì kọ̀wé pé: “Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojì Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí: nítorí níbẹ̀ ni èmi [Jehofa] óò jókòó láti ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.” (Joeli 3:12; fi wé Isaiah 16:5.) Jesu àti Paulu wà nínú ipò ìdájọ́, nínú èyí tí ẹ̀dá ènìyàn kan tí jókòó láti gbẹ́jọ́, tí ó sì ṣèdájọ́.b—Johannu 19:12-16; Ìṣe 23:3; 25:6.

      Ipò Jesu

      13, 14. (a) Ìdálójú wo ni àwọn ènìyàn Ọlọrun ní pé Jesu yóò di Ọba? (b) Nígbà wo ni Jesu jókòó lórí ìtẹ́, ní ọ̀nà wo sì ni ó fi ń ṣàkóso láti 33 C.E. wá?

      13 Jehofa jẹ́ Ọba àti Onídàájọ́. Jesu ń kọ́? Áńgẹ́lì náà tí ó kéde ìbí rẹ̀ wí pé: “Jehofa Ọlọrun yoo sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún un, . . . kì yoo sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Luku 1:32, 33) Jesu yóò jẹ́ ajogún ipò ọba Dafidi títí láé. (2 Samueli 7:12-16) Òun yóò ṣàkóso láti ọ̀run, nítorí Dafidi wí pé: “Ọ̀rọ̀ àsọjáde Jehofa sí Oluwa mi [Jesu] ni: ‘Jókòó ni ọwọ́ ọ̀tún mi títí tí èmi yóò fi gbé àwọn ọ̀tá rẹ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.’ Ọ̀pá okun rẹ ni Jehofa yóò ràn jáde lọ láti Sioni, ní sísọ pé: ‘Lọ jọba láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.’”—Orin Dafidi 110:1-4, NW.

      14 Nígbà wo ni ìyẹn yóò jẹ́? Jesu kò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba nígbà tí ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn. (Johannu 18:33-37) Ní 33 C.E., ó kú, a jí i dìde, ó sì gòkè re ọ̀run. Heberu 10:12 sọ pé: “Ọkùnrin yii rú ẹbọ kanṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ títí lọ kánrin ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.” Ọlá àṣẹ wo ni Jesu ní? “[Ọlọrun] mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ní awọn ibi ọ̀run, lókè fíofío rékọjá gbogbo ìjọba-àkóso ati ọlá-àṣẹ ati agbára ati ipò oluwa . . . ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ.” (Efesu 1:20-22) Nítorí pé Jesu ní ọlá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí àwọn Kristian nígbà náà lọ́hùn-ún, Paulu lè kọ̀wé pé, Jehofa “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ọlá-àṣẹ òkùnkùn ó sì ṣí wa nípò lọ sínú ìjọba Ọmọkùnrin ìfẹ́ rẹ̀.”—Kolosse 1:13; 3:1.

      15, 16. (a) Èé ṣe tí a fi sọ pé Jesu kò di Ọba Ìjọba Ọlọrun ní 33 C.E.? (b) Nígbà wo ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọrun?

      15 Ṣùgbọ́n, ní àkókò yẹn, Jesu kò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Onídàájọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè. Ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọrun, ó ń dúró de àkókò náà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọrun. Paulu kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Èwo ninu awọn áńgẹ́lì ni oun wí nipa rẹ̀ rí pé: ‘Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí emi yoo fi gbé awọn ọ̀tá rẹ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpótí-ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ’?”—Heberu 1:13.

      16 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti tẹ ọ̀pọ̀ ẹ̀rí jáde pé sáà dídúró Jesu ti wá sópin ní 1914, nígbà tí ó di alákòóso Ìjọba Ọlọrun nínú àwọn ọ̀run tí a kò lè fojú rí. Ìṣípayá 11:15, 18 sọ pé: “Ìjọba ayé di ìjọba Oluwa wa ati ti Kristi rẹ̀, oun yoo sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé ati láéláé.” “Ṣugbọn awọn orílẹ̀-èdè kún fún ìrunú, ìrunú tìrẹ sì dé.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn orílẹ̀-èdè fi ìrunú wọn hàn sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì nígbà Ogun Àgbáyé I. (Luku 21:24) Ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, ọ̀wọ́n oúnjẹ, àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, tí a ti ń rí láti 1914 jẹ́rìí sí i pé Jesu ń ṣàkóso nísinsìnyí nínú Ìjọba Ọlọrun, òpin ìkẹyìn ayé yìí sì ti sún mọ́lé.—Matteu 24:3-14.

      17. Àwọn kókó pàtàkì wo ni a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ báyìí?

      17 Láti ṣàtúnyẹ̀wò ráńpẹ́: A lè sọ pé Ọlọrun jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba, ṣùgbọ́n lọ́nà mìíràn, ó lè jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣèdájọ́. Ní 33 C.E., Jesu jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, òun sì ni Ọba Ìjọba náà nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ Jesu tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba nísinsìnyí, tún ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ bí? Èé sì ti ṣe tí èyí fi ní láti kàn wá, ní pàtàkì ní àkókò yìí?

      18. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé Jesu pẹ̀lú yóò jẹ́ Onídàájọ́?

      18 Jehofa, ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti yan àwọn onídàájọ́ sípò, yan Jesu gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ tí ó bá ọ̀pá ìdiwọ̀n Rẹ̀ mu. Jesu fi èyí hàn nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa kí ènìyàn wà láàyè nípa tẹ̀mí: “Baba kì í ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni rárá, ṣugbọn ó ti fi gbogbo ìdájọ́ ṣíṣe lé Ọmọkùnrin lọ́wọ́.” (Johannu 5:22) Síbẹ̀, ipa iṣẹ́ Jesu gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ lọ ré kọjá irú ìdájọ́ yẹn, nítorí pé òun jẹ́ onídàájọ́ àwọn alààyè àti àwọn òkú. (Ìṣe 10:42; 2 Timoteu 4:1) Paulu polongo nígbà kan pé: “[Ọlọrun] ti dá ọjọ́ kan ninu èyí tí oun pète lati ṣèdájọ́ ilẹ̀-ayé tí à ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan [Jesu] tí oun ti yànsípò, ó sì ti pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà kan fún gbogbo ènìyàn níti pé ó ti jí i dìde kúrò ninu òkú.”—Ìṣe 17:31; Orin Dafidi 72:2-7.

      19. Èé ṣe tí o fi tọ́ láti sọ pé Jesu ń jókòó gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́?

      19 Nígbà náà, ó ha tọ́ kí a parí èrò sí pé, Jesu jókòó lórí ìtẹ́ ológo rẹ̀ ní kíkó ipa pàtó gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Jesu sọ fún àwọn aposteli pé: “Ní àtúndá, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tọ̀ mí lẹ́yìn yoo jókòó fúnra yín pẹlu sórí ìtẹ́ méjìlá, ẹ óò máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà Israeli méjìlá.” (Matteu 19:28) Bí Jesu tilẹ̀ ti di Ọba Ìjọba náà nísinsìnyí, ìgbòkègbodò rẹ̀ síwájú sí i tí a mẹ́nu kàn nínú Matteu 19:28 yóò ní jíjókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ nígbà Ẹgbẹ̀rúndún nínú. Ní àkókò yẹn, òun yóò ṣèdájọ́ gbogbo aráyé, àwọn olódodo àti aláìṣòdodo. (Ìṣe 24:15) Yóò ṣèrànwọ́ láti fi èyí sọ́kàn bí a ṣe ń darí àfiyèsí wa sí ọ̀kan nínú àwọn òwe àkàwé Jesu tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àkókò wa àti ìwàláàyè wa.

      Kí Ni Òwe Àkàwé Náà Sọ?

      20, 21. Kí ni àwọn aposteli Jesu béèrè, tí ó jẹ mọ́ àkókò wa, ìbéèrè wo sì ni ó yọrí sí?

      20 Kété ṣáájú kí Jesu tó kú, àwọn aposteli rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọnyi yoo ṣẹlẹ̀, kí ni yoo sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ ati ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan?” (Matteu 24:3) Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì lórí ilẹ̀ ayé ṣáájú kí ‘òpin tó dé.’ Kété kí òpin náà tó dé, àwọn orílẹ̀-èdè yóò “rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹlu agbára ati ògo ńlá.”—Matteu 24:14, 29, 30.

      21 Ṣùgbọ́n, báwo ni nǹkan yóò ti rí fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí a ṣèwádìí nínú òwe àkàwé ti àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ náà: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn áńgẹ́lì pẹlu rẹ̀, nígbà naa ni oun yoo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ni a óò sì kó jọ níwájú rẹ̀.”—Matteu 25:31, 32.

      22, 23. Àwọn kókó wo ni ó fi hàn pé òwe àkàwé nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ kò bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmúṣẹ ní 1914?

      22 Òwe àkàwé yìí ha ní í ṣe pẹ̀lú 1914, nígbà tí Jesu jókòó nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ọba, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe lóye rẹ̀ tẹ́lẹ̀ bí? Tóò, Matteu 25:34 sọ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba, nítorí náà lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, òwe àkàwé náà ní í ṣe pẹ̀lú ìgbà tí Jesu ti di Ọba ní 1914. Ṣùgbọ́n ìdájọ́ wo ni ó ṣe ní kété lẹ́yìn náà? Kì í ṣe ìdájọ́ “gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn tí wọ́n ń sọ pé àwọn para pọ̀ jẹ́ “ilé Ọlọrun.” (1 Peteru 4:17) Ní ìbámu pẹ̀lú Malaki 3:1-3, Jesu, gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ Jehofa, bẹ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró tí ó ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ ayé wò láti ṣèdájọ́ wọn. Ó tún jẹ́ àkókò fún ìdájọ́ lórí Kristẹndọmu, tí ó fi èké jẹ́wọ́ pé òún jẹ́ “ilé Ọlọrun.”c (Ìṣípayá 17:1, 2; 18:4-8) Síbẹ̀, kò sí ohunkóhun tí ó fi hàn pé, nígbà náà lọ́hùn-ún, tàbí láti ìgbà náà wá, Jesu ti jókòó láti ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbẹ̀yìngbẹ́yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́.

      23 Bí a bá ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ ìgbòkègbodò Jesu nínú òwe àkàwé náà, a óò rí i pé, ó ṣèdájọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Òwe àkàwé náà kò fi hàn pé irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ yóò máa bá a nìṣó fún sáà gígùn ọlọ́dún púpọ̀, bí ẹni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń kú ní àwọn ẹ̀wádún tí ó ti kọjá wọ̀nyí ni a ti ṣèdájọ́ wọn pé, wọ́n yẹ fún ikú àìnípẹ̀kun tàbí ìyè àìnípẹ̀kun. Ó dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ó ti kú ní àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́ ti lọ sí isà okú ti gbogbo aráyé. (Ìṣípayá 6:8; 20:13) Ṣùgbọ́n, òwe àkàwé náà ń ṣàpèjúwe àkókò náà nígbà tí Jesu ń ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” tí wọ́n wà láàyè nígbà náà, tí wọ́n sì dojú kọ ìmúṣẹ ìdájọ́ rẹ̀.

      24. Nígbà wo ni òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ yóò ní ìmúṣẹ?

      24 Ní èdè mìíràn, òwe àkàwé náà ń tọ́ka sí ọjọ́ ọ̀la, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀. Òun yóò jókòó láti ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn tí ó bá wà láàyè nígbà náà. Yóò gbé ìdájọ́ rẹ̀ karí ohun tí wọ́n ti fi hàn pé àwọn fúnra wọn jẹ́. Ní àkókò yẹn “ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni búburú” yóò ti fìdí múlẹ̀ lọ́nà ṣíṣe kedere. (Malaki 3:18) Kíkéde ìdájọ́ náà ní ti gidi àti ìmúdàájọ́ṣẹ ni a óò ṣe ní àkókò tí ó mọ níwọ̀n. Jesu yóò ṣe àwọn ìpinnu tí ó tọ́, tí a gbé karí ohun tí ó ti hàn gbangba nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan.—Tún wo 2 Korinti 5:10.

      25. Kí ni Matteu 25:31 ṣàpèjúwe, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa Ọmọkùnrin ènìyàn, tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ológo?

      25 Nítorí náà, èyí túmọ̀ sí pé, ‘jíjókòó tí’ Jesu ‘jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀’ fún ìdájọ́, tí a mẹ́nu kàn nínú Matteu 25:31, ní í ṣe pẹ̀lú àkókò ọjọ́ ọ̀la, nígbà tí Ọba alágbára yìí yóò jókòó láti kéde ìdájọ́, kí ó sì múdàájọ́ ṣẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè. Bẹ́ẹ̀ ni, ìran ìdájọ́ tí ó kan Jesu ní Matteu 25:31-33, 46 ṣeé fi wé ìran inú Danieli orí 7, níbi tí Ọba tí ń ṣàkóso náà, Ẹni-àgbà ọjọ́ nì, ti jókòó láti ṣe ipa tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́.

      26. Àlàyé tuntun wo ní ó wá sí ojútáyé nípa òwe àkàwé náà?

      26 Lílóye òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ lọ́nà yìí fi hàn pé, ṣíṣèdájọ́ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ yóò jẹ́ ní ọjọ́ ọ̀la. Yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí “ìpọ́njú ńlá” náà tí a mẹ́nu kàn ní Matteu 24:29, 30 bá bẹ́ sílẹ̀, tí Ọmọkùnrin ènìyàn sì ‘dé nínú ògo rẹ̀.’ (Fi wé Marku 13:24-26.) Nígbà náà, nígbà tí ètò ìgbékalẹ̀ búburú látòkèdélẹ̀ bá ti lọ sí òpin rẹ̀, Jesu yóò pè àpèjọ ìdájọ́, yóò ṣèdájọ́, yóò sì múdàájọ́ ṣẹ.—Johannu 5:30; 2 Tessalonika 1:7-10.

      27. Kí ni a ní láti lọ́kàn ìfẹ́ sí láti mọ̀ nípa òwe àkàwé Jesu tí ó kẹ́yìn?

      27 Èyí mú òye wa nípa àkókò tí òwe àkàwé Jesu náà ní ìmúṣẹ ṣe kedere, èyí tí ó fi ìgbà tí a óò ṣèdájọ́ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ hàn. Ṣùgbọ́n báwo ni ó ṣe nípa lórí àwa tí a ń fi pẹ̀lú ìtara wàásù ìhìnrere Ìjọba náà? (Matteu 24:14) Ó ha dín ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ wa kù bí, tàbí ó mú ẹrù iṣẹ́ wíwúwo sí i wá bí? Ẹ jẹ kí a wo bí ó ṣe kàn wá nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.

  • Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | October 15
    • Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?

      “Oun yoo sì ya awọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùtàn kan tí ń ya awọn àgùtàn sọ́tọ̀ kúrò lára awọn ewúrẹ́.”—MATTEU 25:32.

      1, 2. Èé ṣe tí òwe àkàwé nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ fi ní láti ru ọkàn ìfẹ́ wa sókè?

      DÁJÚDÁJÚ, Jesu Kristi ni Olùkọ́ tí ó tóbi lọ́lá jù lọ tí ó tí ì gbé ayé rí. (Johannu 7:46) Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìkọ́ni rẹ̀ ni lílo àwọn òwe àkàwé, tàbí àwọn àkàwé. (Matteu 13:34, 35) Àwọn wọ̀nyí rọrùn, síbẹ̀, wọ́n lágbára ní gbígbin àwọn ìjìnlẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ òtítọ́ nípa tẹ̀mí síni lọ́kàn.

      2 Nínú òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, Jesu tọ́ka sí àkókò kan tí òun yóò gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà àkànṣe: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé ninu ògo rẹ̀, ati . . . ” (Matteu 25:31) Èyí yẹ kí ó ru ọkàn ìfẹ́ wa sókè nítorí pé, òun ni àkàwé tí Jesu fi kádìí èsì rẹ̀ sí ìbéèrè náà pé: “Kí ni yoo . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ ati ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan?” (Matteu 24:3) Ṣùgbọ́n kí ni èyí túmọ̀ sí fún wa?

      3. Ṣáájú nínú ìjíròrò rẹ̀, kí ni Jesu sọ pé yóò jẹ yọ kété lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá náà bá ti bẹ̀rẹ̀?

      3 Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ apàfiyèsí tí yóò ṣẹlẹ̀ “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn” ìbẹ́sílẹ̀ ìpọ́njú ńlá, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ń retí. Ó wí pé, nígbà náà ni “àmì Ọmọkùnrin ènìyàn” yóò fara hàn. Èyí yóò nípa jíjinlẹ̀ lórí “gbogbo awọn ẹ̀yà ilẹ̀-ayé” tí wọn yóò “rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹlu agbára ati ògo ńlá.” Ọmọkùnrin ènìyàn yóò wà pẹ̀lú “awọn áńgẹ́lì rẹ̀.” (Matteu 24:21, 29-31)a Kí ni nípa ti òwe àkàwé ti àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́? Àwọn Bibeli òde òní fi í sí orí 25, ṣùgbọ́n ó jẹ́ apá kan èsì Jesu, tí ó pèsè àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé síwájú sí i nípa bíbọ̀ rẹ̀ nínú ògo, tí ó sì darí àfiyèsí sórí ṣíṣe ìdájọ́ “gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.”—Matteu 25:32.

      Àwọn Ẹ̀dá Inú Òwe Àkàwé Náà

      4. Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ wo ni òwe àkàwé nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ sọ nípa Jesu, ẹlòmíràn wo sì ni ó wá sí ojútáyé?

      4 Jesu bẹ̀rẹ̀ òwe àkàwé náà ní sísọ pé: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé ninu ògo rẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kí o mọ ẹni tí “Ọmọkùnrin ènìyàn” náà jẹ́. Àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà fún Jesu. Jesu fúnra rẹ̀ pàápàá ṣe bẹ́ẹ̀, kó sì iyèméjì pé ó ní ìran Danieli lọ́kàn, nípa “ẹnì kan bí [ọmọkùnrin, NW] ènìyàn” tí ó wá sọ́dọ̀ Ẹni-àgbà ọjọ́ nì láti gba “agbára ìjọba . . . , àti ògo, àti ìjọba.” (Danieli 7:13, 14; Matteu 26:63, 64; Marku 14:61, 62) Bí Jesu tilẹ̀ jẹ́ ẹni títayọ nínú òwe àkàwé yìí, kò dá wà ní òun nìkan. Ṣáájú nínú ìjíròrò yìí, gẹ́gẹ́ bí a ti fà á yọ nínú Matteu 24:30, 31, ó wí pé nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn ‘bá wà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá,’ àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ yóò kó ipa ṣíṣe kókó. Bákan náà, òwe àkàwé ti àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ fi hàn pé, àwọn áńgẹ́lì wà pẹ̀lú Jesu, nígbà tí ó ‘jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀’ láti ṣèdájọ́. (Fi wé Matteu 16:27.) Ṣùgbọ́n, Onídàájọ́ náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ wà ní ọ̀run, nítorí náà, a ha jíròrò àwọn ẹ̀dá ènìyàn nínú òwe àkàwé náà bí?

      5. Báwo ni a ṣe lè dá “awọn arákùnrin” Jesu mọ̀ yàtọ̀?

      5 Wíwo òwe àkàwé náà fìrí ṣí àwọn ẹgbẹ́ mẹ́ta payá tí a ní láti mọ̀ yàtọ̀. Ní àfikún sí àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, Ọmọkùnrin ènìyàn fi ẹgbẹ́ kẹta náà kún un, àwọn tí ó ṣe pàtàkì láti dá mọ̀, láti lè dá àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ mọ̀ yàtọ̀. Jesu pe ẹgbẹ́ kẹta yìí ní àwọn arákùnrin òun nípa tẹ̀mí. (Matteu 25:40, 45) Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn olùjọ́sìn tòótọ́, nítorí Jesu wí pé: “Ẹni yòówù tí ó bá ń ṣe ìfẹ́-inú Baba mi . . . , oun kan naa ni arákùnrin, ati arábìnrin, ati ìyá mi.” (Matteu 12:50; Johannu 20:17) Ní àfikún sí kókó náà, Paulu kọ̀wé nípa àwọn Kristian, tí wọ́n jẹ́ apá kan “irú-ọmọ Abrahamu” tí wọ́n sì jẹ́ àwọn ọmọ Ọlọrun. Ó pe àwọn wọ̀nyí ni “awọn arákùnrin” Jesu àti “ajogún ní ìsopọ̀ pẹlu ìlérí.”—Heberu 2:9–3:1; Galatia 3:26, 29.

      6. Àwọn wo ni “awọn kíkéré julọ” nínú àwọn arákùnrin Jesu?

      6 Èé ṣe tí Jesu fi mẹ́nu kan “awọn kíkéré jùlọ” nínú àwọn arákùnrin rẹ̀? Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣe àtúnsọ ohun tí àwọn aposteli ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀ ṣáájú. Nígbà tí ó ń fi Johannu Oníbatisí, tí ó ti kú ṣáájú Jesu, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé wéra pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ní ìwàláàyè ti ọ̀run, Jesu wí pé: “A kò tí ì gbé ẹni kan dìde tí ó tóbi ju Johannu Oníbatisí lọ; ṣugbọn ẹni kan tí ó jẹ́ ẹni tí ó kéré jù ninu ìjọba awọn ọ̀run tóbi jù ú.” (Matteu 11:11) Àwọn kan tí ń lọ sí ọ̀run lè ti jẹ́ ẹni tí ó yọrí ọlá nínú ìjọ, bíi ti àwọn aposteli, tí àwọn yòókù sí rẹlẹ̀, ṣùgbọ́n arákùnrin Jesu nípa tẹ̀mí ní gbogbo wọn. (Luku 16:10; 1 Korinti 15:9; Efesu 3:8; Heberu 8:11) Nípa báyìí, kódà bí àwọn kan bá tilẹ̀ dà bí aláìṣe pàtàkì lórí ilẹ̀ ayé, arákùnrin rẹ̀ ni wọ́n jẹ́, a sì ní láti bá wọn lò lọ́nà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.

      Àwọn Wo Ni Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?

      7, 8. Kí ni Jesu sọ nípa àwọn àgùntàn, nítorí náà, ìparí èrò wo ni a lè dé nípa wọn?

      7 A kà nípa ṣíṣèdájọ́ àwọn àgùntàn pé: “[Jesu] yoo wí fún awọn wọnnì tí wọ́n wà ní ọ̀tún rẹ̀ pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín lati ìgbà pípilẹ̀ ayé. Nitori ebi pa mí ẹ sì fún mi ní nǹkan lati jẹ; òùngbẹ gbẹ mí ẹ sì fún mi ní nǹkan lati mu. Mo jẹ́ àjèjì ẹ sì gbà mí pẹlu ẹ̀mí aájò àlejò; mo wà ní ìhòòhò, ẹ sì fi aṣọ wọ̀ mí. Mo dùbúlẹ̀ àìsàn ẹ sì bójútó mi. Mo wà ninu ẹ̀wọ̀n ẹ sì wá sọ́dọ̀ mi.’ Nígbà naa ni awọn olódodo yoo fi ọ̀rọ̀ wọnyi dá a lóhùn pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni awa rí ọ tí ebi ń pa ọ́ tí a sì bọ́ ọ, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́, tí a sì fún ọ ní nǹkan lati mu? Nígbà wo ni awa rí ọ ní àjèjì tí a sì gbà ọ́ pẹlu ẹ̀mí aájò àlejò, tabi tí o wà ní ìhòòhò, tí a sì fi aṣọ wọ̀ ọ́? Nígbà wo ni awa rí ọ tí o ń ṣàìsàn tabi tí o wà ninu ẹ̀wọ̀n tí a sì lọ sọ́dọ̀ rẹ?’ Ní ìfèsìpadà ọba yoo sì wí fún wọn pé, ‘Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan ninu awọn kíkéré jùlọ ninu awọn arákùnrin mi wọnyi, ẹ̀yin ti ṣe é fún mi.’”—Matteu 25:34-40.

      8 Ó hàn gbangba pé, àwọn àgùntàn tí a dá láre láti wà ní ọwọ́ ọ̀tún ọlá àti ojú rere Jesu ṣàpẹẹrẹ ẹgbẹ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn. (Efesu 1:20; Heberu 1:3) Kí ni wọ́n ṣe, nígbà wo sì ni wọ́n ṣe é? Jesu sọ pé wọ́n fi pẹ̀lú inú rere, ọ̀wọ̀, àti ọ̀làwọ́ fún òun ní oúnjẹ, omi, àti aṣọ, tí wọ́n sì ran òun lọ́wọ́ nígbà tí òun dùbúlẹ̀ àìsàn tàbí nígbà tí òun wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Nígbà tí àwọn àgùntàn náà sọ pé àwọn fúnra wọn kò tí ì ṣe èyí fún Jesu, ó tọ́ka sí i pé, wọ́n ti àwọn arákùnrin òun nípa tẹ̀mí lẹ́yìn, àwọn àṣẹ́kù Kristian ẹni-àmì-òróró, nítorí náà ní ọ̀nà yẹn, wọn ti ṣe é fún òun.

      9. Èé ṣe tí òwe àkàwé náà kò fi ní í ṣe pẹ̀lú ìgbà Ẹgbẹ̀rúndún?

      9 Òwe àkàwé náà ní í ṣe pẹ̀lú àkókò Ẹgbẹ̀rúndún, nítorí pé àwọn ẹni-àmì-òróró náà, nígbà náà, kì yóò jẹ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ń jìyà ebi, òùngbẹ, àìsàn, tàbí ìfisẹ́wọ̀n. Àmọ́ ṣáá o, púpọ̀ lára wọn ti nírìírí irú rẹ̀ nígbà ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí. Láti ìgbà tí a ti lé Satani sọ̀kalẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé, ó ti dojú ìrunú rẹ̀ kọ àwọn àṣẹ́kù náà, ní mímú ìfiniṣẹ̀sín, ìdálóró, àti ikú wá sórí wọn.—Ìṣípayá 12:17.

      10, 11. (a) Èé ṣe tí kò fi lọ́gbọ́n nínú láti rò pé àwọn àgùntàn náà ní gbogbo ẹni tí ń fi inú rere hàn sí àwọn arákùnrin Jesu nínú? (b) Ta ni àwọn àgùntàn náà ń ṣojú fún lọ́nà yíyẹ?

      10 Ṣe ohun tí Jesu ń sọ ni pé, gbogbo ẹni tí ó bá ṣáà ti fi inú rere díẹ̀ hàn sí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ̀, irú bíi fífúnni ní ègé búrẹ́dì kan tàbí ife omi kan, ti tóótun gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn àgùntàn wọ̀nyí bí? Òtítọ́ ni pé, fífi irú inú rere bẹ́ẹ̀ hàn lè ṣàgbéyọ inú rere ẹ̀dá ènìyàn, ṣùgbọ́n ní ti gidi, ó dà bíi pé ohun púpọ̀ sí i wé mọ́ àwọn àgùntàn inú òwe àkàwé yìí. Fún àpẹẹrẹ, ó dájú ṣáká pé, kì í ṣe àwọn aláìgbọlọ́rungbọ́ tàbí àwùjọ àlùfáà tí wọ́n fi inú rere hàn sí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ̀ ní Jesu ń tọ́ka sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbà méjì ni Jesu pe àwọn àgùntàn ní “awọn olódodo.” (Matteu 25:37, 46) Nítorí náà, àwọn àgùntàn náà gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn kan tí wọ́n ti ṣèrànwọ́ jálẹ̀ sáà àkókò kan—nípa fífi taápọntaápọn ṣètìlẹ́yìn—fún àwọn arákùnrin Kristi, tí wọ́n sì ti lo ìgbàgbọ́ títí dé àyè rírí ìdúró òdodo gbà níwájú Ọlọrun.

      11 Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, ọ̀pọ̀ àwọn bí Abrahamu ti gbádùn ìdúró òdodo. (Jakọbu 2:21-23) Noa, Abrahamu, àti àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ wà lára “awọn àgùtàn mìíràn” tí yóò jogún ìyè nínú Paradise lábẹ́ Ìjọba Ọlọrun. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ púpọ̀ sí i ti tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn àgùntàn mìíràn, wọ́n sì ti di “agbo kan” pẹ̀lú àwọn ẹni-àmì-òróró. (Johannu 10:16; Ìṣípayá 7:9) Àwọn wọ̀nyí, tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé mọ àwọn arákùnrin Jesu gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣojú Ìjọba náà, wọ́n sì tìtoríi bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́—nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. Jesu ka ohun tí àwọn àgùntàn mìíràn náà ti ṣe fún àwọn arákùnrin òun lórí ilẹ̀ ayé sí ohun tí wọ́n ṣe sí òun. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tí wọ́n wà láàyè nígbà tí ó bà wá láti ṣèdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni a óò ṣèdájọ́ fún pé wọ́n jẹ́ àgùntàn.

      12. Èé ṣe tí àwọn àgùntàn náà fi lè béèrè bí wọ́n ti ṣe hùwà inú rere sí Jesu?

      12 Bí àwọn àgùntàn mìíràn bá ń wàásù ìhìn rere náà nísinsìnyí pẹ̀lú àwọn ẹni-àmì-òróró, tí wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ fún wọn, èé ṣe tí wọn yóò fi béèrè pé: “Oluwa, nígbà wo ni awa rí ọ tí ebi ń pa ọ́ tí a sì bọ́ ọ, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́, tí a sì fún ọ ní nǹkan lati mu?” (Matteu 25:37) Ìdí púpọ̀ ni ó lè wà. Òwe àkàwé ni èyí jẹ́. Nípa rẹ̀, Jesu fi ìdàníyàn rẹ̀ jíjinlẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí; àánú wọn ṣe é, ó jìyà pẹ̀lú wọn. Jesu ti sọ ṣáájú pé: “Ẹni tí ó bá gbà yín gbà mí pẹlu, ẹni tí ó bá sì gbà mí gba ẹni naa pẹlu tí ó rán mi jáde.” (Matteu 10:40) Nínú àkàwé yìí, Jesu nasẹ̀ ìlànà náà síwájú sí i, ní fífi hàn pé ohun tí a bá ṣe (ìbáà jẹ́ rere tàbí búburú) sí àwọn arákùnrin rẹ̀ ń dé ọ̀run pàápàá; ṣe ni ó dà bíi pé, a ṣe é sí i ní ọ̀run. Bákan náà, níhìn-ín, Jesu ń tẹnu mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n Jehofa fún ṣíṣèdájọ́, ní mímú kí ó ṣe kedere pé ìdájọ́ Ọlọrun, yálà ó dáni láre tàbí ó dáni lẹ́bi, tọ́ ó sì yẹ. Àwọn ewúrẹ́ kò lè rí àwáwí ṣe pé, ‘Tóò, ká ní a ti rí ọ ní tààràtà ni.’

      13. Èé ṣe tí àwọn ẹni bí ewúrẹ́ fi pe Jesu ní “Oluwa”?

      13 Lẹ́yìn tí a bá ti lóye ìgbà tí a ṣe ìdájọ́ náà tí a fi hàn nínú òwe àkàwé yìí, a óò ní ojú ìwòye tí ó túbọ̀ ṣe kedere sí i nípa ẹni tí àwọn ewúrẹ́ náà jẹ́. Ìmúṣẹ náà yóò jẹ́ nígbà tí “àmì Ọmọkùnrin ènìyàn yoo farahàn ní ọ̀run, nígbà naa sì ni gbogbo awọn ẹ̀yà ilẹ̀-ayé yoo lu ara wọn ninu ìdárò, wọn yoo sì rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ . . . pẹlu agbára ati ògo ńlá.” (Matteu 24:29, 30) Àwọn olùla ìpọ́njú tí yóò dé sórí Babiloni Ńlá já, tí wọ́n ti fojú tẹ́ḿbẹ́lú àwọn arákùnrin Ọba náà, nísinsìnyí lè máa fi ìgbékútà pe Onídàájọ́ náà ní “Oluwa,” ní ìrètí pe èyí yóò gbà ẹ̀mí wọn là.—Matteu 7:22, 23; fi wé Ìṣípayá 6:15-17.

      14. Lórí ìpìlẹ̀ wo ni Jesu yóò fi ṣèdájọ́ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́?

      14 A kì yóò gbé ìdájọ́ Jesu karí àwọn ìjẹ́wọ́ tí àwọn olùreṣọ́ọ̀ṣì tẹ́lẹ̀, àwọn aláìgbọlọ́rungbọ́, tàbí àwọn mìíràn fi ìgbékútà ṣe. (2 Tessalonika 1:8) Dípò bẹ́ẹ̀, onídàájọ́ náà yóò tún ipò ọkàn àti ìwà àwọn ènìyàn náà látẹ̀yìnwá wò, pàápàá sí “ọ̀kan ninu awọn ẹni kíkéré jùlọ wọ̀nyí [nínú àwọn arákùnrin rẹ̀].” Òtítọ́ ni pé, iye àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró tí ó kù sórí ilẹ̀ ayé ń dín kù. Bí ó ti wù kí ó rí, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ẹni-àmì-òróró, tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú,” bá ṣì ń bá a lọ láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí àti ìdarísọ́nà, àwọn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n di àgùntàn ní àǹfààní láti ṣe rere sí ẹgbẹ́ ẹrú náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí ‘ogunlọ́gọ̀ ńlá láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo àti ẹ̀yà àti ènìyàn’ ti ṣe.—Ìṣípayá 7:9, 14.

      15. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́? (b) Èé ṣe tí a fi ní láti yẹra fún sísọ pé ẹnì kan jẹ́ àgùntàn tàbí ewúrẹ́?

      15 Báwo ni a ti ṣe bá àwọn arákùnrin Kristi àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn àgùntàn mìíràn tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí agbo kan lò? Ọ̀pọ̀ ènìyàn fúnra wọn lè máà gbéjà ko àwọn aṣojú Kristi, ṣùgbọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò fi ìfẹ́ bá àwọn ènìyàn rẹ̀ lò. Nítorí wọ́n yan ayé búburú náà láàyò, àwọn ẹni bí ewúrẹ́ kọ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, yálà wọ́n gbọ́ ọ ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà. (1 Johannu 2:15-17) Àmọ́ ṣáá o, lópin gbogbo rẹ̀, Jesu ni ẹni náà tí a yàn sípò láti ṣèdájọ́. Kì í ṣe tiwa láti pinnu àwọn tí wọ́n jẹ́ àgùntàn àti àwọn tí wọ́n jẹ́ ewúrẹ́.—Marku 2:8; Luku 5:22; Johannu 2:24, 25; Romu 14:10-12; 1 Korinti 4:5.

      Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà fún Ẹgbẹ́ Kọ̀ọ̀kan?

      16, 17. Ọjọ́ ọ̀la wo ni àwọn àgùntàn ní?

      16 Jesu sọ ìdájọ́ rẹ̀ nípa àwọn àgùntàn náà pè: “Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín lati ìgbà pípilẹ̀ ayé.” Ẹ wo irú ìkésíni ọlọ́yàyà tí èyí jẹ́—“Ẹ wá”! Sínú kí ni? Sínú ìyè àìnípẹ̀kun, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ ní ṣókí pé: “Awọn olódodo [yóò bọ́] sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Matteu 25:34, 46.

      17 Nínú òwe àkàwé àwọn tálẹ́ńtì, Jesu fi ohun tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tí yóò ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run hàn, ṣùgbọ́n nínú òwe àkàwé yìí, ó fi ohun tí a ń retí lọ́wọ́ àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà hàn. (Matteu 25:14-23) Ní pàtó, nítorí ìtìlẹ́yìn tí wọ́n fi tọkàntọkàn ṣe sí àwọn arákùnrin Jesu, àwọn àgùntàn náà jogún ayè kan nínú pápá àkóso ilẹ̀ ayé ti Ìjọba rẹ̀. Wọn yóò gbádùn ìwàláàyè nínú Paradise lórí ilẹ̀ ayé—ìfojúsọ́nà tí Ọlọrun múra sílẹ̀ fún wọn “lati ìgbà pípilẹ̀ ayé” àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ṣeé rà padà.—Luku 11:50, 51.

      18, 19. (a) Ìdájọ́ wo ni Jesu yóò fún àwọn ewúrẹ́? (b) Báwo ni a ṣe lè ní ìdánilójú pé àwọn ewúrẹ́ kì yóò dojú kọ ìjìyà ayérayé?

      18 Ẹ wo bí ìdájọ́ tí a mú ṣẹ sórí àwọn ewúrẹ́ ti jẹ́ òdì kejì tó! “Nígbà naa ni oun yoo wí, ẹ̀wẹ̀, fún awọn wọnnì tí wọ́n wà ní òsì rẹ̀ pé, ‘Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin tí a ti gégùn-ún fún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti pèsè sílẹ̀ fún Èṣù ati awọn áńgẹ́lì rẹ̀. Nitori ebi pa mí, ṣugbọn ẹ̀yin kò fún mi ní nǹkankan lati jẹ, òùngbẹ sì gbẹ mí, ṣugbọn ẹ̀yin kò fún mi ní nǹkankan lati mu. Mo jẹ́ àjèjì, ṣugbọn ẹ̀yin kò gbà mí pẹlu ẹ̀mí aájò àlejò; mo wà ní ìhòòhò, ṣugbọn ẹ̀yin kò fi aṣọ wọ̀ mí; mo ṣàìsàn mo sì wà ninu ẹ̀wọ̀n, ṣugbọn ẹ̀yin kò tọ́jú mi.’ Nígbà naa ni awọn pẹlu yoo fi ọ̀rọ̀ wọnyi dáhùn pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni awa rí ọ tí ebi ń pa ọ́ tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́ tabi tí o jẹ́ àjèjì tabi tí o wà ní ìhòòhò tabi tí o ń ṣàìsàn tabi tí o wà ninu ẹ̀wọ̀n tí a kò sì ṣe ìránṣẹ́ fún ọ?’ Nígbà naa ni oun yoo fi ọ̀rọ̀ wọnyi dá wọn lóhùn pé, ‘Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin kò ṣe é fún ọ̀kan ninu awọn ẹni kíkéré jùlọ wọnyi, ẹ̀yin kò ṣe é fún mi.’”—Matteu 25:41-45.

      19 Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mọ̀ pé èyí kò lè túmọ̀ sí pé, ọkàn àìleèkú ti àwọn ẹni bí ewúrẹ́ yóò jìyà nínú iná ayérayé. Ó tì o, nítorí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ni ọkàn; wọn kò ní ọkàn àìleèkú. (Genesisi 2:7; Oniwasu 9:5, 10; Esekieli 18:4) Nípa ṣíṣèdájọ́ “iná àìnípẹ̀kun” fún àwọn ewúrẹ́ náà, Onídàájọ́ náà ní ìparun tí kò ní ìrètí ọjọ ọ̀la lọ́kàn, èyí tí yóò jẹ́ òpin pátápátá fún Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ pẹ̀lú. (Ìṣípayá 20:10, 14) Nípa báyìí, Onídàájọ́ ti Jehofa gbé àwọn ìdájọ́ yíyàtọ̀ síra kalẹ̀. Ó sọ fún àwọn àgùntàn pé, “Ẹ wá”; ó sì wí fún àwọn ewúrẹ́ pé, “Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n kúrò lọ́dọ̀ mi.” Àwọn àgùntàn yóò jogún “ìyè àìnípẹ̀kun.” Àwọn ewúrẹ́ yóò sì gbà “ìkékúrò àìnípẹ̀kun.”—Matteu 25:46.b

      Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí fún Wa?

      20, 21. (a) Iṣẹ́ pàtàkì wo ni àwọn Kristian ní láti ṣe? (b) Ìyàsọ́tọ̀ wo ní ń lọ lọ́wọ́? (d) Báwo ni nǹkan yóò ṣe rí fún àwọn ènìyàn nígbà tí òwe àkàwé nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ bá bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmúṣẹ?

      20 Àwọn aposteli mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n gbọ́ ìdáhùn Jesu nípa àmì wíwà níhìn-ín rẹ̀ àti òpin ètò ìgbékalẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti gbé yẹ̀wò. Wọn yóò ní láti wà lójúfò, kí wọ́n sì máa ṣọ́nà. (Matteu 24:42) Wọn yóò tún ní láti ṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí tí a mẹ́nu kàn ní Marku 13:10. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fi tokunratokunra lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà lónìí.

      21 Ṣùgbọ́n, kí ni òye tuntun yìí nípa òwe àkàwé ti àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ túmọ̀ sí fún wa? Tóò, àwọn ènìyàn ti ń yan ìhà tí wọn yóò wà. Àwọn kan wà ní ‘ojú ọ̀nà gbígbòòrò tí ó lọ sí ìparun,’ nígbà tí àwọn mìíràn gbìyànjú láti dúró ní ‘ojú ọ̀nà tóóró tí ó lọ sí ìyè.’ (Matteu 7:13, 14) Ṣùgbọ́n, àkókò náà tí Jesu yóò kéde ìdájọ́ ìkẹyìn lórí àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ tí a ṣàpèjúwe nínú òwe àkàwé náà ṣì wà níwájú. Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá wá nínú ipa iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́, òun yóò pinnu pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristian tòótọ́—ní ti gidi, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti àwọn àgùntàn tí wọ́n ti ṣe ìyàsímímọ́—yóò tóótun láti la apá ìkẹyìn “ìpọ́njú ńlá naa” já sínú ayé tuntun. Ìfojúsọ́nà náà ní láti jẹ́ orísun ìdùnnú nísinsìnyí. (Ìṣípayá 7:9, 14) Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ láti inú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” yóò ti fi ẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́ olórí kunkun bí ewúrẹ́. Wọn “yoo kọjá sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun.” Ẹ wo irú ìtura tí èyí yóò jẹ́ fún ilẹ̀ ayé!

      22, 23. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìmúṣẹ òwe àkàwé náà jẹ́ ní ọjọ́ ọ̀la, èé ṣe tí iṣẹ́ ìwàásù wa lónìí fi ṣe pàtàkì?

      22 Bí ìdájọ́ náà tí a ṣàpèjúwe nínú òwe àkàwé tilẹ̀ ṣì wà ní ọjọ́ ọ̀la tí kò jìnnà mọ́, àní nísinsìnyí pàápàá, ohun pàtàkì kan ń ṣẹlẹ̀. Àwa Kristian ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà kan ti pípolongo ìhìn iṣẹ́ kan tí ń fa ìyapa láàárín àwọn ènìyàn. (Matteu 10:32-39) Paulu kọ̀wé pé: “Nitori ‘olúkúlùkù ẹni tí ń ké pe orúkọ Jehofa ni a óò gbàlà.’ Bí ó ti wù kí ó rí, bawo ni wọn yoo ṣe ké pe ẹni tí wọn kò lo ìgbàgbọ́ ninu rẹ̀? Bawo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yoo ṣe lo ìgbàgbọ́ ninu ẹni tí wọn kò gbọ́ nipa rẹ̀? Bawo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yoo ṣe gbọ́ láìsí ẹni kan lati wàásù?” (Romu 10:13, 14) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú orúkọ Ọlọrun àti ìhìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ̀ ń dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ tí ó lé ní 230. Àwọn ẹni-àmì-òróró arákùnrin Kristi ṣì ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ yìí. Nǹkan bí mílíọ̀nù márùn-ún àwọn àgùntàn mìíràn ti dara pọ̀ mọ́ wọn nísinsìnyí. Àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé sì ń dáhùn padà sí ìhìn iṣẹ́ náà tí àwọn arákùnrin Jesu ń pòkìkí.

      23 Ọ̀pọ̀ ti gbọ́ ìhìn iṣẹ́ wa bí a ti ń wàásù láti ilé dé ilé tàbí láìjẹ́ bí àṣà. Àwọn mìíràn lè kọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti ohun tí a ń ṣojú fún ní àwọn ọ̀nà tí a kò mọ̀. Nígbà tí àkókò ìdájọ́ bá dé, títí dé àyè wo ni Jesu yóò fi ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀bi àjùmọ̀pín àti ìtóye ìdílé? A kò lè sọ, kò sí ìdí kankan láti méfò. (Fi wé 1 Korinti 7:14.) Nísinsìnyí, ọ̀pọ̀ ń kọ etí ikún sí wa, wọ́n ń fi wa ṣe yẹ̀yẹ́, tàbí nípìn-ín nínú ṣíṣe inúnibíni ní tààràtà sí àwọn ènìyàn Ọlọrun. Nítorí náà, àkókò pàtàkì ni a wà yìí; irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè dàgbà di àwọn ẹni tí Jesu yóò ṣèdájọ́ wọn pé wọ́n jẹ́ ewúrẹ́.—Matteu 10:22; Johannu 15:20; 16:2, 3; Romu 2:5, 6.

      24. (a) Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láti dáhùn padà lọ́nà rere sí ìwàásù wa? (b) Ìṣarasíhùwà wo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ti ràn ọ́ lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan láti ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?

      24 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a láyọ̀ pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń dáhùn padà lọ́nà rere, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, wọ́n sì ń di Ẹlẹ́rìí fún Jehofa. Àwọn kan tí wọ́n dà bí ewúrẹ́ nìsinsìnyí lè yí padà, kí wọ́n sì di àgùntàn. Kókó náà ni pé, àwọn tí ń dáhùn padà, tí wọ́n sì ń ti àwọn àṣẹ́kù arákùnrin Kristi lẹ́yìn taápọntaápọn, ń tipa báyìí pèsè ẹ̀rí nìsinsìnyí tí yóò pèsè ìpìlẹ̀ fún wọn láti wà ní ọwọ́ ọ̀tún Jesu nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣèdájọ́, ní ọjọ́ ọ̀la tí kò jìnnà mọ́. A ti bù kún àwọn wọ̀nyí, a óò sì tún máa bù kún wọn. Nípa báyìí, òwe àkàwé yìí yẹ kí ó gbún wa ní kẹ́ṣẹ́ sí ìgbòkègbodò onítara púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian. Kí ó tó pẹ́ jù, a fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti pòkìkí ìhìn rere Ìjọba náà, ní ọ̀nà yẹn, a óò sì lè fún àwọn ẹlòmíràn ní àǹfààní láti dáhùn padà. Lẹ́yìn náà yóò kù sọ́wọ́ Jesu láti ṣèdájọ́, ẹ̀bi tàbí àre.—Matteu 25:46.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́