ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Gbogbo Èèyàn Ló Ń Ṣàníyàn!
    Ilé Ìṣọ́—2015 | July 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ BORÍ ÀNÍYÀN

      Gbogbo Èèyàn Ló Ń Ṣàníyàn!

      “Oúnjẹ ni mo ni kí n lọ rà àmọ́ bisikíìtì nìkan ni mo rí lórí igbá, ó sì fi ìlọ́po ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ju iye tí wọ́n ń tà á tẹ́lẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọjọ́ kejì, kò tiẹ̀ wá sí oúnjẹ kankan mọ́.”—Paul, orílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè.

      “Ọ̀sán kan òru kan ni ọkọ mi já mi jù sílẹ̀ tó lóun ń lọ. Ọ̀rọ̀ náà dùn mí wọra. Kí lo máa wá ṣẹlẹ̀ sí èmi àti àwọn ọmọ mi?”—Janet, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

      “Nígbà tí aago ìkìlọ̀ dún, mó sáré lọ fara pa mọ́, mo sì dọ̀bálẹ̀ gbalaja, bí bọ́ǹbù ṣe ń bú gbàù-gbàù. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, ara mi ṣì ń gbọ̀n.”—Alona, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.

      Ọkùnrin kan tó ń ṣàníyàn nípa ogun, àtijẹ-àtimú, àrùn, àtàwọn ìṣòrò míì tó ń bá a fínra

      Àkókò tí àníyàn gbalẹ̀ gbòde là ń gbé, “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1) Oríṣiríṣi ìṣòro ló ń bá wa fínra, bí ìṣòro ìṣúnná owó, ìgbéyàwó tó forí ṣánpọ́n, ogun, àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí àtàwọn àjálù tó dédé wáyé tàbí èyí táwọn èèyàn fọwọ́ ara wọn fà. Òmíràn sì máa ń dá lórí àwọn ìṣòro ara ẹni. Bí àpẹẹrẹ, àwọn míì lè máa ṣàníyàn pé, ‘Ṣé ìfúnpá mi tó ga yìí kò ní yọrí sí àrùn rọpá-rọsẹ̀?’ ‘Ǹjẹ́ inú ayé burúkú yìí náà ni àwọn ọmọ-ọmọ mi máa dàgbà sí?’

      Kì í ṣe gbogbo àníyàn ló burú. A sábà máa ń ṣàníyàn tá a bá fẹ́ ṣe ìdánwò, tá a bá fẹ́ lọ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò láti ríṣẹ́ tàbí àwọn nǹkan míì. Lóòótọ́ ó yẹ ká máa bẹ̀rù, torí ìyẹn ni kò ní jẹ́ ká kó sínú ewu, ó ṣe tán, ẹyẹ ìbẹ̀rù ló ń tọ́jọ́. Àmọ́, ewu tún wà nínú kéèyàn máa ṣe àníyàn àṣejù. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí láàárín àwọn àgbàlagbà tí iye wọn lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́rin [68,000] fi hàn pé, àníyàn díẹ̀ pàápàá lè mú kéèyàn kú ní rèwerèwe. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi béèrè pé: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?” Ká sòótọ́, ńṣe ni àníyàn máa ń ké ẹ̀mí èèyàn kúrú. Abájọ tí Jésù fi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn.” (Mátíù 6:25, 27) Kí la lè ṣe láti dín àníyàn kù?

      Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ò le, ó gba pé ká máa fọgbọ́n hùwà, ká ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú Ọlọ́run ká sì gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ó ṣeé ṣe kí a má ní ìṣòro lílekoko báyìí, àmọ́ nǹkan lè yí pa dà bírí. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Paul, Janet àti Alona ṣe kí wọ́n lè borí àníyàn wọn.

  • Àníyàn Nípa Owó
    Ilé Ìṣọ́—2015 | July 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ BORÍ ÀNÍYÀN

      Àníyàn Nípa Owó

      Baálé ilé ni Paul, ó sì ní ọmọ méjì. Ó sọ pé: “Nígbà kan owó ọjà fò sókè lọ́sàn-án kan orù kan lórílẹ̀-èdè wa, gbogbo nǹkan sì di ọ̀wọ́n gógó, àtijẹ àtimu pàápàá di ìṣòro. Ńṣe la máa ń tò sórí ìlà fún ọ̀pọ̀ wákàtí, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, nígbà tá a bá fi máa dé iwájú, oúnjẹ á ti tán. Ebi pa àwọn èèyàn débi pé ńṣe ni wọ́n rù hangogo, kódà ebi pa àwọn kan kú sójú títì. Gbogbo nǹkan tá à ń rà pátá ló gbowó lórí gegere. Nígbà tó yá, owó wa kò níye lórí mọ́. Gbogbo owó tí mo ní ní báńkì, owó ìbánigbófò mi àti owó ìfẹ̀yìntì mi pátá ló ṣòfò.”

      Bí kò ti sí oúnjẹ mọ́ nílùú, Paul wá ọ̀nà míì táá fi lè máa gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀

      Paul

      Paul mọ̀ pé, òun nílò “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́,” kí òun àti ìdílé rẹ̀ lè máa rí oúnjẹ jẹ. (Òwe 3:21) Ó sọ pé: “Iṣẹ́ mànàmáná ni mò ń ṣe àmọ́ gbogbo iṣẹ́ tó bá ṣáà ti yọjú ni mò ń gbà. Owó tí wọ́n ń san fún mi kéré gan-an sí iye tó yẹ kí n gbà. Nígbà míì, oúnjẹ làwọn kan máa gbé fún mi tàbí ohun èèlò míì. Tí wọ́n bá fún mi ní ọṣẹ mẹ́rin, màá lo méjì màá sì ta méjì tó kù. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo rí ogójì [40] ọmọ adìyẹ gbà. Nígbà tí wọ́n dàgbà, mo tà wọ́n, mo sì fowó rẹ̀ ra ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] míì. Nígbà tó yá, mo fi àádọ́ta [50] adìyẹ ṣe pàṣípààrọ̀ fún àpò àgbàdo lílọ̀ méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì wúwo tó àpò sìmẹ́ǹtì kan. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni ìdílé mi àtàwọn míì fi jẹ ẹ́.”

      Paul mọ̀ pé ohun tó dáa jù téèyàn lè ṣe nírú ipò yìí ni pé kó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá. Tá a bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, yóò ràn wá lọ́wọ́. Ní ti àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé, Jésù sọ pé: “Ẹ sì jáwọ́ nínú àníyàn àìdánilójú; nítorí . . . Baba yín mọ̀ pé ẹ nílò nǹkan wọ̀nyí.”—Lúùkù 12:29-31.

      Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé olórí ọ̀tá Ọlọ́run, ìyẹn Sátánì, ti fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mú ọ̀pọ̀ èèyàn láti máa fi gbogbo ìgbésí ayé wọn kó ohun ìní jọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe àníyàn nípa àwọn ohun tó wù wọ́n yálà wọ́n nílò rẹ̀ àbí wọn ò nílò rẹ̀. Wọ́n sì ń ṣe kìràkìtà kí wọ́n lè ní àwọn nǹkan tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nílò. Ọ̀pọ̀ ló sì máa ń di onígbèsè, wọ́n á wá gbà tipátipá pé ‘ayá-nǹkan ni ìránṣẹ́ awínni.’—Òwe 22:7.

      Àwọn kan máa ń kù gìrì ṣe ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu. Paul sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ ń gbé ládùúgbò ló fi ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ síṣẹ́ olówó ńlá nílẹ̀ òkèèrè. Àwọn kan nínú wọn kò sì rí iṣẹ́ tí wọ́n wá lọ torí wọn kò ní ìwé ìgbélùú tó yẹ. Wọ́n wá dẹni tó ń sun ojú títì, wọ́n á máa sá kiri kí ọwọ́ ìjọba má báa tẹ̀ wọ́n. Wọn ò ṣe ohun táá mú kí Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́ ńṣe lèmi àti ìdílé mi pinnu láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ ká lè kojú ìṣòro ìṣúnná owó.”

      TẸ̀ LÉ ÌMỌ̀RÀN JÉSÙ

      Paul ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Jésù sọ pé: ‘Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.’ Torí náà, ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọ́run lójoojúmọ́ kò ju pé kó fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa, kí ebi má baà pa wá kú. Ọlọ́run sì pèsè fún wa lóòótọ́ bí Jésù ti ṣèlérí. Kì í ṣe gbogbo ìgbà la máa ń rí oúnjẹ tó wù wá jẹ. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan mo lọ tò sórí ìlà láti ra oúnjẹ, láì tiẹ̀ mọ irú oúnjẹ tí wọ́n ń tà. Nígbà tó fi máa kàn mí, mo rí i pé yúgọ́ọ̀tì ni. Èmi ò sì fẹ́ràn yúgọ́ọ̀tì. Àmọ́ oúnjẹ náà ni, òun la sì mu sùn lálẹ́ ọjọ́ náà. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé jálẹ̀ gbogbo àkókò yẹn, èmi àti ìdílé mi ò sùn lébi rí.”a

      Ọlọ́run ti ṣèlérí pé: “Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Hébérù 13:5

      “Nǹkan ti wá ń sàn fún wa báyìí. Àmọ́ a ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí pé ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run kò ní jẹ́ ká máa ṣàníyàn. Ó dájú pé Jèhófàb ò ní fi wá sílẹ̀, tá a bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nìṣó. A ti wá rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Sáàmù 34:8 tó sọ pé: ‘Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere; aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di í.’ Torí náà, tí ètò ọrọ̀ ajé bá tiẹ̀ tún dẹnu kọlẹ̀, a ò ní bẹ̀rù.

      Paul ń gbàdúrà sórí oúnjẹ kékeré kan pẹ̀lú aya àti ọmọbìnrin rẹ̀

      Ọlọ́run máa ń pèsè ‘oúnjẹ òòjọ́’ fáwọn olóòótọ́

      “Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé wa pé oúnjẹ láwa èèyàn nílò láti gbé ẹ̀mí wa ró, kì í ṣe iṣẹ́ tàbí owó. À ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Ọlọ́run máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé: ‘Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ yóò wá wà lórí ilẹ̀.’ Àmọ́ kó tó di ìgbà náà, ‘bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.’ Ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí tún máa ń fún wa lókun, ó ní: ‘Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí òun ti wí pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” Kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà.”’”c

      Ká tó lè bá ‘Ọlọ́run rìn,’ ó gba pé ká ní ojúlówó ìgbàgbọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 6:9) Yálà a ní ìṣòro ìṣúnná owó báyìí àbí bóyá lọ́jọ́ iwájú, a ti kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì lára Paul torí ìgbàgbọ́ tó ní àti ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ tó lò.

      Àmọ́ tó bá wá jẹ́ pé ìṣòro ìdílé ló ń fa àníyàn ńkọ́?

      a Wo Mátíù 6:11, 34.

      b Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

      c Wo Sáàmù 72:16; 1 Tímótì 6:8; Hébérù 13:5, 6.

  • Àníyàn Nípa Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́—2015 | July 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ BORÍ ÀNÍYÀN

      Àníyàn Nípa Ìdílé

      Janet sọ pé: “Kò pẹ́ tí Bàbá mi kú ni ọkọ mi sọ fún mi pé òun ti ní ẹlòmíì tí òun ń fẹ́. Ọ̀sán kan òru kan ló kó ẹrù rẹ̀, tó sì fi èmi àti ọmọ méjì sílẹ̀ láì dágbére fún wa tẹ́lẹ̀.” Janet ríṣẹ́, àmọ́ owó tó ń gbà kò tó san owó ilé wọn. Ọ̀rọ̀ ìṣúnná owó nìkan kọ́ ni ìṣòro tó ní. Janet sọ pé: “Ti pé èmi nìkan ni gbogbo bùkátà náà já lé léjìká máa ń kó ìpayà bá mi. Ó sì ń dùn mí pé mi ò lè pèsè gbogbo ohun táwọn ọmọ mi nílò bí àwọn òbí míì ti ń ṣe. Kódà, mo máa ń ronú nípa ojú tí àwọn èèyàn fi ń wo èmi àtàwọn ọmọ mi. Bóyá wọ́n tiẹ̀ ń wò mí bíi pé mi ò ṣe ohun tó yẹ kí n ṣe ló jẹ́ kí ìgbéyàwó mi forí ṣánpọ́n.”

      Janet sọ̀rọ̀ nípa bí ọkọ rẹ ṣe jà a jù sílẹ̀ lọ́sàn-án kan òru kan

      Janet

      Àdúrà máa ń ran Janet lọ́wọ́ láti gbé àròdùn náà kúrò lọ́kàn, kó sì pọkàn pọ̀ sórí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Janet sọ pé: “Tó bá ti di alẹ́, tí gbogbo nǹkan sì pa rọ́rọ́, ńṣe ni ìrònú yìí á tún gbà mí lọ́kàn. Àmọ́, tí mo bá gbàdúrà tí mo sì ka Bíbélì, mo máa ń rí oorun sùn. Ọ̀kan nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ràn mí lọ́wọ́ ni Fílípì 4:6, 7, tó sọ pé: ‘Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.’ Tí mo bá ti gbàdúrà lóru, ńṣe ni Jèhófà máa ń fi àlàáfíà rẹ̀ jíǹkí mi, èyí sì máa ń tù mí nínú.”

      Nígbà tí Jésù ń wàásù lórí òkè, ó sọ̀rọ̀ nípa àdúrà. Ohun tó sọ sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí a bá ń ṣàníyàn, ó ní: “Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.” (Mátíù 6:8) Lóòótọ́, ó yẹ ká máa gbàdúrà torí pé àdúrà ló máa jẹ́ ká “sún mọ́ Ọlọ́run.” Tá a bá sì sún mọ́ Ọlọ́run, ‘òun náà máa sún mọ́ wa.’—Jákọ́bù 4:8.

      Àǹfààní tí àdúrà ń ṣe wá kọjá kó kàn fi wá lọ́kàn balẹ̀ tá a bá ń ṣàníyàn. Jèhófà tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà,” tún máa wá nǹkan ṣe sí ìṣòro àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Sáàmù 65:2) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa “gbàdúrà nígbà gbogbo àti láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀.” (Lúùkù 18:1) A gbọ́dọ̀ máa bẹ Ọlọ́run pé kó tọ́ wa sọ́nà, kó sì ràn wá lọ́wọ́, ká sì gbà pé ó máa dáhùn àdúrà wa torí ìgbàgbọ́ tá a ní. A kò gbọ́dọ̀ ṣiyèméjì nípa bóyá ó máa dáhùn tàbí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń “gbàdúrà láìdabọ̀,” èyí á fi hàn pé ìgbàgbọ́ wa jinlẹ̀ lóòótọ́.—1 Tẹsalóníkà 5:17.

      OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI NÍ ÌGBÀGBỌ́

      Àmọ́, kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́? Kéèyàn ní ìgbàgbọ́ gba pé kẹ́ni náà mọ Ọlọ́run dáadáa. (Jòhánù 17:3) Tá a bá fẹ́ mọ Ọlọ́run, ohun àkọ́kọ́ ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ nínú Bíbélì. A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run ń rí wa, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ ju pé ká kàn mọ nǹkan kan nípa Ọlọ́run, ó tún gba pé ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Èèyàn ò lè ní irú àjọṣe yìí lọ́sàn kan òru kan. Torí náà, bá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run, tá à ń “ṣe ohun tí ó wù ú,” tá a sì ń ronú nípa àwọn oore tó ń ṣe fún wa, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wa “yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i gidigidi.” (Jòhánù 8:29; 2 Kọ́ríńtì 10:15) Irú ìgbàgbọ́ yìí ló ran Janet lọ́wọ́ láti kojú àwọn àníyàn rẹ̀.

      Janet sọ pé: “Bí mo ṣe ń rọ́wọ́ Ọlọ́run nínú gbogbo nǹkan tí mò ń dáwọ́ lé ti mú kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń wà nínú ipò tó jọ pé kò sọ́nà àbáyọ. Àmọ́ pẹ̀lú àdúrà, ńṣe ni Jèhófà máa ń kó wa yọ nínú àwọn ipò yẹn lọ́nà tí mi ò tiẹ̀ lérò rárá. Tí mo bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, mo máa ń rántí gbogbo oore tó ti ṣe fún mi. Kò sígbà kan tá a nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ tí kò ṣe é fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, ó fún mi láwọn ọ̀rẹ́ gidi lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ Kristẹni. Wọ́n ti dúró tì mí gbágbáágbá nígbà ìṣòro, wọ́n sì tún jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fún àwọn ọmọ mi.”a

      Ìyá kan ń bá ọmọ rẹ̀ ṣeré

      Janet ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mo mọ ìdí tí Jèhófà fi sọ pé ‘òun kórìíra ìkọ̀sílẹ̀’ nínú Málákì 2:16. Òun ni ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó máa ń duni jù lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá tí ọkọ mi ti fi mí sílẹ̀, síbẹ̀ ẹ̀dùn ọkàn yẹn ò tíì tán lára mi. Tí ìrònú yìí bá ti sọ sí mi lọ́kàn, mo máa ń gbìyànjú láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, èyí sì máa ń jẹ́ kára tu èmi náà.” Janet tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé kéèyàn má ṣe ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, èyí ti mú kí àníyàn rẹ̀ dínkù.b—Òwe 18:1.

      Ọlọ́run ni “baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti onídàájọ́ fún àwọn opó.”—Sáàmù 68:5

      Janet sọ pé: “Ohun tó ń tù mí nínú jù ni mímọ̀ tí mo mọ̀ pé Ọlọ́run ni ‘Baba àwọn ọmọ aláìníbaba àti onídàájọ́ fún àwọn opó.’ Kò sì ní pa wá tì láé bí ọkọ mi ṣe pa wá tì.” (Sáàmù 68:5) Janet mọ̀ pé Ọlọ́run kì í fi “ibi” tàbí nǹkan burúkú dán wa wò. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ìwà ọ̀làwọ́” Ọlọ́run pọ̀ gan-an débi pé ó máa ń fún gbogbo àwọn èèyàn ní ọgbọ́n àti “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” ká lè fi kojú àwọn àníyàn wa.—Jákọ́bù 1:5, 13; 2 Kọ́ríńtì 4:7.

      Àmọ́ tá a bá ń ṣàníyàn torí pé ẹ̀mí wa wà nínú ewu ńkọ́?

      a Wo 1 Kọ́ríńtì 10:13; Hébérù 4:16.

      b Fún ìsọfúnni síwájú sí nípa béèyàn ṣe lè borí àníyàn, wo kókó iwájú ìwé nínú Jí! September–October 2015, “Ǹjẹ́ O Lè Pinnu Bí Ìgbésí Ayé Rẹ Ṣe Máa Rí?” Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo.

  • Àníyàn Nípa Ewu
    Ilé Ìṣọ́—2015 | July 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ BORÍ ÀNÍYÀN

      Àníyàn Nípa Ewu

      Obìnrin kan tó ń jẹ́ Alona sọ pé: “Nígbà tí bọ́ǹbù fẹ́ dún, wọ́n tẹ aago ìkìlọ̀, bí mo ṣe gbóhùn aago yìí, àyà mi já pà, ni mo bá sá lọ sí ilé kan tí wọ́n kọ́ fún ààbò nígbà tí wọ́n bá ju bọ́ǹbù. Síbẹ̀ náà, ọkàn mi ò balẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà tún wá burú sí i nígbà tí mo wà níta, tí mi ò sì ríbi sá sí. Lọ́jọ́ kan tí mò ń rìn lọ ládùúgbò, mo kan bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, débi pé mi ò lè mí mọ́. Ó pẹ́ díẹ̀ kí ara mi tó wálẹ̀. Ni aago ìkìlọ̀ náà bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í dún.”

      Alona ń ṣàníyàn nípa bọ́ǹbù tó máa ń bú gbàù

      Alona

      Kì í ṣe ogun nìkan ló máa ń fa ewu. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá gbọ́ pé o ní àrùn tó lè gba ẹ̀mí ẹni tàbí pé ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ ní irú àìsàn bẹ́ẹ̀, ó lè kó ẹ lọ́kàn sókè. Ìbẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú sì máa ń fa àníyàn fún àwọn míì. Wọ́n lè máa ronú pé ṣé inú ayé tó kún fún ogun, ìwà ọ̀daràn, ìbàyíkájẹ́, ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà àti àjàkálẹ̀ àrùn làwọn ọmọ wa àtàwọn ọmọ ọmọ wa máa dàgbà sí? Báwo la ṣe lè kápá irú àníyàn bẹ́ẹ̀?

      Torí a mọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ aburú máa ń ṣẹlẹ̀, ó yẹ ká jẹ́ “afọgbọ́nhùwà tí ó ti rí ìyọnu àjálù [tí ó sì] fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 27:12) Bí a ṣe ń sapá kí ìlera wa lè dára, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ọpọlọ wa jí pépé kí ìrònú wa sì já gaara. Àwọn eré ìnàjú oníwà ipá àti ìròyìn tá à ń gbọ́ máa ń gbé àwòrán tó ń bani lẹ́rù síni lọ́kàn, èyí sì máa ń dá kún àníyàn tí à ń ṣe nípa ara wa àti àwọn ọmọ wa. Àmọ́, a ò wá ní torí pé a ò fẹ́ rí àwọn nǹkan yìí ká wá jókòó pa sílé. Ọlọ́run kò dá wa lọ́nà tó fi jẹ́ pé ohun tó ń báni lọ́kàn jẹ́ nìkan la ó máa rò ṣáá. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, . . . tí ó jẹ́ òdodo, . . . tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, . . . tí ó dára ní fífẹ́, ló yẹ ká fi kún ọkàn wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ “Ọlọ́run àlàáfíà” yóò fi ìbàlẹ̀ ọkàn jíǹkí wa.—Fílípì 4:8, 9.

      ÌDÍ TÍ ÀDÚRÀ FI ṢE PÀTÀKÌ

      Tá a bá ní ìgbàgbọ́ tó dúró digbí, ó máa jẹ́ ká lè borí àníyàn. Bíbélì gbà wá níyànjú pé “kí ẹ sì wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ yín lọ́kàn.” (1 Pétérù 4:7) A lè bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ọgbọ́n àti ìgboyà tó máa jẹ́ ká lè borí ìṣòro wa, ó sì dá wa lójú pé “ó ń gbọ́ tiwa nípa ohun yòówù tí a ń béèrè.”—1 Jòhánù 5:15.

      Avi àti Alona ń gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run

      Alona àti Avi, ọkọ rẹ̀

      Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì ni “olùṣàkóso ayé yìí” kì í ṣe Ọlọ́run, àti pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Jòhánù 12:31; 1 Jòhánù 5:19) Abájọ tí Jésù fi kọ́ wa láti máa gbàdúrà pé: “Dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (Mátíù 6:13) Alona sọ pé: “Nígbàkigbà tí aago ìkìlọ̀ bá dún, ńṣe ni mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n má ṣe kó ọkàn sókè jù. Bákan náà, ọkọ mi máa ń pè mí lórí fóònù, á sì gbàdúrà pẹ̀lú mi. Àdúrà máa ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an.” Ńṣe ló bá ohun tí Bíbélì sọ mu gẹ́lẹ́ pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́.”—Sáàmù 145:18.

      ÌRÈTÍ WÀ PÉ NǸKAN ṢÌ Ń BỌ̀ WÁ DÁA

      Nígbà tí Jésù ń wàásù lórí òkè, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” (Mátíù 6:10) Ìjọba Ọlọ́run máa mú gbogbo ohun tó ń fa àníyàn kúrò títí láé. Ọlọ́run máa lo Jésù “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” láti mú “kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 9:6; Sáàmù 46:9) Ọlọ́run “yóò ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn . . . Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́. . . . Kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” (Míkà 4:3, 4) Àwọn ìdílé aláyọ̀ “yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.” (Aísáyà 65:21) “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

      Lóde òní, kò sí bá a ṣe lè ṣọ́ra ṣe tó, a ò lè dáwọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ aburú dúró, èèyàn sì lè rin àrìnfẹsẹ̀sí tàbí kó ṣe kòńgẹ́ aburú nígbà míì. (Oníwàásù 9:11) Ogun, ìwà jàgídíjàgan àti àrùn ṣì ń pa àwọn èèyàn, bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ǹjẹ́ ìrètí wà fún irú àwọn tó ti bá àjálù bẹ́ẹ̀ lọ?

      Àìmọye mílíọ̀nù èèyàn máa tún pa dà jíǹde. Ní báyìí, ńṣe ni wọ́n ń sùn. Jèhófà kò sì ní gbàgbé wọn. Lọ́jọ́ kan “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò . . . jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde, ó jẹ́ kó dá wa lójú pé: “Ìrètí yìí ni àwa ní gẹ́gẹ́ bí ìdákọ̀ró fún ọkàn, ó dájú, ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in.” (Hébérù 6:19) Ọlọ́run sì ti “pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà fún gbogbo ènìyàn ní ti pé ó ti jí [Jésù] dìde kúrò nínú òkú.”—Ìṣe 17:31.

      Àmọ́ ní àkókò yìí, àwọn tó ń sapá láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ pàápàá máa ń ṣe àníyàn. Paul, Janet, àti Alona tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí kò kọ́kàn sókè mọ́, torí pé wọ́n ṣe ohun tó fọgbọ́n hàn, wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run nínú àdúrà, wọ́n sì gbọ́kàn lé àwọn ìlérí Bíbélì nípa ọjọ́ ọ̀la. Àdúrà wa ni pé, “kí Ọlọ́run tí ń fúnni ní ìrètí fi ìdùnnú àti àlàáfíà gbogbo kún inú yín nípa gbígbàgbọ́ yín,” gẹ́gẹ́ bó ti ṣe fún àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí.—Róòmù 15:13.

      Lọ Rí Dókítà Rẹ!

      Tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ṣì ń ṣàníyàn lẹ́yìn tó o ti ṣe àwọn ohun tó lè dín àníyàn kù, ó máa dáa kó o lọ rí Dókítà rẹ. Bí àníyàn téèyàn ń ṣe lórí ìṣòro kan bá ti wá pọ̀ ju ìṣòro náà lọ, ìyẹn lè jẹ́ àmì pé ẹni náà ti ní àìsàn kan. Fún ìdí yìí, tó o bá lọ rí dókítà, ó lè ṣe àyẹ̀wò rẹ. Torí pé, nígbà míì, àìlera kan tí kò hàn síta máa ń fa àníyàn. Dókítà náà á sì fún ẹ ní ìtọ́jú tó yẹ.a

      a Ìwé ìròyìn yìí kò sọ pé irú ìtọ́jú báyìí ló yẹ kí èèyàn gbà. Àwọn tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìtọ́jú tí wọ́n ń gbà kò tako ìlànà Bíbélì. O tún lè ka àpilẹ̀kọ tó ṣàlàyé nípa bá a ṣe lè ran àwọn tó ń ṣe àníyàn lọ́wọ́, ìyẹn “How to Help Those With Anxiety Disorders” nínú Jí! March 2012, lédè Gẹ̀ẹ́sì. O sì tún lè rí i kà lórí ìkànnì www.jw.org.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́