ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìtàn Tó Ṣe Pàtàkì
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 4
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ ỌLỌ́RUN ṢE PA​—BÍBÉLÌ MỌ́

      Ìtàn Tó Ṣe Pàtàkì

      Ọkùnrin kan mú Bíbélì dání, ó sì ń wò ó pẹ̀lú ìyàlẹ́nu

      Bíbélì dá yàtọ̀ nínú àwọn ìwé ìsìn tó wà láyé. Ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọlọ́run. Bákan náà, kò tíì sí ìwé míì táwọn èèyàn tọ pinpin, tí wọ́n sì ṣàríwísí rẹ̀ bíi Bíbélì.

      Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀mọ̀wé kan ń ṣiyè méjì pé bóyá ni Bíbélì tá a ní báyìí bá èyí tí wọ́n kọ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mu. Onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìsìn kan tiẹ̀ sọ pé: “Kò dá wa lójú pé ohun tó wà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà ló wà nínú Bíbélì tòde òní. Ọ̀pọ̀ àṣìṣe tá a fọwọ́ bò mọ́lẹ̀ ló kún inú rẹ̀. Ọ̀pọ̀ Bíbélì ló sì jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n kọ ọ́, ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló sì wà láàárín wọn.”

      Torí ìsìn táwọn míì ń ṣe, wọ́n gbà pé kì í ṣe òótọ́ lóhun tó wà nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Faizal. Àwọn òbí rẹ̀ tí kì í ṣe Kristẹni kọ́ ọ pé, ìwé mímọ́ ni Bíbélì, àmọ́ wọ́n ti yí ohun tó wà nínú rẹ̀ pa dà. Ó sọ pé: “Fún ìdí yìí, ara mí kì í balẹ̀ tí ẹnì kan bá fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Ó ṣe tán, kì í ṣe ojúlówó Bíbélì ni wọ́n ń gbé kiri. Wọ́n ti yí i pa dà!”

      Tó bá jẹ́ pé Bíbélì ti yàtọ̀ sí ti ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣé a ṣì lè tẹ̀ lé ohun tó bá sọ? Ó dáa, ronú nípa àwọn ìbéèrè yìí ná: Ṣé o lè fọkàn tán àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa ọjọ́ iwájú tí kò bá dá ẹ lójú pé àwọn ìlérí yẹn wà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀? (Róòmù 15:4) Ṣé wàá tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu nípa iṣẹ́, ìdílé, tàbí ẹ̀sìn tó bá jẹ́ pé ayédèrú ni Bíbélì tá à ń gbé kiri báyìí?

      Òótọ́ ni pé kò sí Bíbélì tí wọ́n kọ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mọ́, síbẹ̀ a ṣì lè rí àwọn míì tí wọ́n dà kọ látìgbà láéláé, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ míì tí wọ́n fọwọ́ kọ. Kí ló fà á tí àwọn ìwé àfọwọ́kọ yẹn kò fi bà jẹ́, tí àwọn alátakò kò fi pa á run, tí kò sì ṣeé ṣe láti yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà? Báwo sì ni bí Bíbélì ṣe wà títí dòní ṣe lè mú kó dá ẹ lójú pé òótọ́ lohun tó wà nínú rẹ̀? Wàá rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú apá tó kàn nínú ìtàn bí Ọlọ́run ṣe pa Bíbélì mọ́ títí di àkókò yìí.

  • Ohun Tí Kò Jẹ́ Kí Bíbélì Pa Run
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 4
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ ỌLỌ́RUN ṢE PA​—BÍBÉLÌ MỌ́

      Ohun Tí Kò Jẹ́ Kí Bíbélì Pa Run

      OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: Òrépèté àti awọ ni àwọn tó kọ Bíbélì àtàwọn adàwékọ máa ń lò láyé àtijọ́ láti fi kọ̀wé.a (2 Tímótì 4:13) Báwo làwọn ohun èlò yìí ṣe mú kó ṣòro fún Bíbélì láti wà pẹ́ títí?

      Òrépèté máa ń tètè fàya, ó máa ń yi àwọ̀ pa dà, kì í sì í pẹ́ gbó. Richard Parkinson àti Stephen Quirke tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa ilẹ̀ Íjíbítì àtijọ́ sọ pé: “Kì í pẹ́ kí àwọn ohun èlò ìkọ̀wé yìí tó gbó, táá sì bẹ̀rẹ̀ sí í rún. Tí wọ́n bá fi pa mọ́, bóyá tí wọ́n tọ́jú rẹ̀ sábẹ́ ilẹ̀, ooru máa mú kó jẹra, eku, kòkòrò tàbí àwọn eèrà sì lè jẹ ẹ́ bà jẹ́.” Lẹ́yìn tí wọ́n rí àwọn ìwé òrépèté kan, kò pẹ́ tí wọ́n fi bà jẹ́, torí pé ooru tàbí ọ̀rinrin pọ̀ níbi tí wọ́n kó wọn sí.

      Ìwé awọ ní tiẹ̀ lágbára díẹ̀ ju òrépèté lọ, àmọ́ òun náà máa ń bà jẹ́ téèyàn ò bá bójú tó o dáadáa, bóyá tí wọ́n kó o síbi tí ooru ti mú un tàbí tí ọ̀rinrin tàbí ìmọ́lẹ̀ wà.b Kòkòrò máa ń jẹ ìwé awọ náà. Ìdí nìyí tí ìwé Everyday Writing in the Graeco-Roman East, fi sọ pé “àwọn ìwé àtijọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ pẹ́ lọ títí.” Ká ní Bíbélì náà ti gbó bà jẹ́, àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ náà á ti bà jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.

      OHUN TÓ JẸ́ KÍ BÍBÉLÌ WÀ DÒNÍ: Òfin àwọn Júù pa á láṣẹ fún gbogbo ọba pé “kí ó kọ ẹ̀dà òfin yìí sínú ìwé kan fún ara rẹ̀,” ìyẹn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì. (Diutarónómì 17:18) Láfikún sí i, àwọn adàwékọ ṣe àdàkọ ọ̀pọ̀ ìwé Bíbélì débi pé, nígbà tó fi máa dí ìgbà ayé Jésù, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí sínágọ́gù kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì àti làwọn ibi tó jìnnà gan-an bíi Makedóníà téèyàn ò ti ní rí Ìwé Mímọ́! (Lúùkù 4:16, 17; Ìṣe 17:11) Báwo ni àwọn ìwé àfọwọ́kọ yẹn ṣe wá wà títí dòní?

      1. Ìkòkò kan; 2. Àjákù Ìwé Òkun Òkú

      Wọ́n rí ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n pè ní Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, nínú ìkòkò tí wọ́n tọ́jú sí ibi tó gbẹ nínú ihò àpáta, ó sì ti wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún

      Ihò àpáta níbi tí wọ́n ti rí àwọn Bíbélì àfọwọ́kọ

      Philip W. Comfort tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Májẹ̀mú Tuntun sọ pé: “Àwọn Júù máa ń tọ́jú àwọn àkájọ Ìwé Mímọ́ sínú ìkòkò kó má báa tètè bà jẹ́. Ohun tí àwọn Kristẹni náà sì máa ń ṣe nìyẹn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé inú ìkòkò, ibi tó ṣókùnkùn tàbí inú ihò àpáta ni wọ́n ti rí ọ̀pọ̀ Bíbélì àfọwọ́kọ ayé ìgbàanì. Ó sì máa ń jẹ́ ibi tó gbẹ dáadáa.

      ÀBÁJÁDE RẸ̀: Ẹgbẹẹgbẹ̀rún apá kan Bíbélì àfọwọ́kọ, tó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún ló ṣì wà títí dòní. Kò tún sí ìwé àfọwọ́kọ míì tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tó sì ti pẹ́ láyé tó bẹ́ẹ̀.

      a Irúgbìn òrépèté ni wọ́n fi ń ṣe ohun èlò ìkọ̀wé tí wọ́n ń pè ní òrépèté. Awọ ẹran ni wọ́n fi ń ṣe ohun èlò ìkọ̀wé tó jẹ́ awọ.

      b Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gba òmìnira, ìwé awọ ni wọ́n fi kọ ìkéde òmìnira tí wọ́n fi òǹtẹ̀ ìjọba lù. Ní báyìí èèyàn fẹ́rẹ̀ẹ́ má rí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kà mọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò tíì pé ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ [250] ọdún tí wọ́n ṣe ìwé náà.

  • Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Alátakò
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 4
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ ỌLỌ́RUN ṢE PA​—BÍBÉLÌ MỌ́

      Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Alátakò

      OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: Ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti lo agbára wọn láti má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn ní Bíbélì tiwọn, kí wọ́n tẹ̀ é jáde, tàbí kí wọ́n sì tú u sí èdè míì. Wo àpẹẹrẹ méjì yìí:

      • Nǹkan Bí Ọdún 167 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni: Ọba Seleucid Antiochus Epiphanes, gbìyànjú láti mú kí àwọn Júù máa ṣe ẹ̀sìn àwọn Gíríìkì, torí náà ó pàṣẹ pé kí wọ́n ba gbogbo Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù jẹ́. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Heinrich Graetz kọ̀wé pé, àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ máa ń “fa gbogbo ìwé Òfin tí wọ́n bá ti rí ya, wọ́n á sì dáná sun ún. Wọ́n sì tún máa ń pa ẹni tí wọ́n bá rí i pé ó gbádùn láti máa ka Bíbélì láti fún ara rẹ̀ lókun àti ìtùnú.”

      • Àkókò Ọ̀làjú: Àwọn kan lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kátólíìkì máa ń bínú pé àwọn ọmọ ìjọ ń kọ́ni ní ohun tí Bíbélì sọ dípò ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì. Ojú burúkú ni wọ́n fi ń wo ọmọ ìjọ tó bá ní àwọn ìwé Bíbélì míì yàtọ̀ sí Sáàmù ní èdè Látìn. Ìgbìmọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì kan tiẹ̀ pàṣẹ pé kí àwọn ọkùnrin kan lọ máa tú ilé àwọn èèyàn tí wọ́n fura sí pé ó ní Bíbélì. Ńṣe ni wọ́n máa ń ba ilé tí wọ́n bá ti rí Bíbélì jẹ́.

      Ká sọ pé àwọn tó ń tako Bíbélì ti ṣàṣeyọrí láti pa á run, àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ náà ì bá ti pa run.

      Ojú ìwé kan lára Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì tí William Tyndale túmọ̀

      Wọ́n fòfin de Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì tí William Tyndale túmọ̀, wọ́n dáná sun ún, wọ́n sì pa Tyndale fúnra rẹ̀ lọ́dún 1536, síbẹ̀ Bíbélì náà kò pa run

      OHUN TÓ JẸ́ KÍ BÍBÉLÌ WÀ DÒNÍ: Ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni Ọba Antiochus dojú ìjà kọ, àmọ́ àwọn Júù ti fọ́n ká sí àwọn ilẹ̀ míì káàkiri. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tiẹ̀ sọ pé nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù tó ń gbé nílẹ̀ òkèèrè ti pọ̀ gan-an ju àwọn tó ń gbé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lọ. Àwọn Júù wọ̀nyẹn máa ń tọ́jú Ìwé Mímọ́ sínú àwọn sínágọ́gù wọn. Àwọn Ìwé Mímọ́ tí wọ́n tọ́jú yìí ni àwọn ìran tó tẹ̀ lẹ́ wọn lò, tó fi mọ́ àwọn Kristẹni.—Ìṣe 15:21.

      Láàárín Àkókò Ọ̀làjú, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Bíbélì fara da ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n, kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì kí wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde. Ní àárín ọdún 1500, àwọn apá kan lára Bíbélì wà ní èdè mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33], bẹ́ẹ̀ wọn ò tíì ṣe ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ayára-bí-àṣá nígbà yẹn! Àmọ́ lẹ́yìn àkókò náà, iṣẹ́ títúmọ̀ Bíbélì àti títẹ̀ ẹ́ jáde wá túbọ̀ yára kánkán.

      ÀBÁJÁDE RẸ̀: Àwọn ọba aláṣẹ àtàwọn aṣáájú ìsìn ti gbéjà ko Bíbélì, síbẹ̀ nínú gbogbo ìwé tó wà láyé, Bíbélì nìkan làwọn èèyàn ní nílé-lóko, tó sì tún wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè. Ó ti ran àwọn orílẹ̀-èdè kan lọ́wọ́ nínú òfin àti èdè wọn, ó sì ti mú kí ìgbésí ayé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn dára sí i.

  • Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Tó Fẹ́ Yí Ọ̀rọ̀ Inú Rẹ̀ Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 4
    • Ẹnì kan tó ń ṣe àdàkọ Bíbélì

      Àwọn Másórétì fara balẹ̀ ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ ỌLỌ́RUN ṢE PA​—BÍBÉLÌ MỌ́

      Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Tó Fẹ́ Yí Ọ̀rọ̀ Inú Rẹ̀ Pa Dà

      OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO: A ti sọ̀rọ̀ nípa ohun méjì tó lè mú ká má mọ ohun tó ń jẹ́ Bíbélì rárá, àkọ́kọ́ ni bí ohun tí wọ́n kọ ọ́ sí ṣe lè tètè jẹrà àti báwọn kan ṣe fẹ́ rẹ́yìn Bíbélì. Àmọ́ kò tán síbẹ̀, àwọn adàwékọ àtàwọn atúmọ̀ èdè náà ti gbìyànjú láti yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà. Nígbà míì, wọ́n máa ń fẹ́ yí ọ̀rọ̀ Bíbélì pa dà kó lè bá ẹ̀kọ́ tiwọn mu, dípò ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan:

      • Ilé ìjọsìn: Láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin àti ìkejì Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn tó kọ Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ ti Àwọn Ará Samáríà fi gbólóhùn yìí sí ìparí Ẹ́kísódù 20:17, pé “ní Aargaareezem. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò kọ pẹpẹ sí.” Àwọn ará Samáríà tipa bẹ́ẹ̀ gbà pé èyí máa mú kí Ìwé Mímọ́ ṣètìlẹ́yìn fún bí àwọn ṣe ń kọ́ tẹ́ńpìlì sí “Aargaareezem,” tàbí Òkè Gérísímù.

      • Ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan: Ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n parí kíkọ Bíbélì, ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan kan fi ọ̀rọ̀ yìí kún 1 Jòhánù 5:7, “ní ọ̀run, Baba, Ọ̀rọ̀, àti Ẹ̀mí Mímọ́: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí jẹ́ ọ̀kan.” Gbólóhùn yìí kò sí nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Onímọ̀ nípa Bíbélì kan tó ń jẹ́ Bruce Metzger sọ pé: “Láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ni ọ̀rọ̀ yìí ti ń fara hàn lemọ́lemọ́ nínú ìwé àfọwọ́kọ àwọn Látìn Àtijọ́ àti ti Vulgate lédè Látìn.”

      • Orúkọ Ọlọ́run: Ọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì pinnu láti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Ìwé Mímọ́. Ìdí sì ni pé wọ́n fara mọ́ àṣà kan táwọn Júù ń dá. Torí náà, wọ́n yọ orúkọ tí Ẹlẹ́dàá ń jẹ́ gangan kúrò, wọ́n sì fi orúkọ oyè rọ́pò rẹ̀, ìyẹn “Ọlọ́run” tàbí “Olúwa.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kì í ṣe Ẹlẹ́dàá nìkan ni Bíbélì pè ní orúkọ yẹn, àwọn ibì kan wà tí Bíbélì ti pe àwọn èèyàn, òrìṣà àti Èṣù ní “ọlọ́run.”—Jòhánù 10:34, 35; 1 Kọ́ríńtì 8:5, 6; 2 Kọ́ríńtì 4:4.a

      OHUN TÓ JẸ́ KÍ BÍBÉLÌ WÀ DÒNÍ: Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn kan lára àwọn tó ṣe àdàkọ Bíbélì kò ka nǹkan sí, àwọn míì sì jẹ́ ẹlẹ̀tàn. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló jẹ́ ọ̀jáfáfá, tí wọ́n sì fara balẹ̀ ṣe àdàkọ Bíbélì. Àwọn Másórétì ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà sí ìkẹwàá Sànmánì Kristẹni. Àdàkọ tí wọ́n ṣè yìí la wá mọ̀ sí Ìwé Másórétì. Ìtàn fi hàn pé wọ́n máa ń fara balẹ̀ ka ẹyọ ọ̀rọ̀ àti lẹ́tà, kó lè dá wọn lójú pé kò sí àṣìṣe kankan. Tí wọ́n bá rí ohun kan tó dà bí àṣìṣe nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe àdàkọ, wọ́n á kọ ọ́ sí etí ìwé tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́. Àwọn Másórétì kò yí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pa dà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Moshe Goshen-Gottstein sọ pé “Ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jù lọ ni wọ́n kà á sí tẹ́nì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ yí ọ̀rọ̀ Bíbélì pa dà lọ́nàkọnà.”

      Ìkejì, bí àwọn ìwé àfọwọ́kọ ṣe wà lóríṣiríṣi lónìí ti jẹ́ kó rọrùn fún àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì láti rí ibi tí àṣìṣe wà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn fi ń kọ́ àwọn èèyàn pé Bíbélì èdè Látìn táwọn ń lò ni ojúlówó Bíbélì tó bá ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi fọ̀rọ̀ tiwọn kún 1 Jòhánù 5:7, bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Àṣìṣe yìí tún wọnú Bíbélì King James Version lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì tí wọ́n ṣàwárí fi hàn pé kò sí ọ̀rọ̀ yẹn nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bruce Metzger sọ pé: “Gbólóhùn tó wà [nínú 1 Jòhánù 5:7] yẹn kò sí nínú gbogbo àwọn ìwé àfọwọ́kọ ayé ìgbàanì míì tí wọ́n rí, àwọn ìwé àfọwọ́kọ bíi (Syriac, Coptic, Armenian, Ethiopic, Arabic, Slavonic), àyàfi nínú ti èdè Látìn nìkan.” Èyí ló mú kí wọ́n yọ gbólóhùn náà kúrò nínú Bíbélì King James Version tí wọ́n tún ṣe àtàwọn Bíbélì míì.

      Bíbélì àfọwọ́kọ Chester Beatty P46, ó ti wà láti ọgọ́rùn-⁠ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni

      Bíbélì àfọwọ́kọ Chester Beatty P46 tí wọ́n fi òrépèté kọ, ó ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni

      Ǹjẹ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ fi hàn pé ọ̀rọ̀ Bíbélì kò tíì yí pa dà? Nígbà tí wọ́n rí Àkájọ Ìwé Òkun Òkú lọ́dún 1947, àwọn ọ̀mọ̀wé fi ohun tó wà nínú ìwé Másórétì lédè Hébérù wéra pẹ̀lú èyí tó wà nínú àwọn àkájọ Bíbélì tí wọ́n ti kọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan ṣáájú ìgbà rẹ̀. Ẹnì kan lára àwùjọ tó ṣiṣẹ́ lórí Àkájọ Ìwé Òkun Òkú sọ pé àkájọ ìwé kan péré “fi ẹ̀rí hàn lọ́nà tó ṣe kedere pé àwọn adàwékọ náà kò figbá kan bọ̀kan nínú, wọ́n sì fara balẹ̀ ṣe iṣẹ́ náà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún kan tí wọ́n ti kọ̀ ọ́ kó tó di pé wọ́n ṣe àdàkọ rẹ̀.”

      Ilé ìkówèésí Chester Beatty nílùú Dublin, lórílẹ̀-èdè Ireland, pàtẹ àkójọ àwọn òrépèté tó fẹ́rẹ̀ẹ́ ní gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì nínú àtàwọn ìwé àfọwọ́kọ míì tó ti wà láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni, ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n parí kíkọ Bíbélì. Ìwé The Anchor Bible Dictionary ṣàlàyé pé: “Àwọn òrépèté yìí ti jẹ́ ká rí àwọn ìsọfúnni tó túbọ̀ ṣe kedere nípa ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ó sì tún ti jẹ́ kó ṣe kedere sí wa pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò yí pa dà.”

      “Òótọ́ pọ́ńbélé ni pé kò sí ìwé ayé ìgbàanì tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ péye bíi Bíbélì”

      ÀBÁJÁDE RẸ̀: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ wọ̀nyí ti pẹ́ tí wọ́n sì wà lóríṣiríṣi, síbẹ̀ ó ti mú kí ọ̀rọ̀ Bíbélì sunwọ̀n sí i. Sir Frederic Kenyon sọ nípa Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pé: “Kò sí ìwé ayé ìgbàanì kankan tó ní àwọn ẹ̀rí tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti fi ti ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lẹ́yìn. Àwọn ọ̀mọ̀wé tí kì í ṣe ẹlẹ́tanú sì gbà pé ohun tó wà nínú Bíbélì láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà ló ṣì wà nínú rẹ̀ di báyìí.” Ọ̀mọ̀wé William Henry Green sọ nípa Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù pé: “Òótọ́ pọ́ńbélé ni pé kò sí ìwé ayé ìgbàanì tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ péye bíi Bíbélì.”

      a Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, wo Àsomọ́ 1 nínú Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ó wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo.

  • Ìdí Tí Bíbélì Fi Wà Títí Dòní
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 4
    • Ọkùnrin kan ń ka Bíbélì

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ ỌLỌ́RUN ṢE PA​—BÍBÉLÌ MỌ́

      Ìdí Tí Bíbélì Fi Wà Títí Dòní

      Bíbélì kò mà pa run. Ìdí nìyẹn tó o fi lè ra Bíbélì kó o sì kà á. Tó bá tún wá jẹ́ èyí tí ìtúmọ̀ rẹ̀ péye lò ń kà, á jẹ́ pé ojúlówó Bíbélì tó ṣe é gbára lé bíi ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ lò ń kà yẹn.a Àmọ́ kí nìdí tí Bíbélì ṣì fi wà títí dòní láìka onírúurú ìṣòro tó ti là kọjá sí, irú bíi kó fúnra rẹ̀ bà jẹ́, àtakò gbígbóná táwọn kan ṣe àti bí àwọn kan ṣe gbìyànjú láti yí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ pa dà? Kí ló mú kí ìwé yìí ṣàrà ọ̀tọ̀?

      “Ó ti wá dá mi lójú pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì tí mo ní”

      Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló fara mọ́ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Wọ́n gbà pé ohun tó jẹ́ kí Bíbélì wà títí dòní ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àti pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló pa á mọ́ tí kò jẹ́ kó pa run. Faizal, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ìwé yìí pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra rẹ̀, kó lè mọ ohun tó wà nínú rẹ̀. Ohun tó sì rí yà á lẹ́nu. Kò pẹ́ tó fi rí i pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ èké tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni kò sí nínú Bíbélì rárá. Láfikún sí i, nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa tún ayé yìí ṣe láìpẹ́, ó wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an.

      Ó sọ pé: “Ó ti wá dá mi lójú pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì tí mo ní. Ó ṣe tán, tí Ọlọ́run bá lè dá ayé àti ọ̀run, ṣé kò wá ní lágbára láti fún wa ní ìwé kan, kó sì pa á mọ́ fún wa? Tá a bá ní èrò tó yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ pé à ń fojú kéré agbára Ọlọ́run tó jẹ́ Olódùmarè nìyẹn! Ta wá lèmi tí màá fi fojú kéré agbára Ọlọ́run?”—Aísáyà 40:8.

      a Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Lọ́nà Tó Dára?” nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2008.

      Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé òótọ́ ni Bíbélì ń sọ?

      Àwọn àpilẹ̀kọ yìí tí jẹ́ ká rí ohun tí kò jẹ́ kí Bíbélì pa run. Àmọ́, báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ni Bíbélì lóòótọ́, pé kì í ṣe àkójọ àwọn ìtàn àròsọ kan lásán? (1 Tẹsalóníkà 2:13) Wo fídíò náà Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì? ní ìkànnì www.jw.org/yo. (Tẹ bọ́tìnì Wá A, lẹ́yìn náà tẹ àkòrí fídíò náà)

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́