ORIN 70
Ẹ Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Kristi kọ́ wa bá a ṣe máa fòótọ́ kọ́ni
Àti bí a ó ṣe máa wàásù.
Ó sọ pé: ‘Ẹ wá àwọn ẹni yíyẹ
Tó ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́ òótọ́.
Tẹ́ ẹ bá délé kan, kí ẹ kọ́kọ́ kí wọn,
Kí ẹ bá wọn sọ̀rọ̀ àlàáfíà.
Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá sọ pé àwọn ò gbọ́,
Ẹ kúrò, ẹ lọ síbòmíràn.’
2. Ẹ bá àwọn tó tẹ́wọ́ gbà yín sọ́rọ̀;
Ẹ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Wọ́n máa gbọ́ torí pé wọ́n lọ́kàn tó dáa.
Láìpẹ́, àwọn náà yóò wá sin Jáà.
Má ṣe dààmú torí ohun tó o máa sọ;
Jèhófà yóò fi sí ọ lẹ́nu.
Tó o bá ń sọ̀rọ̀ tó dáa, tó ń tuni lára,
Yóò mú kí onírẹ̀lẹ̀ fẹ́ gbọ́.
(Tún wo Ìṣe 13:48; 16:14; Kól. 4:6.)